Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run—Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa
JÈHÓFÀ ni ‘Olùkọ́ni Atóbilọ́lá’ wa. (Aísá. 30:20) Ìfẹ́ ló ń mú kó máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Jésù gan-an, ó fi “gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe” hàn án. (Jòh. 5:20) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí rẹ̀, ó fún wa ní “ahọ́n àwọn tí a kọ́,” bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa láti bọlá fún un tá a sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.—Aísá. 50:4.
Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Jèhófà. Wọ́n ń lo ilé ẹ̀kọ́ mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jẹ́ ti ètò Ọlọ́run láti fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ tí ipò wọn sì yọ̀ǹda ní ìdálẹ́kọ̀ọ́. Ǹjẹ́ o gbà pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run tó wà báyìí ká sì gbọ́ ohun tí àwọn kan tí wọ́n ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà sọ. Lẹ́yìn náà, kó o wá bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run ń kọ́ wa yìí?’
JÀǸFÀÀNÍ LÁTINÚ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÈTÒ ỌLỌ́RUN
Nítorí pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run ìfẹ́,” àwọn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wa ń mú kí ìgbé ayé wa dára sí i, wọ́n ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè borí ìṣòro, wọ́n sì ń mú ká ní ayọ̀ púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (2 Kọ́r. 13:11) Bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ọ̀rúndún kìíní, a ti gbára dì dáadáa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, a fẹ́ “máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun” tá a ti pa láṣẹ fún wa mọ́.—Mát. 28:20.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó lè má ṣeé ṣe fún wa láti lọ sí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ yìí, a lè jàǹfààní látinú ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú wọn. A sì lè máa fi àwọn ìtọ́ni Bíbélì tá a bá kọ́ níbẹ̀ sílò. A tún lè jáfáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nípa bíbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ dáadáa ṣiṣẹ́.
O lè bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ipò mi yọ̀ǹda fún mi láti lọ sí èyíkéyìí lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí?’
Àǹfààní ńlá ni àwọn olùjọ́sìn Jèhófà kà á sí láti máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye yìí kí wọ́n sì máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀. Àdúrà wa ni pé kí ẹ̀kọ́ tí wàá gbà mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, kó o lè gbára dì láti ṣe ojúṣe tó gbé lé ẹ lọ́wọ́, pàápàá jù lọ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tó jẹ́ kánjúkánjú.