Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tí Ọlọ́run Bá Ti Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Jini, Ṣé Ó Máa Ń Gbàgbé Rẹ̀?

Tí Ọlọ́run Bá Ti Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Jini, Ṣé Ó Máa Ń Gbàgbé Rẹ̀?

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Tí Ọlọ́run Bá Ti Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Jini, Ṣé Ó Máa Ń Gbàgbé Rẹ̀?

NÍ KÚKÚRÚ, bẹ́ẹ̀ ni. Ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa àwọn tó ṣe ojú rere sí ni pé: “Èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.” (Jeremáyà 31:34) Jèhófà tipa báyìí jẹ́ kó dá wa lójú pé tí òun bá ti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, òun kì í tún rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. Àmọ́ ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé tí Ẹlẹ́dàá ayé òun ìsálú ọ̀run bá fẹ́ rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dárí jini, kò ní lè rántí wọn mọ́? Ọ̀rọ̀ inú ìwé Ìsíkíẹ́lì jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini tó sì máa ń gbàgbé rẹ̀.—Ka Ìsíkíẹ́lì 18:19-22.

Jèhófà lo wòlíì Ísíkíẹ́lì bí agbọ̀rọ̀sọ láti kéde ìdájọ́ sórí ilẹ̀ Júdà àti ìlú Jerúsálẹ́mù nítorí àìṣòdodo wọn. Ilẹ̀ Júdà lápapọ̀ pa ìjọsìn Jèhófà tì, ìwà ipá sì gbòde kan níbẹ̀. Jèhófà wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ará Bábílónì máa pa ìlú Jerúsálẹ́mù run. Àmọ́ bí Jèhófà ṣe kéde ìdájọ́ sorí wọn yìí, ó tún sọ̀rọ̀ tó fún wọn nírètí. Olúkúlùkù wọn ló ní òmìnira láti yan ohun tó wù ú; kálukú wọn ni yóò sì jíhìn ohun tó bá yàn láti ṣe.—Ẹsẹ 19, 20.

Bí èèyàn bá wá yí pa dà kúrò lọ́nà búburú tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere ńkọ́? Jèhófà sọ pé: “Ní ti ẹni burúkú, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó yí padà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá, tí ó sì pa gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ mi mọ́ ní ti tòótọ́, tí ó sì mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo ṣẹ ní kíkún, dájúdájú, òun yóò máa wà láàyè nìṣó. Òun kì yóò kú.” (Ẹsẹ 21) Jèhófà “ṣe tán láti dárí ji” ẹni tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tó sì yí pa dà kúrò ní ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—Sáàmù 86:5.

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹni náà ti wá dá ńkọ́? Jèhófà sọ pé: “Gbogbo ìrélànàkọjá rẹ̀ tí ó ti ṣe—a kì yóò rántí wọn lòdì sí i.” (Ẹsẹ 22) Kíyè sí i pé Ọlọ́run “kì yóò rántí” ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tó ronú pìwà dà yẹn “lòdì sí i.” Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì?

Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí a tú sí “rántí” ní ìtumọ̀ tó ju pé kéèyàn kàn rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Ohun tí ìwé ìwádìí kan sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí ni pé: “Ká sòótọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, [ó] máa ń túmọ̀ sí pé onítọ̀hún fẹ́ ṣe nǹkan kan nípa ohun tó rántí tàbí kí wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà pa pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ ìṣe tó máa fi hàn pé onítọ̀hún máa gbé ìgbésẹ̀ kan.” Torí náà, “kéèyàn rántí” nǹkan kan lè túmọ̀ sí “kéèyàn gbé ìgbésẹ̀.” Nípa báyìí, nígbà tí Jèhófà sọ nípa ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni òun “kì yóò rántí lòdì sí i,” ohun tó ń sọ ni pé òun kò ní tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ náà gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí ẹni náà, bóyá pé kí òun ka ẹ̀ṣẹ̀ sí onítọ̀hún lọ́rùn tàbí kí òun jẹ ẹ́ níyà. *

Ọ̀rọ̀ inú Ìsíkíẹ́lì 18:21, 22 jẹ́ ká rí bí ìdáríjì Ọlọ́run ṣe máa ń jinlẹ̀ tó. Tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini kò ní ka ẹ̀ṣẹ̀ yẹn sí wa lọ́rùn mọ́ lọ́jọ́ iwájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó ronú pìwà dà sí ẹ̀yìn rẹ̀. (Aísáyà 38:17) Yóò ṣe é lọ́nà táá fi dà bíi pé ó pa àkọsílẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yẹn rẹ́.—Ìṣe 3:19.

Torí pé a jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, a nílò àánú Ọlọ́run. Ó ṣe tán ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máa ń ṣẹ̀. (Róòmù 3:23) Àmọ́ Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé tí a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, òun ṣe tán láti dárí jì wá. Àti pé tó bá ti dárí jini, ó máa ń gbàgbé rẹ̀, ìyẹn ni pé kò ní máa ronú nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà láti lè kà wọ́n sí wa lọ́rùn tàbí láti torí rẹ̀ jẹ wá níyà. Ẹ ò rí i pé ìyẹn tuni nínú gan-an! Ǹjẹ́ àánú tí Ọlọ́run ní yìí kò mú kí ìwọ náà fẹ́ láti sún mọ́ ọn?

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún July:

Ìsíkíẹ́lì 6-20

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Lọ́nà kan náà, “kéèyàn rántí ẹ̀ṣẹ̀” lè túmọ̀ sí “kéèyàn gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí ẹlẹ́ṣẹ̀.”—Jeremáyà 14:10.