Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Ìbàjẹ́ Yóò Dópin!

Ìwà Ìbàjẹ́ Yóò Dópin!

“Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́ . . . Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.”—SÁÀMÙ 37:34.

ǸJẸ́ ìwọ náà máa ń ronú bí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí tí wọ́n rò pé kò sí bí èèyàn ò ṣe ní lọ́wọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ àti pé kò lè kásẹ̀ nílẹ̀ láé? Tó o bá rò bẹ́ẹ̀, o kò jayò pa. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí oríṣi ìjọba tí aráyé kò tíì dán wò rí. Síbẹ̀, kò tíì sí èyí tó mú kí ìwà ìbàjẹ́ kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá. Ǹjẹ́ ìrètí wà pé ìgbà kan ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn yóò máa fi òtítọ́ bá ara wọn lò?

Ó dùn mọ́ni gan-an pé Bíbélì fi hàn pé ó máa rí bẹ́ẹ̀! Ó ní Ọlọ́run máa tó ṣe nǹkan kan láti mú kí ìwà ìbàjẹ́ dópin nínú ayé. Báwo ló ṣe máa ṣe é? Ìjọba rẹ̀ tó ń ṣàkóso láti ọ̀run, ló máa lò láti fi mú kí gbogbo ayé yí pa dà pátápátá. Ìjọba yìí ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún. Jésù sọ nínú àdúrà tí àwọn èèyàn ń pè ní Àdúrà Olúwa, pé: “Kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe ní ayé.”—Mátíù 6:10, Ìròhìn Ayọ̀.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi Ọba Ìjọba yẹn pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 72:12-14) Kíyè sí i pé àánú àwọn tí wọ́n hu ìwà ìbàjẹ́ sí máa ń ṣe Jésù, yóò sì wá nǹkan ṣe sí bí wọ́n ṣe ń tẹ àwọn èèyàn lórí ba! Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí tuni nínú gan-an!

Nígbà tí Jésù aláàánú àti alágbára yìí bá ń ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, yóò fòpin sí ìwà ìbàjẹ́ ní gbogbo ayé. Báwo ló ṣe máa ṣe é? Ṣe ni yóò mú kí ohun mẹ́ta tó ń fa ìwà ìbàjẹ́ kásẹ̀ nílẹ̀.

Ipa Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Ń Ní Lórí Wa

Ní báyìí, ìjàkadì gidi ni gbogbo wa máa ń jà ká tó lè borí ẹran ara wa ẹlẹ́ṣẹ̀ tó máa ń fẹ́ mú ká hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan. (Róòmù 7:21-23) Síbẹ̀, àwọn èèyàn dáadáa ṣì wà tó fẹ́ láti máa ṣe ohun tó tọ́. Wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà, ìyẹn ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ta sílẹ̀, èyí sì ń jẹ́ kí wọ́n rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. * (1 Jòhánù 1:7, 9) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè jàǹfààní ìfẹ́ ńláǹlà tí Ọlọ́run fi hàn sí wa, tí Jòhánù 3:16 sọ, pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

Ọlọ́run máa ṣe ohun àgbàyanu fún àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ nínú ayé tuntun, Ọlọ́run yóò mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá, yóò sì mú kí àwọn olóòótọ́ èèyàn di ẹ̀dá pípé tó kà sí olódodo. (Aísáyà 26:9; 2 Pétérù 3:13) Kò ní sí pé ẹran ara wa ẹlẹ́ṣẹ̀ ń mú kí ẹnikẹ́ni hùwà ìbàjẹ́ mọ́. Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, àwọn olóòótọ́ yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ohun tó ń múni hùwà ìbàjẹ́.—Róòmù 8:20-22.

Ipa Tí Ayé Burúkú Tí À Ń Gbé Yìí Ń Ní Lórí Wa

Ó bani nínú jẹ́ pé, lóde òní ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń mọ̀ọ́mọ̀ hùwà ìkà sí ọmọnìkejì wọn. Wọ́n máa ń rẹ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àti aláìní jẹ, wọ́n sì tún máa ń kó ìwà ìbàjẹ́ ran àwọn míì. Bíbélì gba irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ níyànjú pé: “Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí apanilára sì fi ìrònú rẹ̀ sílẹ̀.” Tí irú àwọn oníwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ bá ronú pìwà dà, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “yóò dárí jì lọ́nà títóbi.”—Aísáyà 55:7.

Àmọ́ o, ṣe ni Ọlọ́run máa pa àwọn tí wọ́n bá kọ̀ láti yí pa dà rún. Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì ṣẹ, ìyẹn ìlérí tó ṣe pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́ . . . Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.” * (Sáàmù 37:34) Tí àwọn ẹni ibi tó kọ̀ láti yí pa dà kò bá sí mọ́, kò ní sí oníwà ìbàjẹ́ tí yóò máa yọ àwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lẹ́nu mọ́.

Ipa Tí Sátánì Èṣù Ń Ní Lórí Ẹni

Sátánì Èṣù ni olórí nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó fàáké kọ́rí tí wọn kò ronú pìwà dà. Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà yóò ká a lọ́wọ́ kò láìpẹ́, tí kò fi ní lè nípa lórí àwọn èèyàn. Níkẹyìn, Ọlọ́run yóò wá pa á run pátápátá. Sátánì òkú òǹrorò yìí kò sì ní lè mú kí àwọn èèyàn máa hùwà ìbàjẹ́ mọ́ títí láé.

Lóòótọ́, ó lè dà bí àlá tí kò lè ṣẹ pé Ọlọ́run máa mú gbogbo ohun tó ń fa ìwà ìbàjẹ́ kúrò pátápátá. O lè máa rò ó pé, ‘Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ lè mú kí irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ wáyé? Tó bá sì lè ṣe é, kí ló dé tí kò fi tíì ṣe é?’ Àwọn ìbéèrè yẹn ṣe pàtàkì gan-an, Bíbélì sì dáhùn wọn lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn. * A rọ̀ ọ́ pé kí o fúnra rẹ ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ọjọ́ iwájú, nígbà tí gbogbo ìwà ìbàjẹ́ kò ní sí mọ́ títí láé.

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ẹbọ ìràpadà Jésù, ka orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.