Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Sọ̀rètí Nù Bí Ìgbéyàwó Rẹ Kò Bá Fún Ẹ Láyọ̀

Má Sọ̀rètí Nù Bí Ìgbéyàwó Rẹ Kò Bá Fún Ẹ Láyọ̀

Má Sọ̀rètí Nù Bí Ìgbéyàwó Rẹ Kò Bá Fún Ẹ Láyọ̀

“Àwọn tí wọ́n gbéyàwó ni mo fún ní àwọn ìtọ́ni, síbẹ̀ kì í ṣe èmi bí kò ṣe Olúwa.”—1 KỌ́R. 7:10.

ǸJẸ́ O LÈ ṢÀLÀYÉ?

Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà so tọkọtaya pọ̀?

Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn Kristẹni tó ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó wọn lọ́wọ́?

Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìgbéyàwó?

1. Ojú wo ni àwọn Kristẹni fi ń wo ìgbéyàwó, kí sì nìdí?

 ÀWỌN Kristẹni máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá ṣègbéyàwó, èyí sì jẹ́ ojúṣe kan tí wọ́n gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ pàtàkì mú. (Oníw. 5:4-6) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, òun ló máa ń “so” àwọn tó bá ṣègbéyàwó “pọ̀.” (Máàkù 10:9) Ipò àwọn tá a so pọ̀ nínú ìgbéyàwó ni wọ́n wà lójú Ọlọ́run, láìka ohun tí òfin orílẹ̀-èdè fàyè gbà sí. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ máa wo ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ìṣètò Ọlọ́run tó so ẹni méjì pọ̀ yálà wọ́n ti ń sin Ọlọ́run nígbà tí wọ́n ṣègbéyàwó tàbí wọn kò tíì máa sìn ín.

2. Àwọn ìbéèrè wo la máa rí ìdáhùn sí nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Ìgbéyàwó tó yọrí sí rere lè mú kéèyàn ní ayọ̀ ńláǹlà. Àmọ́ kí ni tọkọtaya lè ṣe bí ìgbéyàwó wọn kò bá fún wọn láyọ̀? Ǹjẹ́ a lè rí nǹkan ṣe sí ìgbéyàwó tó ti fẹ́ tú ká? Ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn tọkọtaya tí àárín wọn kò gún lè rí gbà?

ṢÉ AYỌ̀ LÓ MÁA MÚ WÁ ÀBÍ Ẹ̀DÙN ỌKÀN?

3, 4. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí ẹnì kan bá ṣe ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání nígbà tó ń yan ẹni tó máa fẹ́?

3 Bí ìgbéyàwó Kristẹni kan bá kẹ́sẹ járí, ohun ayọ̀ ló jẹ́, ó sì máa ń bọlá fún Jèhófà. Àmọ́, tó bá forí ṣánpọ́n, ẹ̀dùn ọkàn ló máa ń fà. Bí Kristẹni kan bá ń ronú láti ṣe ìgbéyàwó, ó máa fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún ìgbéyàwó rẹ̀ tó bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Àmọ́, bí ẹnì kan bá ṣe ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání nígbà tó ń yan ẹni tó máa jẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ̀, ó lè ṣàìní ìtẹ́lọ́rùn kó sì tún ní ẹ̀dùn ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀dọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra nígbà tí wọn kò tíì ṣe tán láti bójú tó ojúṣe tó wé mọ́ ìgbéyàwó. Àwọn kan rí ẹni tí wọ́n rò pé àwọn lè jọ fẹ́ra lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì wọ́n sì kánjú ṣègbéyàwó, àmọ́ wọn kò láyọ̀ rárá. Àwọn míì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà, síbẹ̀ wọ́n pàpà fẹ́ra, èyí lè mú kí wọ́n fi ohun tí kò dára bẹ̀rẹ̀ ìgbéyàwó wọn torí pé wọn kò ní máa fi bẹ́ẹ̀ bọ̀wọ̀ fún ara wọn.

4 Àwọn Kristẹni kan kò ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa,” èyí sì mú kí wọ́n máa fojú winá àwọn ìṣòro tó sábà máa ń wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. (1 Kọ́r. 7:39) Tó bá jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ tìrẹ náà ṣe rí nìyí, gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dárí jì ẹ́ kó sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ọlọ́run kì í mú àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn ti ṣẹ̀ kọjá kúrò, àmọ́ ó máa ń ran àwọn tó bá ronú pìwà dà lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tó bá tìdí rẹ̀ yọ. (Sm. 130:1-4) Fi sọ́kàn pé ohun tó wù ú ni wàá máa ṣe ní báyìí àti títí láé, ‘ìdùnnú Jèhófà á sì di odi agbára rẹ.’—Neh. 8:10.

BÍ ÌGBÉYÀWÓ BÁ FẸ́ FORÍ ṢÁNPỌ́N

5. Bí ìgbéyàwó kan kò bá fúnni láyọ̀, irú èrò wo lèèyàn kò gbọ́dọ̀ fàyè gbà?

5 Àwọn tí ìgbéyàwó wọn ti kó ẹ̀dùn ọkàn bá lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣé ó pọn dandan kí n wá nǹkan ṣe sí ìgbéyàwó tí kò fún mi láyọ̀ yìí? Ì bá ti dára tó ká ní mo lè pa dà wá ẹlòmíì tí mo máa fẹ́!’ Wọ́n lè máa ronú pé kí oníkálukú kúkú máa lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kí òmìnira lè dé! A ò ṣe kọra wa sílẹ̀? Bí mi ò bá tiẹ̀ lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nítorí ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu, a ò ṣe kúkú pínyà, kí n lè pa dà máa gbádùn ara mi bíi ti tẹ́lẹ̀?’ Dípò tí àwọn Kristẹni á fi máa ronú lọ́nà yìí tàbí tí wọ́n á fi máa fojú yàwòrán ibi tí ọ̀rọ̀ náà lè já sí, ńṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe nínú ipò tí wọ́n bá ara wọn yìí láti wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run kí wọ́n sì tẹ̀ lé e.

6. Ṣàlàyé ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 19:9.

6 Bí Kristẹni kan bá ní láti kọ ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, ó lè ní òmìnira tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti fẹ́ ẹlòmíì, ó sì lè máà ní in. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mát. 19:9) Nínú ẹsẹ yìí, àwọn ohun tó wé mọ́ “àgbèrè” ni panṣágà àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ míì tó burú jáì. Bí èrò nípa ìkọ̀sílẹ̀ bá wá síni lọ́kàn láìjẹ́ pé ọkọ tàbí aya ẹni ṣe àgbèrè, ó ṣe pàtàkì kéèyàn gbàdúrà dáadáa nípa rẹ̀.

7. Kí ni àwọn èèyàn á máa rò bí ìgbéyàwó Kristẹni kan bá forí ṣánpọ́n?

7 Bí ìgbéyàwó Kristẹni kan bá forí ṣánpọ́n, ìyẹn lè mú káwọn èèyàn máa ṣiyè méjì pé bóyá ló ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè ìbéèrè pàtàkì yìí pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí kò bá mọ agbo ilé ara rẹ̀ bójú tó, báwo ni yóò ṣe bójú tó ìjọ Ọlọ́run?” (1 Tím. 3:5) Bí tọkọtaya kan bá sọ pé Kristẹni làwọn síbẹ̀ tí ìgbéyàwó wọn forí ṣánpọ́n, àwọn tó ń wò wọ́n lè máa rò pé àwọn méjèèjì kò fi ohun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ ṣèwà hù.—Róòmù 2:21-24.

8. Bí tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni bá pinnu pé àwọn máa pínyà, kí ló kù díẹ̀ káàtó nínú ọ̀rọ̀ wọn?

8 Bí tọkọtaya tó ti ṣèrìbọmi bá ń gbèrò láti pínyà tàbí láti kọ ara wọn sílẹ̀ láìsí ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu, a jẹ́ pé àjọṣe àárín wọn àti ti Ọlọ́run kò gún mọ́ nìyẹn. Ó sì lè jẹ́ pé ọ̀kan nínú wọn tàbí àwọn méjèèjì ni kò fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò mọ́. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n ń ‘fi gbogbo ọkàn-àyà wọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,’ kò sí ìdí tó fi yẹ ká ronú pé wọn kò lè wá nǹkan ṣe sí i kí ìgbéyàwó wọn má bàa forí ṣánpọ́n.—Ka Òwe 3:5, 6.

9. Èrè wo ni àwọn Kristẹni kan ti rí gbà torí pé wọn kò tètè sọ̀rètí nù nígbà tí ìṣòro fẹjú mọ́ ìgbéyàwó wọn?

9 Ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó tó jọ pé ó ti fẹ́ forí ṣánpọ́n ló ti pa dà wá kẹ́sẹ járí. Àwọn Kristẹni tí kò bá tètè sọ̀rètí nù nígbà tí ìṣòro bá fẹjú mọ́ ìgbéyàwó wọn sábà máa ń rí èrè tó pọ̀ gbà. Ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé kan tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pét. 3:1, 2) Ó dájú pé bí ìwà ọkọ tàbí ìyàwó kan bá dára, ẹnì kejì rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lè di Kristẹni! Bí Kristẹni kan kò bá jẹ́ kí ìgbéyàwó òun forí ṣánpọ́n, irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ máa bọlá fún Ọlọ́run, ìbùkún ńláǹlà ló sì máa jẹ́ fún ọkọ, aya àti àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí.

10, 11. Àwọn ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ wo ló ṣeé ṣe kó wáyé nínú ìgbéyàwó, àmọ́ kí ló lè dá Kristẹni kan lójú?

10 Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó fẹ́ láti ṣe ohun tó wu Jèhófà, torí náà ẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ ni wọ́n fẹ́. Síbẹ̀, àwọn nǹkan tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀ lè wáyé. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì pé kí ọkọ tàbí ìyàwó ní ìṣòro ìdààmú ọkàn tó lè kenkà. Tàbí kẹ̀ láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó, ọkọ tàbí ìyàwó lè dí akéde aláìṣiṣẹ́mọ́. Àpẹẹrẹ kan rèé: Kristẹni tó jẹ́ onítara ni Linda * ó sì tún jẹ́ ìyá rere, àmọ́ ojú rẹ̀ ni ọkọ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, wọ́n sì yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ torí pé kò ronú pìwà dà. Kí ló yẹ kí Kristẹni kan ṣe bí ìgbéyàwó rẹ̀ bá fẹ́ forí ṣánpọ́n nítorí irú nǹkan bẹ́ẹ̀?

11 O lè béèrè pé, ‘Ṣé dandan ni kí n máa sapá kí ìgbéyàwó mi má bàa forí ṣánpọ́n láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí?’ Kò sẹ́ni tó lè bá ẹ ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ tàbí tó gbọ́dọ̀ bá ẹ ṣé e. Síbẹ̀, àwọn ìdí tó jíire wà tí o kò fi gbọ́dọ̀ sọ ìrètí nù bí ìgbéyàwó rẹ bá fẹ́ forí ṣánpọ́n. Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run bá ń fara da àdánwò nínú ìgbéyàwó rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe iyebíye lójú Ọlọ́run. (Ka 1 Pétérù 2:19, 20.) Jèhófà máa fi Ọ̀rọ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ ran Kristẹni kan tó bá ń sapá tọkàntọkàn lọ́wọ́ kí ìgbéyàwó rẹ̀ má bàa forí ṣánpọ́n nítorí ìṣòro tó ń fẹjú mọ́ ọn.

WỌ́N ṢE TÁN LÁTI ṢÈRÀNWỌ́

12. Ojú wo ni àwọn alàgbà máa fi wò wá tá a ba wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ wọn?

12 Bí ìṣòro bá fẹjú mọ́ ìgbéyàwó rẹ, má ṣe fà sẹ́yìn láti wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí. Olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run ni àwọn alàgbà, inú wọ́n sì máa dùn láti pe àfiyèsí rẹ sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (Ìṣe 20:28; Ják. 5:14, 15) Má ṣe rò pé àwọn alàgbà á máa fi ojú àbùkù wo ìwọ àti ẹnì kejì rẹ bó o bá wá ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí lọ sọ́dọ̀ wọn, tó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa ìṣòro líle koko kan tó wà nínú ìgbéyàwó yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fún ẹ máa pọ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń rí i pé tọkàntọkàn lo fi fẹ́ láti ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí.

13. Ìmọ̀ràn wo ló wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:10-16?

13 Bí àwọn Kristẹni tó wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá ní kí àwọn alàgbà ran àwọn lọ́wọ́, àwọn alàgbà máa ń fi ìmọ̀ràn irú èyí tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa rẹ̀ hàn wọ́n. Ó sọ pé: “Àwọn tí wọ́n gbéyàwó ni mo fún ní àwọn ìtọ́ni, síbẹ̀ kì í ṣe èmi bí kò ṣe Olúwa, pé kí aya má lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀; ṣùgbọ́n bí ó bá lọ ní ti gidi, kí ó wà láìlọ́kọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀; kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀. . . . Nítorí, aya, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba ọkọ rẹ là? Tàbí, ọkọ, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba aya rẹ là?” (1 Kọ́r. 7:10-16) Ìbùkún ńlá ló jẹ́ bí ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ bá wá sínú ìjọsìn tòótọ́!

14, 15. Ìgbà wo ni aya kan tó jẹ́ Kristẹni lè pinnu láti lọ kúrò ní ti gidi lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀, àmọ́ kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó gbàdúrà nípa rẹ̀, kó sì fi òótọ́ inú gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò?

14 Lábẹ́ àwọn ipò wo gan-an ni aya kan tó jẹ́ Kristẹni ti lè “lọ kúrò . . . ní ti gidi”? Àwọn aya kan tó jẹ́ Kristẹni ti yàn láti pínyà pẹ̀lú ọkọ wọn torí pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọ́ bùkátà ìdílé. Ohun tó sì mú kí àwọn míì pínyà ni pé ọkọ wọn máa ń lù wọ́n ní àlùbami tàbí kó fi ipò tẹ̀mí wọn sínú ewu.

15 Kristẹni kan fúnra rẹ̀ ló máa pinnu yálà kí òun lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ òun tàbí kí òun má lọ. Àmọ́, kí aya tó jẹ́ Kristẹni tó fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó yẹ kó gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà kó sì fi òótọ́ inú gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. Bí àpẹẹrẹ, ṣé òótọ́ ni pé aláìgbàgbọ́ náà ló ń fi ipò tẹ̀mí ìyàwó rẹ̀ sínú ewu, àbí ńṣe ni aya fúnra rẹ̀ kò fi ọwọ́ pàtàkì mú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí ìpàdé lílọ rẹ̀ ń ṣe ségesège, tí kì í sì í lọ sóde ẹ̀rí déédéé?

16. Kí ni kò ní jẹ́ kí àwọn Kristẹni máa kánjú ṣe ìpinnu nípa ìkọ̀sílẹ̀?

16 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọwọ́ pàtàkì la fi mú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run tá a sì mọyì ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ rẹ̀, ó yẹ kí èyí mú ká ṣọ́ra fún fífi ìkánjú ṣe ìpinnu nípa ìkọ̀sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ìsọdimímọ́ orúkọ rẹ̀ jẹ wá lógún. Torí náà, ó dájú pé a kò jẹ́ fi ọgbọ́n já ọkọ tàbí aya wa jù sílẹ̀ nítorí pé a ti ní in lọ́kàn láti fẹ́ ẹlòmíì.—Jer. 17:9; Mál. 2:13-16.

17. Kí ni àwọn nǹkan tó lè mú ká sọ pé Ọlọ́run ti pe àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó sí àlàáfíà?

17 Kristẹni kan tó fẹ́ aláìgbàgbọ́ gbọ́dọ̀ sapá tọkàntọkàn kí ohunkóhun má bàa ba ìgbéyàwó rẹ̀ jẹ́. Síbẹ̀, kò yẹ kí Kristẹni kan máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi tó bá jẹ́ pé lẹ́yìn tó ti sa gbogbo ipá rẹ̀ tọkàntọkàn láti mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan, ẹnì kejì rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò bá a gbé mọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ẹni tí kò gbà gbọ́ náà bá tẹ̀ síwájú láti lọ, jẹ́ kí ó lọ; arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan kò sí ní ipò ìsìnrú lábẹ́ irúfẹ́ àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pè yín sí àlàáfíà.”—1 Kọ́r. 7:15. *

GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

18. Bí kò bá tiẹ̀ ṣeé ṣe láti mú kí ìgbéyàwó kan má forí ṣánpọ́n, ohun rere wo ni ìsapá wa lè yọrí sí?

18 Tó o bá ń dojú kọ ìṣòro èyíkéyìí nínú ìgbéyàwó, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ìgboyà kó o sì máa gbẹ́kẹ̀ lé e nígbà gbogbo. (Ka Sáàmù 27:14.) Ronú nípa Linda, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Òun àti ọkọ rẹ̀ pàpà kọ ara wọn sílẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti sapá fún ọ̀pọ̀ ọdún kí ìgbéyàwó náà má bàa forí ṣánpọ́n. Ǹjẹ́ Linda ronú pé ńṣe ni òun fi àkókò òun ṣòfò? “Rárá o.” Ohun tó sọ ni pé: “Ìwàásù ni ìsapá mi jẹ́ fún àwọn tó ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Mo ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Èyí tó wá dára jù lọ níbẹ̀ ni pé ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọdún wọ̀nyẹn mú kí ọmọbìnrin wa fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́. Ó dàgbà di Ẹlẹ́rìí onítara tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.”

19. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí a bá sapá kí ìgbéyàwó kan má bàa forí ṣánpọ́n?

19 Inú arábìnrin kan tó ń jẹ́ Marilyn dùn pé òun ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti pé òun túbọ̀ sapá kí ìgbéyàwó òun má bàa forí ṣánpọ́n. Ó sọ pé: “Ó ṣe mi bíi pé kí n fi ọkọ mi sílẹ̀ nítorí pé kì í gbọ́ bùkátà ìdílé ó sì ń fi ipò tẹ̀mí mi sínú ewu. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, alàgbà ni kó tó di pé ó tọwọ́ bọ òwò kan tí kò mọ́gbọ́n dání. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ, a kò sì bá ara wa sọ̀rọ̀ mọ́ nígbà tó yá. Nígbà tí àwọn apániláyà gbéjà ko ìlú wa, jìnnìjìnnì bò mí débi pé mi ò tiẹ̀ wá dá sí ẹnikẹ́ni mọ́. Ìgbà yẹn ni mo tó wá mọ̀ pé èmi gan-an jẹ nínú ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà. Èmi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í bára wa sọ̀rọ̀ pa dà, a tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé a sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé déédéé. Àwọn alàgbà ṣe dáadáa sí wa, wọ́n ràn wá lọ́wọ́ gan-an, ìyẹn sì sọ ìgbéyàwó wa dọ̀tun. Nígbà tó ṣe, ọkọ mi tún kúnjú ìwọ̀n fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Ẹ̀kọ́ tó nira lèyí jẹ́ àmọ́ ibi tó dára ló yọrí sí.”

20, 21. Kí la gbọ́dọ̀ pinnu láti ṣe lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó?

20 Yálà a ti ṣègbéyàwó tàbí a kò tíì ṣègbéyàwó, ẹ jẹ́ ká máa lo ìgboyà nígbà gbogbo ká sì máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí a bá ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó wa, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè yanjú àwọn ìṣòro náà, ká sì máa rántí pé àwọn tó bá ti ṣègbéyàwó “kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan.” (Mát. 19:6) Ẹ sì jẹ́ ká fi sọ́kàn pé bí a kò bá fi ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sílẹ̀ láìka ìṣòro tó wà níbẹ̀ sí, àwa náà lè gbádùn ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn ran ọkọ tàbí aya rẹ̀ lọ́wọ́ láti wá sínú ìjọsìn tòótọ́.

21 Ipò yòówù ká bá ara wa, ǹjẹ́ ká máa bá a nìṣó láti kíyè sára ní gbogbo ọ̀nà ká lè ní ẹ̀rí rere látọ̀dọ̀ àwọn tó ń wò wá lẹ́yìn òde ìjọ Ọlọ́run. Bí ìṣòro bá fẹjú mọ́ ìgbéyàwó wa, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà kíkankíkan, ká fi òótọ́ inú ṣàyẹ̀wò èrò ọkàn wa, ká fara balẹ̀ gbé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yẹ̀ wò, ká sì wá ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ jẹ́ ká múra tán láti máa ṣe ohun tó wu Jèhófà Ọlọ́run nínú ohun gbogbo ká sì fi hàn pé a ní ojúlówó ìmọrírì fún ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu tó fún wa.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

^ Wo ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run,’ ojú ìwé 219 sí 221; Ilé-Ìṣọ́nà November 1, 1988, ojú ìwé 26 sí 27; Ilé Ìṣọ́ [Gẹ̀ẹ́sì] September 15, 1975, ojú ìwé 575.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

Àwọn Kristẹni tí kò bá tètè sọ̀rètí nù nígbà tí ìṣòro bá fẹjú mọ́ ìgbéyàwó wọn sábà máa ń rí èrè tó pọ̀ gbà

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

Máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà gbogbo kó o sì máa bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ ní ìgboyà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Jèhófà máa ń bù kún tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ń sapá kí ìgbéyàwó wọn má bàa forí ṣánpọ́n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

A lè rí ìtùnú àti ìtìlẹ́yìn tẹ̀mí gbà nínú ìjọ Kristẹni