Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ayé Yìí Ṣe Máa Dópin

Bí Ayé Yìí Ṣe Máa Dópin

“Ẹ kò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn yóò fi dé bá yín lójijì gẹ́gẹ́ bí yóò ti dé bá àwọn olè.”​—1 TẸS. 5:4.

1. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣọ́nà ká sì lè máa fara da àdánwò?

 ÀWỌN ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa mi ayé tìtì yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń ní ìmúṣẹ fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, torí náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣọ́nà. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣọ́nà? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé ká “tẹ ojú wa mọ́ àwọn ohun tí a . . . kò rí.” Ó ṣe pàtàkì pé ká pọkàn pọ̀ sórí èrè ìyè àìnípẹ̀kun tá a máa gbà, yálà ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ṣáájú àti lẹ́yìn gbólóhùn yìí fi hàn pé ńṣe ló ń gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ níyànjú pé kí wọ́n máa ronú lórí ayọ̀ tó máa yọrí sí nígbẹ̀yìngbẹ́yín tí wọ́n bá ń bá a nìṣó láti máa hùwà títọ́. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó tún máa jẹ́ kí wọ́n lè fara da àdánwò àti inúnibíni.—2 Kọ́r. 4:8, 9, 16-18; 5:7.

2. (a) Tá a bá fẹ́ kí ìrètí wa túbọ̀ máa dájú, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e?

2 Ìlànà pàtàkì kan wà nínú ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù yìí. Ìyẹn sì ni pé, tá a bá fẹ́ kí ìrètí wa túbọ̀ máa dájú, a gbọ́dọ̀ máa wò kọjá àwọn nǹkan tá à ń rí ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. A gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí a kò tíì rí. (Héb. 11:1; 12:1, 2) Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́wàá tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun tí à ń retí. *

ÀWỌN NǸKAN WO LÓ MÁA ṢẸLẸ̀ KÍ ÒPIN TÓ DÉ?

3. (a) Kí ni ìwé 1 Tẹsalóníkà 5:2, 3 sọ pé ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀? (b) Kí ni àwọn aṣáájú òṣèlú máa ṣe, àwọn wo ló sì ṣeé ṣe kó dara pọ̀ mọ́ wọn?

3 Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:2, 3.) Ó sọ nípa “ọjọ́ Jèhófà” níbẹ̀. Ọ̀nà tó gbà lo ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé “ọjọ́ Jèhófà” jẹ́ àkókò kan tó máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìparun ìsìn èké tó sì máa dópin nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Àmọ́, kí ọjọ́ Jèhófà yẹn tó bẹ̀rẹ̀, àwọn aṣáájú ayé á máa sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣoṣo tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò máa wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Àwọn orílẹ̀-èdè lè ronú pé àwọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ rí ojútùú sí àwọn kan lára ìṣòro ńláńlá tó ń bá wọn fínra. Àwọn olórí ẹ̀sìn wá ńkọ́? Apá kan ayé ni wọ́n, torí náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn náà dara pọ̀ mọ́ àwọn aṣáájú òṣèlú láti máa bá wọn sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” (Ìṣí. 17:1, 2) Lọ́nà yìí, àwọn olórí ẹ̀sìn yìí á dà bí àwọn wòlíì èké tó wà ní Júdà ìgbàanì. Jèhófà sọ nípa wọn pé: “Wọ́n [ń sọ] pé, ‘Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!’ nígbà tí kò sí àlàáfíà.”—Jer. 6:14; 23:16, 17.

4. Àwọn nǹkan wo làwa Kristẹni tòótọ́ ń fòye mọ̀ báyìí àmọ́ táwọn yòókù nínú ayé kò fiyè sí?

4 Ẹni yòówù kó wà lára àwọn tí yóò máa sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” ńṣe ni ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn máa fi hàn pé ọjọ́ Jèhófà ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Ẹ̀yin, ará, ẹ kò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn yóò fi dé bá yín lójijì gẹ́gẹ́ bí yóò ti dé bá àwọn olè, nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.” (1 Tẹs. 5:4, 5) Àwa Kristẹni tòótọ́ kò dà bí àwọn tó kù nínú ayé, látàrí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, à ń fòye mọ bí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ti ṣe pàtàkì tó. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa bí wọ́n á ṣe máa sọ pé “Àlàáfíà àti ààbò!” ṣe máa ní ìmúṣẹ? Àfi ká ní sùúrù dìgbà yẹn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó máa bá a nìṣó láti “wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.”—1 Tẹs. 5:6; Sef. 3:8.

“ỌBABÌNRIN” KAN TÍ Ọ̀NÀ KÒ GBA IBI TÓ FOJÚ SÍ

5. (a) Báwo ni “ìpọ́njú ńlá” ṣe máa bẹ̀rẹ̀? (b) “Ọbabìnrin” wo ni ọ̀nà kò ní gba ibi tó fojú sí?

5 Ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò tíì rí wo ló máa tó ṣẹlẹ̀? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.” Ìkọlù “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tá a tún mọ̀ sí “aṣẹ́wó náà” ló máa bẹ̀rẹ̀ “ìparun òjijì” yìí. (Ìṣí. 17:5, 6, 15) Ìkọlù tó máa bá gbogbo onírúurú ẹ̀sìn èké, tó fi mọ́ àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì yìí, ló máa bẹ̀rẹ̀ “ìpọ́njú ńlá.” (Mát. 24:21; 2 Tẹs. 2:8) Òjijì ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa dé bá ọ̀pọ̀ èèyàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé títí di àkókò yẹn, ńṣe ni aṣẹ́wó náà á máa wo ara rẹ̀ bí “ọbabìnrin” tí ‘kì yóò rí ọ̀fọ̀ láé.’ Àmọ́, òjijì ló máa rí i pé ọ̀nà kò gba ibi tí òun fojú sí rárá. Ńṣe ló máa pa run lójijì, bíi pé “ní ọjọ́ kan ṣoṣo.”—Ìṣí. 18:7, 8.

6. Ta ló máa pa ìsìn èké run?

6 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “ẹranko ẹhànnà” tó ní “ìwo mẹ́wàá” ló máa kọ lu aṣẹ́wó náà. Ohun tó wà nínú ìwé Ìṣípayá fi hàn pé ẹranko ẹhànnà náà dúró fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè. “Ìwo mẹ́wàá” náà dúró fún gbogbo ìjọba òṣèlú tó ń ṣètìlẹyìn fún “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” náà ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. * (Ìṣí. 17:3, 5, 11, 12) Báwo ni ìkọlù yìí ṣe máa burú tó? Àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ara Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè máa fipá gba gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀, wọ́n á tú àṣírí iṣẹ́ ibi rẹ̀, wọ́n á jẹ ẹ́ run, wọ́n á sì “fi iná sun ún pátápátá.” Ìparun yán-án-yán-án ló máa bá aṣẹ́wó náà.—Ka Ìṣípayá 17:16.

7. Kí ló máa mú kí “ẹranko ẹhànnà” náà kọ lu aṣẹ́wó náà?

7 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tún jẹ́ ká mọ ohun tó máa fa ìkọlù yìí. Lọ́nà kan ṣá, Jèhófà máa fi sínú ọkàn àwọn aṣáájú òṣèlú “láti mú ìrònú òun ṣẹ,” ìyẹn láti pa aṣẹ́wó náà run. (Ìṣí. 17:17) Wàhálà àti ìyapa tí ẹ̀sìn ń dá sílẹ̀ ń mú kí ogun máa gbilẹ̀ káàkiri àgbáyé; torí náà, èyí lè mú kí àwọn aṣáájú òṣèlú ronú pé ó máa ṣàǹfààní fún orílẹ̀-èdè àwọn tí àwọn bá pa aṣẹ́wó náà run. Kódà, nígbà tí àwọn aṣáájú òṣèlú bá kọ lu aṣẹ́wó náà, ńṣe ni wọ́n máa rò pé “ìrònú kan ṣoṣo” tiwọn làwọn ń mú ṣẹ. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé ńṣe ni Ọlọ́run lò wọ́n láti pa gbogbo ìsìn èké run. Nípa bẹ́ẹ̀, lọ́nà tó yani lẹ́nu, apá kan lára ètò Sátánì máa ṣàdédé yí pa dà bìrí láti gbéjà ko apá mìíràn lára ètò rẹ̀, Sátánì ò sì ní lè ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀.—Mát. 12:25, 26.

WỌ́N MÁA GBÉJÀ KO ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN

8. Ìkọlù wo ló máa wá látọ̀dọ̀ “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù”?

8 Lẹ́yìn tí ìsìn èké bá ti pa run, àwọn orílẹ̀-èdè máa rí i pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣì ń “gbé ní ààbò” àti “láìsí ògiri.” (Ìsík. 38:11, 14) Kí ló wá máa ṣẹlẹ̀ sí àwùjọ èèyàn tó dà bíi pé wọn kò ní ààbò kankan tí wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà yìí? Ó jọ pé ńṣe ni “ọ̀pọ̀ ènìyàn” máa fi gbogbo agbára wọn kọ lù wọ́n. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pè ní ìkọlù tàbí ìgbéjàkò láti ọ̀dọ̀ “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:2, 15, 16.) Ojú wo ló yẹ ká fi wo ìkọlù yẹn?

9. (a) Kí ló yẹ kó jẹ àwa Kristẹni lógún jù lọ? (b) Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa ṣe báyìí kí ìgbàgbọ́ wa bàa lè lágbára?

9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ nípa ìkọlù tó ń bọ̀ wá bá àwa èèyàn Ọlọ́run yìí, ìyẹn ò mú ká máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, dípò tá a ó fi máa ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa rí ìgbàlà, ohun tó jẹ wá lógún jù lọ ni bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́ tó sì máa dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre. Kódà, nínú Bíbélì, ó ju ọgọ́ta [60] ìgbà lọ tí Jèhófà sọ pé: “Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsík. 6:7) Nípa bẹ́ẹ̀, à ń fi ìháragàgà retí ìmúṣẹ apá tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì yìí, ọkàn wa sì balẹ̀ pé “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.” (2 Pét. 2:9) Àmọ́ ní báyìí, a fẹ́ máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti máa ṣe àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti pa ìwà títọ́ wa sí Jèhófà mọ́ láìka àdánwò tá a lè dojú kọ sí. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe? A gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tí à ń kọ́, ká sì máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyè àìnípẹ̀kun tí à ń retí á túbọ̀ fìdí múlẹ̀ lọ́kàn wa bí “ìdákọ̀ró.”—Héb. 6:19; Sm. 25:21.

ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ YÓÒ WÁ MỌ JÈHÓFÀ

10, 11. Báwo ni ogun Amágẹ́dọ́nì ṣe máa bẹ̀rẹ̀, kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn?

10 Ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa mi gbogbo ayé tìtì wo ló máa wáyé nígbà tí wọ́n bá gbéjà ko àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà? Jèhófà máa mú kí Jésù àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run jà fún àwọn èèyàn Rẹ̀. (Ìṣí. 19:11-16) Ìjà tó máa ṣẹlẹ̀ yìí ni “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” ìyẹn Amágẹ́dọ́nì.—Ìṣí. 16:14, 16.

11 Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Ísíkíẹ́lì sọ nípa ogun yẹn pé: “‘Èmi yóò pe idà kan jáde lòdì sí [Gọ́ọ̀gù] jákèjádò ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá mi,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. ‘Idà olúkúlùkù yóò wá lòdì sí arákùnrin rẹ̀.’” Jìnnìjìnnì máa bá àwọn ọmọ ogun Sátánì, wọ́n á kó sínú ìdàrúdàpọ̀, wọ́n á sì máa gbéjà ko ara wọn. Ṣùgbọ́n, àjálù máa bá Sátánì fúnra rẹ̀ pẹ̀lú. Jèhófà sọ pé: “Iná àti imí ọjọ́ ni èmi yóò rọ̀ lé [Gọ́ọ̀gù] lórí àti sórí àwùjọ ọmọ ogun rẹ̀ àti sórí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí yóò wà pẹ̀lú rẹ̀.” (Ìsík. 38:21, 22) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ohun tí Ọlọ́run máa ṣe yìí?

12. Kí ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá mọ̀ tipátipá?

12 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá mọ̀ pé bí ìparun ṣe ń dé bá àwọn kò ṣẹ̀yìn Jèhófà. Lẹ́yìn náà, bíi tí àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì tí wọ́n lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Òkun Pupa, ọ̀ràn náà lè tojú sú àwọn ọmọ ogun Sátánì débi tí wọn yóò fi ké jáde pé: “Jèhófà ń jà fún wọn dájúdájú”! (Ẹ́kís. 14:25) Èyí ni yóò wá mú kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ Jèhófà tipátipá. (Ka Ísíkíẹ́lì 38:23.) Báwo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa wáyé tẹ̀ lé ara wọn yìí ṣe sún mọ́lé tó?

KÒ NÍ SÍ AGBÁRA AYÉ KANKAN MỌ́

13. Kí la mọ̀ nípa apá karùn-ún lara ère tí Dáníẹ́lì ṣàlàyé rẹ̀?

13 Àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Dáníẹ́lì jẹ́ ká mọ ibi tí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn ti ní ìmúṣẹ dé báyìí. Dáníẹ́lì ṣàlàyé ère kan tó ní ìrísí èèyàn, tó sì ní ẹ̀yà ara tó jẹ ti wúrà, fàdákà, bàbà àti irin. (Dán. 2:28, 31-33) Ère yìí dúró fún àwọn agbára ayé tó ṣàkóso tẹ̀ lé ara wọn, tí wọ́n sì ti ní ipa pàtàkì lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run, nígbà àtijọ́ àti lóde òní. Àwọn agbára ayé náà ni, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, Róòmù àti èyí tó gbẹ̀yìn, tó wà lójú ọpọ́n ní àkókò tá a wà yìí. Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì fi hàn pé ẹsẹ̀ àti àwọn ọmọ ìka ẹsẹ̀ èrè náà ló dúró fún agbára ayé tó gbẹ̀yìn. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wọnú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ kan. Látàrí èyí, Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà ni apá karùn-ún lára ère tí Dáníẹ́lì rí náà. Ẹsẹ̀ ni apá tó gbẹ̀yìn lára ère náà, èyí tó fi hàn pé kò ní sí agbára ayé mìíràn lẹ́yìn wọn. Bí ẹsẹ̀ àti àwọn ọmọ ìka ẹsẹ̀ eré náà ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀ ṣàpẹẹrẹ ipò ẹlẹgẹ́ tí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà wà.

14. Agbára ayé wo ló máa wà lójú ọpọ́n nígbà tí Amágẹ́dọ́nì bá dé?

14 Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà yẹn tún jẹ́ ká mọ̀ pé ní ọdún 1914, òkúta ńlá kan tó dúró fún Ìjọba Ọlọ́run gé kúrò lára òkè ńlá kan tó dúró fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Òkúta tó ń já ṣòòròṣò bọ̀ náà máa tó kọ lu ẹsẹ̀ ère yẹn. Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ẹsẹ̀ àti apá tó kù lára ère yẹn máa rún wómúwómú. (Ka Dáníẹ́lì 2:44, 45.) Torí náà, Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà ló máa wà lójú ọpọ́n nígbà tí Amágẹ́dọ́nì bá dé. Ẹ sì wo bí inú wa ṣe máa dùn tó láti rí ìmúṣẹ apá tó gbẹ̀yìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí! * Ṣùgbọ́n, kí wá ni Jèhófà máa ṣe fún Sátánì fúnra rẹ̀?

KÍ LÓ MÁA ṢẸLẸ̀ SÍ OLÓRÍ ELÉNÌNÍ ỌLỌ́RUN?

15. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀?

15 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Sátánì máa fojú ara rẹ̀ rí bí gbogbo ètò rẹ̀ tó wà láyé ṣe máa pa run. Lẹ́yìn náà, Sátánì á wá gba ìdájọ́ tirẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù ṣàlàyé èyí nínú Ìṣípayá 20:1-3. (Kà á.) Jésù Kristi, ‘áńgẹ́lì tó mú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ dání,’ máa de Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, ó máa jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, wọ́n á sì wà níbẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún. (Lúùkù 8:30, 31; 1 Jòh. 3:8) Èyí ló máa jẹ́ apá àkọ́kọ́ nínú bí Jésù ṣe máa fọ́ ejò náà lórí. *Jẹ́n. 3:15.

16. Ipò wo ni Sátánì máa wà nínú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀”?

16 Kí ni “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” tí Jésù Kristi máa ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sí? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Jòhánù lò, ìyẹn aʹbys·sos, tá a tú sí “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” lédè Yorùbá túmọ̀ sí “nǹkan tó jìn gan-an.” Wọ́n tún máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí “nǹkan tí kò ṣeé díwọ̀n” tàbí “tí kò lópin.” Torí náà, ẹnì kankan kò lè dé ibẹ̀ àyàfi Jèhófà àti áńgẹ́lì rẹ̀ ‘tó ní kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà ní ọwọ́ rẹ̀.’ Níbẹ̀, Sátánì máa wà ní ipò àìlè-ṣe-ohunkóhun kí “ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́kẹ́ á pa mọ́ “kìnnìún tí ń ké ramúramù” yẹn lẹ́nu!—1 Pét. 5:8.

ÀWỌN OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ KÍ ÀLÀÁFÍÀ TÓ DÉ

17, 18. (a) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò tíì rí wo la ti jíròrò báyìí? (b) Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ìgbà ọ̀tun wo ló máa dé sí ayé?

17 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí yóò mi ayé tìtì ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. À ń retí bí ìkéde “Àlàáfíà àti ààbò!” ṣe máa wáyé. Lẹ́yìn náà, a máa rí bí Bábílónì Ńlá ṣe máa pa run, bí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù ṣe máa gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, bí ogun Amágẹ́dọ́nì ṣe máa jà àti bí Jésù Kristi ṣe máa ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, nígbà tí gbogbo ìwà ibi bá ti dópin, ìgbà ọ̀tun máa dé sí ayé, Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi máa bẹ̀rẹ̀. Ní àkókò yìí, gbogbo wa la máa gbádùn “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sm. 37:10, 11.

18 Ní àfikún sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tá a ti jíròrò yìí, “àwọn ohun tí a kò rí” kan ṣì wà tó yẹ ká “tẹ ojú wa mọ́.” Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ A máa jíròrò ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́wàá náà nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e.

^ Wo ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! ojú ìwé 251 sí 258.

^ Gbólóhùn náà, ‘yóò sì fi òpin sí gbogbo ìjọba wọ̀nyí’ tó wà ní Dáníẹ́lì 2:44 ń tọ́ka sí àwọn ìjọba tí onírúurú apá tó wà nínú ère tí Dáníẹ́lì rí ṣàpẹẹrẹ. Ṣùgbọ́n, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn tó jọ èyí fi hàn pé “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” máa kó ara wọn jọ lòdì sí Jèhófà ní “ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣí. 16:14; 19:19-21) Torí náà, kì í ṣe àwọn ìjọba tí ère yẹn ṣàpẹẹrẹ nìkan ni ogun Amágẹ́dọ́nì máa pa run, ṣùgbọ́n ó tún máa pa gbogbo ìjọba yòókù nínú ayé run.

^ Jésù Kristi máa fọ́ orí ejò yẹn pátápátá lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún náà nígbà tó bá fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sínú “adágún iná àti imí ọjọ́.”​—Ìṣí. 20:7-10; Mát. 25:41.