Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Gbà Pé Ó Ṣe Pàtàkì Nígbà Kérésì?

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Gbà Pé Ó Ṣe Pàtàkì Nígbà Kérésì?

“Pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ìgbà ọdún Kérésì máa ń pọ̀, ó sì máa ń gbani ní àkókò gan-an. Á wá di pé èèyàn kàn ń tiraka láti ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì lásìkò ọdún náà, èèyàn kò sì ní fi bẹ́ẹ̀ ráyè gbọ́ ti àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́. Gbogbo wàhálà yìí kì í jẹ́ kí èèyàn lè gbádùn àjọyọ̀ yẹn bó ṣe yẹ.”—BRAD HENRY TÓ JẸ́ GÓMÌNÀ TẸ́LẸ̀ RÍ NÍ ÌPÍNLẸ̀ OKLAHOMA NÍ AMẸ́RÍKÀ, DECEMBER 23, 2008.

TÍ ỌDÚN Kérésì bá ti ń sún mọ́lé, onírúurú orin, eré àti ètò orí tẹlifíṣọ̀n máa ń gbòde kínú àwọn èèyàn lè máa dùn pé ọdún ń bọ̀, kí wọ́n máa múra ọdún lóríṣiríṣi ọ̀nà, kí wọ́n sì ní ẹ̀mí rere tí àwọn èèyàn máa ń fẹ́ ní nígbà Kérésìmesì. Kí lo rò pé ó yẹ kó ṣe pàtàkì jù lọ́kàn àwọn èèyàn nígbà ọdún náà? Ṣé kí wọ́n máa

  • Rántí Jésù Kristi ni?

  • Fúnni lẹ́bùn kí wọ́n sì máa láyọ̀ ni?

  • Ran àwọn aláìní lọ́wọ́ ni?

  • Wáyè láti fara mọ́ ìdílé wọn ni?

  • Jẹ́ kí àlàáfíà wà ni?

Ohun tí Gómìnà Henry tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ fi hàn pé, ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ṣọdún Kérésì kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè ṣe èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn yìí. Lásìkò ọdún Kérésì, ìnira àti wàhálà máa ń pọ̀ gan-an, òwò ṣíṣe sì máa ń gbòde kan. Ṣé ayọ̀ àti ìfẹ́ tí àwọn tó ń ṣe Kérésì ń retí pé àwọn máa rí kò wá ní ṣeé ṣe mọ́ ni?

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa rántí Jésù Kristi, ká jẹ́ ọ̀làwọ́, ká máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́, ká sì máa wá àyè láti fara mọ́ ìdílé wa. Bíbélì tún kọ́ wa ní bí a ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Torí náà, nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, a ò ní sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí àwọn kan kì í fi í ṣe Kérésìmesì. * Ṣe la kàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni àwọn kan rò pé ó yẹ kó jẹ́ ìdí tí àwọn èèyàn fi ń ṣe ọdún Kérésì?

  • Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn fún àwọn èèyàn láti ṣe ohun tí wọ́n tìtorí rẹ̀ ń ṣe ọdún Kérésì?

  • Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn rí ohun míì tó dára ju Kérésìmesì lọ?

^ Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tó bá Bíbélì mu tí àwọn kan fi pinnu pé àwọn kò ní máa ṣe ọdún Kérésì wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé—Kí nìdí tí àwọn kan kì í fi í ṣe Kérésìmesì?”