Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ Bá Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mu

Ohun Tí Bíbélì Sọ Bá Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mu

Ohun Tí Bíbélì Sọ Bá Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mu

“Èmi kò ha ti kọ̀wé sí ọ ṣáájú àkókò yìí pẹ̀lú àwọn ìgbani- nímọ̀ràn àti ìmọ̀, láti fi ìjótìítọ́ àwọn àsọjáde tòótọ́ hàn ọ́, láti lè mú àwọn àsọjáde tí í ṣe òtítọ́ padà?”—ÒWE 22:20, 21.

KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Àwọn ìwé ayé àtijọ́ sábà máa ń sọ àwọn nǹkan tí kò ṣeé gbára lé tó sì tún léwu, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní sì ti já wọn nírọ́ pátápátá. Kódà lónìí, ó pọndandan pé kí àwọn òǹṣèwé máa ṣe àwọn àyípadà sí ohun tí wọ́n ti kọ sínú ìwé wọn látìgbàdégbà kó lè bá àwọn àwárí tuntun mu. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa ló ni Bíbélì àti pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “wà títí láé.”—1 Pétérù 1:25.

ÀPẸẸRẸ: Nínú Òfin Mósè Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìgbọ̀nsẹ̀, kí wọ́n gbẹ́ ilẹ̀ tí wọ́n máa ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí “ní òde ibùdó,” kí wọ́n sì bò ó mọ́lẹ̀ lẹ́yìn náà. (Diutarónómì 23:12, 13) Àti pé tí wọ́n bá fọwọ́ kan òkú ẹranko tàbí ti èèyàn, wọ́n gbọ́dọ̀ fi omi fọ aṣọ wọn. (Léfítíkù 11:27, 28; Númérì 19:14-16) Láyé ìgbà yẹn, ṣe ni wọ́n máa ń sé àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ títí dìgbà tí àyẹ̀wò yóò fi hàn pé àrùn ara wọn kò lè ranni mọ́.—Léfítíkù 13:1-8.

OHUN TÍ ÌMỌ̀ ÌṢÈGÙN ÒDE ÒNÍ SỌ: Pípalẹ̀ ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́ bó ṣe yẹ, fífọ ọwọ́ wa àti sísé ẹni tó ní àrùn tó lè ranni mọ́, jẹ́ ọ̀nà tó dára jù láti fi gbógun ti àrùn. Níbi tí kò bá sí ṣáláńgá tàbí oríṣi ilé ìgbọ̀nsẹ̀ míì, ìmọ̀ràn tí Ibùdó Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (U.S. Centers for Disease Control and Prevention) gbani ni pé: “Jẹ́ kí ibi tó o máa ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ rẹ sí jìnnà tó ọgbọ́n [30] mítà síbi tí odò èyíkéyìí wà, lẹ́yìn náà, kó o bò ó mọ́lẹ̀.” Ohun tí Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ ni pé, tí gbogbo ará ìlú bá ń palẹ̀ ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́ bó ṣe yẹ, àrùn ìgbẹ́ gbuuru máa dín kù gan-an. Kò tíì tó igba [200] ọdún sí ìsinsìnyí tí àwọn oníṣègùn ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i pé àwọn ń kó àrùn ran ọ̀pọ̀ aláìsàn tí àwọn kò bá fọwọ́ lẹ́yìn tí àwọn fọwọ́ kan òkú èèyàn, tí àwọn sì lọ fi ọwọ́ yẹn kan náà tọ́jú aláìsàn. Ibùdó Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Fífọ ọwọ́ ni ọ̀nà kan tó dára jù lọ láti gbà dènà títan àrùn tó ń ranni kálẹ̀.” Sísé àwọn tó lárùn ẹ̀tẹ̀ tàbí àrùn míì tó lè ranni mọ́ ńkọ́? Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ohun tí ìwé kan tó ń jẹ́ Saudi Medical Journal sọ ni pé: “Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ó jọ pé yíya àwọn tó ní àrùn yẹn sọ́tọ̀ àti sísé wọn mọ́ ni ọ̀nà kan ṣoṣo láti gbà dènà ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn tó ń ranni.”

KÍ LÈRÒ RẸ? Ṣé o rò pé èyíkéyìí lára àwọn ìwé àtijọ́ tí wọ́n ń pè ní ìwé mímọ́ tún wà tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní mu bíi ti Bíbélì? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Kò sí ẹni tó bá kà nípa àwọn ètò ìmọ́tótó tí wọ́n là kalẹ̀ láti dènà àrùn nígbà ayé Mósè, tí kò ní wú u lórí gan-an.”​—MANUAL OF TROPICAL MEDICINE, LÁTI ỌWỌ́ DỌ́KÍTÀ ALDO CASTELLANI ÀTI ALBERT J. CHALMERS