Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Kò Mọ Ọjọ́ Tàbí Wákàtí Náà”

“Ẹ Kò Mọ Ọjọ́ Tàbí Wákàtí Náà”

“Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.” —MÁT. 25:13.

1-3. (a) Ipò wo la lè fi ṣàpèjúwe kókó pàtàkì tó wà nínú méjì lára àwọn àkàwé Jésù? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká dáhùn?

 JẸ́ KÁ sọ pé aláṣẹ kan ní kó o fi ọkọ̀ gbé òun lọ síbi ìpàdé pàtàkì kan. Àmọ́, nígbà tó ku ìṣẹ́jú bíi mélòó kan kó o lọ gbé e, o wá rí i pé epo tó wà nínú ọkọ̀ yẹn kò lè gbé e yín débi tí ẹ̀ ń lọ. O wá sáré lọ ra epo díẹ̀. Ṣùgbọ́n bó o ṣe lọ báyìí ni aláṣẹ náà dé. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá ẹ, àmọ́ kò rí ẹ. Nígbà tí kò lè dúró mọ́, ó pe ẹlòmíì pé kó gbé òun lọ. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà lo pa dà dé láti ibi tó o ti lọ ra epo, o wá rí i pé aláṣẹ yẹn ti fi ẹ́ sílẹ̀. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ?

2 Wàyí o, jẹ́ ká sọ pé ìwọ ni aláṣẹ náà, o sì yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó jáfáfá láti ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan. O ṣàlàyé iṣẹ́ náà fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, wọ́n sì gbà láti ṣe é. Ṣùgbọ́n, nígbà tó ṣe díẹ̀ tó o pa dà dé, o wá rí i pé àwọn méjì ló ṣe iṣẹ́ wọn. Èyí tí kò ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sì tún wá ń ṣe àwáwí. Kò tiẹ̀ fọwọ́ kan iṣẹ́ náà rárá. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ?

3 Nínú àkàwé nípa àwọn wúńdíá àti tálẹ́ńtì, Jésù lo irú ipò tó wà nínú àwọn àpèjúwe méjì yìí láti ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé nígbà ìkẹyìn, àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró máa jẹ́ olóòótọ́ àti olóye tí àwọn yòókù kò sì ní jẹ́ bẹ́ẹ̀. * (Mát. 25:1-30) Ó sọ kókó pàtàkì tó fẹ́ fà yọ, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà,” ìyẹn, àkókò náà gan-an tí Jésù máa mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ sórí ayé Sátánì. (Mát. 25:13) Àwa náà gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn yẹn sílò lónìí. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ṣíṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe fún wa ní ìṣírí pé ká ṣe? Àwọn wo ló ti fi hàn pé àwọn ti ṣe tán láti là á já? Kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe báyìí ká lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà?

JÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ṢÍṢỌ́NÀ

4. Kí nìdí tí “ṣíṣọ́nà” kò fi túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣáà máa wojú aago?

4 Àwọn iṣẹ́ kan wà tó má ń gba pé kéèyàn tẹ̀ lé àkókò kan pàtó tí wọ́n ti ṣètò kalẹ̀, irú bíi téèyàn bá ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ kan, téèyàn bá fẹ́ rí dókítà tàbí téèyàn bá fẹ́ wọ ọkọ̀ èrò. Àwọn iṣẹ́ míì sì wà tó jẹ́ pé tó bá lọ jẹ́ ọ̀rọ̀ aago ló jẹ èèyàn lógún, ó lè fa ìpínyà ọkàn, ó tiẹ̀ lè léwu gan-an pàápàá, irú bí iṣẹ́ panápaná tàbí iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà nígbà àjálù. Ní irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kéèyàn gbájú mọ́ iṣẹ́ náà, dípò kó máa tẹ̀ lé ìṣètò àkókò kan pàtó. Bí òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, àkókò yìí ló ṣe pàtàkì jù lọ fún wa láti máa sọ fún àwọn èèyàn nípa bí Jèhófà ṣe máa mú ìgbàlà wá. Ti pé àwa Kristẹni ń ṣọ́nà kò túmọ̀ sí pé ká ṣáà máa wojú aago. Ó kéré tán, ọ̀nà márùn-ún la gbà ń jàǹfààní látinú bí a ṣe mọ ọjọ́ àti wákàtí náà gan-an tí òpin máa dé.

5. Báwo ni ṣíṣàìmọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà ṣe lè fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn?

5 Lákọ̀ọ́kọ́, bí a kò ṣe mọ ìgbà tí òpin máa dé ń jẹ́ kí àwa fúnra wa fi ohun tó wà lọ́kàn wa gan-an hàn. Kódà, bí a kò ṣe mọ ọjọ́ yẹn ń buyì kún wa, torí pé ó ń jẹ́ ká lè lo òmìnira tí Ọlọ́run dá mọ́ wa láti fi hàn pé a dúró ṣinṣin ti Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wù wá pé ká la òpin nǹkan ìsinsìnyí já, ìdí pàtàkì tá a fi ń sin Jèhófà ni pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe torí pé ká lè ní ìyè. (Ka Sáàmù 37:4.) Bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ń mú inú wa dùn, a sì mọ̀ pé ńṣe ni Ọlọ́run ń kọ́ wa ká lè ṣe ara wa láǹfààní. (Aísá. 48:17) A kì í wo àwọn òfin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹrù ìnira.—1 Jòh. 5:3.

6. Tá a bá ń sin Ọlọ́run torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ̀, kí sì nìdí?

6 Àǹfààní kejì tó wà nínú bí a kò ṣe mọ ọjọ́ tàbí wákátì náà ni pé, ó ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa mú inú Jèhófà dùn. Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run ló ń mú ká sìn ín, tí kì í ṣe nítorí pé òpin máa tó dé tàbí nítorí èrè tá a fẹ́ gbà nìkan, ńṣe là ń fara mọ́ Jèhófà láti dá Sátánì elénìní rẹ̀ lóhùn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó fi kàn án. (Jóòbù 2:4, 5; ka Òwe 27:11.) Látàrí gbogbo ìrora àti ìbànújẹ́ tí Èṣù ti fà, tayọ̀tayọ̀ la fi fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ tá a sì kọ ìṣàkóso búburú Sátánì.

7. Kí nìdí tó o fi ronú pé ó ṣàǹfààní kéèyàn máa gbé ìgbé ayé onífara-ẹni-rúbọ?

7 Àǹfààní kẹta ni pé, bá a ṣe ń sin Jèhófà láìní ọjọ́ kan pàtó lọ́kàn ń jẹ́ ká lè máa gbé ìgbé ayé onífara-ẹni-rúbọ. Lóde òní, àwọn kan tí kò mọ Ọlọ́run pàápàá gbà pé ayé yìí kò ní pẹ́ wá sí òpin. Torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ìjábá kan pa ayé yìí run nígbàkigbà, bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn mú kó dà bí ìgbà tí wọ́n ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́r. 15:32) Ṣùgbọ́n ẹ̀rù kò bà wá, ọ̀ràn ara tiwa nìkan sì kọ́ ló ń jẹ wá lógún. (Òwe 18:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń sẹ́ ara wa tá a sì ń fínnú fíndọ̀ lo àkókò wa, okun wa àtàwọn nǹkan míì tá a ní ká lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. (Ka Mátíù 16:24.) A máa ń láyọ̀ bá a ṣe ń sin Ọlọ́run, ní pàtàkì bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ ọ́n.

8. Àpẹẹrẹ wo nínú Bíbélì ló jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pátápátá?

8 Àǹfààní kẹrin tó wà nínú bí a kò ṣe mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí òpin máa dé ni pé ó ń jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì ń jẹ́ ká lè máa fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò dáradára nígbèésí ayé wa. Torí pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, a sábà máa ń fẹ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé ara wa. Pọ́ọ̀lù gba gbogbo Kristẹni níyànjú pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” Ó sọ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún [23,000] lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí Jèhófà wọ́n sì kú nígbà tó kù díẹ̀ kí Jóṣúà kó wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Nǹkan wọ̀nyí [ni] . . . a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.”—1 Kọ́r. 10:8, 11, 12.

9. Báwo ni ìṣòro ṣe lè yọ́ wa mọ́ kó sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?

9 Ọ̀nà karùn-ún tí à ń gbà jàǹfààní látinú bí a kò ṣe mọ ìgbà tí òpin máa dé ni pé ó ń jẹ́ kí àwọn àdánwò tí à ń dojú kọ nísinsìnyí yọ́ wa mọ́. (Ka Sáàmù 119:71.) Kò sí àní-àní pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí jẹ́ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1-5) Nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló kórìíra wa, torí náà, wọ́n lè ṣe inúnibíni sí wa nítorí ohun tá a gbà gbọ́. (Jòh. 15:19; 16:2) Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tá a sì bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà nígbà tí irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ bá wáyé, ìgbàgbọ́ wa á dọ̀tun, bí ìgbà tí a fi iná yọ́ ọ mọ́. A ò ní jẹ́ kó rẹ̀ wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà ju bí àwa fúnra wa ṣe rò lọ.—Ják. 1:2-4; 4:8.

10. Kí ló máa ń mú kó dà bíi pé àkókò ń yára kánkán?

10 Ó lè dà bíi pé àkókò ń yára kánkán tàbí ó ń falẹ̀. Bí ọwọ́ wa bá dí tá a sì ní ohun tá à ń fi àkókò wa ṣe, tí kì í ṣe pé a kàn ń wojú aago, ńṣe ni àkókò á máa yára kánkán. Bákan náà ló ṣe máa rí tá a bá jára mọ́ iṣẹ́ aláyọ̀ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, wẹ́rẹ́ ni òpin máa dé. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ẹni àmì òróró ti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa èyí. Ẹ jẹ́ ká ṣe àyẹ̀wò ṣókí nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù gorí itẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́dún 1914, ká wá wo bí àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró ṣe fi hàn pé àwọn wà lójúfò nígbà tí àwọn yòókù kò ṣe bẹ́ẹ̀.

ÀWỌN ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ FI HÀN PÉ ÀWỌN WÀ LÓJÚFÒ

11. Lẹ́yìn ọdún 1914, kí nìdí tí àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró fi ronú pé Olúwa ń fi dídé rẹ̀ falẹ̀?

11 Ẹ jẹ́ ká rántí àkàwé tí Jésù ṣe nípa àwọn wúńdíá àti tálẹ́ńtì. Tó bá jẹ́ pé àwọn wúńdíá inú àkàwé yẹn tàbí àwọn ẹrú yẹn mọ ìgbà tí ọkọ ìyàwó tàbí ọ̀gá náà máa dé ni, kò bá má pọn dandan fún wọn láti máa ṣọ́nà. Ṣùgbọ́n, wọn kò mọ ìgbà tó máa dé, torí náà wọ́n gbọ́dọ̀ wà lójúfò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí àwọn ẹni àmì òróró ti ń wo ọdún 1914 gẹ́gẹ́ bí ọdún tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan máa wáyé, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kò tíì yé wọn dáadáa. Nígbà tí nǹkan kò rí bí wọ́n ṣe rò, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú pé ńṣe ni Ọkọ Ìyàwó ń fi dídé rẹ̀ falẹ̀. Arákùnrin kan rántí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé, “Ká sòótọ́, díẹ̀ lára wa ronú pé ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ nínú oṣù October, ọdún 1914 la máa lọ sọ́run.”

12. Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye?

12 Ẹ wo bí wọ́n ṣe máa rẹ̀wẹ̀sì tó nígbà tí wọ́n retí àkókò òpin, àmọ́ tí òpin náà kò dé! Àwọn arákùnrin náà tún dojú kọ inúnibíni nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Àkókò kan wà tí wọ́n di aláìṣiṣẹ́mọ́, bí ìgbà tí oorun gbé wọn lọ. Àmọ́, lọ́dún 1919 ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí wọ́n ta jí lójú oorun! Jésù wá sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Ọlọ́run, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò bí nǹkan ṣe ń lọ sí. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn àyẹ̀wò yìí, àwọn kan kò kúnjú ìwọ̀n, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti máa bá a nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ Ọba náà. (Mát. 25:16) Ńṣe ló dà bíi pé wọn kò wà lójúfò láti rí i pé àwọn ní òróró tẹ̀mí tó pọ̀ tó, torí náà wọ́n dà bí àwọn òmùgọ̀ wúńdíá inú àkàwé Jésù. Wọ́n tún dà bí ẹrú onílọ̀ọ́ra yẹn ní ti pé, wọn kò ṣe tán láti lo ara wọn fún ire Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹni àmì òróró ló fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n sì fi hàn pé tọkàntọkàn làwọn fẹ́ láti sin Ọ̀gá wọn, kódà láwọn ìgbà tó le koko tí ogun ń jà.

13. Irú ẹ̀mí wo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà ní lẹ́yìn ọdún 1914, irú ẹ̀mí wo ni wọ́n sì ní lónìí?

13 Lẹ́yìn ọdún 1914, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ [lédè Gẹ̀ẹ́sì] sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí: “Ẹ̀yin ará, àwa tá a ní ẹ̀mí tí ó tọ́ sí Ọlọ́run kì í ní ìjákulẹ̀ nítorí èyíkéyìí lára ètò tí Ọlọ́run ṣe. Kì í ṣe ìfẹ́ ti ara wa la fẹ́ ṣe; torí náà, nígbà tá a rí i pé ohun tí kò tọ́ là ń retí ní oṣù October ọdún 1914, inú wa dùn pé Olúwa kò yí Ètò tó ti ṣe pa dà kó lè bá tiwa mu. A ò tiẹ̀ fẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó wù wá ni pé ká lóye ètò rẹ̀ àtàwọn nǹkan tó ní lọ́kàn láti ṣe.” Irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfọkànsìn yìí ni àwọn ẹni àmì òróró Olúwa ṣì ní títí dòní. Wọn kò sọ pé Ọlọ́run mí sí àwọn, ṣùgbọ́n wọ́n ti pinnu láti máa bójú tó iṣẹ́ Olúwa lórí ilẹ̀ ayé. Ní báyìí, àwọn Kristẹni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n ní ìrètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, wọ́n ń bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà wọ́n sì ń fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù.—Ìṣí. 7:9; Jòh. 10:16.

BÍ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ A WÀ LÓJÚFÒ

14. Báwo ni fífara mọ́ ètò tí Ọlọ́run ṣe fún wa láti máa rí oúnjẹ tẹ̀mí ṣe máa dáàbò bò wá?

14 Bíi ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àwọn tó wà lójúfò lára àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá máa ń fara mọ́ ètò tí Ọlọ́run ṣe fún wa láti máa rí oúnjẹ tẹ̀mí. Bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ darí wọn, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń ṣe àfikún òróró wọn nípa tẹ̀mí. (Ka Sáàmù 119:130; Jòhánù 16:13.) Wọ́n ń tipa báyìí rí okun tẹ̀mí gbà. Èyí ń mú kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ de ìpadàbọ̀ Kristi kí wọ́n sì máa bá iṣẹ́ Olúwa nìṣó bí wọ́n tilẹ̀ ń dojú kọ àwọn àdánwò líle koko. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọ̀kan lára àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba Násì, àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ kò kọ́kọ́ ní ju Bíbélì kan ṣoṣo lọ. Torí náà, wọ́n gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún àwọn ní oúnjẹ tẹ̀mí púpọ̀ sí i. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n gbọ́ pé arákùnrin kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mú wá sẹ́wọ̀n ti dọ́gbọ́n kó ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde bíi mélòó kan wọlé, ó fi wọ́n há inú igi tí wọ́n fi gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ dúró. Ọ̀kan lára àwọn tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà ni arákùnrin kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ernst Wauer. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn pé: “Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ ní ọ̀nà àgbàyanu láti há àwọn ẹ̀kọ́ tó ń gbéni ró nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà sórí.” Lẹ́yìn náà ló wá sọ pé: “Lóde òní, ó rọrùn gan-an láti rí oúnjẹ tẹ̀mí, ṣùgbọ́n ṣé gbogbo ìgbà la máa ń mọyì rẹ̀? Ó dá mi lójú pé Jèhófà ní ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún ní ìpamọ́ fún àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, tí wọ́n sì ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀.”

15, 16. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún tọkọtaya kan nítorí ìtara wọn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, kí lo sì lè rí kọ́ nínú irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀?

15 Àwọn àgùntàn mìíràn pẹ̀lú ń bá iṣẹ́ Ọ̀gá náà nìṣó ní pẹrẹu, wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin Kristi. (Mát. 25:40) Wọn kò dà bí ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra tí Jésù sọ nínú àkàwé rẹ̀, wọ́n fínnú fíndọ̀ yááfì àwọn nǹkan, wọ́n sì ń lo okun wọn bí wọ́n ṣe ń fi àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ti tọkọtaya kan tí wọ́n ń jẹ́ Jon àti Masako. Nígbà tí wọ́n ní kí wọ́n lọ ṣèrànwọ́ fún àwọn ará tó ń wàásù ní ìpínlẹ̀ kan táwọn tó ń sọ èdè Chinese pọ̀ sí lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, wọn ò kọ́kọ́ fẹ́ lọ. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí wọ́n gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, tí wọ́n sì rí i pé ipò àwọn lè yọ̀ǹda fún àwọn láti lọ, wọ́n pinnu láti kó lọ síbẹ̀.

16 Jèhófà bù kún wọn lọ́pọ̀ yanturu nítorí ìsapá wọn. Wọ́n sọ pé, “À ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gan-an níbí yìí.” Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méje. Wọ́n sì tún ní ọ̀pọ̀ ìrírí míì tó ń gbádùn mọ́ni. Wọ́n tún sọ pé, “Ojoojúmọ́ la máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ ká wá sí ibí yìí.” Ọ̀pọ̀ sì tún wà lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí ìpinnu tí wọ́n ṣe ń fi hàn pé ìgbà yòówù kí òpin dé, wọ́n ti ṣe tán láti máa lo ara wọn taratara lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ronú nípa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tí wọ́n sì ti rán láti lọ sìn gẹgẹ bíi míṣọ́nnárì. A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka ìrírí wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn àkànṣe yìí nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2001 nínú àpilẹ̀kọ tó ní àkọlé náà, “A Ń Sa Gbogbo Ipá Wa!” Bí o ti ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìrírí tí wọ́n ní lọ́jọ́ kan ṣoṣo nínú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì, kí ìwọ náà ronú nípa bó o ṣe lè máa ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ, èyí tó máa mú ìyìn bá orúkọ Ọlọ́run táá sì mú inú ìwọ pẹ̀lú dùn.

ÌWỌ NÁÀ MÁA BÁ A NÌṢÓ NÍ ṢÍṢỌ́NÀ

17. Báwo ni ṣíṣàì mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà ṣe jẹ́ ìbùkún fún wa?

17 Ó ti ṣe kedere báyìí pé, ìbùkún ló jẹ́ fún wa bí a kò ṣe mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà gan-an tí òpin máa dé. Dípò tí a fi máa jẹ́ kó sú wa tàbí kí inú wa bà jẹ́, ńṣe là ń lo gbogbo okun wa láti máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́, èyí sì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bá a ṣe ń bá a nìṣó láti máa ṣe iṣẹ́ tí Ọ̀gá wa gbé lé wa lọ́wọ́ láìbojúwẹ̀yìn, tá a sì ń yẹra fún àwọn ohun tó lè pín ọkàn wa níyà, a máa ń láyọ̀ gan-an.—Lúùkù 9:62.

18. Kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa yingin?

18 Ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé báyìí. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó máa fẹ́ já Jèhófà tàbí Jésù kulẹ̀. Wọ́n ti gbé ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lé wa lọ́wọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí. Inú wa dùn gan-an pé wọ́n fọkàn tán wa!—Ka 1 Tímótì 1:12.

19. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a wà lójúfò?

19 Yálà a ní ìrètí láti gbé ní ọ̀run tàbí a ní ìrètí láti máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, ẹ jẹ́ ká pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́. Títí di báyìí, a kò tíì mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí ọjọ́ Jèhófà máa dé, ṣó tiẹ̀ pọn dandan ká mọ̀ ọ́n ni? Ó dájú pé a lè wà lójúfò, a ó sì máa bá a nìṣó láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 24:36, 44) Ó dá wa lójú pé tí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà kò bá ti yingin, tí a sì ń fi Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́, Jèhófà kò ní já wa kulẹ̀ láé.—Róòmù 10:11.

^ Wo Ilé Ìṣọ́ March 1, 2004, ojú ìwé 14 sí 18.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kódà, láwọn àkókò tí nǹkan kò bá rọgbọ, máa ní ìyánhànhàn fún oúnjẹ tẹ̀mí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àkókò máa ń yára kánkán tó bá jẹ́ pé àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni la gbájú mọ́