Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní Mátíù 19:10-12 fi hàn pé ńṣe ni àwọn tó yàn láti má ṣe ní ọkọ tàbí aya gba ẹ̀bùn yìí lọ́nà ìyanu?

Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó mú kí Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí kò ní ọkọ tàbí aya. Nígbà tí àwọn Farisí ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Jésù nípa ìkọ̀sílẹ̀, ó ṣàlàyé ohun tí òfin Ọlọ́run sọ nípa ìgbéyàwó fún wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin sọ pé ọkùnrin kan lè kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tó bá ṣe “ohun àìbójúmu kan,” èyí kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ nígbà tó dá tọkọtaya àkọ́kọ́. (Diu. 24:1, 2) Jésù wá sọ pé: ‘Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe nítorí àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.’—Mát. 19:3-9.

Nígbà tí àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ gbọ́ ohun tó sọ, wọ́n ní: “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn ọkùnrin rí pẹ̀lú aya rẹ̀, kò bọ́gbọ́n mu láti gbéyàwó.” Jésù wá dá wọn lóhùn pé: “Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ní ń wá àyè fún àsọjáde náà, bí kò ṣe kìkì àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn náà. Nítorí àwọn ìwẹ̀fà wà tí a bí bẹ́ẹ̀ láti inú ilé ọlẹ̀ ìyá wọn, àwọn ìwẹ̀fà sì wà tí àwọn ènìyàn sọ di ìwẹ̀fà, àwọn ìwẹ̀fà sì wà tí wọ́n ti sọ ara wọn di ìwẹ̀fà ní tìtorí ìjọba ọ̀run. Kí ẹni tí ó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.”—Mát. 19:10-12.

Bí ẹnì kan bá jẹ́ ìwẹ̀fà, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n bí onítọ̀hún pẹ̀lú àbùkù ara tàbí kó jẹ́ pé jàǹbá ló fà á. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n gé ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn kan kì í ṣe ìwẹ̀fà rárá. Wọ́n lè ní ọkọ tàbí aya bí wọ́n bá fẹ́, àmọ́ wọ́n yàn láti wà bẹ́ẹ̀ ‘nítorí ìjọba ọ̀run.’ Wọ́n ṣe bíi ti Jésù kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Wọn ò bí wọn pẹ̀lú ẹ̀bùn yẹn kò sì sẹ́ni tó fún wọn ní irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni wọ́n wá àyè fún un. Ìyẹn ni pé, wọ́n dìídì yàn láti wà láìní ọkọ tàbí aya.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé síwájú sí i lórí ohun tí Jésù sọ yìí. Ó ní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn Kristẹni ló lè sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́, àwọn tó ṣe “dáadáa jù” ni àwọn tí kò ní ọkọ tàbí aya tí wọ́n sì ti ‘pinnu tán nínú ọkàn wọn’ láti wà bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn tó ní ọkọ tàbí aya gbọ́dọ̀ máa lo lára àkókò àti okun wọn láti bójú tó ẹnì kejì wọn. Ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni tí kò ní ọkọ tàbí aya lè máa ṣe iṣẹ́ Olúwa láìsí ìpínyà ọkàn. Wọ́n ń wo ipò tí wọ́n wà gẹ́gẹ́ bíi pé Ọlọ́run ló fún wọn ni “ẹ̀bùn” yẹn.—1 Kọ́r. 7:7, 32-38.

Nítorí náà, Ìwé Mímọ́ kò sọ pé àwọn Kristẹni ń gba ẹ̀bùn wíwà láìní ọkọ tàbí aya lọ́nà ìyanu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń pinnu láti wà láìní ọkọ tàbí aya kí wọ́n bàa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run láìsí ìpínyà ọkàn. Lóde òní, ọ̀pọ̀ Kristẹni ti pinnu nínú ọ̀kan wọn láti má ṣe ní ọkọ tàbí aya nítorí iṣẹ́ Ọlọ́run. Ó sì yẹ kí àwa yòókù máa fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ìṣírí.