Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkókò Ìsinmi Tí Mo Gbádùn Jù!

Àkókò Ìsinmi Tí Mo Gbádùn Jù!

Lẹ́tà Kan Láti Orílẹ̀-èdè Ireland

Àkókò Ìsinmi Tí Mo Gbádùn Jù!

ÀWỌN òbí mi sọ fún mi pé: “Ó yẹ kó o wá nǹkan kan ṣe tí wàá fi lè túra ká, kó o yéé dààmú nípa ìdánwò tó o fẹ́ ṣe. Jẹ́ ká lọ kí ọmọ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àti ọkọ rẹ̀ tó wà ní ilẹ̀ Ireland, kí á bá wọn lọ wàásù fún àwọn tí kì í sábà rẹ́ni wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn.”

Ní tèmi, èmi ò rò pé ìyẹn ló kàn lọ́wọ́ ti mo wà yẹn. Yàtọ̀ sí pé àyà mi ń já nípa ìdánwò ti mo ń gbára dì fún lọ́wọ́, àyà mi tún ń já pé mi ò tíì rìnrìn àjò kúrò ní orílẹ̀-èdè England rí, mi ò sì tíì wọ ọkọ̀ òfuurufú rí. Báwo tiẹ̀ ni ìgbé ayé tẹ̀-ẹ́-jẹ́jẹ́ táwọn èèyàn ń gbé ní ìlú kékeré kan tó wà ní ìpẹ̀kun gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Ireland kò ṣe ní sú èmi ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún tí ara rẹ̀ yá gágá, tí mo sì ń gbé láàárín ìgboro ìlú London tí gbogbo èèyàn tí ń ṣe nǹkan ní kánmọ́kánmọ́?

Àṣé kò yẹ kí n tiẹ̀ yọ ara mi lẹ́nu. Torí pé gbàrà tí ọkọ̀ òfuurufú wa ti balẹ̀ lọ́hùn-ún ni ibẹ̀ ti di àrímáleèlọ fún mi. Àmọ́, nítorí pé ìdájí la bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa níbẹ̀, ṣe ni mo sùn lọ nínú mọ́tò. Bí mo ṣe ń ta jí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo ń rí àwọn gegele àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹlẹ́wà tó wà káàkiri bí a ṣe ń lọ láwọn ojú ọ̀nà tóóró tí wọ́n fi òkúta mọ ògiri tí kò ga sí ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì.

Ní alẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́, a dé sí ìlú Skibbereen. Àwa àti ìdílé kan tó wá sí orílẹ̀-èdè Ireland láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọ́run sì jọ gbádùn alẹ́ alárinrin, tó gbéni ró gan-an. A ṣe eré kan téèyàn ti máa ń fi ara ṣàpèjúwe àwọn èèyàn inú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wa ń mú orúkọ ọ̀kan lára àwọn èèyàn inú Bíbélì, èyí tí wọ́n kọ sí àwọn ìwé pélébé tí wọ́n sì kó sínú àpò kan. Ẹni tó mú orúkọ náà yóò wá fi ara ṣàpèjúwe ohun kan tí ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn ṣe nínú ìtàn Bíbélì. Àwa yòókù á gbìyànjú láti dárúkọ ẹni tó ṣe nǹkan ọ̀hún.

Lọ́jọ́ kejì, èmi, àwọn òbí mi, àbúrò mi ọkùnrin, ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá mi obìnrin àti ọkọ rẹ̀, pẹ̀lú ìdílé kan wọ ọkọ̀ ojú omi ńlá kan lọ sí erékùṣù kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Heir Island. Àwọn èèyàn tó ń gbé ibẹ̀ kò tó ọgbọ̀n [30]. Ohun tí Jésù ṣáà sọ ni pé a gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé pátá. Nítorí náà, a fi ọjọ́ yẹn wàásù fún àwọn èèyàn yìí, tí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́, tí ara wọn sì yọ̀ mọ́ni, a sì tún wo bí ilẹ̀ erékùṣù ẹlẹ́wà náà tí àwọn èèyàn kò tíì sọ dìbàjẹ́, ṣe dára tó.

Oòrùn ń ràn rekete lójú òfuurufú aláwọ̀ búlúù. Òórùn dídùn láti ara òdòdó àwọn ewéko gorse aláwọ̀ pupa, tó ń rùn bí àgbọn, ń ta sánsán ní gbogbo ibẹ̀. Onírúurú òdòdó ìgbà ìrúwé sì bo ojú ilẹ̀ irà tó wà láàárín erékùṣù náà. Àwọn àpáta gàǹgà tí àwọn ẹyẹ àgò àti ẹyẹ gannet ṣe ìtẹ́ wọn sí tàwọn ti ọmọ wọn, wà lẹ́bàá etíkun oníyanrìn tó wà níbẹ̀. Àgbájọ àwọn erékùṣù kéékèèké kan tí wọ́n ń pè ní Roaringwater Bay kàn pọ̀ lọ súà níbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọn kò sì ní olùgbé. Ìyanu ńlá ló jẹ́ fún wa láti rí bí nǹkan ṣe ń lọ létòlétò láàárín àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà tó wà níhìn-ín!

Inú mi dùn gan-an pé mo tún wá ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Skibbereen, mo sì tún gbìyànjú láti ṣe àwọn nǹkan míì tí mi ò ṣe rí. Nǹkan tuntun tí mo ṣe tó dùn mọ́ mi jù ni wíwa ọkọ̀ olóbèlè àrà ọ̀tọ̀ kan lójú omi. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tó dáa tó kéèyàn wà nínú irú ọkọ̀ olóbèlè àrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀, kó máa wo bí àwọn etíkun ilẹ̀ Ireland ṣe rí láti ojú omi! A gbéra pé ká lọ pẹja tá a máa fi jẹ oúnjẹ alẹ́, àmọ́ àwọn kìnnìún òkun tó dé bá wa níbẹ̀ ń yára pa àwọn ẹja náà ṣáájú wa. Kódà a dá àwọn eré ìdárayá kan sílẹ̀ fún ara wa létíkun níbẹ̀, mo tiẹ̀ gbìyànjú láti jó ijó àwọn ará ilẹ̀ Ireland.

A tún wá àyè láti kọ́ àwọn nǹkan díẹ̀ nípa ìlú Skibbereen. Lára ohun tá a kọ́ ni pé nígbà tí irúgbìn ànàmọ́ ilẹ̀ Ireland kò fi bẹ́ẹ̀ méso jáde láàárín ọdún 1840 sí 1849, ìlú Skibbereen àti àgbègbè rẹ̀ wà lára àwọn ibi tí ìyà jẹ jù. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni ebi pa kú, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] lára wọn ni wọ́n sì sin pa pọ̀ sójú kan náà. Ìtùnú gidi ló jẹ́ fún wa bí a ṣe mọ̀ pé láìpẹ́, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, kò ní sí ìyàn mọ́ àti pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí ebi pa kú bẹ́ẹ̀ yóò jíǹde sí ìyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

Àwa àti àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ lọ wàásù fún àwọn tí wọn kì í sábà lè wàásù dé ọ̀dọ̀ wọn, torí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn pọ̀. A wa ọkọ̀ gba ojú ọ̀nà tóóró kan tó da fíríì lọ síbi tí àwọn ilé kan wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta gàǹgà kan tó wà létí òkun Irish Sea. Nígbà tí a débẹ̀, àwọn èèyàn tá a tún rí níbẹ̀ náà jẹ́ ọ̀làwọ́, ara wọn sì yọ̀ mọ́ni. Bá a ti ṣe ní erékúṣù Heir náà la tún ṣe níbí, a sọ fún wọn pé a wà ní àkókò ìsinmi ni àmọ́ a fẹ́ lò lára àkókò náà láti sọ ìròyìn ayọ̀ fún wọn láti inú Bíbélì.

Màmá mi wàásù fún obìnrin kan tó fi ìdùnnú gba àwọn ìwé ìròyìn wa, ìyẹn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, a tún bá obìnrin náà pàdé, ó sì sọ fún wa pé òun gbádùn ohun tí òun kà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà.

Ó wá rọ̀ wá pé: “Ẹ pa dà wá kí ẹ tún wá bá mi sọ̀rọ̀ o, kí ẹ sì tún bá mi kó àwọn ìwé ìròyìn dání.” A sọ fún un pé a ti fẹ́ pa dà sí ìlú wa àti pé a máa sọ pé kí ẹlòmíì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

Obìnrin náà wá fèsì pé: “Kò burú, àmọ́ ìgbàkigbà tẹ́ ẹ bá pa dà wá síbí, ẹ jọ̀ọ́, ẹ dé ọ̀dọ̀ mi. Àwa èèyàn ilẹ̀ Ireland kì í tètè gbàgbé èèyàn o!”

Ní ọjọ́ tá a lò kẹ́yìn níbẹ̀, àwa àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà ní ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú náà jọ ṣeré lọ sí etíkun. A fi àwọn òkúta etí odò ṣe ààrò a sì fi àwọn igi tí omi gbé wá sí etí odò dáná nínú rẹ̀ láti se àwọn òkòtó òkun tá a pa nínú omi òkun tó mọ́ nigín-nigín yẹn. Èmi ọmọbìnrin tí kò jáde láàárín ìgboro ìlú ńlá rí yìí sì gbádùn gbogbo rẹ̀ dọ́ba!

Kí wá ni mo rò nípa àkókò ìsinmi tí mo lò ní ilẹ̀ Ireland yìí? Òun ni àkókò ìsinmi tí mo tíì gbádùn jù! Yàtọ̀ sí pé mo gbádùn ara mi dọ́ba níbẹ̀, inú mi tún dùn gan-an pé mo fi àkókò yẹn ṣe ohun tó múnú Jèhófà dùn tó sì tún gbé orúkọ rẹ̀ ga. Mo fẹ́ràn láti máa sin Ọlọ́run wa, téèyàn bá sì tún ní àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé àtàtà tí àwọn náà ní irú èrò bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì ń tini lẹ́yìn, orísun ayọ̀ ńlá ni ìyẹn máa jẹ́ fúnni. Nígbà tí mo délé, ṣe ni mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó fún mi ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí wọ́n fẹ́ràn ìjọsìn Ọlọ́run bẹ́ẹ̀, títí ayé ni màá sì máa rántí àkókò alárinrin tí mo gbádùn yẹn.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

An Post, Ireland