Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àṣírí” Tí A Kọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́

“Àṣírí” Tí A Kọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́

Ìtàn Ìgbésí Ayé

“Àṣírí” Tí A Kọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́

Gẹ́gẹ́ bí Olivier Randriamora ṣe sọ ọ́

“Ní tòótọ́, mo mọ bí a ṣe ń wà pẹ̀lú àwọn ìpèsè bín-ín-tín, ní tòótọ́ mo mọ bí a ṣe ń ní ọ̀pọ̀ yanturu. Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi . . . Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílí. 4:12, 13.

TIPẸ́TIPẸ́ ni ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yìí ti máa ń fún èmi àti Oly ìyàwó mi ní ìṣírí ńláǹlà. A ti kọ́ “àṣírí” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí, a gbára lé Jèhófà pátápátá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa ní orílẹ̀-èdè Madagásíkà.

Lọ́dún 1982 nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ màmá Oly lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èmi àti Oly ti gbà pé a jọ máa ṣe ìgbéyàwó. Èmi náà gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, Oly náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 1983, a ṣe ìrìbọmi ní ọdún 1985, kété lẹ́yìn náà la bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ní oṣù July ọdún 1986, a di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Ní oṣù September ọdún 1987, a di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ìlú kékeré kan tó wà ní àríwá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Madagásíkà ni wọ́n kọ́kọ́ rán wa lọ, kò sì sí ìjọ kankan níbẹ̀. Nǹkan bí ẹ̀yà pàtàkì méjìdínlógún [18] pẹ̀lú àìmọye agbo ìdílé ló wà ní orílẹ̀-èdè Madagásíkà, àṣà ìbílẹ̀ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn tó wà níbẹ̀ sì yàtọ̀ síra. Èdè Malagasy ni èdè àjùmọ̀lò wọn, àmọ́ àwọn èdè ìbílẹ̀ kan wà tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ń sọ. Torí náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, èyí sì mú kí àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ túbọ̀ fẹ́ láti tẹ́wọ́ gbà wá.

Nígbà tá a kọ́kọ́ débẹ̀, èmi ni mo máa ń sọ àsọyé ní gbogbo ọjọ́ Sunday, ti Oly sì ni pé kó pàtẹ́wọ́. Àwa méjèèjì nìkan la máa ń wà níbẹ̀. Gbogbo apá ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run la máa ń ṣe, Oly á sì ṣe bí ẹni tó ń bá onílé kan tó jókòó sọ̀rọ̀ nígbà tó bá ń ṣe àṣefihàn. Ìtùnú ńlá ló jẹ́ fún wa nígbà tí alábòójútó àyíká tó wá bẹ̀ wá wò dábàá pé ká yí ọ̀nà tí a gbà ń ṣèpàdé pa dà!

Torí pé ètò ìfìwéránṣẹ́ kò láyọ̀lé, a kì í rí owó ìtìlẹ́yìn wa gbà déédéé. Torí náà, a kọ́ bí èèyàn ṣe ń wà pẹ̀lú àwọn ìpèsè bín-ń-tín. Ìgbà kan wà tí a kò rí owó tó pọ̀ tó tá a máa fi wọkọ̀ lọ sí àpéjọ àyíká, ibẹ̀ sì jìnnà tó àádóje [130] kìlómítà sí ibi tá a wà. A rántí ìmọ̀ràn dáradára tí Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa kan fún wa tó sọ pé: “Ẹ sọ àwọn ìṣòro yín fún Jèhófà. Ó ṣe tán, iṣẹ́ rẹ̀ lẹ̀ ń ṣe.” Nítorí náà, a gbàdúrà a sì pinnu pé a máa fi ẹsẹ̀ rìn. Àmọ́ nígbà tó kù díẹ̀ ká gbéra, arákùnrin kan wá kí wa láìròtẹ́lẹ̀, ó sì fún wa ní ẹ̀bùn owó. Iye tó fún wa yẹn gan-an la sì nílò fún owó ọkọ̀!

IṢẸ́ ÌSÌN ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ

Ní oṣù February, ọdún 1991, wọ́n yàn mí láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Nígbà yẹn, àwọn tó wà ní àwùjọ wa ti di mẹ́sàn-án, àwọn mẹ́ta ti ṣe ìrìbọmi, iye àwa tá a sábà máa ń pé jọ sí ìpàdé jẹ́ àádọ́ta [50]. Lẹ́yìn tá a gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, a lọ sìn ní àyíká kan tó wà ní Antananarivo, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Madagásíkà. Ní ọdún 1993 wọ́n rán wa lọ sí àyíká kan tó wà ní apá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Madagásíkà. Ipò nǹkan yàtọ̀ níbẹ̀ pátápátá sí bó ṣe rí ní ìgboro.

Tá a bá fẹ́ lọ ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ àti àwọn àwùjọ tó wà ní àdádó, ẹsẹ̀ la fi ń rìn. Nígbà míì, a máa ń rin ìrìn tó tó kìlómítà márùnlélógóje [145] nínú igbó kìjikìji láàárín àwọn òkè ńláńlá. A kì í di ẹrù púpọ̀. Àmọ́ ṣá o, ẹrù wa máa ń wúwo sí i, nígbàkigbà tí àsọyé tí mo fẹ́ sọ bá ní àwòrán ara ògiri nínú, gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí nígbà míì lákòókò yẹn. Oly á gbé ẹ̀rọ tó ń gbé àwòrán yọ, èmi á sì gbé bátìrì ọkọ̀ tá a máa ń lò dípò iná mànàmáná.

A sábà máa ń rin ìrìn tó tó ogójì [40] kìlómítà lójúmọ́ ká tó lè dé ìjọ tó kàn tá a fẹ́ bẹ̀ wò. A máa ń gba orí àwọn òkè ńlá kọjá, a máa ń la àwọn odò kọjá, a sì máa ń rìn gba inú ẹrọ̀fọ̀. Ìgbà míì wà tá a máa ń sùn sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, àmọ́ a sábà máa ń wá abúlé tá a ti lè rí ibì kan sùn. Nígbà míì, a máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tí a kò mọ̀ rí pé kí wọ́n jẹ́ ká sùn mọ́jú lọ́dọ̀ wọn. Lẹ́yìn tá a bá ti rí ibi tá a máa sùn, a ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bá a ṣe máa jẹun. Oly á wá ìkòkò kan yá láti fi se oúnjẹ, á sì tún lọ sí odò tó bá wà nítòsí láti lọ pọn omi. Bó ti ń ṣe gbogbo ìyẹn lọ́wọ́, èmi á lọ wá àáké kan yá láti fi la igi tá a máa fi dáná. Ká tó ṣe gbogbo èyí tán, ọjọ́ á ti lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ra adìyẹ kan, a ó pa á, a ó sì sè é.

Lẹ́yìn tá a bá ti jẹun tán, a máa lọ pọn omi tá a máa fi wẹ̀. Ìgbà míì wà tá a máa ń sùn sí ilé ìdáná. Àmọ́ tí òjò bá ń rọ̀, kí ara wa má bàa tutù nítorí òrùlé tó ń jò, ńṣe la máa ń fara ti ògiri, bá a sì ṣe máa sùn nìyẹn.

A kò lè ṣe ká má wàásù fún àwọn tó gbà wá sílé. Nígbà tí a bá dé ibi tí à ń lọ, bí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe máa ń fi inú rere hàn sí wa tí wọ́n sì máa ń ṣe wá lálejò máa ń wú wa lórí. Ìmọrírì àtọkànwá tí wọ́n ní fún ìbẹ̀wò wa máa ń jẹ́ ká gbàgbé gbogbo ìnira tí a ti kojú lójú ọ̀nà.

Tá a bá dé sí ilé àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwa, a máa ń gbádùn bíbá wọn ṣe iṣẹ́ ilé. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n ráyè bá wa jáde òde ẹ̀rí. A kì í retí láti wà ní gbẹdẹmukẹ tàbí pé kí wọ́n máa fún wa ní àwọn oúnjẹ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ èyí tí apá àwọn tó gbà wá lálejò kò ká.

ṢÍṢE ÌBẸ̀WÒ SÍ ÀWỌN ÀWÙJỌ TÓ WÀ NÍ ÀDÁDÓ

A máa ń gbádùn ṣíṣe ìbẹ̀wò sí àwọn àwùjọ tó wà ní àdádó, àwọn ará tí wọ́n wà níbẹ̀ ti máa ń ṣètò ìgbòkègbodò lóríṣiríṣi dè wá. A kì í sábà ráyè “sinmi díẹ̀.” (Máàkù 6:31) Ibì kan wà tí tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan ti ké sí gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn tí wọ́n tó ogójì [40] pé kí wọ́n wá sí ilé àwọn, ká lè jọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn. Oly àti ìyàwó arákùnrin náà jọ darí ogún ìkẹ́kọ̀ọ́, èmi àti arákùnrin náà sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ogún èèyàn tó ṣẹ́ kù. Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe ń lọ ni òmíràn ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tirẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Nígbà tó yá, a dúró díẹ̀ ká bàa lè ṣe ìpàdé lọ́jọ́ náà, lẹ́yìn ìyẹn a tún pa dà sẹ́nu àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó tó aago mẹ́jọ alẹ́ ká tó lè parí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a bẹ̀rẹ̀ láti àárọ̀!

Nígbà tá a lọ ṣèbẹ̀wò sí àwùjọ míì, gbogbo wa forí lé abúlé kan tó wà ní àyíká ibẹ̀, nǹkan bí aago mẹ́jọ àárọ̀ la gbéra. Aṣọ tó ti gbó ni gbogbo wa wọ̀. Lẹ́yìn tá a ti rin ọ̀nà jíjìn nínú igbó, a dé ìpínlẹ̀ ìwàásù náà ní nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán. A pààrọ̀ àwọn aṣọ wa, a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́ àwọn ilé tó wà níbẹ̀ kò tó nǹkan, àwa akéde tó wá sì pọ̀. Èyí mú ká parí gbogbo ìpínlẹ̀ ìwàásù náà láàárín nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú. Lẹ́yìn náà, a lọ sí abúlé tó kàn. Nígbà tá a ṣe tán níbẹ̀, a fi ẹsẹ̀ rin ọ̀nà jíjìn pa dà sílé. Ní ìbẹ̀rẹ̀, ọ̀nà tí a ń gbà wàásù yìí máa ń mú ká rẹ̀wẹ̀sì díẹ̀. Ìdí ni pé a ti máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun wa ká tó dé ibi tá a ti máa wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ nǹkan bí wákàtí kan péré la máa fi wàásù níbẹ̀. Láìka gbogbo èyí sí, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àdúgbò yẹn kò ṣàròyé. Wọ́n ń bá a nìṣó láti jẹ́ onítara.

Àwùjọ àdádó kan tó wà ní Taviranambo kò jìnnà sí orí òkè kan. Nígbà tí a dé ibẹ̀, a rí ìdílé Ẹlẹ́rìí kan tó ń gbé nínú ilé oníyàrá kan. Inú ilé kékeré kan tó wà nítòsí ni wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ṣàdédé la gbọ́ tí arákùnrin tó gbà wá sílé ń nahùn pe àwọn èèyàn, ó ní: “Ẹ̀yin ará!” Ẹnì kan dáhùn láti orí òkè tó wà lódì kejì pé, “Òóò!” Arákùnrin náà wá sọ pé, “Alábòójútó àyíká ti dé o!” A sì tún gbọ́ ìdáhùn pé, “A ti gbọ́ o!” Àwọn ará wọ̀nyẹn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn tí wọ́n ń gbé ní àwọn ibi tó tún jìnnà gan-an. Láìpẹ́, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í dé, a sì bẹ̀rẹ̀ ìpàdé, àwọn èèyàn tó wá lé ní ọgọ́rùn-ún [100].

KÒ RỌRÙN LÁTI RIN ÌRÌN ÀJÒ

Ní ọdún 1996, wọ́n tún rán wa lọ sí àyíká kan tó túbọ̀ sún mọ́ ìlú Antananarivo ní àárín gbùngbùn àwọn ilẹ̀ olókè. A tún dojú kọ àwọn ìṣòro míì tó yàtọ̀ ní àyíká yìí. Kò sí ọkọ̀ tó ń ná àwọn abúlé tó jìnnà sí ìgboro déédéé. A ti ṣètò láti bẹ àwùjọ kan tó wà ní Beankàna (ìyẹn Besakay) wò, ibẹ̀ jìnnà tó nǹkan bí òjìlérúgba [240] kìlómítà sí ìlú Antananarivo. Lẹ́yìn tá a bá ẹni tó ń wa ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan tó ń lọ sí ọ̀nà ibẹ̀ dúnàádúrà, ó gbà kí a wọlé. Àwọn èrò míì tó wà nínú ọkọ̀ náà jẹ́ ọgbọ̀n [30], àwọn kan dùbúlẹ̀ sórí ọkọ̀, àwọn kan sì rọ̀ mọ́ ọkọ̀ náà lẹ́yìn.

Bó ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, kò pẹ́ tí ọkọ̀ náà fi ta kú, a sì ń fi ẹsẹ̀ rìn nìṣó. Lẹ́yìn tá a ti rọra ń rìn lọ fún wákàtí mélòó kan, ọkọ̀ akẹ́rù ńlá kan bá wa lọ́nà. Èrò àti ẹrù ti kún inú rẹ̀ fọ́fọ́, síbẹ̀ awakọ̀ náà dúró. A wọ inú ọkọ̀ náà, àmọ́ ńṣe la dúró torí pé a kò ríbi jókòó sí. Nígbà tó yá, ọkọ̀ wa dé ibi odò kan, àmọ́ wọ́n ń ṣe àtúnṣe afárá tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a tún fi ẹsẹ̀ rìn títí tá a fi dé abúlé kékeré kan tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan ń gbé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kọ́ la fẹ́ lọ bẹ̀ wò, síbẹ̀ a máa ń bá wọn jáde òde ẹ̀rí ní gbogbo àsìkò tá a fi dúró sọ́dọ̀ wọn títí tí iṣẹ́ afárá náà fi parí tá a sì tún wá ọkọ̀ míì tó máa gbé wa.

Odindi ọ̀sẹ̀ kan la fi dúró kí ọkọ̀ kan tó kọjá, òun la wọ̀ ká lè máa bá ìrìn-àjò wa lọ. Ọ̀pọ̀ kòtò ńlá ló wà lójú ọ̀nà náà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ní láti ti ọkọ̀ náà gba inú omi tó mù wá dé orúnkún, a máa ń fẹsẹ̀ kọ, a sì máa ń ṣubú. Nígbà tó di ìdájí, a dé abúlé kékeré kan a sì sọ̀ kalẹ̀ níbẹ̀. A wá yà kúrò ní ojú ọ̀nà, a sì fi ẹsẹ̀ rìn gba inú oko ìrẹsì tí ẹrọ̀fọ̀ ibẹ̀ mù wá dé ìbàdí bá a ṣe ń lọ.

Ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ tá a ṣe sí agbègbè náà nìyẹn, torí náà a pinnu láti wàásù fún àwọn kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní àwọn oko ìrẹsì náà ká sì béèrè ibi tá a ti lè rí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àdúgbò náà lọ́wọ́ wọn. Àmọ́, ẹ wo bí inú wa ti dùn tó láti mọ̀ pé àwọn ará wa ló ń ṣiṣẹ́ nínú oko yẹn!

A GBA ÀWỌN MÍÌ NÍYÀNJÚ LÁTI DI ÒJÍṢẸ́ ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN

Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, a túbọ̀ ń láyọ̀ bá a ṣe ń rí i tí àwọn tá a gbà níyànjú ń di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Nígbà kan tá a ṣe ìbẹ̀wò sí ìjọ kan tó ní aṣáájú-ọ̀nà déédéé mẹ́sàn-án, a gba gbogbo àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà níbẹ̀ níyànjú pé kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ran akéde kan lọ́wọ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tá a lọ bẹ̀ wọ́n wò ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé tó wà níbẹ̀ ti di méjìlélógún [22]. Àwọn arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà méjì kan ti gba àwọn bàbá wọn tí wọ́n jẹ́ alàgbà níyànjú pé kí wọ́n gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àwọn arákùnrin méjèèjì yìí náà gba alàgbà kẹta níyànjú pé kóun náà di aṣáájú-ọ̀nà. Kò pẹ́ tí wọ́n fi yan alàgbà kẹta yìí láti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Nígbà tó yá, òun àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Àwọn alàgbà méjì yòókù ńkọ́? Ọ̀kan ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, ìkejì sì wà lárá àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.

A máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ pé ó ràn wá lọ́wọ́, a mọ̀ pé kò sí àṣeyọrí kankan tá a lè dá ṣe. Lóòótọ́, ìgbà míì wà tó máa ń rẹ̀ wá tá a sì máa ń ṣàìsàn, síbẹ̀ inú wa máa ń dùn nígbà tí a bá ń rí bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣe ń yọrí sí rere. Jèhófà ni ó ń mú kí iṣẹ́ rẹ̀ tẹ̀ síwájú. Inú wa dùn láti ní ìpín kékeré nínú rẹ̀, kódà ní báyìí tí à ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ó dájú pé a ti kọ́ “àṣírí” náà nípa gbígbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “ẹni tí ń fi agbára” fún wa.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

A ti kọ́ “àṣírí” náà nípa gbígbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Orílẹ̀-èdè Madagásíkà, tí wọ́n ń pè ní Big Red Island, ni ìkẹrin nínú àwọn erékùṣù tó tóbi jù lọ láyé. Ilẹ̀ pupa àti oríṣiríṣi ẹranko àti igi tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ló wà níbẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìrìn àjò jẹ́ ọ̀kan lára ìṣòro tó ga jù lọ tá a dojú kọ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

A máa ń gbádùn ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn