Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Hùwà Bí Ẹni Tó Kéré Jù

Máa Hùwà Bí Ẹni Tó Kéré Jù

“Ẹni tí ó bá hùwà bí ẹni tí ó kéré jù láàárín gbogbo yín ni ẹni ńlá.”—LÚÙKÙ 9:48.

1, 2. Ìṣílétí wo ni Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀? Kí nìdí tó fi fún wọn ní ìṣílétí?

 OHUN kan ṣẹlẹ̀ ní ọdún 32 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Jésù wà lágbègbè Gálílì. Àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń bára wọn jiyàn nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láàárín wọn. Òǹkọ̀wé ìhìn rere náà, Lúùkù sọ pé: “Èrò kan wọ àárín wọn ní ti ẹni tí yóò jẹ́ ẹni ńlá jù lọ nínú wọn. Jésù, ní mímọ èrò ọkàn-àyà wọn, mú ọmọ kékeré kan, ó gbé e dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ó sì wí fún wọn pé: ‘Ẹnì yòówù tí ó bá gba ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi gbà mí pẹ̀lú, ẹnì yòówù tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó rán mi jáde pẹ̀lú. Nítorí ẹni tí ó bá hùwà bí ẹni tí ó kéré jù láàárín gbogbo yín ni ẹni ńlá.’” (Lúùkù 9:46-48) Jésù fi sùúrù ṣàlàyé ìdí tó fi pọn dandan pé káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.

2 Ǹjẹ́ àwọn Júù tó gbáyé ní ọ̀rúndún kìíní gbà pé ó yẹ kéèyàn máa hùwà bí ẹni tó kéré jù? Rárá, wọn kò gbà bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ìwé atúmọ̀ èdè kan tó dá lórí ẹ̀kọ́ ìsìn, ìyẹn Theological Dictionary of the New Testament, ń ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí láwùjọ àwọn tó gbáyé nígbà yẹn, ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù sábà máa ń jẹ yọ nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe, kò sì sẹ́ni tí kì í fẹ́ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ wọ òun.” Àmọ́, Jésù ṣí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ létí torí pé kò fẹ́ kí wọ́n dà bí àwọn èèyàn ìgbà yẹn.

3. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn máa ṣe bí ẹni tó kéré jù? Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún wa láti máa hùwà bí ẹni tó kéré jù? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ nípa híhùwà bí ẹni tó kéré jù?

3 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ẹni tí ó kéré jù” lédè Yorùbá túmọ̀ sí ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, onírẹ̀lẹ̀, ẹni tí kì í ṣe èèyàn ńlá, ẹni tí kò gbà pé òun san ju àwọn míì lọ, tí kì í sì í ṣe ẹni táwọn èèyàn ń wárí fún. Kí ohun tí Jésù ń sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lè yé wọn dáadáa ó fi ọmọ kékeré kan ṣàpèjúwe bí wọ́n ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ ìṣítí yẹn ṣe wúlò fún àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní náà ló ṣe wúlò fún àwa Kristẹni tòótọ́ lónìí. Ó lè má rọrùn fún wa nígbà míì láti máa hùwà bí ẹni tó kéré jù. Àìpé máa ń mú kí àwa ẹ̀dá èèyàn gbéra ga, èyí sì máa ń mú ká wá ipò ọlá. Ẹ̀mí ìbára-ẹni-díje tó gbilẹ̀ nínú ayé lè mú ká di ajọra-ẹni-lójú, aríjàgbá, tàbí ẹlẹ̀tàn. Kí ló lè mú ká máa hùwà bí ẹni tó kéré jù? Báwo ni ‘ẹni tí ó kéré jù láàárín wa ṣe jẹ́ ẹni ńlá’? Àwọn ìgbà wo ló yẹ ká máa sapá láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn?

“ÌJÌNLẸ̀ ÀWỌN ỌRỌ̀ ÀTI ỌGBỌ́N ÀTI ÌMỌ̀ ỌLỌ́RUN MÀ PỌ̀ O!”

4, 5. Kí ló lè mú ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.

4 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni pé ká máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe tóbi lọ́lá jù wá lọ. Ìwé Mímọ́ tiẹ̀ sọ pé “kò sí àwárí òye rẹ̀.” (Aísá. 40:28) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bí Jèhófà ṣe tóbi lọ́lá tó, ó ní: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!” (Róòmù 11:33) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ aráyé ti pọ̀ sí i látìgbà tí Pọ́ọ̀lù ti sọ̀rọ̀ yìí ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, òótọ́ ṣì lọ̀rọ̀ yẹn. Bó ti wù kí ohun tá a mọ̀ pọ̀ tó, kò sí bá a ṣe lè mọ ohun gbogbo tán nípa Jèhófà, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àti ìrònú rẹ̀.

5 Ohun tó ran ẹnì kan tó ń jẹ́ Leo * lọ́wọ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara rẹ̀ bí ẹni tó kéré jù ni pé ó mọ̀ pé àwámárìídìí ni àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run. Látìgbà tí Leo ti wà ní ọ̀dọ́ ló ti fẹ́ràn ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ó wù ú kó mọ gbogbo ohun tó bá lè mọ̀ nípa àgbáyé, torí náà ó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà lójú sánmà. Ìyẹn gan-an ló sì mú kó ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Ó sọ pé: “Ohun tí mo kọ́ mú kí ń rí i pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nìkan ò lè mú kí aráyé lóye gbogbo nǹkan tó wà lágbàáyé. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òfin.” Nígbà tó ṣe, Leo di agbẹjọ́rò, lẹ́yìn ìgbà náà ló wá di adájọ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ òun àti ìyàwó rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn méjèèjì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Pẹ̀lú gbogbo ìwé tí Leo kà, kí ló mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà bí ẹni tó kéré jù? Ó dáhùn pé, “Mo ti wá gbà pé bó ti wù ká mọ̀ nípa Jèhófà àti àgbáyé yìí tó, ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà tó yẹ ká mọ̀.”

6, 7. (a) Báwo ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó pabanbarì fún wa? (b) Báwo ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Ọlọ́run ṣe lè sọni di “ńlá”?

6 Ohun mìíràn tó lè mú ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni pé Jèhófà fúnra rẹ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:9) Jèhófà, Ọlọ́run tí gíga rẹ̀ kò láfiwé, sọ pé a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òun. Ìyẹn mà ga o! Ọlọ́run buyì kún wa nípa fífún wa ní àǹfààní láti máa fi Bíbélì wàásù ìhìn rere. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló ń mú kí àwọn irúgbìn tá à ń gbìn tá a sì ń bomi rin máa hù, ipò tó lọ́lá ló fi wá sí gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. (1 Kọ́r. 3:6, 7) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó pabanbarì ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí Ọlọ́run fi hàn yìí jẹ́ fún wa! Dájúdájú, ó yẹ kí àpẹẹrẹ tí Jèhófà fi lélẹ̀ fún wa yìí mú kí olúkúlùkù wa máa hùwà bí ẹni tó kéré jù.

7 Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Ọlọ́run wọ onísáàmù náà, Dáfídì lọ́kàn ṣinṣin. Èyí mú kó sọ fún Jèhófà nínú orin tó kọ pé: “Ìwọ yóò sì fún mi ní apata ìgbàlà rẹ, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni ó sọ mí di ńlá.” (2 Sám. 22:36) Dáfídì gbà pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà, ìyẹn bí Ọlọ́run ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ débi tó fi lè rí òun, ló mú kí òun lè wà ní ipò ńlá ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (Sm. 113:5-7) Àwa náà ńkọ́? Tá a bá ní ànímọ́, òye àti àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí, èwo níbẹ̀ la ní tí ‘kì í ṣe pé a gbà’ látọ̀dọ̀ Jèhófà? (1 Kọ́r. 4:7) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí ẹni tó bá ń hùwà bí ẹni tó kéré jù gbà jẹ́ ẹni “ńlá” ni pé á jẹ́ ìránṣẹ́ tó túbọ̀ wúlò fún Jèhófà. (Lúùkù 9:48) Ẹ jẹ́ ká wo bí èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀.

‘ẸNI TÍ Ó KÉRÉ JÙ LÁÀÁRÍN YÍN NI ẸNI ŃLÁ’

8. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwa tá a wà nínú ètò Jèhófà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

8 Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká bàa lè ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ètò Ọlọ́run ká sì lè máa kọ́wọ́ ti ètò tí ìjọ bá ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Petra, ọ̀dọ́bìnrin kan tí àwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tọ́ dàgbà. Torí pé Petra máa ń fẹ́ láti ṣe bó ti wù ú, kò lọ sí ìpàdé mọ́. Ṣùgbọ́n, ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé. Ní báyìí, inú rẹ̀ dùn pé òun wà nínú ètò Jèhófà, ó sì ń kọ́wọ́ ti ètò tí ìjọ bá ṣe. Kí ló mú kó yí pa dà? Ó sọ pé: “Kí ètò Ọlọ́run lè tù mí lára, mo ti wá rí i pé ó yẹ kí n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí n sì mọ̀wọ̀n ara mi.”

9. Bí ẹnì kan bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ojú wo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ á máa fi wo Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa? Báwo nìyẹn á sì ṣe jẹ́ kó túbọ̀ wúlò fún Jèhófà?

9 Bí ẹnì kan bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó máa mọyì àwọn ohun rere tí Jèhófà ń fún wa, tó fi mọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa. Torí náà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń fi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ó sì máa ń hára gàgà láti ka àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bíi tàwọn olùṣòtítọ́ mìíràn tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, á máa rí i pé òun ń ka gbogbo ìtẹ̀jáde tá a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà kó tó fi wọ́n síbi ìkówèésí rẹ̀. Bí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tá a ní bá mú ká mọrírì àwọn ìtẹ̀jáde wa tó ṣàlàyé Bíbélì débi tá a fi ń kà wọ́n, a óò túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Jèhófà á sì túbọ̀ máa lò wá nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.—Héb. 5:13, 14.

10. Báwo la ṣe lè máa hùwà bí ẹni tó kéré jù nínú ìjọ?

10 Ọ̀nà míì tún wà tí ẹni tó bá ń hùwà bí ẹni tó kéré jù gbà jẹ́ ẹni “ńlá.” Gbogbo ìjọ ló ní àwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yàn, kí wọ́n lè máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Wọ́n máa ń ṣètò àwọn ìpàdé ìjọ àti iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Tá a bá ń fínnú fíndọ̀ kọ́wọ́ ti àwọn ìṣètò yìí, ńṣe là ń hùwà bí ẹni tó kéré jù, a ó sì máa pa kun ayọ̀, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ. (Ka Hébérù 13:7, 17.) Tó o bá jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ṣé o máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún ẹ ní irú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé o jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.

11, 12. Kí nìdí tí ìwà àti ìṣe wa fi gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé?

11 Ẹni tó bá ń hùwà bí ẹni tó kéré jù jẹ́ ẹni “ńlá” tàbí ẹni tó túbọ̀ wúlò fún ètò Jèhófà torí pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ á mú kí Jèhófà lè máa rí i lò. Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa hùwà bí ẹni tó kéré jù. Ìdí sì ni pé ìwà ìgbéraga tó wọ́pọ̀ nígbà yẹn ti ran àwọn kan lára wọn. Ìwé Lúùkù 9:46 sọ pé: “Nígbà náà ni èrò kan wọ àárín wọn ní ti ẹni tí yóò jẹ́ ẹni ńlá jù lọ nínú wọn.” Ṣé a kì í ronú pé a sàn ju àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ tàbí ká máa ronú pé kò sí ẹni tó mọ nǹkan ṣe tó wa? Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé nínú ayé lónìí ló jẹ́ agbéraga àti onímọtara-ẹni-nìkan. Tá a bá fẹ́ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ìwà wa gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí tiwọn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, tá a sì fi ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́, ara á máa tu àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nígbà tí wọ́n bá wà pẹ̀lú wa.

12 Ó dájú pé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Jésù sọ yìí á mú ká lè máa hùwà bí ẹni tó kéré jù nínú ohun gbogbo tá a bá ń ṣe. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa fìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú ìgbéyàwó, nínú ìjọ àti nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn.

SAPÁ LÁTI JẸ́ ẸNI TÓ KÉRÉ JÙ

13, 14. Báwo ni ọkọ tàbí aya ṣe lè máa hùwà bí ẹni tó kéré jù, kí nìyẹn sì máa yọrí sí?

13 Nínú ìgbéyàwó. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń jà fún ẹ̀tọ́ wọn, wọn ò sì kọ̀ kí wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ àwọn míì lójú nítorí ẹ̀. Àmọ́, ẹni tó ń hùwà bí ẹni tó kéré jù yàtọ̀, irú ìwà tí Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká ní ló máa ń hù. Nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Róòmù, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 14:19) Ẹni tó bá ń hùwà bí ẹni tó kéré jù máa ń wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn, pàápàá jù lọ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ̀.

14 Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa eré ìtura. Irú eré ìnàjú tí ọkọ kan fẹ́ràn lè yàtọ̀ sí ti aya rẹ̀. Bóyá ọkọ fẹ́ láti máa jókòó jẹ́ẹ́ sínú ilé kó sì máa kàwé nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá dilẹ̀. Kí ìyàwó sì fẹ́ káwọn máa ṣeré jáde láti lọ jẹun tàbí láti lọ kí àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Ǹjẹ́ kò ní túbọ̀ rọrùn fún irú aya bẹ́ẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ tó bá rí i pé ó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, tó sì tún rí i pé ó máa ń gba tòun rò dípò kó jẹ́ pé tiẹ̀ ṣáá ló ń rò? Ẹ sì wo bí ọkọ ṣe máa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ táá sì tún mọyì rẹ̀ bí kì í bá kàn ṣe ohun tó fẹ́ láì gba ti ọkọ rẹ̀ rò! Bí àwọn méjèèjì bá ń hùwà bí ẹni tó kéré jù lọ́nà yìí, àárín wọn á túbọ̀ gún.—Ka Fílípì 2:1-4.

15, 16. Nínú Sáàmù 131, kí ni Dáfídì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa ṣe? Báwo làwa náà ṣe lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ?

15 Nínú ìjọ. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ̀ ju pé kí ọwọ́ wọn ṣáà ti tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́ lójú ẹsẹ̀. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í fẹ́ ṣe sùúrù rárá. Ṣùgbọ́n, tá a bá ń hùwà bí ẹni tó kéré jù, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti dúró de Jèhófà, ìyẹn ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé e. (Ka Sáàmù 131:1-3.) Àǹfààní púpọ̀ wà nínú dídúró de Jèhófà. Lára wọn ni pé, ó máa dáàbò bò wá, ó máa bù kún wa, ó máa tù wá nínú, ó sì máa mú ká ní ìtẹ́lọ́rùn. Abájọ tí Dáfídì fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa fi sùúrù dúró de Ọlọ́run wọn.

16 Bí ìwọ náà bá ń fìrẹ̀lẹ̀ dúró de Jèhófà bíi ti Dáfídì, o máa rí ìtùnú gbà. (Sm. 42:5) Tó o bá ‘ń fẹ́ iṣẹ́ àtàtà,’ tó o sì ń “nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó” ńkọ́? (1 Tím. 3:1-7) Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe kó o lè fàyè gba ẹ̀mí Ọlọ́run láti mú kó o ní àwọn ànímọ́ tó máa wúlò fún ẹ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó. Àmọ́, tó bá wá dà bíi pé o kò tètè ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn náà bíi tàwọn míì ńkọ́? Bó o bá ń hùwà bí ẹni tó kéré jù, wàá máa fi sùúrù dúró dé àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, wàá máa fìdùnnú sin Jèhófà, wàá sì máa fayọ̀ ṣe iṣẹ́ yòówù tí wọ́n bá ní kó o ṣe nínú ìjọ.

17, 18. (a) Tá a bá ń tọrọ àforíjì tí àwa náà sì ń dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá, àwọn àǹfààní wo la máa rí gbà? (b) Kí ni Òwe 6:1-5 sọ pé ká máa ṣe?

17 Nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn láti tọrọ àforíjì. Àmọ́, torí pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń hùwà bí ẹni tó kéré jù, wọ́n máa ń gbà pé àwọn ṣe àṣìṣe, wọ́n sì máa ń tọrọ àforíjì. Wọ́n tún máa ń ṣe tán láti dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wọ́n. Ńṣe ni ìgbéraga máa ń fa ìyapa àti asọ̀, àmọ́ ìdáríjì máa ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀ láàárín ìjọ.

18 Bí a bá ṣé ìlérí kan àmọ́ tí a kò lè mú un ṣẹ torí pé ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká ‘rẹ ara wa sílẹ̀’ ká sì tọrọ àforíjì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristẹni kan tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ lè rí ibi tí ẹnì kejì ti pín nínú ẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀, àṣìṣe tiẹ̀ ló máa gbájú mọ́, ó sì máa múra tán láti ṣe àtúnṣe tó bá yẹ.—Ka Òwe 6:1-5.

19. Kí nìdí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi gbọ́dọ̀ máa dúpẹ́ nítorí ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún wa pé ká máa hùwà bí ẹni tó kéré jù?

19 A mà dúpẹ́ o, pé Ìwé Mímọ́ fún wa ní ìṣírí pé ká máa hùwà bí ẹni tó kéré jù! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòro fún wa nígbà míì láti ṣe bẹ́ẹ̀, tá a bá ń ronú nípa bí Ẹlẹ́dàá wa ṣe tóbi lọ́lá jù wá lọ, síbẹ̀ tó fìrẹ̀lẹ̀ hàn, ìyẹn lè mú káwa náà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, a óò túbọ̀ wúlò fún Jèhófà. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti hùwà bí ẹni tó kéré jù.

^ A ti yí orúkọ náà pa dà.