Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpàdé Tó Fi Ìṣọ̀kan Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Hàn Tó sì Sọ Nípa Àwọn Ìwéwèé Tó Wúni Lórí

Ìpàdé Tó Fi Ìṣọ̀kan Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Hàn Tó sì Sọ Nípa Àwọn Ìwéwèé Tó Wúni Lórí

Ìròyìn Ìpàdé Ọdọọdún

Ìpàdé Tó Fi Ìṣọ̀kan Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Hàn Tó sì Sọ Nípa Àwọn Ìwéwèé Tó Wúni Lórí

ÀKÓKÒ ìmóríyá àti ìfojúsọ́nà ni ìpàdé ọdọọdún ti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania sábà máa ń jẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn níbi ìpàdé ọdọọdún ìkẹtàdínláàádóje [127] tó wáyé ní ọjọ́ Saturday, October 1, 2011! Àwọn tí wọ́n ké sí láti apá ibi gbogbo lágbàáyé pé jọ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Jersey City, ní ìpínlẹ̀ New Jersey, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Arákùnrin Gerrit Lösch tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀ fún àwùjọ àwọn èèyàn aláyọ̀ náà. Ó sọ fún àwọn tí wọ́n wá sí ìpàdé náà láti orílẹ̀-èdè márùndínláàádọ́rùn-ún [85] pé wọ́n ń gbádùn ìṣọ̀kan àrà ọ̀tọ̀ tó wà láàárín wa kárí ayé. Irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ ń jẹ́rìí fún àwọn èèyàn, ó sì ń fògo fún Jèhófà. Lemọ́lemọ́ ni wọ́n ń mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀kan nínú ìpàdé náà.

ÌRÒYÌN RERE LÁTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ MẸ́SÍKÒ

Apá àkọ́kọ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fi hàn pé àwọn èèyàn Jèhófà wà ní ìṣọ̀kan. Arákùnrin Baltasar Perla fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn mẹ́ta tí wọ́n jọ jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò nípa bí wọ́n ṣe pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì mẹ́fà tó wà ní Amẹ́ríkà Àárín pọ̀ mọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Nítorí èyí, ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Mẹ́síkò ti kún fún àwọn ará tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ṣe ti onírúurú ilẹ̀ wá dara pọ̀ mọ́ wọn yìí ti mú kí wọ́n ní pàṣípààrọ̀ ìṣírí. Ńṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run mú ààlà ilẹ̀ tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè náà kúrò.

Ohun kan tó wá kù báyìí ni bí wọ́n ṣe máa ran àwọn akéde lọ́wọ́ kí wọ́n má ṣe máa rò pé àwọn ti jìnnà sí ètò Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní orílẹ̀-èdè àwọn mọ́. Látàrí èyí, ìṣètò tó fini lọ́kàn balẹ̀ ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan yálà láti kọ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tàbí kí wọ́n rí irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀ gbà láti ẹ̀ka ọ́fíìsì. Kódà, ìṣètò yìí kan àwọn tó wà ní àwọn ibi àdádó pàápàá.

ÌRÒYÌN LÁTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ JAPAN

Arákùnrin James Linton tó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Japan ṣàlàyé bí ìsẹ̀lẹ̀ àti ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ òkun ṣe fa àkúnya omi tó wáyé lórílẹ̀-èdè yẹn ní oṣù March, ọdún 2011. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni àwọn èèyàn wọn kú, tí wọ́n sì tún pàdánù àwọn ohun ìní wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí míì tí wọ́n ń gbé ní àwọn apá ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò dé gba àwọn ará tí àjálù yìí dé bá sínú ilé tó lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún àti ọgọ́rùn-ún [3,100], wọ́n sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìrìnnà fún ìlò wọn. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ṣiṣẹ́ kára láì dáwọ́ dúró láti tún ilé àwọn ará ṣe. Ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700] èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ níbikíbi tí wọ́n bá ti nílò wọn. Àwùjọ àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà yọ̀ǹda ara wọn láti bá wọn tún Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ́, gbogbo àwọn tó ṣe iṣẹ́ náà jẹ́ ọ̀rìn-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó dín márùn-ún [575].

Ohun tá a fún láfiyèsí jù lọ ni bá a ṣe máa ran àwọn tí ọ̀ràn kàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí ká sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Àwọn alàgbà tó lé ní irínwó [400] ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn tó nílò rẹ̀. Bí àwọn méjì lára àwọn alábòójútó láti ilẹ̀ òkèèrè tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí rán láti oríléeṣẹ́ wa ṣe lọ sáwọn ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé kí wọ́n lè fún wọn ní ìṣírí mú kó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ àwọn ará náà jẹ wọ́n lógún. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí kárí ayé ṣe fi hàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kan àwọn náà tu àwọn ará wa yìí nínú gan-an ni.

ILÉ ẸJỌ́ DÁ WA LÁRE

Àwùjọ tó pésẹ̀ sí ìpàdé náà tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí Arákùnrin Stephen Hardy tó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Britain, bó ṣe ń jíròrò nípa bí ilé ẹjọ́ ṣe dá wa láre nínú àwọn ẹjọ́ kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìjọba ilẹ̀ Faransé ní kí àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà san mílíọ̀nù méjìlélọ́gọ́rin owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà gẹ́gẹ́ bí owó orí. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá wa láre, ó sì sọ pé ìjọba ilẹ̀ Faransé ti tẹ òfin tó fàyè gba òmìnira ẹ̀sìn lójú, ìyẹn Abala Kẹsàn-án nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Ìdájọ́ náà fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ owó lásán ni ẹjọ́ náà dá lé lórí, ó kà pé: “Yálà wọ́n kùnà láti fàyè gba àjọ ẹ̀sìn kan ni o, tàbí wọ́n gbìyànjú láti tú u ká, tàbí wọ́n sọ̀rọ̀ àbùkù nípa àjọ ẹ̀sìn kan, àpẹẹrẹ títẹ ẹ̀tọ́ tó wà nínú Abala Kẹsàn-án nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù lójú ni gbogbo ìyẹn jẹ́.”

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù tún dá wa láre nínú ẹjọ́ tó da àwa àti orílẹ̀-èdè Armenia pọ̀. Láti ọdún 1965 ni Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti gbà pé Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù kò ní gbèjà ẹ̀tọ́ ẹni tí wọ́n bá fipá mú wọ iṣẹ́ ológun. Nínú ìdájọ́ tí Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe, ó sọ pé “bí ẹnì kan bá kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí pé ìyẹn ta ko ohun tó gbà gbọ́ gidigidi,” ó yẹ kí Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù lè gbèjà ẹ̀tọ́ rẹ̀. Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ yìí ṣe ló mú kí orílẹ̀-èdè Armenia àtàwọn orílẹ̀-èdè bí Azerbaijan àti Tọ́kì náà gbà láti gbèjà irú ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀.

IṢẸ́ ÌKỌ́LÉ

Arákùnrin Guy Pierce tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ̀rọ̀ tó kàn, ó sọ pé gbogbo àwọn tó pésẹ̀ ló máa fẹ́ gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ New York. Ó fi fídíò kan hàn wọ́n tó ṣàfihàn bí iṣẹ́ ṣe ń lọ sí ní Wallkill, Patterson àti àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà ní ilú Warwick àti Tuxedo ní ìpínlẹ̀ New York. Ní Wallkill, ilé tuntun kan tí wọ́n máa parí lọ́dún 2014 máa ní àwọn yàrá tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300].

Ètò ti wà nílẹ̀ láti kọ́lé sorí ọgọ́rùn-ún hẹ́kítà ilẹ̀ (248 éékà) tó wà ní ìlú Warwick. Arákùnrin Pierce sọ pé, “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ká fi ilẹ̀ tó wà ní Warwick ṣe kò tíì dá wa lójú, à ń bá iṣẹ́ lọ níbẹ̀, a sì lérò pé ibẹ̀ la máa kó oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ tá a bá kó o kúrò ní Brooklyn.” A tún ti ń ṣètò láti lo ogún hẹ́kítà ilẹ̀ (50 éékà) tó wà ní kìlómítà mẹ́wàá sí apá àríwá ìlú Warwick gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n á kó àwọn irinṣẹ́ àti àwọn ohun èlò ìkọ́lé sí. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Gbàrà tí a bá ti gba àṣẹ láti kọ́ ibẹ̀, a nírètí pé a máa parí gbogbo iṣẹ́ náà láàárín ọdún mẹ́rin. Lẹ́yìn náà, a lè ta ibi tá à ń lò ní Brooklyn.”

Arákùnrin Pierce béèrè pé: “Ṣé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ò tún gbà mọ́ pé ìpọ́njú ńlá ti sún mọ́lé ni?” Ó dáhùn pé: “Rárá o.” Ó wá fi kún un pé: “Bí ìpọ́njú ńlá ò bá jẹ́ ká lè parí iṣẹ́ náà, ìyẹn á mà ga o, ohun àgbàyanu ló sì máa jẹ́!”

Ẹ ṢỌ́RA FÚN KÌNNÌÚN TÍ Ń KÉ RAMÚRAMÙ

Arákùnrin Stephen Lett tóun náà jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ̀rọ̀ tó kàn, ó ṣàlàyé 1 Pétérù 5:8 tó sọ pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” Arákùnrin Lett ṣàlàyé pé àwọn ohun mélòó kan tí Pétérù sọ nípa kìnnìún jẹ́ ká rí i pé àpèjúwe tó ṣe nípa Èṣù bá a mu gẹ́lẹ́.

Níwọ̀n bí àwọn kìnnìún ti lágbára tí wọ́n sì yára ju àwa èèyàn lọ, kò yẹ ká gbìyànjú láti bá Sátánì jà tàbí ká rò pé a lè dá borí rẹ̀. A nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. (Aísá. 40:31) Kìnnìún máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ tó bá ń dọdẹ ẹran tó fẹ́ pa jẹ́, torí náà a kò gbọ́dọ̀ wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí níbi tí Sátánì máa ń wá ẹran ọdẹ rẹ̀ lọ. Bí kìnnìún ṣe máa ń pa ẹtu tó jẹ́ ẹranko tí kì í pani lára tàbí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà tó ń sùn, bẹ́ẹ̀ ni Sátánì ṣe máa ń fẹ́ láti pa wá torí pé ọ̀dájú ni. Lẹ́yìn tí kìnnìún bá sì ti jẹun yó tán, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹran ọdẹ rẹ̀ kì í ṣeé dá mọ̀ mọ́, bí “ipò ìgbẹ̀yìn” àwọn tí Sátánì pa jẹ nípa tẹ̀mí ṣe máa ń ‘burú ju ti àkọ́kọ́’ wọn lọ nìyẹn. (2 Pét. 2:20) Torí náà, ó yẹ ká mú ìdúró wa lòdì sí Sátánì, ká sì di àwọn ìlànà Bíbélì tá a ti kọ́ mú gírígírí.—1 Pét. 5:9.

MỌRÍRÌ IBI TÍ JÈHÓFÀ FI Ẹ́ SÍ NÍNÚ ILÉ RẸ̀

Arákùnrin Samuel Herd tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ni olùbánisọ̀rọ̀ tó kàn, ó sọ pé: “Gbogbo wa la ní ibi tí Jèhófà fi wá sí nínú ilé rẹ̀.” Gbogbo Kristẹni ló ní ibi tí Ọlọ́run fi ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sí nínú “ilé” rẹ̀, ìyẹn tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ tó jẹ́ ìṣètò tá a fi ń jọ́sìn rẹ̀ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. Ó yẹ ká mọyì ibi tó fi wá sí, ká sì kà á sí àǹfààní ṣíṣeyebíye. Bíi ti Dáfídì, a fẹ́ láti máa “gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé [wa].”—Sm. 27:4.

Lẹ́yìn tí Arákùnrin Herd tọ́ka sí Sáàmù 92:12-14, ó béèrè pé: “Báwo ni Jèhófà ṣe ń jẹ́ ká ṣàṣeyọrí?” Ó dáhùn pé: “Nínú Párádísè tẹ̀mí, Ọlọ́run máa ń ṣìkẹ́ wa, ó ń dáàbò bò wá, ó sì ń fún wa ní omi òtítọ́ tó ń tuni lára. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.” Lẹ́yìn èyí ni Arákùnrin Herd wá rọ àwọn tó wà láwùjọ pé: “Ẹ jẹ́ ká ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ilé Jèhófà tá a wà, kì í wulẹ̀ ṣe fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ títí láé.”

ÀWỌN KRISTẸNI MÁA Ń BỌ̀WỌ̀ FÚN Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Arákùnrin David Splane tí òun náà jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣàlàyé nínú àsọyé tó kàn pé ọjọ́ pẹ́ tí àwọn Kristẹni tòótọ́ ti ń bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n fẹ́ yanjú ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ ní ọ̀rúndún kìíní, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n gbára lé. (Ìṣe 15:16, 17) Àmọ́ àwọn kan tó pera wọn ní Kristẹni ní ọ̀rúndún kejì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì tí wọ́n fi kọ́ wọn lárugẹ ju ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lọ. Nígbà tó yá, àwọn míì fi èrò àwọn tí wọ́n ń pè ní Bàbá Ìjọ àti èrò àwọn olú ọba Róòmù rọ́pò ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ tan ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ èké kálẹ̀.

Arákùnrin Splane ṣàlàyé pé àkàwé kan tí Jésù ṣe fi hàn pé àwọn ojúlówó Kristẹni ẹni àmì òróró á ṣì máa wà lórí ilẹ̀ ayé láti máa gbèjà òtítọ́. (Mát. 13:24-30) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè sọ àwọn tí wọ́n jẹ́ ní pàtó. Síbẹ̀, láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá ni ọ̀pọ̀ èèyàn kò ti fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ àtàwọn àṣà ti kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Díẹ̀ lára wọn ni Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Agobard ti ìlú Lyons ní ọ̀rúndún kẹsàn-án, Peter ti Bruys, Henry ti Lausanne àti Valdès (tàbí Waldo) ní ọ̀rúndún kejìlá, John Wycliffe ní ọ̀rúndún kẹrìnlá, William Tyndale ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún àti Henry Grew òun George Storrs ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún. Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́, orí òtítọ́ Bíbélì ni wọ́n sì gbé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ kà. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi yan Jòhánù 17:17 tó sọ pé, “òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ,” gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2012.

ÀWỌN ÌYÍPADÀ TÓ WÚNI LÓRÍ DÉ BÁ ÌDÁNILẸ́KỌ̀Ọ́ ÀTI IṢẸ́ ÌSÌN

Nínú ìfilọ̀ kan tí Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe, ó sọ àwọn ìyípadà tó ti dé bá iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Tó bá fi máa di oṣù September ọdún 2012, wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tá a yàn. Ìyàtọ̀ ti dé bá Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì báyìí. Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù October ọdún tó kọjá, gbogbo àwọn tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ní láti wà lẹ́nu irú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kan, yálà kí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì tí kò tíì lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí ẹni tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. A ó máa lo àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege láti fún àwọn èèyàn Ọlọ́run lókun kí wọ́n lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú òtítọ́. A lè yanṣẹ́ fún wọn ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, wọ́n lè wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò tàbí ká rán wọn lọ sí àwọn àgbègbè tí àwọn èèyàn pọ̀ sí kí wọ́n lè máa fún àwọn ìjọ ní ìṣírí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe púpọ̀ sí i á máa lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó wà ní àwọn àgbègbè jíjìnnà réré àti láwọn ibi àdádó. Láti January 1, ọdún 2012 la ti ń yan àwọn kan lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n àti ní Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ìgbà díẹ̀, a sì ń lò wọ́n láti máa lọ wàásù láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó jìnnà réré kí iṣẹ́ náà lè gbòòrò níbẹ̀. A ó máa yan iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún wọn lọ́dọọdún, títí tó fi máa pé ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà la máa fún àwọn tó bá kúnjú ìwọ̀n nínú wọn ní àǹfààní láti máa bá iṣẹ́ náà lọ.

Àkókò aláyọ̀ ni ìpàdé ọdọọdún tá a ṣe lọ́dún 2011 yìí jẹ́. A retí pé Jèhófà yóò bù kún àwọn ètò tuntun tá à ń ṣe láti túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa, kó sì mú kí àwọn ará túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan, kí gbogbo èyí sì mú ògo àti ìyìn wá bá orúkọ rẹ̀.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

A TÚBỌ̀ MỌ̀ WỌ́N

Nígbà ìpàdé náà, wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu márùn-ún lára àwọn mẹ́sàn-án tó ṣẹ́ kù nínú àwọn ìyàwó àwọn Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ti kú. Arábìnrin Marina Sydlik, Edith Suiter, Melita Jaracz, Melba Barry àti Sydney Barber sọ bí wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti bí wọ́n ṣe wọṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Olúkúlùkù wọ́n sọ àwọn ohun tó jẹ́ mánigbàgbé fún wọn, wọ́n sọ nípa àwọn ànímọ́ rere táwọn ọkọ wọ́n ní, àtàwọn ohun tí wọ́n jọ gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Wọ́n parí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà lọ́nà tó wúni lórí. Àwùjọ náà kọ orin ìkẹrìndínláàádọ́rùn-ún [86] tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin.”

[Àwòrán]

(Òkè) Daniel àti Marina Sydlik; Grant àti Edith Suiter; Theodore àti Melita Jaracz

(Ìsàlẹ̀) Lloyd àti Melba Barry; Carey àti Sydney Barber

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Wọ́n pa ẹ̀ka ọ́fíìsì mẹ́fà pọ̀ sábẹ́ ìdarí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

MẸ́SÍKÒ

GUATEMALA

HONDURAS

EL SALVADOR

NICARAGUA

COSTA RICA

PANAMA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bá a ṣe lérò pé oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a fẹ́ kọ́ sí ìlú Warwick, ní ìpínlẹ̀ New York á ṣe rí rèé