Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Ṣí Àwọn Ọba Mẹ́jọ Payá

A Ṣí Àwọn Ọba Mẹ́jọ Payá

A Ṣí Àwọn Ọba Mẹ́jọ Payá

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì àti ìwé Ìṣípayá jẹ́ ká mọ ohun tí àwọn ọba mẹ́jọ tàbí ìṣàkóso àwọn èèyàn jẹ́, wọ́n sì tún sọ bí wọ́n ṣe máa fara hàn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. A máa mọ ohun tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn túmọ̀ sí, tá a bá lóye àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ pàá nínú Bíbélì.

Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń ṣètò irú ọmọ rẹ̀ sí onírúurú ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí àwọn ìjọba. (Lúùkù 4:5, 6) Àmọ́, díẹ̀ lára àwọn ìjọba èèyàn ló tíì ní ipa tó lágbára gan-an lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run, ì báà jẹ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tàbí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. A ṣàpèjúwe mẹ́jọ péré lára irú àwọn ìjọba alágbára bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìran tí Dáníẹ́lì àti Jòhánù rí.

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀

INÚ ÌWÉ DÁNÍẸ́LÌ INÚ ÌWÉ ÌṢÍPAYÁ

1. Íjíbítì

2. Ásíríà

3. Bábílónì

4. Mídíà òun Páṣíà

5. Gíríìsì

6. Róòmù

7. Gẹ̀ẹ́sì àti

Amẹ́ríkà *

8. Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti

Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè *

ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN

Ọdún 2000 Ṣ.S.K.

Ábúráhámù

1500

Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì

1000

Dáníẹ́lì 500

Ṣ.S.K./S.K.

Jòhánù

Ísírẹ́lì Ọlọ́run 500

1000

1500

2000 S.K.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àwọn ọba méjèèjì ló wà ní àkókò òpin. Wo ojú ìwé 19.

^ Àwọn ọba méjèèjì ló wà ní àkókò òpin. Wo ojú ìwé 19.

[Àwòrán]

Ère arabarìbì (Dán. 2:31-45)

Àwọn ẹranko mẹ́rin tí wọ́n jáde wá látinú òkun (Dán. 7:3-8, 17, 25)

Àgbò àti òbúkọ (Dán., orí 8)

Ẹranko ẹhànnà olórí méje (Ìṣí. 13:1-10, 16-18)

Ẹranko oníwo méjì náà ṣagbátẹrù yíyá ère ẹranko ẹhànnà náà (Ìṣí. 13:11-15)

[Àwọn Credit Line]

Ibi tí a ti mú àwọn àwòrán: Íjíbítì àti Róòmù: A ya fọ́tò yìí nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Ibi Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì; Mídíà òun Páṣíà: Musée du Louvre, Paris