Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

KÍ LÓ mú kí ọkùnrin kan tún pa dà sínú ẹ̀sìn tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, èyí tó ti fi sílẹ̀ tẹ́lẹ̀? Báwo ni ọkùnrin kan tó ti ń wá ẹni tó máa fi ṣe bàbá ṣe dẹni tó fi Jèhófà ṣe bàbá? Gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.

“Mo ní láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.”—ELIE KAHLIL

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1976

ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: KÍPÍRỌ́SÌ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌ ONÍNÀÁKÚNÀÁ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Orílẹ̀-èdè Kípírọ́sì ni wọ́n ti bí mi àmọ́ ilẹ̀ Ọsirélíà ni mo gbé dàgbà. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn òbí mi, wọ́n sì sapá gidigidi láti gbin ìfẹ́ Jèhófà àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí mi lọ́kàn. Láàárín ìgbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, mo ya aláìgbọràn. Màá yọ̀ jáde nílé lálẹ́ láti lọ bá àwọn ọ̀dọ́mọdé míì kẹ́gbẹ́. A máa ń jí mọ́tò, a sì máa ń kó ara wa sí oríṣiríṣi ìjàngbọ̀n.

Ṣe ni mo kọ́kọ́ ń yọ́lẹ̀ ṣe nǹkan wọ̀nyẹn torí mi ò fẹ́ mú àwọn òbí mi bínú. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ẹ̀rù ò tiẹ̀ bà mí mọ́. Àwọn tó dàgbà jù mí lọ, tí wọn kò fẹ́ràn Jèhófà ni mo ń bá kẹ́gbẹ́, wọ́n sì kó ìwàkiwà ràn mí. Níkẹyìn mo sọ fún àwọn òbí mi pé mi ò ṣe ẹ̀sìn wọn mọ́. Wọ́n fi sùúrù ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ràn mí lọ́wọ́, ṣùgbọ́n mo kọ̀ jálẹ̀. Èyí ba àwọn òbí mi lọ́kàn jẹ́ gan-an.

Lẹ́yìn ti mo kúrò nílé, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo onírúurú oògùn olóró, mo tiẹ̀ ń gbin igbó púpọ̀ rẹpẹtẹ, mo sì ń tà á. Mo ya oníṣekúṣe, mi kì í sì í wọ́n lágbo àríyá tí wọ́n máa ń ṣe mọ́jú. Mo tún wá di onínúfùfù èèyàn. Tí àwọn èèyàn bá sọ ohun kan tàbí wọ́n hùwà kan tí mi ò fẹ́, kíá ni màá ti gbaná jẹ, tí màá pariwo mọ́ wọn tí màá sì lù wọ́n nígbà míì. Láìfọ̀rọ̀ gùn, gbogbo ohun tí wọ́n kọ́ mi nílé pé kò yẹ Kristẹni ni mò ń ṣe.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Mo di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn pẹ̀lú ọmọkùnrin kan tóun náà ń lo oògùn olóró, àmọ́ tó jẹ́ pé bàbá rẹ̀ kú nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé. A sábà jọ máa ń sọ̀rọ̀ títí wọ ààjìn òru. Nígbà míì, ní àwọn alẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa ń sọ bí òun ṣe ń ṣàárò bàbá òun. Níwọ̀n bí mo ti mọ̀ nípa ìrètí àjíǹde láti kékeré, máa kàn rí i pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un nípa Jésù ni, pé ó jí àwọn òkú dìde, àti pé ó ṣe ìlérí pé òun yóò tún jí àwọn òkú dìde lọ́jọ́ iwájú. (Jòhánù 5:28, 29) Màá bí i pé: “Ǹjẹ́ inú rẹ kò ní dùn tó o bá tún lè pa dà rí bàbá rẹ? Gbogbo wa la lè dẹni tó wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.” Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn máa ń múnú ọ̀rẹ́ mi dùn gan-an ni.

Nígbà míì, ọ̀rẹ́ mi máa ń dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀ nípa àwọn nǹkan bí ọjọ́ ìkẹyìn tàbí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan. Màá gba Bíbélì rẹ̀, màá sì fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣàlàyé òtítọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run, Jésù àti ọjọ́ ìkẹyìn hàn án nínú rẹ̀. (Jòhánù 14:28; 2 Tímótì 3:1-5) Mo wá rí i pé bí mo ṣe ń bá ọ̀rẹ́ mi sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà tó, ni èmi náà ṣe túbọ̀ ń ronú nípa Jèhófà.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, irúgbìn òtítọ́ látinú Bíbélì, tí àwọn òbí mi sapá gan-an láti gbìn sí mi lọ́kàn tipẹ́tipẹ́, àmọ́ tí kò hù, wá bẹ̀rẹ̀ sí í hù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà míì tí mo bá wà ní òde àríyá tí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi jọ ń lo oògùn olóró, màá kàn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi ló máa ń sọ pé àwọn fẹ́ràn Ọlọ́run, àmọ́ ìwà tí kò dáa ni wọ́n ń hù. Èmi ò fẹ́ dà bíi tiwọn, ìyẹn sì jẹ́ kí n rántí ohun tó yẹ kí n ṣe. Ìyẹn ni pé mo ní láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.

Àmọ́ ṣá o, ọ̀tọ̀ ni kéèyàn mọ ohun tó yẹ láti ṣe, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn ṣe nǹkan ọ̀hún. Àwọn àyípadà kan rọrùn fún mi láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kò ṣòro fún mi láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró. Mo tún jáwọ́ nínú kíkó ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́, alàgbà kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ṣùgbọ́n, àwọn ìwà kan ò rọrùn fún mi rárá láti yí pa dà. Ara rẹ̀ ni pé ó ṣòro fún mi gan-an láti borí ìbínú mi. Nígbà míì, màá ti máa ṣe dáadáa o, àmọ́ tó bá yá màá kàn tún bára mi nínú ìwà tí mi ò fẹ́ yìí. Inú mi á tún bà jẹ́ gan-an, màá máa rò ó pé mi ò lè yí pa dà mọ́. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi, mo wá lọ bá alàgbà tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Alàgbà yẹn jẹ́ onísùúrù àti onínúure èèyàn, ó sì máa ń fún mi ní ìṣírí gan-an. Nígbà kan, ó ṣí àpilẹ̀kọ kan fún mi nínú Ilé Ìṣọ́, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó kéèyàn má ṣe juwọ́ sílẹ̀, ó ní kí n kà á mo sì kà á. * A tún jọ jíròrò àwọn ohun tí mo lè ṣe tínú bá ń bí mi. Lọ́lá àdúrà sí Jèhófà àti bí mo ṣe fi ohun tí mo kà nínú àpilẹ̀kọ yẹn sọ́kàn, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo borí ìṣòro ìbínú mi. Níkẹyìn, ní oṣù April ọdún 2000, mo ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ wò ó, inú àwọn òbí mi dùn gan-an ni.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ní báyìí, mo ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ bí mo ṣe mọ̀ pé mi ò fi oògùn olóró àti ìṣekúṣe sọ ara mi di ẹlẹ́gbin mọ́. Nínú gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe, yálà mo ń ṣiṣẹ́ ni o, mo wà ní ìpàdé Kristẹni ni o tàbí mo ń ṣeré, mo rí i pé mo máa ń láyọ̀ gan-an. Mo ni èrò tó dáa lọ́kàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé àwọn òbí mi kò pa mí tì àti pé gbogbo ìsapá wọn kò já sí asán. Mo tún máa ń rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 6:44 pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” Mo máa ń rò ó lọ́kàn pé, ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà tó fà mí pa dà, ǹ bá má lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.

“Mò ń wá ẹni tí máa fi ṣe bàbá.”—MARCO ANTONIO ALVAREZ SOTO

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1977

ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: CHILE

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: OLÓRIN RỌ́Ọ̀KÌ ONÍLÙ DÍDÚN KÍKANKÍKAN TÀWỌN ÌPÁǸLE

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìyá mi ló tọ́ mi dàgbà ní ìlú Punta Arenas, tó jẹ́ ìlú dáadáa kan tó wà ní àgbègbè tó ń jẹ́ Strait of Magellan, ní ìpẹ̀kun gúúsù Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Ọmọ ọdún márùn-ún ni mo wà nígbà tí àwọn òbí mi pìn yá, èyí sì máa ń jẹ́ kí n wo ara mi bí ẹni tí wọ́n pa tì. Mo wá ń wá ẹni tí màá fi ṣe bàbá.

Ìyá mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì máa ń mú mi lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́ mo kórìíra àwọn ìpàdé yẹn, mo sì sábà máa ń bínú tí màá sì máa sunkún tá a bá ti ń lọ. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́tàlá mi ò lọ sí ìpàdé yẹn mọ́.

Nígbà yẹn, mo fẹ́ràn orin gan-an, mo sì rí i pé mo lẹ́bùn orin púpọ̀. Nígbà tí mo fi máa di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo ti di ara òṣèré olórin rọ́ọ̀kì onílù dídún kíkankíkan àti ti orin rọ́ọ̀kì tàwọn ìpáǹle, èyí tí wọ́n ti máa ń fi àwòrán ẹhànnà àti oníwà ipá hàn. A máa ń lọ ṣeré níbi àríyá, ilé ọtí àti ní àwọn ibi àpèjẹ míì. Àwọn tó lẹ́bùn orin tí mò ń bá rìn jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ sí orin abágbàmu tí wọ́n máa ń kọ lẹ́sọ̀lẹsọ̀. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ní àgbègbè wa. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ogún ọdún, mo kó lọ sí ìlú Santiago tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè wa láti túbọ̀ lọ kọ́ ẹ̀kọ́ sí i níbẹ̀. Àmọ́ mo ṣì ń bá àwọn òṣèré olórin rọ́ọ̀kì onílù dídún kíkankíkan àti ti orin rọ́ọ̀kì tàwọn ìpáǹle, èyí tí wọ́n ti máa ń fi àwòrán ẹhànnà àti oníwà ipá hàn, ṣe eré.

Ní gbogbo ìgbà yẹn, ó sábà máa ń ṣe mí bíi pé ìgbésí ayé mi kò nítumọ̀. Kí n lè pa ìrònú rẹ́, mo máa ń mutí yó kẹ́ri, èmi àti àwọn òṣèré ẹlẹ́gbẹ́ mi kan tí mo mú bí ọmọ ìyá sì jọ máa ń lo oògùn olóró. Mo ya ọmọ ìta, ó sì hàn nínú ìrísí mi. Aṣọ dúdú ni mo máa ń wọ̀, mo dá irùngbọ̀n sí, mo sì fi irun orí mi sílẹ̀ títí tó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn dé ìgbáròkó mi.

Nítorí ìwà mi, àìmọye ìgbà ni mo máa ń jà tí màá sì kó sọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá. Lọ́jọ́ kan, lẹ́yìn tí mo ti mutí yó, mo gbéjà ko àwọn kan tó ń ta oògùn olóró torí pé wọ́n ń yọ èmi àti ọ̀rẹ́ mi lẹ́nu. Àwọn ọkùnrin yẹn nà mí ṣe léṣe débi pé wọ́n fọ́ párì ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi.

Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ló dọ́gbẹ́ sí mi lọ́kàn jù. Lọ́jọ́ kan, àṣírí tú sí mi lọ́wọ́ pé ọ̀rẹ́bìnrin mi àti ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi ti ń bára wọn ṣe ìṣekúṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún, tí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi kò sì jẹ́ kí n mọ̀. Inú mi bà jẹ́, ọkàn mi sì gbọgbẹ́.

Mo pa dà lọ sí Punta Arenas, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn ní iṣẹ́ orin, mo sì ń ṣe iṣẹ́ títa gìtá olóhùn ìsàlẹ̀. Mo ń bá a nìṣó láti máa ṣe eré orin rọ́ọ̀kì onílù dídún kíkankíkan àti ti rọ́ọ̀kì tàwọn ìpáǹle, mo sì ń ṣe àwo orin náà jáde. Mo wá pàdé ọmọbìnrin arẹwà kan tó ń jẹ́ Sussan, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pa pọ̀. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Sussan wá mọ̀ pé ìyá òun gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́, àmọ́ èmi ò gba ẹ̀kọ́ yẹn gbọ́. Ó wá bi mí pé: “Èwo ló wá jóòótọ́?” Mo sọ fún un pé mo mọ̀ pé irọ́ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan jẹ́, àmọ́ mi ò mọ bí màá ṣe fi Bíbélì ṣàlàyé rẹ̀. Àmọ́ mo mọ àwọn tó lè fi Bíbélì ṣàlàyé rẹ̀. Mo sọ fún un pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè fi òótọ́ ọ̀rọ̀ náà hàn án nínú Bíbélì. Mo wá ṣe ohun kan tí mi ò tíì ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́.

Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, mo pàdé ọkùnrin kan tó jọ pé mo mọ̀ rí, mo sì bi í bóyá Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrísí mi bà á lẹ́rù, ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dáhùn àwọn ìbéèrè mi nípa àwọn ìpàdé tí wọ́n ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó dá mi lójú pé àdúrà mi yẹn ló gbà tí mo fi bá a pàdé. Mo lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, àmọ́ ọwọ́ ẹ̀yìn pátápátá ni mo jókòó sí kí ẹnikẹ́ni má bàa dá mi mọ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló rántí ojú mi pé mò ń wà síbẹ̀ nígbà tí mo ṣì wà lọ́mọdé. Wọ́n fi ọ̀yàyà kí mi, wọ́n gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀ débi pé ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Ńṣe ló dà bíi pé mo pa dà wá sílé. Nígbà tí mo rí ọkùnrin tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà kékeré mi, mo sọ fún un pé kó tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Lọ́jọ́ kan, mo ka ìwé Òwe 27:11 tó sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀.” Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi pé èèyàn ẹlẹ́ran ara lásánlàsàn lè mú inú Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run dùn. Ìgbà yẹn ni mo wá rí i pé àṣé Jèhófà ni ẹni tí mo ti ń wá láti fi ṣe bàbá láti kékeré mi!

Mo fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú Baba mi ọ̀run dùn, kí n sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, àmọ́ mo ti sọ ara mi di ẹrú oògùn olóró àti ọtí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ìgbà yẹn ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá lóye ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:24 pé, “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì.” Bí mo ṣe ń gbìyànjú láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, mo rí i pé òótọ́ ni ìlànà tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:33 pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” Mo rí i pé àgùntàn tó bá ń bá ajá rìn yóò jẹ̀gbẹ́, èyí tó fi hàn pé mi ò ní lè jáwọ́ nínú àwọn ìwàkiwà mi bí mo bá ṣì ń lọ sí àwọn ibi tí mo ń lọ tẹ́lẹ̀, tí mo sì ń bá àwọn tá a ti jọ ń kẹ́gbẹ́ tẹ́lẹ̀ rìn. Ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe kedere, ìyẹn sì ni pé mo ní láti sa gbogbo ipá mi láti já ara mi gbà lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún mi.—Mátíù 5:30.

Torí pé mo fẹ́ràn orin gan-an, jíjáwọ́ nínú orin rọ́ọ̀kì onílù dídún kíkankíkan ló ṣòro fún mi jù. Àmọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi nínú ìjọ ràn mí lọ́wọ́, mo sì jáwọ́ níkẹyìn. Mo jáwọ́ nínú ìmutípara àti lílo oògùn olóró. Mo gé irun orí mi, mo fá irùngbọ̀n mi, mi ò sì wọ aṣọ dúdú nìkan mọ́. Nígbà tí mo sọ fún Sussan pé mo fẹ́ gé irun mi, ó yà á lẹ́nu débi pé ó fẹ́ mọ ohun tó mú mi ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Ó wá sọ pé: “Màá tiẹ̀ bá ẹ dé Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn kí n lè fojú ara mi rí ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀!” Ohun tó rí níbẹ̀ wù ú gan-an débi tí òun náà fí pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Níkẹyìn, èmi àti Sussan wá ṣe ìgbéyàwó. A ṣe ìrìbọmi lọ́dún 2008, a sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú wa dùn gan-an pé àwa àti ìyá mi wá jọ ń sin Jèhófà pa pọ̀.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Mo bọ́ lọ́wọ́ ayọ̀káyọ̀ inú ayé yìí àti ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́. Mo ṣì fẹ́ràn orin títí di ìsinsìnyí, àmọ́ ṣe ni mo máa ń fara balẹ̀ yan àwọn orin tí mo ń kọ. Mo ń fi ìrírí tèmi kọ́ àwọn èèyàn mi àtàwọn ẹlòmíì, pàápàá àwọn ọ̀dọ́, lẹ́kọ̀ọ́. Mo fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí i pé gbogbo ohun tó ń dán kọ́ ni wúrà, ọ̀pọ̀ ohun tí ayé yìí ń gbé gẹ̀gẹ̀ lè dà bíi pé ó fani mọ́ra lóòótọ́, àmọ́ níkẹyìn, èèyàn máa rí i pé “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí” ló jẹ́.—Fílípì 3:8.

Mo ti wá ní àwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ adúróṣinṣin nínú ìjọ Kristẹni, ní ibi tí ìfẹ́ àti àlàáfíà ti gbilẹ̀. Lékè gbogbo rẹ̀, torí pé mo sún mọ́ Jèhófà, mo di ẹni tó ní bàbá.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àpilẹ̀kọ kan tó ní àkòrí náà “Ìforítì Ní Ń Múni Ṣàṣeyọrí” jáde nínú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2000 ojú ìwé 4 sí 6.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

“Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà tó fà mí pa dà, ǹ bá má lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́”