Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan

Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀. Jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Jèhófà Ọlọ́run àti Mósè

Àkópọ̀: Jèhófà yan Mósè pé kí ó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA Ẹ́KÍSÓDÙ 3:1-14; 4:1-17.

Ṣàpèjúwe bí iná tó ń jó igi kékeré náà ṣe rí lójú tìrẹ.

․․․․․

Kí lo rò pé Mósè ṣe, báwo sì ni ojú rẹ̀ àti ohùn rẹ̀ ṣe rí, nígbà tó gbọ́ ohùn Ọlọ́run tó ń pè é, bó ṣe wà nínú Ẹ́kísódù 3:4?

․․․․․

Báwo ni ohùn Mósè ṣe rí nígbà tó ń béèrè àwọn ìbéèrè tó wà nínú Ẹ́kísódù 3:11, 13 àti 4:1, 10 lọ́wọ́ Jèhófà?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Lo àwọn ìwé ìwádìí míì tó o mọ̀ láti fi ṣèwádìí síwájú sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ̀rọ̀ yẹn láti fi dáhùn ìbéèrè tí Mósè béèrè nípa orúkọ Ọlọ́run? *

․․․․․

Kí lo rò pé ó fà á tí Mósè kò fi fẹ́ láti lọ sọ́dọ̀ Fáráò? (Ojútùú: Ka Númérì 12:3.)

․․․․․

Kí lo rò pé ó fà á tí Mósè kò fi fẹ́ láti lọ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀?

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀rù sábà máa ń ba èèyàn nígbà tó bá fẹ́ ṣe ohun kan tí yóò wá dà bíi pé òun kò ní lè ṣe é.

․․․․․

Bó ṣe dá Jèhófà lójú pé o lè ṣe àwọn nǹkan tó bá sọ pé kó o ṣe.

․․․․․

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Àwọn nǹkan wo ló máa ń bà ọ́ lẹ́rù pé o kò ní lè ṣe nígbà tó o bá fẹ́ ṣe é?

․․․․․

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan lo lè ṣe, àwọn nǹkan wo ni Jèhófà Ọlọ́run lè sọ pé kó o ṣe?

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÀWỌN ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Tí o bá fẹ́ ka àpilẹ̀kọ yìí tàbí o fẹ́ tẹ̀ ẹ́ jáde, lọ sí orí ìkànnì wa www.pr418.com

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org àti www.pr418.com

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ńlá àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ jáde tí o lè fi ṣèwádìí jinlẹ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀. Tí o bá fẹ́ mọ̀ sí i, gbìyànjú láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí.