Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Má Ṣe Máa Wá Ipò Ńlá!

Má Ṣe Máa Wá Ipò Ńlá!

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀. Jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Dáfídì, Ábúsálómù àti Jóábù

Àkópọ̀: Ábúsálómù fẹ́ fi ọgbọ́n lé bàbá rẹ̀ kúrò ní ipò ọba kí òun wá di ọba.

KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA 2 SÁMÚẸ́LÌ 14:25-33; 15:1-17; 18:9-17, 30-33.

Sọ bí Ábúsálómù ṣe rí lójú tìrẹ. (Tún ka 2 Sámúẹ́lì 14:25, 26.)

Kí lo rò pé Ábúsálómù ṣe, báwo sì ni ojú rẹ̀ àti ohùn rẹ̀ ṣe rí nígbà tó ń dọ́gbọ́n ṣe bí ọ̀rẹ́ sí àwọn tó ń wá fi ẹjọ́ sùn lọ́dọ̀ ọba? (Tún 2 Sámúẹ́lì 15:2-6 kà.)

Nígbà tó o ka ohun tí Ábúsálómù ṣe nínú 2 Sámúẹ́lì 14:28-30, irú èèyàn wo lo rò pé ó jẹ́?

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Kí ni Ábúsálómù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kó lè gba ìjọba lọ́wọ́ bàbá rẹ̀? (Ojútùú: Ka 2 Sámúẹ́lì 13:28, 29. Ámínónì ni ó dàgbà jù láàárín àwọn ọmọkùnrin Dáfídì, torí náà òun ni ó yẹ kó di ọba lẹ́yìn bàbá rẹ̀.)

Lóòótọ́ Ábúsálómù wá ipò ńlá àti ògo fún ara rẹ̀, àmọ́ tó o bá wo bí wọ́n ṣe sin òkú rẹ̀, irú èèyàn wo ni àwọn èèyàn kà á sí? (Ka 2 Sámúẹ́lì 18:17.)

Kí lo rò pé ó mú kí Ábúsálómù máa wá bó ṣe máa wà ní ipò ńlá? (Láti rí ìwà ẹni tó jọ tirẹ̀, ka ohun tí Bíbélì sọ nípa Dìótíréfè nínú 3 Jòhánù 9, 10.)

Báwo ni ohun tí Ábúsálómù ṣe ṣe rí lára Dáfídì? (Ojútùú: Ka Sáàmù 3, tí Dáfídì kọ nígbà tí Ábúsálómù fẹ́ pa á.)

MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ewu tó wà nínú kéèyàn máa wá ipò ńlá.

Ìbànújẹ́ tí ohun tí ẹnì kan ṣe lè fà bá àwọn míì, títí kan àwọn òbí rẹ̀.

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Kí lo rò pé ó lè mú kí o bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó o ṣe máa wà ní ipò ńlá?

Kí lo lè ṣe kí o má bàa di agbéraga?

KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

Àbá kan rèé: Ronú ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí ìtàn yìí ì bá fi parí sí ibi tó dára. Kí ni ì bá ṣẹlẹ̀ ká ní Ábúsálómù hùwà ìrẹ̀lẹ̀ dípò tó fi ń wá ipò ńlá?—Òwe 18:12.