Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Ọ̀dàlẹ̀ Àmì Búburú Kan Tó Fi Hàn Pé À Ń gbé Ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn!

Ìwà Ọ̀dàlẹ̀ Àmì Búburú Kan Tó Fi Hàn Pé À Ń gbé Ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn!

Ìwà Ọ̀dàlẹ̀ Àmì Búburú Kan Tó Fi Hàn Pé À Ń gbé Ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn!

“A . . . jẹ́ adúróṣinṣin àti olódodo àti aláìṣeé-dálẹ́bi.”—1 TẸS. 2:10.

WÁ ÌDÁHÙN SÍ ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ YÌÍ:

Báwo ni ìwà ọ̀dàlẹ̀ Dẹ̀lílà, Ábúsálómù àti Júdásì Ísíkáríótù ṣe jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa?

Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jónátánì àti Pétérù tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin?

Báwo la ṣe lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya wa àti sí Jèhófà?

1-3. (a) Kí ni àmì búburú kan tó fi hàn pé à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, kí ló sì túmọ̀ sí? (b) Ìbéèrè mẹ́ta wo la máa rí ìdáhùn sí nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 ÀWỌN mẹ́ta kan wà tí ìwà wọn jọra. Àwọn ni Dẹ̀lílà, Ábúsálómù àti Júdásì Ísíkáríótù. Ọ̀dàlẹ̀ ni gbogbo wọn. Dẹ̀lílà dalẹ̀ ọkùnrin tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìyẹn Sámúsìnì Onídàájọ́; Ábúsálómù dalẹ̀ bàbá rẹ̀, Dáfídì Ọba; Júdásì sì dalẹ̀ Kristi Jésù tó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀. Ìwà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn hù dá wàhálà sílẹ̀, ó sì kó ìdààmú bá àwọn míì! Àmọ́, ọ̀nà wo ni ohun tí wọ́n ṣe gbà kàn wá?

2 Òǹkọ̀wé òde òní kan sọ pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwà ibi tó wọ́pọ̀ jù lọ lónìí. Kò sì yẹ kí ìyẹn yà wá lẹ́nu. Nígbà tí Jésù ń sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn . . . yóò sì da ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.” (Mát. 24:3, 10) Ohun tó túmọ̀ sí láti “da” ẹnì kan ni pé kéèyàn lo ọgbọ́n ẹ̀tàn tàbí ọgbọ́n àyínìke láti fa onítọ̀hún lé ọ̀tá lọ́wọ́.” Irú ìwà ọ̀dàlẹ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó fi hàn pé à ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Pọ́ọ̀lù sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn èèyàn yóò jẹ́ “aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, . . . ọ̀dàlẹ̀.” (2 Tím. 3:1, 2, 4, Ìròhìn Ayọ̀) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òǹkọ̀wé àti àwọn akọ̀tàn sábà máa ń mú kí ìwà àrékérekè gbádùn mọ́ni kó sì fani mọ́ra nínú àwọn ìwé àti fíìmù wọn, ní ti gidi, ìrora àti ìjìyà ni àìṣòótọ́ àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ máa ń fà. Ara àwọn àmì búburú tó fi hàn pé à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ni wọ́n jẹ́ ní tòótọ́!

3 Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú Bíbélì nípa àwọn kan tí wọ́n ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ rí? Àpẹẹrẹ àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin wo la lè tẹ̀ lé? Ta ló sì yẹ ká máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí? Ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí.

BÍ ÀWỌN OHUN TÓ TI ṢẸLẸ̀ KỌJÁ ṢE JẸ́ ÌKÌLỌ̀ FÚN WA

4. Báwo ni Dẹ̀lílà ṣe da Sámúsìnì, kí sì nìdí tí ohun tó ṣe yẹn fi burú?

4 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Dẹ̀lílà tó jẹ́ ẹlẹ́tàn, ẹni tí Sámúsìnì Onídàájọ́ nífẹ̀ẹ́ gan-an. Sámúsìnì ti múra tán láti lọ ṣojú fún àwọn èèyàn Ọlọ́run láti bá àwọn Filísínì jagun. Àmọ́, bóyá nítorí pé àwọn Filísínì ti mọ̀ pé Dẹ̀lílà kò nífẹ̀ẹ́ Sámúsìnì dénú, àwọn alákòóso wọn márààrún sọ pé àwọn máa fún un ní owó tabua tó bá lè bá àwọn wá ìdí agbára àrà ọ̀tọ̀ tí Sámúsìnì ní kí àwọn lè pa á. Dẹ̀lílà, agbowó-ìkà gbà sí wọn lẹ́nu, àmọ́ ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kùnà láti rí ìdí agbára Sámúsìnì. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í “fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ pin ín lẹ́mìí ní gbogbo ìgbà, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ ṣáá.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, “ọkàn rẹ̀ kò lélẹ̀ títí dé ojú àtikú.” Torí náà, Sámúsìnì sọ fún un pé wọn kò tíì gé irun orí òun rí, bí wọ́n bá sì gé e, òun kò ní ní agbára mọ́. * Lẹ́yìn tí Dẹ̀lílà ti mọ ìdí agbára Sámúsìnì, ó pe ọ̀kan lára àwọn Filísínì wọlé pé kó wá gé irun orí rẹ̀ nígbà tí Sámúsìnì sùn sí orí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó sì fà á lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe é bí wọ́n bá ṣe fẹ́. (Oníd. 16:4, 5, 15-21) Ìwà tó hù yẹn mà burú gan-an ni o! Ìwọra mú kí Dẹ̀lílà da ẹni tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

5. (a) Báwo ni Ábúsálómù ṣe hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí Dáfídì, kí nìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀? (b) Báwo ló ṣe rí lára Dáfídì nígbà tí Áhítófẹ́lì di ọlọ̀tẹ̀?

5 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Ábúsálómù tí òun náà hùwà àdàkàdekè. Torí pé ó wù ú láti dé ipò àṣẹ, ó pinnu láti fipá gba ìjọba lọ́wọ́ bàbá rẹ̀, Dáfídì Ọba. Ohun tí Ábúsálómù kọ́kọ́ ṣe ni pé ó “jí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ” nípa mímú kí àwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe àwọn ìlérí asán ó sì tún ń fi ìfẹ́ hàn sí wọ́n lọ́nà ẹ̀tàn. Á gbá wọn mọ́ra, á sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, bíi pé lóòótọ́ ni ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún. (2 Sám. 15:2-6) Kódà, Ábúsálómù fa ojú Áhítófẹ́lì tí Dáfídì máa ń finú hàn mọ́ra, òun náà di ọlọ̀tẹ̀ ó sì dara pọ̀ mọ́ àwọn tó fẹ́ fipá gba ìjọba. (2 Sam. 15:31) Nínú Sáàmù 3 àti 55, Dáfídì sọ ohun tí ìwà ọ̀dàlẹ̀ wọn fi ojú òun rí. (Sm. 3:1-8; ka Sáàmù 55:12-14.) Bí ìfẹ́ fún ipò àṣẹ ṣe mú kí Ábúsálómù pète ibi tó sì di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun lòdì sí ọba tí Jèhófà yàn sípò yìí fi hàn pé kò ní ọ̀wọ̀ kankan fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. (1 Kíró. 28:5) Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ìpètepèrò rẹ̀ já sí asán, Dáfídì sì ń bá a nìṣó láti máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ẹni àmì òróró Jèhófà.

6. Báwo ni Júdásì ṣe da Jésù, bí àwọn èèyàn bá sì ti gbọ́ orúkọ náà Júdásì, kí ló máa ń wá sọ́kàn wọn?

6 Ní báyìí, ronú nípa ohun tí ọ̀dàlẹ̀ náà Júdásì Ísíkáríótù ṣe fún Kristi. Nígbà àjọyọ̀ Ìrékọjá tí Jésù bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá ṣe kẹ́yìn, ó sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.” (Mát. 26:21) Nígbà tó ṣe, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, Jésù sọ fún Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù nínú ọgbà Gẹtisémánì pé: “Wò ó! Afinihàn mi ti sún mọ́ tòsí.” Lójú ẹsẹ̀, Júdásì àtàwọn tí wọ́n jọ lẹ̀dí àpò pọ̀ dé sínú ọgbà náà. Júdásì “lọ tààràtà sọ́dọ̀ Jésù, ó wí pé: ‘Kú déédéé ìwòyí o, Rábì!’ ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ gan-an.” (Mát. 26:46-50; Lúùkù 22:47, 52) Júdásì ‘fi ẹ̀jẹ̀ olódodo lé wọn lọ́wọ́’ nígbà tó fa Jésù lé àwọn ọ̀tá Kristi lọ́wọ́. Kí ló sì mú kí Júdásì tó fẹ́ràn owó fà á lé wọn lọ́wọ́? Nítorí ọgbọ̀n owó fàdákà lásán! (Mát. 27:3-5) Látìgbà náà wá, bí àwọn èèyàn bá ti gbọ́ orúkọ Júdásì, ìwà “ọ̀dàlẹ̀” tó hù ló máa ń wá sí wọn lọ́kàn, pàápàá irú ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó máa ń mú kí ọ̀tá tó fojú jọ ọ̀rẹ́ dalẹ̀ ẹnì kejì rẹ̀. *

7. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la ti rí kọ́ nínú ìgbésí ayé (a) Ábúsálómù àti Júdásì àti (b) Dẹ̀lílà?

7 Àwọn ẹ̀kọ́ wo la ti rí kọ́ nínú ohun tí Ábúsálómù, Júdásì àti Dẹ̀lílà ṣe? Ábúsálómù àti Júdásì kú ikú ẹ̀sín torí pé wọ́n hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró Jèhófà. (2 Sám. 18:9, 14-17; Ìṣe 1:18-20) Ìgbàkigbà táwọn èèyàn bá gbọ́ orúkọ Dẹ̀lílà ni wọ́n á máa rántí ìwà àdàkàdekè àti ìfẹ́ ẹ̀tàn tó ní sí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Sm. 119:158) Torí náà, ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká sá fún ìwọra tàbí wíwá ipò àṣẹ ní gbogbo ọ̀nà, èyí tí kò ní jẹ́ ká rí ojú rere Jèhófà! Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ tó ju ẹ̀kọ́ lọ ni èyí jẹ́ fún wa pé ká sá fún ohunkóhun tó bá máa mú ká hùwà ọ̀dàlẹ̀!

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÀWỌN TÓ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN

8, 9. (a) Kí nìdí tí Jónátánì fi ṣèlérí pé òun á jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jónátánì?

8 Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì lára wọn ká sì wo ohun tá a lè rí kọ́ lára wọn, bẹ̀rẹ̀ látorí ọkùnrin kan tó fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jónátánì, ọmọkùnrin tí Sọ́ọ̀lù Ọba kọ́kọ́ bí, ni ì bá gorí ìtẹ́ lẹ́yìn bàbá rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ torí pé Dáfídì ni Jèhófà yàn gẹ́gẹ́ bí ọba tó máa jẹ tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù. Jónátánì bọ̀wọ̀ fún ìpinnu Ọlọ́run. Kò jowú Dáfídì, kò sì bá a ṣọ̀tá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ‘ọkàn rẹ̀ fà mọ́ ọkàn Dáfídì,’ ó sì ṣèlérí fún un pé òun á jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Kódà, ó bọlá fún Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba nípa kíkó ẹ̀wù rẹ̀, idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti ìgbànú rẹ̀ fún un. (1 Sám. 18:1-4) Jónátánì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè ‘fún ọwọ́ Dáfídì lókun,’ débi pé ó tiẹ̀ fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè gbèjà Dáfídì níwájú Sọ́ọ̀lù. Ìwà ìdúróṣinṣin Jónátánì mú kó sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ ni yóò sì jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì di igbá-kejì rẹ.” (1 Sám. 20:30-34; 23:16, 17) Torí náà, kò yani lẹ́nu pé lẹ́yìn ikú Jónátánì, Dáfídì kọ orin arò kan tó fi hàn bí inú rẹ̀ ṣe bà jẹ́ tó àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó.—2 Sám. 1:17, 26.

9 Jónátánì mọ ẹni tó yẹ kí òun jẹ́ adúróṣinṣin sí. Ó tẹrí ba pátápátá fún Jèhófà Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, ó sì ti Dáfídì tó jẹ́ ẹni àmì òróró Ọlọ́run lẹ́yìn gbágbáágbá. Bákan náà lónìí, bí a kò tilẹ̀ ní àǹfààní àkànṣe nínú ìjọ, ó yẹ ká máa fi tinútinú kọ́wọ́ ti àwọn arákùnrin tá a yàn pé kí wọ́n máa mú ipò iwájú láàárín wa.—1 Tẹs. 5:12, 13; Héb. 13:17, 24.

10, 11. (a) Kí nìdí tí Pétérù fi jẹ́ adúróṣinṣin sí Jésù? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pétérù, kí ló sì yẹ ká fẹ́ láti ṣe?

10 Àpẹẹrẹ rere mìíràn tá a máa gbé yẹ̀ wò ni ti àpọ́sítélì Pétérù, tó pinnu pé òun máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jésù. Nígbà tí Kristi lo èdè ìṣàpẹẹrẹ láti fi ṣàlàyé bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ tí òun máa tó fi ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ òun rú, ọ̀rọ̀ náà mú kí ọ̀pọ̀ lára wọn gbọ̀n rìrì, wọ́n sì fi Jésù sílẹ̀. (Jòh. 6:53-60, 66) Torí náà, Jésù yíjú sí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá ó sì bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” Pétérù ló dá a lóhùn, ó sọ pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun; àwa sì ti gbà gbọ́, a sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” (Jòh. 6:67-69) Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán nípa ẹbọ tó máa tó fi ara rẹ̀ rú ló yé Pétérù? Bóyá ni. Síbẹ̀, Pétérù pinnu pé òun á jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọmọ tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ yàn.

11 Pétérù kò ronú pé ó ní láti jẹ́ pé Jésù kò lóye ohun tó ń sọ àti pé bí òun bá ní sùúrù díẹ̀ sí i, Ó máa tó kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Rárá o, ńṣe ni Pétérù gbà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé Jésù ní “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” Bákan náà lónìí, kí la máa ṣe tí a bá rí kókó kan nínú àwọn ìtẹ̀jáde “olóòótọ́ ìríjú náà” tó ṣòro láti lóye tàbí tí kò bá ìrònú wa mu? Ńṣe ló yẹ ká gbìyànjú gidigidi ká lè lóye rẹ̀ dípò tí a ó fi máa retí pé wọ́n máa tó ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó bá ohun tó wà lọ́kàn wa mu.—Ka Lúùkù 12:42.

MÁ ṢE DALẸ̀ ỌKỌ TÀBÍ AYA RẸ

12, 13. Kí ló lè mú kí ẹnì kan dalẹ̀ ọkọ tàbí aya rẹ̀, kí sì nìdí tí èèyàn ò fi lè sọ pé ọjọ́ orí òun ló fà á tí òun fi ṣe bẹ́ẹ̀?

12 A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí irú ìwà ọ̀dàlẹ̀ èyíkéyìí ba àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìdílé tàbí ti ìjọ Kristẹni jẹ́, torí pé ìwà tó burú jáì ni. Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn wa, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya wa àti sí Ọlọ́run.

13 Ọ̀kan lára ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó máa ń bani nínú jẹ́ jù lọ ni panṣágà. Ọkọ tàbí aya tó bá ṣe panṣágà ti gba ohun mìíràn láyè láti ba àdéhùn àárín òun àti ẹnì kejì rẹ̀ jẹ́, ó sì ti darí ọkàn rẹ̀ sọ́dọ̀ ẹlòmíì. Ọkọ tàbí aya irú ẹni bẹ́ẹ̀ á ṣàdédé bá ara rẹ̀ ní òun nìkan, á sì dà bíi pé ìgbésí ayé rẹ̀ ti dorí kodò. Báwo ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe lè wáyé láàárín àwọn méjì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn tẹ́lẹ̀? Lọ́pọ̀ ìgbà, ibi tí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ni pé kí tọkọtaya má máa rí tara wọn rò. Ọ̀jọ̀gbọ́n Gabriella Turnaturi, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ṣàlàyé pé “níbi kí ọkàn má pa pọ̀ sórí àjọṣe lọ́kọláya ni ìwà ọ̀dàlẹ̀ ti ń bẹ̀rẹ̀.” Ìṣòro kí tọkọtaya má máa rí àyè gbọ́ tara wọn yìí ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn kan tó pẹ́ díẹ̀ tí wọ́n ti ṣègbéyàwó pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni àádọ́ta [50] ọdún kọ obìnrin tí wọ́n ti jọ fẹ́ra láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sílẹ̀ kó lè lọ fẹ́ obìnrin mìíràn tí ọkàn rẹ̀ fà sí. Àwọn kan máa ń sọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó ti dàgbà tó ọkùnrin yẹn. Àmọ́, dípò tí èyí á fi mú ká wo ọ̀rọ̀ náà bíi pé bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn, ó yẹ ká mọ̀ pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ ló jẹ́. *

14. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó bá dalẹ̀ ọkọ tàbí aya wọn? (b) Kí ni Jésù sọ nípa kí ọkọ tàbí aya jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn?

14 Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó já ọkọ tàbí aya wọn jù sílẹ̀ láìsí ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu? Ọlọ́run wa “kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,” ó sì sọ̀rọ̀ líle sí àwọn tó fìyà jẹ aya wọn, tí wọ́n sì pa wọ́n tì. (Ka Málákì 2:13-16.) Bíi ti Baba rẹ̀, Jésù jẹ́ kó yé àwọn èèyàn pé kò sí ẹni tó lè lé ọkọ tàbí aya rẹ̀ dà nù tàbí tó pa á tì láìnídìí, tó lè mú un jẹ.—Ka Mátíù 19:3-6, 9.

15. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè túbọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn?

15 Báwo ni àwọn tọkọtaya ṣe lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya [tàbí ọkọ] ìgbà èwe rẹ.” Ó sì tún sọ pé: “Máa gbádùn ìgbésí ayé pẹ̀lú aya [tàbí ọkọ] tí o nífẹ̀ẹ́.” (Òwe 5:18; Oníw. 9:9) Bí tọkọtaya ṣe ń dàgbà sí i, wọ́n gbọ́dọ̀ ‘ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe kí àjọṣe wọn lè lágbára sí i nípa tara, kí wọ́n sì túbọ̀ máa gba tara wọn rò.’ Ìyẹn túmọ̀ sí pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí ara wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa lo àkókò pẹ̀lú ara wọn, wọn kò sì gbọ́dọ̀ jìnnà sí ara wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ sórí bí àjọṣe àárín àwọn méjèèjì àti àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà kò ṣe ní bà jẹ́. Kí èyí lè ṣeé ṣe, ó pọn dandan pé kí tọkọtaya máa jùmọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n máa jùmọ̀ lọ sóde ẹ̀rí déédéé, kí wọ́n sì máa jùmọ̀ gbàdúrà láti tọrọ ìbùkún Jèhófà.

JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN SÍ JÈHÓFÀ

16, 17. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé àti nínú ìjọ tó máa fi hàn bóyá lóòótọ́ la jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run? (b) Àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká rí àǹfààní tó wà nínú ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run tó ní ká má ṣe kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́?

16 Àwọn kan wà nínú ìjọ tí wọ́n ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n sì ti bá wọn wí “pẹ̀lú ìmúnájanjan, kí wọ́n lè jẹ́ onílera nínú ìgbàgbọ́.” (Títù 1:13) Ní ti àwọn kan, ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá ti yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́. Àmọ́, ní ti “àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀,” ìbáwí náà ti mú kí wọ́n pa dà ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. (Héb. 12:11) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n yọ ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ kan lẹ́gbẹ́ ńkọ́? Irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ló máa fi hàn bóyá ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà la jẹ́ adúróṣinṣin sí tàbí Ọlọ́run. Jèhófà ń wò wá kó lè mọ̀ bóyá a máa ṣègbọràn sí àṣẹ òun pé ká má ṣe kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́.—Ka 1 Kọ́ríńtì 5:11-13.

17 Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká rí àǹfààní tó wà nínú kí ìdílé jẹ́ adúróṣinṣin kí wọ́n sì ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé kí wọ́n má ṣe kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìbátan wọn tá a ti yọ lẹ́gbẹ́. Ó ti lé ní ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti yọ ọ̀dọ́kùnrin kan lẹ́gbẹ́. Ní gbogbo àkókó yẹn, bàbá rẹ̀, ìyá rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin àtàwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta “jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú” rẹ̀. Nígbà míì, ó máa ń gbìyànjú láti bá wọn da nǹkan pọ̀, àmọ́ wọn kì í gbà fún un, gbogbo wọn máa ń rí sí i pé ohunkóhun kò da àwọn pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbà á pa dà, ó sọ pé ó máa ń dun òun gan-an nígbà yẹn pé wọn kò bá òun dá nǹkan pọ̀, àárò wọn sì sábà máa ń sọ òun, pàápàá jù lọ, nígbà tí òun bá dá wà lọ́wọ́ alẹ́. Àmọ́, ó gbà pé ká ní wọ́n ní àjọṣe ráńpẹ́ pẹ̀lú òun nígbà yẹn ni, ìyẹn ì bá ti tẹ́ òun lọ́rùn. Àmọ́, ńṣe ni wọ́n pa á tì sí àyè ara rẹ̀, ẹnikẹ́ni nínú ìdílé kì í sì í bá a sọ ohunkóhun, torí náà bó ṣe ń wù ú gan-an pé kí wọ́n máa rí tirẹ̀ rò wá mú kó fẹ́ láti pa dà ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Ohun tó yẹ kó o máa rò nìyẹn tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé kó o má ṣe kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìbátan rẹ tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́.

18. Lẹ́yìn tá a ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin àti àwọn àbájáde búburú tó wà nínú kéèyàn jẹ́ ọ̀dàlẹ̀, kí lo pinnu láti ṣe?

18 Inú ayé tó kún fún àdàkàdekè, tí àwọn èèyàn ti ń hùwà àìṣòótọ́ là ń gbé. Síbẹ̀, tá a bá wò yí ká wa nínú ìjọ Kristẹni, a máa rí àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Ńṣe ló dà bíi pé bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn ń sọ nípa wọn pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí, Ọlọ́run jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí [ẹ] ti jẹ́ adúróṣinṣin àti olódodo àti aláìṣeé-dálẹ́bi sí [àwọn] onígbàgbọ́.” (1 Tẹs. 2:10) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run àti sí ara wa lẹ́nì kìíní kejì.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Kì í ṣe irun yẹn gan-an ló mú kí Sámúsìnì ní agbára, bí kò ṣe ohun tí irun náà dúró fún, ìyẹn ni àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tí Sámúsìnì ní pẹ̀lú Jèhófà torí pé ó jẹ́ Násírì Ọlọ́run.

^ Nínú àwọn èdè kan ohun tí “ìfẹnukonu Júdásì” túmọ̀ sí ni “kéèyàn dalẹ̀ ẹlòmíì.”

^ Bó o bá nílò ìrànlọ́wọ́ nípa ohun tó o lè ṣe bí ọkọ tàbí aya rẹ bá já ẹ jù sílẹ̀, wo àpilẹ̀kọ náà, “Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á bí Ọkọ Tàbí Aya Rẹ Bá Já Ẹ Jù Sílẹ̀,” nínú Ilé Ìṣọ́, June 15, 2010, ojú ìwé 29 sí 32.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Pétérù jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọmọ tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ yàn bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míì fi Í sílẹ̀