Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Kí Bẹ́ẹ̀ Ni Rẹ Jẹ́ Bẹ́ẹ̀ Ni

Jẹ́ Kí Bẹ́ẹ̀ Ni Rẹ Jẹ́ Bẹ́ẹ̀ Ni

“Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.”—MÁT. 5:37.

1. Kí ni Jésù sọ nípa bíbúra, kí sì nìdí?

 KÌ Í ṣe àṣà àwa Kristẹni tòótọ́ pé ká máa búra. Ìdí ni pé a máa ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù tó sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni.” Ohun tí Jésù ń sọ ni pé bí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀, ńṣe ló yẹ ká bá ọ̀rọ̀ náà bẹ́ẹ̀. Kí Jésù tó pa àṣẹ yẹn, ó ti kọ́kọ́ sọ pé: “Má ṣe búra rárá.” Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí láti fi hàn pé àṣà káwọn èèyàn máa búra nínú ọ̀rọ̀ wọn ojoojúmọ́ láìní ṣe ohun tí wọ́n torí rẹ̀ búra kò dára. Bí àwọn èèyàn yẹn ṣe ń sọ ‘ohun tí ó ju’ Bẹ́ẹ̀ ni tàbí Bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn ò ṣeé fọkàn tán àti pé abẹ́ ìdarí “ẹni burúkú náà” làwọn wà.—Ka Mátíù 5:33-37.

2. Ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló burú kéèyàn búra.

2 Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé gbogbo ìbúra ni kò dára? Rárá o! Bí a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, Jèhófà Ọlọ́run àti Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀ olódodo búra láwọn àkókò pàtàkì kan. Bákan náà, Òfin Ọlọ́run sọ pé kí àwọn èèyàn tó lè yanjú àwọn ọ̀ràn kan, wọ́n gbọ́dọ̀ búra. (Ẹ́kís. 22:10, 11; Núm. 5:21, 22) Torí náà, ó lè pọn dandan pé kí Kristẹni kan búra nígbà tó bá ń jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ kan ní ilé ẹjọ́. Nígbà míì sì rèé, ó lè pọn dandan pé kí Kristẹni kan búra láti fi hàn pé òótọ́ lòun máa ṣe ohun kan tàbí kó búra láti fi hàn pé òótọ́ tó wà nídìí ọ̀rọ̀ kan lòun máa sọ. Kódà, nígbà tí àlùfáà àgbà sọ pé kí Jésù búra, kò jiyàn, àmọ́ ńṣe ló wulẹ̀ sọ òótọ́ pọ́ńbélé fún ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ti àwọn Júù. (Mát. 26:63, 64) Ṣùgbọ́n, Jésù kò nílò láti búra fún ẹnikẹ́ni. Síbẹ̀, kó bàa lè fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni òun ń sọ, kó tó sọ ọ̀rọ̀ kan, ó sábà máa ń kọ́kọ́ sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín.” (Jòh. 1:51; 13:16, 20, 21, 38) Ẹ jẹ́ ká tún wo ohun míì tá a lè kọ́ lára Jésù, Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì tí wọ́n jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wọn jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni.

JÉSÙ FI ÀPẸẸRẸ TÓ DÁRA JÙ LỌ LÉLẸ̀

3. Ìlérí wo ni Jésù ṣe fún Ọlọ́run nígbà tó ń gbàdúrà, kí sì ni Baba rẹ̀ ọ̀run sọ?

3 “Wò ó! . . . Mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.” (Héb. 10:7) Ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ yìí ni Jésù fi sọ fún Ọlọ́run pé òun ṣe tán láti ṣe gbogbo nǹkan tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Irú-ọmọ tí a ṣèlérí náà, títí kan bí Sátánì ṣe máa “pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́n. 3:15) Yàtọ̀ sí Jésù, kò tún sí èèyàn míì tó tíì yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe irú iṣẹ́ ńlá bẹ́ẹ̀. Jèhófà wá sọ̀rọ̀ láti ọ̀run láti fi hàn pé òun fọkàn tán Ọmọ òun pátápátá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní kí Jésù búra kí òun lè gbà gbọ́ pé òótọ́ ló máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.—Lúùkù 3:21, 22.

4. Kí ni Bíbélì sọ tó fi hàn dájú pé Jésù máa ń jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni rẹ̀ jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni?

4 Ìgbà gbogbo ni Bẹ́ẹ̀ ni Jésù máa ń jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni, ní ti pé ó máa ń fi ohun tó ń wàásù ṣèwà hù. Kò jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí Baba rẹ̀ gbé lé e lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn tí Ọlọ́run fà wá sọ́dọ̀ Jésù di ọmọ ẹ̀yìn. (Jòh. 6:44) Kódà, Bíbélì sọ ọ̀rọ̀ kan tá a mọ̀ dáadáa tó fi hàn bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ tó. Ó sọ pé: “Bí ó ti wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di Bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ rẹ̀.” (2 Kọ́r. 1:20) Kò sí àní-àní pé, Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ ní ti pé ó mú ìlérí tó ṣe fún Baba rẹ̀ ṣẹ. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù.

PỌ́Ọ̀LÙ ṢEÉ FỌKÀN TÁN

5. Àpẹẹrẹ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ fún wa?

5 “Kí ni kí n ṣe, Olúwa?” (Ìṣe 22:10) Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n mọ̀ sí Sọ́ọ̀lù nígbà yẹn, ló béèrè ìbéèrè àtọkànwá yìí nígbà tí Jésù Olúwa tí a ti ṣe lógo fara hàn án nínú ìran tó sì sọ fún un pé kó jáwọ́ nínú ṣíṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. Àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni pé, Sọ́ọ̀lù fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sẹ́yìn, ó ṣèrìbọmi, ó sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àkànṣe tá a gbé lé e lọ́wọ́ pé kó máa jẹ́rìí Jésù fún àwọn orílẹ̀-èdè. Láti ìgbà náà lọ ni Pọ́ọ̀lù ti ń pe Jésù ní “Olúwa,” ó sì ń ṣe ohun tó fi hàn pé òótọ́ ló gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Olúwa rẹ̀ títí tó fi kú. (Ìṣe 22:6-16; 2 Kọ́r. 4:5; 2 Tím. 4:8) Pọ́ọ̀lù kò dà bí àwọn tí Jésù sọ fún pé: “Èé ṣe tí ẹ fi wá ń pè mí ní ‘Olúwa! Olúwa!’ ṣùgbọ́n tí ẹ kò ṣe àwọn ohun tí mo wí?” (Lúùkù 6:46) Ó dájú pé Jésù retí pé kí àwọn tó bá gbà á gẹ́gẹ́ bí Olúwa wọn máa mú ìlérí wọn ṣẹ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣe.

6, 7. (a) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù kò fi lọ sí Kọ́ríńtì ní àkókò tó pinnu, kí sì nìdí tí kò fi tọ̀nà fún àwọn alátakò rẹ̀ láti sọ pé kò ṣeé fọkàn tán? (b) Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tá a yàn sípò láti máa mú ipò iwájú láàárín wa?

6 Pọ́ọ̀lù fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run káàkiri Éṣíà Kékeré àti ilẹ̀ Yúróòpù, ó ń dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀ ó sì ń pa dà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn. Nígbà kan, ó rí i pé ó pọn dandan pé kí òun búra láti fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí òun kọ. (Gál. 1:20) Nígbà tí àwọn kan ní ìlú Kọ́ríńtì sọ pé Pọ́ọ̀lù kò ṣeé fọkàn tán, ó kọ lẹ́tà kan láti gbèjà ara rẹ̀, ó ní: “Ọlọ́run ṣeé gbójú lé pé ọ̀rọ̀ wa tí a sọ fún yín kì í ṣe Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀ kí ó sì jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (2 Kọ́r. 1:18) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yẹn, ó ti kúrò ní ìlú Éfésù, ó sì ń rìnrìn-àjò gba Makedóníà kọjá lọ sí ìlú Kọ́ríńtì. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ó ní in lọ́kàn láti pa dà lọ ṣèbẹ̀wò sí ìlú Kọ́ríńtì kó tó lọ sí Makedóníà. (2 Kọ́r. 1:15, 16) Ṣùgbọ́n, bíi ti àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lóde-òní, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ nígbà míì tó máa mú kí ìgbà tí wọ́n máa bẹ àwọn ìjọ kan wò yí pa dà. Irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ kì í wáyé torí ìdí tí kò ṣe pàtàkì tàbí kí wọ́n lè tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn, àfi bí ohun pàjáwìrì kan bá ṣẹlẹ̀. Ní ti Pọ́ọ̀lù, torí àǹfààní àwọn tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì ni kò ṣe lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn ní àkókò tó pinnu. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

7 Nígbà kan lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti pinnu láti rìnrìn-àjò lọ sí ìlú Kọ́ríńtì, ó gbọ́ ìròyìn tí kò bára dé pé àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ ń fàyè gba ìyapa àti ìṣekúṣe. (1 Kọ́r. 1:11; 5:1) Kí Pọ́ọ̀lù lè yanjú ọ̀ràn náà, ó kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì, ó sì fún wọn ní ìmọ̀ràn tó lágbára nínú lẹ́tà náà. Lẹ́yìn náà, dípò tí Pọ́ọ̀lù ì bá fi wọkọ̀ ojú omi tààràtà láti ìlú Éfésù lọ sí ìlú Kọ́ríńtì, ó pinnu láti fún àwọn ará náà ní àkókò láti ronú lórí ìmọ̀ràn tó fún wọn kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ lé e lórí, kó lè jẹ́ pé nígbà tó bá pa dà dé, ìbẹ̀wò rẹ̀ á lè túbọ̀ fún wọn níṣìírí. Àmọ́, kí wọ́n lè mọ ohun tó fà á tí kò fi wá sọ́dọ̀ wọn ní àkókò tó pinnu, ó sọ fún wọn nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì pé: “Mo ké pe Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí lòdì sí ọkàn èmi tìkára mi pé láti dá yín sí ni kò tíì jẹ́ kí n wá sí Kọ́ríńtì.” (2 Kọ́r. 1:23) Ẹ má ṣe jẹ́ ká dà bí àwọn alátakò Pọ́ọ̀lù; kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa fi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn fún àwọn tá a yàn láti máa mú ipò iwájú láàárín wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa tẹ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, bí òun pẹ̀lú ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi.—1 Kọ́r. 11:1; Héb. 13:7.

ÀWỌN ÀPẸẸRẸ RERE MÌÍRÀN

8. Àpẹẹrẹ wo ni Rèbékà fi lélẹ̀ fún wa?

8 “Mo múra tán láti lọ.” (Jẹ́n. 24:58) Ọ̀rọ̀ ṣókí yìí ni Rèbékà fi dáhùn nígbà tí ìyá rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó wù ú láti fi ilé sílẹ̀ lọ́jọ́ yẹn gangan kó sì bá àjèjì kan rìnrìn-àjò tí ó ju ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà lọ, kí ó lè di aya Ísákì ọmọ Ábúráhámù. (Jẹ́n. 24:50-58) Rèbékà jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni rẹ̀ jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni, ó sì fi hàn pé aya olóòótọ́ àti olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni òun jẹ́ fún Ísákì. Ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀ tó kù, ó gbé inú àgọ́ gẹ́gẹ́ bí àtìpó ní Ilẹ̀ Ìlérí. Ó rí èrè ìṣòtítọ́ rẹ̀ gbà ní ti pé ó di ọ̀kan lára àwọn ìyá ńlá fún Irú-ọmọ tí a ṣèlérí náà, Jésù Kristi.—Héb. 11:9, 13.

9. Báwo ni Rúùtù ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ?

9 “Rárá, ṣùgbọ́n àwa yóò bá ọ padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.” (Rúùtù 1:10) Rúùtù àti Ópà, àwọn opó tó jẹ́ ọmọ ìlú Móábù ló ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Náómì ìyá ọkọ wọn tí òun náà jẹ́ opó, nígbà tó kúrò ní Móábù tó sì ń pa dà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nígbà tí Náómì ṣáà ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n pa dà, níkẹyìn Ópà pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, Rúùtù jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ kọ́ rẹ̀ jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́. (Ka Rúùtù 1:16, 17.) Ó dúró ṣinṣin ti Náómì, ó sì fi ìdílé rẹ̀ àti ẹ̀sìn èké tí wọ́n ń ṣe ní Móábù sílẹ̀ títí gbére. Kò dẹ́kun láti máa fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà, ó sì rí ìbùkún Jèhófà gbà. Kódà, ó wà lára àwọn obìnrin márùn-ún péré tí Mátíù to orúkọ wọn sára ìlà ìdílé Kristi.—Mát. 1:1, 3, 5, 6, 16.

10. Kí nìdí tí Aísáyà fi jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa?

10 “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8) Kí Aísáyà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó ti rí ìran ológo kan nínú èyí tí Jèhófà jókòó lórí ìtẹ́ Rẹ̀ lókè tẹ́ńpìlì Ísírẹ́lì. Bí Aísáyà ṣe tẹjú mọ́ ìran ológo yìí, ó gbọ́ tí Jèhófà sọ pé: “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?” Ńṣe ni Jèhófà ń tipa báyìí wá ẹni tó máa lọ ṣe agbẹnusọ fún un, kó lè jíhìn iṣẹ́ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn Rẹ̀ tí wọ́n ti di oníwàkiwà. Aísáyà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, ó jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni òun jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni. Ó fi ìṣòtítọ́ sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì fún ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta [46], ó ń jíṣẹ́ ìdálẹ́bi tó rinlẹ̀ fún àwọn èèyàn, ó sì ń sọ àwọn ìlérí àgbàyanu nípa bí Ọlọ́run ṣe máa mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò.

11. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa mú ìlérí wa ṣẹ? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn kan tí kò sòótọ́, báwo nìyẹn sì ṣe jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa?

11 Kí nìdí tí Jèhófà fi mú kí a ṣàkọsílẹ̀ àwọn àpẹẹrẹ yìí fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀? Báwo ló sì ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wa jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni? Bíbélì kìlọ̀ fún wa lọ́nà tó ṣe kedere pé ẹni tó bá jẹ́ “olùyẹ àdéhùn” wà lára àwọn tó “yẹ fún ikú.” (Róòmù 1:31, 32) Fáráò ti ilẹ̀ Íjíbítì, Sedekáyà Ọba Jùdíà àti Ananíà àti Sáfírà wà lára àwọn àpẹẹrẹ burúkú tó wà nínú Bíbélì nípa àwọn tí kò jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wọn jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni. Láburú ló gbẹ̀yìn gbogbo wọn, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa.—Ẹ́kís. 9:27, 28, 34, 35; Ìsík. 17:13-15, 19, 20; Ìṣe 5:1-10.

12. Kí ló máa jẹ́ ká lè máa mú ìlérí wa ṣẹ?

12 Torí pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí, àwọn èèyàn tó yí wa ká jẹ́ “aláìdúróṣinṣin,” àwọn tí wọ́n “ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (2 Tím. 3:1-5) Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, a gbọ́dọ̀ yẹra fún irú àwọn ẹgbẹ́ búburú bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ká máa pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn tó ń sapá nígbà gbogbo láti jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wọn jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni.—Héb. 10:24, 25.

BẸ́Ẹ̀ NI TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ LỌ TÓ O SỌ

13. Bẹ́ẹ̀ ni tó ṣe pàtàkì jù lọ wo ni ẹnì kan tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi sọ?

13 Ìyàsímímọ́ sí Ọlọ́run ni ìlérí tó ṣe pàtàkì jù lọ tí èèyàn kan lè ṣe. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn tó bá fẹ́ láti sẹ́ ara wọn kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní àǹfààní láti sọ pé Bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí wọ́n bá ní kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n pinnu láti ṣe. (Mát. 16:24) Nígbà tí àwọn alàgbà méjì bá fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó fẹ́ di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, wọ́n á bi onítọ̀hún pé, “Ṣé òótọ́ lo fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” Lẹ́yìn èyí, nígbà tí ẹni náà bá ti tẹ̀ síwájú sí i nípa tẹ̀mí tó sì wù ú pé kí àwọn alàgbà fọwọ́ sí i pé kó ṣèrìbọmi, àwọn alàgbà á pàdé pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n á sì bi í pé, “Ṣé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà?” Tó bá wá di ọjọ́ ìrìbọmi, olùbánisọ̀rọ̀ á bi àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi pé, “Lọ́lá ẹbọ Jésù Kristi, ǹjẹ́ o ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ṣé o sì ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀?” Nípa báyìí, níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn ẹni tuntun yìí á sọ pé Bẹ́ẹ̀ ni láti fi hàn pé àwọn ti ṣèlérí pé títí ayé làwọn á máa sin Ọlọ́run.

14. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká máa bí ara wa látìgbàdégbà?

14 Yálà o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tàbí ọjọ́ pẹ́ tó o ti ń sin Ọlọ́run bọ̀, ó yẹ kó o máa ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀ látìgbàdégbà, kó o sì bi ara rẹ̀ láwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: ‘Bíi ti Jésù Kristi, ǹjẹ́ mo ṣì ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Bẹ́ẹ̀ ni tó ṣe pàtàkì jù lọ tí mo sọ? Ṣé mo ṣì ń bá a nìṣó láti jẹ́ kí ṣíṣe ìgbọràn sí àṣẹ Jésù pé ká máa wàásù ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé mi?’—Ka 2 Kọ́ríńtì 13:5.

15. Láwọn ìgbà wo nínú ìgbésí ayé wa ló yẹ ká máa jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wa jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni?

15 Tá a bá fẹ́ máa mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ, a tún gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ nínú àwọn ọ̀ràn pàtàkì míì nínú ìgbésí ayé wa. Bí àpẹẹrẹ: Ǹjẹ́ o ti ṣègbéyàwó? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa bá a nìṣó láti fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ tó ṣeyebíye tó o jẹ́ pé wàá máa nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ, wàá sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ ìwọ àti ẹnì kan ti tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn iṣẹ́ tàbí o ti kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù torí àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ olóòótọ́, má sì ṣe yẹ àdéhùn tó o ṣe. Ṣé o ti gbà láti lọ sílé ẹnì kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ tó sọ pé kó o wá jẹun nílé òun? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe yẹ àdéhùn yẹn torí pé ẹlòmíì tó rí já jẹ dáadáa pè ẹ́. Àbí o ti ṣèlérí fún ẹnì kan tó o wàásù fún lóde ẹ̀rí pé o máa pa dà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kó o lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni rẹ jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yóò sì bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.—Ka Lúùkù 16:10.

BÁ A ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ LÁTỌ̀DỌ̀ ÀLÙFÁÀ ÀGBÀ ÀTI ỌBA WA

16. Bí a kò bá mú ìlérí wa ṣẹ, kí ló yẹ ká ṣe?

16 Bíbélì sọ pé nítorí pé a jẹ́ aláìpé, “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà,” pàápàá jù lọ nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀. (Ják. 3:2) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé a kò mú ìlérí wa ṣẹ? Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ṣe ètò kan tó fi àánú hàn fún ẹnì kan tó bá jẹ̀bi fífi “ètè rẹ̀ sọ̀rọ̀ láìronú.” (Léf. 5:4-7, 11) Ètò kan tó fìfẹ́ hàn tún wà fún Kristẹni kan tó bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí. Tá a bá jẹ́wọ́ fún Jèhófà pé ìlérí kan wà tí a kò mú ṣẹ, ó máa fi àánú hàn sí wa, a sì máa rí ìdáríjì gbà nípasẹ̀ Àlùfáà Àgbà wa, Jésù Kristi. (1 Jòh. 2:1, 2) Àmọ́, tá a bá fẹ́ máa bá a nìṣó láti rí ojú rere Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó fi hàn pé òótọ́ la ti ronú pìwà dà nípa ṣíṣàì sọ irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ di àṣà, ká sì máa ṣe gbogbo ohun tó bá wà ní agbára wa láti ṣàtúnṣe ìpalára èyíkéyìí tó bá ti wáyé nítorí ọ̀rọ̀ àìnírònú tá a sọ. (Òwe 6:2, 3) Ohun tó dáa jù lọ ni pé, ká máa fara balẹ̀ ronú dáadáa ká tó máa ṣèlérí, ká má lọ sọ ohun tí a kò ní lè ṣe.—Ka Oníwàásù 5:2.

17, 18. Ọjọ́ ọ̀la ológo wo ló ń dúró de gbogbo àwọn tó bá jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wọn jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni?

17 Ọjọ́ ọ̀la ológo ń dúró de gbogbo àwọn olùjọsìn Jèhófà tó ń sapá láti jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wọn jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró máa wà láàyè títí láé ní ọ̀run, níbi tí wọn yóò ti máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba rẹ̀, “wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣí. 20:6) Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó kù a máa gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n máa rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti di ẹni pípé. Wọ́n á ní ìlera tó jíire, wọ́n á sì máa ronú lọ́nà tó já gaara.—Ìṣí. 21:3-5.

18 Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nígbà ìdánwò ìkẹyìn tó máa wáyé ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Jésù, a ò ní máa ṣiyè méjì mọ́ nípa ọ̀rọ̀ tí ẹnikẹ́ni bá sọ. (Ìṣí. 20:7-10) Gbogbo Bẹ́ẹ̀ ni ló máa jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo Bẹ́ẹ̀ kọ́ á sì jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́. Torí pé, tó bá dìgbà yẹn, gbogbo èèyàn pátá ló máa fìwà jọ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, Jèhófà “Ọlọ́run òtítọ́.”—Sm. 31:5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Látìgbà tí Jésù ti ṣèrìbọmi títí tó fi kú, ó mú ìlérí tó ṣe fún Baba rẹ̀ ṣẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ǹjẹ́ ò ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Bẹ́ẹ̀ ni tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o sọ?