Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà La Ojú Mi

Jèhófà La Ojú Mi

Jèhófà La Ojú Mi

Gẹ́gẹ́ bí Patrice Oyeka ṣe sọ ọ́

Ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yìí, tó jẹ́ pé inú ìbànújẹ́ ọkàn tó lékenkà ni mo ti wà látàárọ̀, bí ìgbà téèyàn wà nínú òkùnkùn biribiri, tí mi ò ríran rárá, tí mo kàn dá nìkan wà, àyàfi rédíò tó kàn ń dún sí mi létí ṣáá, ayé sú mi gbáà. Mo bá pinnu pé ikú yá ju ẹ̀sín. Mo da ìyẹ̀fun onímájèlé sínú ife omi kan, mo gbé e kalẹ̀ sórí tábìlì tó wà níwájú mi. Mo fẹ́ wẹ ìwẹ̀ ìkẹyìn, kí n múra lọ́nà tó dáa, kí n tó gbé májèlé yẹn mu láti gbẹ̀mí ara mi. Kí nìdí tí mo fi fẹ́ pa ara mi? Báwo ni mo sì ṣe wà láàyè títí dòní láti lè sọ ìtàn yìí?

WỌ́N bí mi ní ìpínlẹ̀ Kasaï Oriental tó wà ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò ní February 2, ọdún 1958. Bàbá mi kú nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ló sì tọ́jú mi dàgbà.

Nígbà tí mo parí ilé ìwé, mo ríṣẹ́ sí oko rọ́bà kan. Láàárọ̀ ọjọ́ kan lọ́dún 1989, bí mo ṣe ń kọ ìwé kan lọ́wọ́ nínú ọ́fíìsì mi, ibi gbogbo kàn dédé ṣókùnkùn biribiri. Mo kọ́kọ́ rò pé iná mànàmáná ló lọ, àmọ́ mo ṣì ń gbọ́ ìró ẹ̀rọ amúnáwá bó ṣe ń ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àárọ̀ la wà! Jìnnìjìnnì bò mí, mo rí i pé mi ò rí nǹkan kan mọ́, kódà mi ò tiẹ̀ rí ìwé tí mò ń kọ nǹkan sí tó wà níwájú mi!

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo pe ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ mi, pé kó mú mi lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn tó wà nílé ìtọ́jú aláìsàn tó wà níbẹ̀. Ọkùnrin náà rí i pé awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó ń gba ìmọ́lẹ̀ sára nínú ojú mi ti fà ya àti pé ojú mi ti bà jẹ́ gan-an. Ó ní kí wọ́n gbé mi lọ sí olú ìlú orílẹ̀-èdè wa, ìyẹn Kinshasa, kí n lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ oníṣègùn tó mọ̀ nípa ojú ju òun lọ.

Bí Nǹkan Ṣe Rí fún Mi ní Ìlú Kinshasa

Ní ìlú Kinshasa, mo lọ sọ́dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dókítà tó mọ̀ nípa ojú, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Lẹ́yìn ti mo ti lo ọjọ́ mẹ́tàlélógójì [43] ní ilé ìwòsàn, àwọn dókítà sọ fún mi pé mi ò ní lè ríran mọ́ fún ìyókù ayé mi! Àwọn ẹbí mi mú mi lọ sí onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì bóyá wọ́n á lè fi iṣẹ́ ìyanu wò mí sàn, àmọ́ mi ò rí ìwòsàn.

Níkẹyìn, mo gba kámú, mo gbà pé mi ò lè ríran mọ́ nìyẹn. Ìbànújẹ́ wá dorí mi kodò bámúbámú. Mi ò ríran mọ́, mi ò níṣẹ́ lọ́wọ́ mọ́, mi ò sì tún ní aya mọ́, torí ìyàwó mi ti fi mí sílẹ̀ lọ, ó sì ti kó gbogbo ohun tí a ní nílé lọ. Àtijáde síta tàbí kí n yọjú sí àwọn èèyàn wá di ìtìjú fún mi. Bó ṣe di pé mo ń dá jókòó sílé láì yọjú síta látàárọ̀ ṣúlẹ̀ nìyẹn. Mo wá ya ara mi láṣo, mo gbà pé tèmi ti tán pátápátá.

Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ti gbìyànjú láti pa ara mi. Ìgbà kejì ni mo mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí. Ọpẹ́lọpẹ́ ọmọ kékeré kan nínú ilé wa, ǹ bá ti kú báyìí. Nígbà tí mo ń wẹ̀ lọ́wọ́, ọmọ kékeré yẹn tí kò dákan mọ̀ kàn gbé ife yẹn ní tiẹ̀, ó sì da ohun tó wà nínú rẹ̀ nù. Mo tiẹ̀ dúpẹ́ pé kò mu nínú rẹ̀. Ìgbà tí mo fi máa pa dà débẹ̀, mi ò rí ife yẹn mọ́, mo wá a títí, mi ò rí i. Mo wá jẹ́wọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ tí mo fi ń wá ife náà fún ìdílé mi àti ohun tí mo fẹ́ ṣe.

Ọpẹ́lọpẹ́ Ọlọ́run àti ìdílé mi tó ń ṣọ́ mi, tí wọn kò sì fi mí sílẹ̀. Gbogbo ìsapá tí mo ṣe láti para mi kò bọ́ sí i.

Bí Mo Ṣe Dẹni Tó Tún Ń Láyọ̀

Lọ́jọ́ Sunday kan lọ́dún 1992, bí mo ṣe wà ní ilé tí mò ń mu sìgá lọ́wọ́, ni àwọn ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan bá yà sọ́dọ̀ mi nígbà tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ilé dé ilé. Nígbà tí wọ́n rí i pé afọ́jú ni mí, wọ́n ka Aísáyà 35:5 tó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí.” Ọ̀rọ̀ tí mo gbọ́ yìí mú inú mi dùn gidigidi! Ti àwọn Ẹlẹ́rìí yìí yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n máa ń sọ fún mi nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí mo ti lọ, wọn kò sọ fún mi pé wọ́n á fi iṣẹ́ ìyanu wò mí sàn ní tiwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ṣàlàyé pé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, ojú mi máa là, tí n bá lè dẹni tó mọ Ọlọ́run. (Jòhánù 17:3) Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí yìí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé Kristẹni tí wọ́n ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó wà ládùúgbò wa, mo sì ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Mo jáwọ́ nínú sìgá mímu.

Àmọ́ torí pé mi ò ríran, mi ò tètè tẹ̀ síwájú bó ṣe yẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Torí náà, mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn afọ́jú láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń kàwé àti bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé lọ́nà tàwọn afọ́jú. Èyí jẹ́ kí èmi náà lè kópa nínú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tó máa ń wáyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Láìpẹ́-láìjìnnà, èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ládùúgbò wa. Mo wá dẹni tó tún pa dà ń láyọ̀. Mo tẹ̀ síwájú débi pé mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Mo sì ṣe ìrìbọmi ní May 7, 1994.

Bí mo ṣe túbọ̀ ń fẹ́ràn Jèhófà àti ọmọnìkejì mi, ó wù mí pé kí n bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókó tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run. Láti December 1, 1995, ni mo ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Mo sì dúpẹ́ pé láti oṣù February, ọdún 2004 ni wọ́n ti fún mi láǹfààní láti máa sìn bí alàgbà nínú ìjọ tí mo wà. Ìgbà míì, wọ́n máa pè mí láti ìjọ míì tó wà ládùúgbò wa pé kí n wá sọ àsọyé Bíbélì níbẹ̀. Gbogbo ìbùkún tí mo rí gbà yìí ló ń fún mi láyọ̀ gan-an, ó sì jẹ́ kí n wá rí i pé jíjẹ́ aláàbọ̀ ara kò lè díni lọ́wọ́ rárá láti sin Jèhófà Ọlọ́run, tá a bá fẹ́ sìn ín.

Jèhófà Pèsè Ohun Tó Dà Bí Ojú fún Mi

Bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí, ìyàwó mi fi mí sílẹ̀ lọ torí pé mi ò ríran mọ́. Ṣùgbọ́n Jèhófà tún wá dá mi lọ́lá lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ó pèsè ojú fún mi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, tí mo fi ń ríran. Arábìnrin Anny Mavambu, tó gbà láti fẹ́ mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo jẹ́ afọ́jú, ló dà bí ojú fún mi. Ó máa ń bá mi jáde lọ sí ẹnu iṣẹ́ ìwàásù torí òun náà jẹ́ ẹni tó máa ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó tún máa ń ka àwọn ìwé tí mo fi ń múra àsọyé sí mi létí, tí màá wá kọ ọ́ lọ́nà ìkọ̀wé àwọn afọ́jú. Ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ fún mi. Aya mi yìí ti wá jẹ́ kí n rí òótọ́ inú ọ̀rọ̀ Òwe 19:14, tó sọ pé: “Ogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ni ilé àti ọlà, ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni aya olóye ti wá.”

Jèhófà tún fi ọmọ méjì, ọkùnrin kan àti obìnrin kan ta èmi àti Anny lọ́rẹ. Mo ń fojú sọ́nà láti rí bí ojú wọn ṣe rí nínú Párádísè! Ìbùkún míì tí mo ti rí gbà ni pé, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ṣe wá lóore pé ká máa gbé níbi tí òun wà, tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó sì ṣe ìrìbọmi! Gbogbo wa la sì jọ wà nínú ìjọ kan náà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo jẹ́ afọ́jú, ìfẹ́ ọkàn mi ni pé kí n túbọ̀ máa sa gbogbo ipá mi síwájú sí i lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, torí Ọlọ́run ti bù kún mi púpọ̀ gan-an. (Málákì 3:10) Ojoojúmọ́ ni mò ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kó wá mú gbogbo ìyà kúrò nínú ayé. Látìgbà tí mo ti mọ Jèhófà ni mo ti lè fi ìdánilójú sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—Òwe 10:22.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Níbí, mo ń sọ àsọyé látinú Bíbélì. Èmi tún rèé pẹ̀lú ìdílé mi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin