Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wàásù Láti Ilé Dé Ilé?

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wàásù Láti Ilé Dé Ilé?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wàásù Láti Ilé Dé Ilé?

▪ Nínú Bíbélì, a rí àṣẹ kan tí Jésù pa fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn.” (Mátíù 28:19, 20) Ǹjẹ́ gbogbo Kristẹni ni àṣẹ yìí kàn? Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù láyé àtijọ́ mọ̀ pé gbogbo Kristẹni ló kàn. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ó [Jésù] pa àṣẹ ìtọ́ni fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 10:42) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!”—1 Kọ́ríńtì 9:16.

Kì í ṣe Pọ́ọ̀lù àti Pétérù nìkan ló ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù, gbogbo àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lápapọ̀ ló ń pa àṣẹ Jésù yẹn mọ́. Iṣẹ́ ìwàásù ló gba iwájú nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. (Ìṣe 5:28-32, 41, 42) Ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ń gbìyànjú láti ṣe lónìí nìyẹn. “Ìjọba ọ̀run” tí Jésù ń wàásù fún àwọn èèyàn ni àwọn náà ń wàásù rẹ̀.—Mátíù 10:7.

Àwọn wo ló yẹ kí wọ́n máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run yìí fún? Jésù fi hàn pé gbogbo èèyàn ni kí wọ́n máa wàásù rẹ̀ fún níbi gbogbo. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ó tiẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé kí òpin ètò nǹkan yìí tó dé, ‘a ó wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí.’ (Mátíù 24:14) Àṣẹ yìí ni àwọn Kristẹni ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń tẹ̀ lé, tó fi jẹ́ pé kì í ṣe kìkì àwọn ojúlùmọ̀ wọn tàbí àwọn tí kò ní ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe nìkan ni wọ́n ń wàásù fún, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti wàásù fún gbogbo èèyàn. (Kólósè 1:23; 1 Tímótì 2:3, 4) Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ń gbìyànjú láti rí i pé wọ́n wàásù dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn. *

Ọ̀nà wo ló dára jù láti gbà máa tan ìhìn Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀? Jésù tó mọ ọ̀nà tó dára jù láti gbà tan ìhìn náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ gan-an rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú ńlá, àwọn abúlé àti ilé àwọn èèyàn. (Mátíù 10:7, 11, 12) Lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá a nìṣó láti máa wàásù “láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 5:42) Àwọn náà sì máa ń wàásù níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀, bíi ti Jésù. (Jòhánù 4:7-26; 18:20; Ìṣe 17:17) Lónìí, àwọn ọ̀nà yìí kan náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà wàásù fún gbogbo èèyàn.

Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa tẹ́tí sí ìwàásù yìí. (Mátíù 10:14; 24:37-39) Ṣé ó wá yẹ kí ìyẹn mú kí àwa Kristẹni ṣíwọ́ iṣẹ́ ìwàásù? Wo àfiwé yìí ná: Ká sọ pé o wà lára àwọn kan tó fẹ́ yọ àwọn èèyàn níbi tí jàǹbá omíyalé ti ṣẹlẹ̀, ṣé wàá ṣíwọ́ wíwá àwọn èèyàn torí pé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí ẹ ti ń gbìyànjú, ìwọ̀nba èèyàn mélòó kan lẹ rí fà yọ? Ó tì o. Ṣe ni wàá tẹra mọ́ ọn, bí o bá mọ̀ pé ó ṣì ṣeé ṣe láti rí èèyàn fà jáde kí wọ́n tó kú. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa fara dà á nìṣó níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ṣì nírètí pé wọ́n máa rí àwọn èèyàn tó máa fetí sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 10:23; 1 Tímótì 4:16) Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ láti ilé dé ilé, ṣe ni wọ́n fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ọmọnìkejì wọn tó jẹ́ pé gbígbọ́ tí wọ́n bá gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run yẹn tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́, ló máa jẹ́ kí wọ́n rí ìgbàlà.—Mátíù 22:37-39; 2 Tẹsalóníkà 1:8.

Ìhìn rere yẹn láti inú Bíbélì ni ìwé ìròyìn tí ò ń kà lọ́wọ́ yìí ń sọ. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, jọ̀wọ́ béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n bá tún wá sí ọ̀dọ̀ rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tó tẹ ìwé yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ní ilẹ̀ igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236]. Lọ́dún tó kọjá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lo wákàtí tí ó tó bílíọ̀nù kan àti mílíọ̀nù méje lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì kọ́ àwọn èèyàn tí ó tó mílíọ̀nù mẹ́jọ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ẹ̀kọ́ Bíbélì.