Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ohun Tí Àwọn Ẹ̀dá Ẹ̀mí Ń Ṣe fún Wa?

Kí Ni Ohun Tí Àwọn Ẹ̀dá Ẹ̀mí Ń Ṣe fún Wa?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kí Ni Ohun Tí Àwọn Ẹ̀dá Ẹ̀mí Ń Ṣe fún Wa?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.

1. Àwọn wo ni àwọn áńgẹ́lì?

Àwọn áńgẹ́lì jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tó ń gbé ní ọ̀run. Ẹ̀dá tiwọn yàtọ̀ pátápátá sí ti àwa èèyàn, wọ́n jù wá lọ gidigidi. Ọlọ́run tòótọ́, tí òun náà jẹ́ ẹ̀mí, ló dá àwọn áńgẹ́lì kí ó tó dá ilẹ̀ ayé wa yìí. (Jóòbù 38:4, 7; Mátíù 18:10) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ yìí ni Jèhófà dá sí ọ̀run ní ibi tó wà.—Ka Sáàmù 103:20, 21; Dáníẹ́lì 7:9, 10.

2. Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì máa ń ranni lọ́wọ́?

Àwọn áńgẹ́lì ran ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. Ọkùnrin yìí ń gbé ní ìlú kan tí Ọlọ́run ti pinnu pé òun máa pa run nítorí ìwà burúkú àwọn èèyàn ibẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì méjì wá láti kìlọ̀ fún Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ pé kí wọ́n sá kúrò ní ìlú náà. Àwọn èèyàn kan ka ìkìlọ̀ rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwàdà, wọn kò sì tẹ̀ le. Àmọ́ Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ là á já torí wọ́n ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún wọn nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì yẹn.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 19:1, 13-17, 26.

Bíbélì fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lónìí nípa bí wọ́n ṣe ń darí àwọn tó ń fi òdodo ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Ìhìn rere yìí ní ìkìlọ̀ nínú. Ṣe ló dà bí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún Lọ́ọ̀tì, kì í ṣe àwàdà rárá. Ọlọ́run ló fi rán àwọn áńgẹ́lì láti máa kéde rẹ̀.—Ka Ìṣípayá 1:1; 14:6, 7.

Ọlọ́run lè lo àwọn áńgẹ́lì láti gbé wa ró nígbà tí a bá wà nínú àdánwò. Ọlọ́run lo áńgẹ́lì kan láti fún Jésù lókun.—Ka Lúùkù 22:41-43.

Láìpẹ́, Ọlọ́run tún máa lo àwọn áńgẹ́lì lọ́nà míì, ìyẹn láti pa àwọn ẹni burúkú tó ń dá wàhálà sílẹ̀, run. Ìyẹn yóò sì mú ìtura ńláǹlà bá aráyé.—Ka 2 Tẹsalóníkà 1:6-8.

3. Kí ni àwọn ẹ̀mí èṣù ń ṣe sí àwọn èèyàn?

Bí ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé ṣe ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, èyí tó jẹ́ ohun tí kò dáa, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ní ọ̀run ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (2 Pétérù 2:4) Àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn ni a ń pè ní ẹ̀mí èṣù. Sátánì Èṣù ni aṣáájú wọn. Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ló ń ṣi aráyé lọ́nà.—Ka Ìṣípayá 12:9.

Sátánì ti lo àwọn ètò ìṣòwò oníwà ìbàjẹ́, ìjọba èèyàn àti ẹ̀sìn èké láti fi ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, kí wọ́n sì kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Torí náà, Sátánì ló fa ìwà ìrẹ́jẹ, ìwà ipá àti ìyà tó ń pọ́n aráyé lójú.—Ka 1 Jòhánù 5:19.

4. Báwo ni àwọn ẹ̀mí èṣù ṣe ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà?

Sátánì ń ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà nípa títan ẹ̀kọ́ èké kálẹ̀ pé àwọn òkú máa ń di ẹni àìrí tó lè fara han àwọn èèyàn kí wọ́n sì máa bá wọn sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn òkú kò lè ṣe ohunkóhun. (Oníwàásù 9:5) Àmọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù sábà máa ń sọ̀rọ̀ bíi ti àwọn èèyàn wa tó ti kú láti lè tanni jẹ. (Aísáyà 8:19) Àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń lo àwọn abókùúsọ̀rọ̀, àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ oríire, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ àti àwọn awòràwọ̀ láti fi ṣi àwọn èèyàn míì lọ́nà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé ká yàgò fún irú gbogbo nǹkan bẹ́ẹ̀. Torí náà, tí a bá ní ohunkóhun tó jẹ mọ́ ti àwọn ẹ̀mí èṣù àti iṣẹ́ òkùnkùn, ṣe ló yẹ ká kó o dà nù.—Ka Diutarónómì 18:10, 11; Ìṣe 19:19.

Tá a bá fẹ́ràn Jèhófà kò sídìí tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí a sì ń ṣe àwọn ohun tí ó sọ, a kọjú ìjà sí Èṣù nìyẹn, a sì wá sún mọ́ Ọlọ́run. Jèhófà lágbára gan-an ju àwọn ẹ̀mí èṣù yẹn lọ. Àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ olóòótọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá á bá nílò ìrànlọ́wọ́.—Ka Sáàmù 34:7; Jákọ́bù 4:7, 8.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 10 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.