Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ọkàn Rẹ Yóò . . . Tẹ̀ Ba Mọ́lẹ̀ Lórí Mi”

“Ọkàn Rẹ Yóò . . . Tẹ̀ Ba Mọ́lẹ̀ Lórí Mi”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Ọkàn Rẹ Yóò . . . Tẹ̀ Ba Mọ́lẹ̀ Lórí Mi”

ÌWÀ ìrẹ̀lẹ̀ máa ń fani mọ́ra gan-an. A sábà máa ń fà mọ́ àwọn tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé láyé òde òní, àwọn tó ní ojúlówó ìrẹ̀lẹ̀ kò wọ́pọ̀, pàápàá láàárín àwọn tí wọ́n ní agbára tàbí àṣẹ lórí àwọn ẹlòmíì. Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ alágbára jù lọ láyé àtọ̀run wá ńkọ́? Ṣé òun náà níwà ìrẹ̀lẹ̀? Jẹ́ ká wo ohun tí wòlíì Jeremáyà sọ nínú ìwé Ìdárò 3:20, 21.—Kà á.

Àkókò tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà nínú ìbànújẹ́ ni Jeremáyà kọ ìwé Ìdárò. Nígbà yẹn, ohun kan tó dùn ún dọ́kàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni. Àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ ìlú rẹ̀ tó fẹ́ràn run. Wòlíì tí ìbànújẹ́ ńlá bá yìí mọ̀ pé àjálù tó dé bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn jẹ́ ìdájọ́ tó tọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àmọ́ ǹjẹ́ Jeremáyà ní ìrètí kankan? Ǹjẹ́ ó ń ṣe é bíi pé Jèhófà ti jìnnà jù tàbí pé ó ta kété sí àwọn débi pé kò ní rí àwọn tó ronú pìwà dà kó sì dá wọn sílẹ̀ nínú ipò àìnírètí tí wọ́n wà? Gbọ́ ohun tí Jeremáyà sọ bó ṣe ń gbẹnu sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbànújẹ́ dorí wọn kodò, Jeremáyà ní ìrètí tó dájú. Ó ké pe Jèhófà pé: “Láìkùnà, ọkàn * rẹ [Jèhófà fúnra rẹ̀] yóò rántí, yóò sì tẹ̀ ba mọ́lẹ̀ lórí mi.” (Ẹsẹ 20) Jeremáyà kò ṣiyè méjì nípa ọ̀rọ̀ náà rárá. Ó mọ̀ pé Jèhófà kò ní gbàgbé òun àti àwọn èèyàn Ọlọ́run tó bá ronú pìwà dà. Kí ni Ọlọ́run Olódùmarè wá ṣe?—Ìṣípayá 15:3.

Ó dá Jeremáyà lójú pé Jèhófà máa “tẹ̀ ba mọ́lẹ̀” lórí àwọn èèyàn tó bá ronú pìwà dà. Ìtúmọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Jọ̀wọ́ rántí, kó o sì bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi.” Gbólóhùn yìí jẹ́ ká lè máa fojú inú wo Jèhófà pé ó jẹ́ Ọlọ́run aláàánú. Jèhófà tó jẹ́ “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé” yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, láti gbé àwọn tó ń sìn ín kúrò ní ipò ìrẹ̀sílẹ̀ tí wọ́n wà, á sì mú kí wọ́n pa dà rí ojú rere òun. (Sáàmù 83:18) Ìrètí tí Jeremáyà ní yìí tù ú nínú gan-an lákòókò tí ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́ yẹn. Wòlíì olóòótọ́ yìí ti pinnu láti fi sùúrù dúró de àkókó tí Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn Ọlọ́run tó ronú pìwà dà nídè.—Ẹsẹ 21.

Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà kọ sílẹ̀ yìí kọ́ wa ní ohun méjì nípa Jèhófà. Àkọ́kọ́ ni pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Sáàmù 18:35) Lóòótọ́, ẹni tí “ó ga ní agbára” ni, ó ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, láti ràn wá lọ́wọ́ tí a bá wà nínú ìbànújẹ́. (Jóòbù 37:23; Sáàmù 113:5-7) Ǹjẹ́ èyí kò tù wá nínú gan-an? Ìkejì, Jèhófà jẹ́ aláàánú; ó ‘ṣe tán láti dárí ji’ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà, kó sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n pa dà. (Sáàmù 86:5) Ìwà rẹ̀ méjèèjì yìí, ìyẹn ìrẹ̀lẹ̀ àti àánú, jọ ń bá ara wọn rìn ni.

A mà dúpẹ́ gan-an o, pé Jèhófà kò dà bí àwọn alákòóso èèyàn tí ìgbéraga máa ń mú kí wọ́n ya ọlọ́kàn lílé àti aláìláàánú! Ǹjẹ́ kò wù ọ́ láti mọ̀ sí i nípa irú Ọlọ́run onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó máa ń fẹ́ láti “bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti gbé àwọn tó ń sìn ín kúrò nínú ipò àìnírètí tí wọ́n wà kó sọ wọ́n dẹni tó nírètí?

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún June:

Jeremáyà 51Ìsíkíẹ́lì 5

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àwọn akọ̀wé kan ní ayé ìgbàanì yí ẹsẹ yìí sí “ọkàn mi,” bíi pé Jeremáyà ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí. Ṣe ni wọ́n gbà pé ó máa bu Ọlọ́run kù tí a bá sọ pé ó jẹ́ ọkàn, torí ọ̀rọ̀ yẹn ni Bíbélì máa ń lò fún àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí inú ayé. Àmọ́ Bíbélì sábà máa ń fi ohun tó jẹ mọ́ àwa èèyàn júwe Ọlọ́run kí ohun tó ń sọ lè tètè yé wa. Ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” lè túmọ̀ sí “ìwàláàyè wa,” nítorí náà, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn rẹ” túmọ̀ sí “ìwọ” fúnra rẹ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Jèhófà ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, láti ràn wá lọ́wọ́ tí a bá wà nínú ìbànújẹ́