Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Rán “Ìràwọ̀” Náà?

Ta Ló Rán “Ìràwọ̀” Náà?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ta Ló Rán “Ìràwọ̀” Náà?

▪ Ǹjẹ́ o ti rí àwọn àwòrán tàbí eré kan nípa ìgbà tí wọ́n bí Jésù, tí àwọn ọba tàbí amòye mẹ́ta kan lọ kí i nígbà tó wà lọ́mọ jòjòló tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran? Ohun tí ìtàn yẹn ń sọ ni pé Ọlọ́run ló lo ìràwọ̀ kan láti ṣamọ̀nà wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n tiẹ̀ ń sọ pé kí àwọn ọmọdé kọ́ àwọn orúkọ kan ní àkọ́sórí, ìyẹn Melchior, Caspar àti Baltazar, pé òun ni orúkọ ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹn. Àmọ́, ṣé ìtàn tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ yẹn bá ohun tí Bíbélì sọ mu? Rárá o. Onírúurú ọ̀nà ló ti hàn pé ìtàn náà kò bá Bíbélì mu.

Lákọ̀ọ́kọ́, ta ni àwọn ọkùnrin yẹn? Bíbélì tí wọ́n kọ lédè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò pe àwọn ọkùnrin yìí ní ọba tàbí amòye. Awòràwọ̀ làwọn ọkùnrin yìí. Ẹ̀rí fi hàn pé abọ̀rìṣà paraku ni àwọn ọkùnrin, tí wọ́n máa ń fi ìràwọ̀ woṣẹ́ yìí. Bíbélì kò sì sọ orúkọ tàbí iye àwọn tó wá kí Jésù yẹn.

Ìkejì, ìgbà wo ni àwọn ọkùnrin yẹn wá sí ibẹ̀? Kì í ṣe ìgbà tí Jésù ṣì jẹ́ ọmọ ọwọ́ tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran ni wọ́n wá. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ohun tí Mátíù òǹkọ̀wé Ìhìn Rere sọ ni pé: “Nígbà tí wọ́n sì wọ ilé náà, wọ́n rí ọmọ kékeré náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀.” (Mátíù 2:11) Ṣàkíyèsí pé Jésù kì í ṣe ọmọ jòjòló tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran mọ́ nígbà yẹn, ó ti di ẹni tí Bíbélì pè ní “ọmọ kékeré.” Lẹ́yìn náà, kì í ṣe inú ibùjẹ ẹran ni Màríà àti Jósẹ́fù ń gbé nígbà náà, kàkà bẹ́ẹ̀, inú ilé kan ni Bíbélì sọ pé wọ́n wà.

Ẹ̀kẹta, ta ló rán “ìràwọ̀” yẹn láti darí àwọn awòràwọ̀ náà? Àwọn aṣáájú ìsìn sábà máa ń kọ́ni pé Ọlọ́run ló rán “ìràwọ̀” náà. Àmọ́ ǹjẹ́ Ọlọ́run ló rán “ìràwọ̀” yẹn lóòótọ́? Rántí pé “ìràwọ̀” yẹn kò kọ́kọ́ darí àwọn awòràwọ̀ yẹn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ̀ Hẹ́rọ́dù Ọba ní Jerúsálẹ́mù ló darí wọn lọ. Àwọn awòràwọ̀ náà fi tó òjòwú ọba alágbára tó jẹ́ apààyàn yẹn létí pé wọ́n ti bí ọmọ kan tó ń jẹ́ Jésù, wọ́n sì sọ ohun tó lè mú kí ọba náà kórìíra ọmọ tí wọ́n sọ pé ó máa di “ọba àwọn Júù” yẹn. (Mátíù 2:2) Hẹ́rọ́dù wá lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ó ní kí wọ́n pa dà wá sọ ibi tí ọmọ náà wà gan-an fún òun pé òun náà fẹ́ lọ júbà rẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà náà ni “ìràwọ̀” yẹn tún ṣẹ̀ṣẹ̀ wá darí àwọn awòràwọ̀ yẹn lọ sọ́dọ̀ Jósẹ́fù àti Màríà. Torí náà, tí kì í bá ṣe pé Ọlọ́run dá sí ọ̀rọ̀ náà ni, ìrìn àjò àwọn awòràwọ̀ yẹn ì bá yọrí sí ikú ọmọ náà. Ó sì dùn mọ́ni pé Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà. Inú bí Hẹ́rọ́dù gidigidi nígbà tí àwọn awòràwọ̀ yẹn kò pa dà wá jábọ̀ fún un, ó wá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọdékùnrin láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀ ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti agbègbè rẹ̀.—Mátíù 2:16.

Nígbà tó yá, Jèhófà pe Jésù ní “Ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Ìwọ rò ó wò ná: Ṣé Jèhófà, Baba onífẹ̀ẹ́ àti olódodo, máa wá yan àwọn awòràwọ̀ tó jẹ́ abọ̀rìṣà láti fi ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ ti ka irú nǹkan bẹ́ẹ̀ léèwọ̀ nínú Òfin Mósè? (Diutarónómì 18:10) Ǹjẹ́ ó máa lo ìràwọ̀ láti fi darí wọn lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù ọba alágbára àti apààyàn tó ya ìkà jù ní orílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n lọ jẹ́ iṣẹ́ nípa ọmọ náà fún un, èyí tó dájú pé ó máa tanná ran ẹ̀mí owú àti ìkórìíra tó wà lọ́kàn rẹ̀? Ṣé lẹ́yìn tí wọ́n wá sọ́dọ̀ irú èèyàn bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run á tún wá lo ìràwọ̀ kan náà àti àwọn awòràwọ̀ yẹn láti fi sọ ọ̀gangan ibi tí ọmọ rẹ̀ jòjòló náà wá?

Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gágun ọlọ́gbọ́n kan tó fẹ́ wọlé sí àwọn ọ̀tá rẹ̀ lára, rán ẹni tó jẹ́ akíkanjú jù lára ọmọ ogun rẹ̀ lọ ṣe iṣẹ́ eléwu kan láàárín ibi tí àwọn ọ̀tá náà wà. Ṣé ó máa wá sọ ibi tí ọmọ ogun yẹn wà gan-an fún àwọn ọ̀tá náà? Kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láéláé! Bákan náà, Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sí inú ayé eléwu yìí. Ǹjẹ́ o rò pé ó máa sọ ibi tí Ọmọ rẹ̀, tí kò tíì dákan mọ̀, wà fún Hẹ́rọ́dù Ọba tó jẹ́ ìkà èèyàn yẹn? Kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láéláé!

Ta ló wá rán “ìràwọ̀” tàbí ohun tó jọ ìràwọ̀ yẹn? Ta ni ìwọ rò pé ó máa fẹ́ kí wọ́n pa ọmọ yẹn, kí ọmọ náà máa bàa ṣe ohun tí Ọlọ́run rán an wá ṣe láyé? Ta ló máa ń wá ọ̀nà láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, tó sì ń tan irọ́, ìwà ipá àti ìpànìyàn kálẹ̀? Jésù fúnra rẹ̀ sọ ẹni tó jẹ́ “òpùrọ́ àti baba irọ́,” tó sì jẹ́ “apànìyàn nígbà tó bẹ̀rẹ̀,” ó ní Sátánì Èṣù ni.—Jòhánù 8:44.