Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n Máa Wá “Ìdarí Jíjáfáfá”

Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n Máa Wá “Ìdarí Jíjáfáfá”

Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n Máa Wá “Ìdarí Jíjáfáfá”

Àwọn kan sọ pé ńṣe ni ìgbésí ayé èèyàn dà bí ìrìn àjò orí omi. Àmọ́ ṣá o, gbogbo ìgbà kọ́ ni ọgbọ́n ẹ̀dá máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́sẹ járí. Bí ẹni tí kò mọ̀wẹ̀ ṣe máa ń rì sínú agbami tó ń ru gùdù, bẹ́ẹ̀ ló ṣe ṣòro fún ọ̀pọ̀ láti wẹ òkun ayé já. (Sm. 107:23, 27) Kí nìdí tó fi bá a mu láti fi ìgbésí ayé wé ìrìn àjò orí omi?

Ní ayé àtijọ́, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ atukọ̀ máa ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro lórí òkun èyí sì gba pé kí wọ́n ní ìrírí. Iṣẹ́ ọpọlọ ni, ó sì gba pé kéèyàn kọ́ ọ lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti ń tukọ̀ ojú omi látọjọ́ pípẹ́ tàbí lọ́dọ̀ ẹni tó máa ń wà nídìí àgbá ìtọ́kọ̀. (Ìṣe 27:9-11) Bí ẹni tó máa ń wà nídìí àgbá ìtọ́kọ̀ ṣe máa ń tóbi ju àwọn tó kù lọ nínú ọ̀pọ̀ àwòrán ayé àtijọ́ máa ń fi bí ojúṣe rẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó hàn. Kí àwọn atukọ̀ tó lè rìnrìn-àjò lọ sójú agbami òkun, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa àwọn ìràwọ̀, ẹ̀fúùfù àti àwọn ohun pàtàkì míì tó yẹ kí wọ́n fún láfiyèsí. Bíbélì ṣàpèjúwe àwọn atukọ̀ kan bí “ọ̀jáfáfá,” èyí tó túmọ̀ lóréfèé sì “ọlọ́gbọ́n.”—Ìsík. 27:8, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

Bí àwọn atukọ̀ ojú omi láyé àtijọ́ ṣe máa ń kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe ń kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro nínú ìgbésí ayé lóde òní. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́?

BÁWO LA ṢE LÈ RÍ “ÌDARÍ JÍJÁFÁFÁ”?

A ti rí i báyìí pé àwọn kan fi ìgbésí ayé wé ìrìn àjò ojú omi, bó bá rí bẹ́ẹ̀ ẹ jẹ́ ká ronú lórí òtítọ́ pàtàkì kan tí Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i, ẹni òye sì ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá.” (Òwe 1:5, 6) Ọ̀rọ̀ Hébérù náà tá a túmọ̀ sí “ìdarí jíjáfáfá” lè ṣàpèjúwe àwọn ohun tí ọ̀gá atukọ̀ kan máa ń ṣe láyé àtijọ́. Ó túmọ̀ sí agbára láti pèsè ìtọ́sọ́nà àti ìdarí lọ́nà tó jáfáfá.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsapá, a lè rí “ìdarí jíjáfáfá” ká sì tún kọ́ bí a ṣe lè “tukọ̀” ìgbésí ayé wa dé èbúté ayọ̀ nínú òkun ayé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Òwe ṣe fi hàn, a ní láti jẹ́ kí “ọgbọ́n,” “òye” àti “ìjìnlẹ̀ òye” máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀. (Òwe 1: 2-6; 2: 1-9) A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí wa, torí pé àwọn ẹni burúkú pàápàá lè mọ bí wọ́n á ṣe ‘darí’ èèyàn sí ọ̀nà tí kò tọ́.—Òwe 12:5.

Ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójú méjèèjì. Nípasẹ̀ irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, a lè máa gba ìsọfúnni tó ṣeyebíye nípa Jèhófà àti Jésù Kristi ẹni tó gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ jù lọ. (Jòh. 14:9) A máa ń rí ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n gbà ní àwọn ìpàdé ìjọ. Ní àfikún sí ìyẹn, a tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí àwọn míì, títí kan àwọn òbí wa.—Òwe 23:22.

FOJÚ SỌ́NÀ KÓ O SÌ WÉWÈÉ OHUN TÓ O MÁA ṢE

A nílò “ìdarí jíjáfáfá” gan-an, pàápàá jù lọ nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro. Tí a bá ń ṣiyè méjì nípa ohun tá a máa ṣe nígbà tá a bá dojú kọ ipò kan tó díjú, èyí lè mú kí ọ̀rọ̀ náà tojú sú wa, kí gbogbo nǹkan sì tipa bẹ́ẹ̀ dojú rú.—Ják. 1:5, 6.

Ó tún gbàfiyèsí pé wọ́n lo ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “ìdarí jíjáfáfá” nínú ọ̀ràn ogun jíjà. A kà pé: “Nípasẹ̀ ìdarí jíjáfáfá ni ìwọ yóò fi máa bá ogun rẹ lọ, ìgbàlà sì ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.”—Òwe 20:18; 24:6.

Bí ọ̀jáfáfá kan tó mọ̀ nípa ogun jíjà ṣe máa ń múra sílẹ̀ de ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe máa ń fojú sọ́nà fún àwọn ohun tó lè wu wá léwu nípa tẹ̀mí. (Òwe 22:3) Bí àpẹẹrẹ, ó lè gba pé kó o yàn bóyá wàá gba iṣẹ́ tuntun kan tàbí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́. O ní láti fara balẹ̀ ronú lórí owó tí wọ́n á máa san fún ẹ, àkókò táá máa gbà ẹ́ láti dé ibi iṣẹ́, láti pa dà wálé àti láti ṣe àwọn nǹkan míì. Àmọ́, àwọn ohun mìíràn wà tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Ǹjẹ́ irú iṣẹ́ yìí máa bá àwọn ìlànà Bíbélì mu? Ṣé wákàtí tí màá fi máa ṣe iṣẹ́ àṣegbà kò ní pa àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni mi lára?—Lúùkù 14:28-30.

Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Loretta, ó sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń pèsè oúnjẹ. Nígbà tí wọ́n fẹ́ gbé ilé iṣẹ́ náà lọ sí ibòmíràn, wọ́n fún un ní ipò ńlá kan ní ibi tí wọ́n ń kó lọ, àwọn olùdarí ilé iṣẹ́ náà sọ fún un pé “irú àǹfààní yìí ṣọ̀wọ́n, o sì lè máà rí irú rẹ̀ mọ́ láé.” Wọ́n tún sọ fún un pé: “A ti wádìí, a sì ti rí i pé Gbọ̀ngàn Ìjọba kan wà níbẹ̀.” Àmọ́, Loretta fẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ òun lọ́rùn kó bàa lè ní àkókò púpọ̀ sí i láti sin Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Ó rí i pé ipò tuntun yìí kò ní jẹ́ kí òun ráyè fún àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. Nítorí náà, ó kọ̀wé láti fi iṣẹ́ sílẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé olùdarí ilé iṣẹ́ náà sọ fún un ní bòókẹ́lẹ́ pé òun nìkan ni wọn kò ní dá dúró nínú gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tó wà níbẹ̀. Ó ti tó ogún [20] ọdún báyìí tí Loretta ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ó sì dá a lojú pé ohun tó mú kó rí àwọn àbájáde rere ni pé, ó ṣètò àwọn nǹkan pẹ̀lú “ìdarí jíjáfáfá,” èyí tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó mú kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà lágbára, ó sì láǹfààní láti ran àwọn mélòó kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì.

Ó dájú pé “ìdarí jíjáfáfá” wúlò gan-an nínú ìdílé. Àkókò kékeré kọ́ ló máa ń gbà láti tọ́ àwọn ọmọ, ọwọ́ tí àwọn òbí bá fi mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run àti ojú tí wọ́n fi ń wo àwọn ohun ìní tara sì lè nípa lórí ọjọ́ ọ̀la gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé. (Òwe 22:6) Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni lè bi ara wọn pé: ‘Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti àpẹẹrẹ wa ń kọ́ àwọn ọmọ wa láti sún mọ́ Jèhófà kí wọ́n lè fi ọgbọ́n kojú àwọn ìpèníjà tó bá ń yọjú bí wọ́n ṣe ń dàgbà? Ǹjẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé wa ń ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye bí wọ́n ṣe lè ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun ìní tara, kí wọ́n sì pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn Kristẹni wọn?’—1 Tím. 6: 6-10, 18, 19.

Ojúlówó àṣeyọrí kò dá lórí àwọn nǹkan tara àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tí àwọn èèyàn inú ayé ń lépa. Sólómọ́nì Ọba gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí. Ọlọ́run mí sí i láti sọ pé: “Yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀.” (Oníw. 8:12) Lóòótọ́ ni èyí ń jẹ́rìí sí ọgbọ́n tó wà nínú “ìdarí jíjáfáfá” tí ó dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó sì tún wà ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀.—2 Tím. 3:16, 17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Bí ẹni tó máa ń wà nídìí àgbá ìtọ́kọ̀ ṣe máa ń tóbi ju àwọn tó kù lọ nínú ọ̀pọ̀ àwòrán máa ń fi bí ojúṣe rẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó hàn

[Credit Line]

Su concessione del Ministero per i Beni e le Attività Culturali. A kò gba ẹnikẹ́ni láyè láti tún àwòrán yìí yà tàbí láti ṣe ẹ̀dà rẹ̀ ní ọ̀nà èyíkéyìí tàbí nípa lílo ohun èlò èyíkéyìí.