Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Wọ́n Ṣe Ń Lo Ohun Ìṣaralóge Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Bí Wọ́n Ṣe Ń Lo Ohun Ìṣaralóge Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Tí obìnrin bá wẹ̀ tán, á fi òróró olóòórùn dídùn pa ara rẹ̀ tó jọ̀lọ̀. Yóò wá ṣí àpótí kan tí wọ́n ya àwòrán mèremère sí lára, èyí tó kó àwọn ìgò, àwo òdòdó àti kòlòbó kéékèèké, tí wọ́n fi gíláàsì, eyín erin, ìkarawun tàbí òkúta ṣe sí. Onírúurú òróró àti lọ́fínńdà tó ní àwọn èròjà tó ń ta sánsán bíi básámù, kádámómì, sínámónì, oje igi tùràrí, oyin, òjíá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló wà nínú àwọn ohun ìkó-nǹkan-sí yìí.

Obìnrin tó fẹ́ ṣe ara lóge yóò kó àwọn ṣíbí, abọ́ àti àwo ẹlẹgẹ́ tí wọ́n dárà sí jáde nínú àpótí rẹ̀ yìí. Yóò fi wọ́n po ohun ìṣaralóge tó fẹ́ lò lọ́jọ́ yẹn. Á máa wo ara rẹ̀ nínú dígí idẹ bó ṣe ń fi àwọn nǹkan wọ̀nyẹn para bó ti máa ń ṣe láti fi gbé ẹwà ara rẹ̀ yọ.

LÁTI ìgbà ìjímìjí ló jọ pé àwọn obìnrin ti fọwọ́ pàtàkì mú ṣíṣe ara wọn lóge. Àwọn àwòrán tí àwọn ará ìgbàanì yà sí ara ibojì, èyí tí wọ́n yà sí ara ògiri àti àwòrán aláràbarà tí wọ́n tò pọ̀, ń fi hàn pé àwọn ará Mesopotámíà àti Íjíbítì máa ń lo ohun ìṣaralóge gan-an. Bí ojú àwọn obìnrin ọmọ Íjíbítì tí wọ́n ti ṣe lóge gan-an ṣe máa ń rí nínú àwòrán máa ń wu ọ̀pọ̀ èèyàn.

Láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ńkọ́? Ṣé àwọn obìnrin ń lo ohun ìṣaralóge ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́? Tí wọ́n bá ń lò, irú èwo ni? Lóòótọ́, a kò rí àwòrán ara ibojì kankan tàbí èyí tí wọ́n yà sára ògiri ní Ísírẹ́lì àtijọ́ tí a lè tọ́ka sí. Ṣùgbọ́n àwọn àkọsílẹ̀ kan nínú Bíbélì àti àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tí àwọn awalẹ̀pìtàn wú jáde ní àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn jẹ́ ká lè mọ díẹ̀ nínú bí wọ́n ṣe lo ohun ìṣaralóge láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì.

Àwọn Nǹkan Tí Wọ́n Ń Lò

Àìmọye nǹkan tó fi hàn pé wọ́n ń lo ohun ìṣaralóge àti lọ́fínńdà ni wọ́n ti wú jáde nínú ilẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Àwọn àwo kó-kò-kó tí wọ́n fi òkúta ṣe àti àwọn àwo pẹrẹsẹ tí wọ́n fi ń lọ ohun ìṣaralóge tí wọ́n sì fi ń pò ó, àwọn ìgò lọ́fínńdà tẹ́ẹ́rẹ́, orùba alabásítà tí wọ́n ń da òróró onílọ́fínńdà sí àti dígí kékeré tí wọ́n fi idẹ dídán ṣe wà lára àwọn nǹkan tí wọ́n wú jáde. Ṣíbí kan tí wọ́n fi eyín erin ṣe wà níbẹ̀ tí wọ́n ya imọ̀ ọ̀pẹ sí lápá kan tí wọ́n sì ya obìnrin tí àwọn àdàbà yí ká sí apá kejì rẹ̀.

Ó jọ pé ìkarawun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ni àwọn tó rí já jẹ sábà máa ń kó ohun ìṣaralóge wọn sí. Bákan náà, ní àwọn ibi tí wọ́n yẹ̀ wò ní ilẹ̀ Íjíbítì àti ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n rí àwọn ṣíbí kékeré tí wọ́n fi eyín erin ṣe àti èyí tí wọ́n fi igi ṣe, tí wọ́n sì gbẹ́ àwọn ọmọbìnrin tó ń lúwẹ̀ẹ́ àti oríṣiríṣi iṣẹ́ ọnà sí lára. Gbogbo èyí jẹ́rìí sí i pé àwọn obìnrin sábà máa ń lo ohun ìṣaralóge láyé ìgbà yẹn.

Èyí Tí Wọ́n Ń Lò fún Ojú

Orúkọ tí Bíbélì sọ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jóòbù ń jẹ́ ni “Kereni-hápúkì.” Lédè Hébérù, ó ṣeé ṣe kí orúkọ náà túmọ̀ sí “Ìwo Tìróò,” ìyẹn ilé tìróò tàbí akóló tí wọ́n ń da tìróò sí. (Jóòbù 42:14) Ó lè jẹ́ pé torí ẹwà ọmọbìnrin yẹn ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní orúkọ náà o, àmọ́ ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn ìgbà yẹn mọ̀ nípa ohun ìṣaralóge.

Kókó pàtàkì kan ni pé, ọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin burúkú bíi Jésíbẹ́lì ayaba elétekéte àti Jerúsálẹ́mù aláìṣòótọ́ tí wòlíì Jeremáyà àti Ìsíkíẹ́lì fi wé aṣẹ́wó, ni Bíbélì ń sọ ní àwọn ibi tó ti sọ pé ẹnì kan lé tìróò tàbí pé ó tọ́jú. (2 Àwọn Ọba 9:30; Jeremáyà 4:30; Ìsíkíẹ́lì 23:40) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun èlò onígíláàsì tàbí olókùúta tí wọ́n ń kó nǹkan tí wọ́n fi ń lé tìróò àti ohun ìṣaralóge kéékèèké sí ni wọ́n rí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Èyí fi hàn pé nígbà tí ilẹ̀ Ísírẹ́lì pẹ̀yìn dà sí ìjọsìn Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ obìnrin, pàápàá àwọn ti ìdílé ọba àti àwọn ọlọ́lá, ló gba àṣà lílé tìróò àti lílo ohun ìṣaralóge tó pọ̀ gan-an bíi ti àwọn obìnrin orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà.

Òróró Onílọ́fínńdà Tí Wọ́n Ń Lò fún Ìjọsìn àti Èyí Tí Gbogbo Gbòò Ń Lò

Tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n ti ń fi òróró ólífì ṣe lọ́fínńdà tí wọ́n ń lò ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ìwé Ẹ́kísódù sọ bí wọ́n ṣe ń ṣe òróró onílọ́fínńdà mímọ́ tí àwọn àlùfáà ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn wọn ní tẹ́ńpìlì. Òjíá àti igi sínámónì àti àwọn ewéko míì tó ń ta sánsán ni wọ́n máa ń lọ̀ pa pọ̀ láti fi ṣe é. (Ẹ́kísódù 30:22-25) Ní Jerúsálẹ́mù, àwọn awalẹ̀pìtàn rí ibì kan tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ ilé iṣẹ́ kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tí wọ́n ti ń ṣe lọ́fínńdà àti tùràrí tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì. Ibi púpọ̀ nínú Bíbélì ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa òróró onílọ́fínńdà, yálà èyí tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn tàbí èyí tí àwọn èèyàn fúnra wọn máa ń lò.—2 Kíróníkà 16:14; Lúùkù 7:37-46; 23:56.

Kò fi bẹ́ẹ̀ sí omi ní gbogbo àgbègbè ilẹ̀ Ísírẹ́lì, torí náà òróró onílọ́fínńdà wà lára ohun tí wọ́n sábà máa ń lò fún ìmọ́tótó ara. Yàtọ̀ sí pé wọ́n fi òróró para láti fi dáàbò bo ara nítorí pé àgbègbè ibẹ̀ gbóná, tó sì máa ń gbẹ táútáú, wọ́n tún máa ń lò ó láti fi mú kí ara jọ̀lọ̀. (Rúùtù 3:3; 2 Sámúẹ́lì 12:20) Kí wọ́n tó mú omidan Ẹ́sítérì ọmọ Júù wá sọ́dọ̀ Ahasuwérúsì Ọba, wọ́n kọ́kọ́ fi òróró òjíá wọ́ ọ lára fún oṣù mẹ́fà, wọ́n sì tún fi òróró básámù wọ́ ọ lára fún oṣù mẹ́fà míì.—Ẹ́sítérì 2:12.

Irú ojú iyebíye tí wọ́n fi ń wo fàdákà àti wúrà, náà ni wọ́n fi ń wo lọ́fínńdà tàbí òróró onílọ́fínńdà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rin ìrìn àjò rẹ̀ tí àwọn èèyàn mọ̀ gan-an láti wá kí Sólómọ́nì Ọba, ara ẹ̀bùn iyebíye tó kó wá ni wúrà àti àwọn òkúta iyebíye àti òróró básámù. (1 Àwọn Ọba 10:2, 10) Nígbà tí Hesekáyà Ọba fi àwọn ìṣúra rẹ̀ han àwọn aṣojú kan tó wá láti Bábílónì, “òróró básámù àti òróró dáradára” wà lára ohun tó kà sí ìṣúra pàtàkì tó fi hàn wọ́n pa pọ̀ mọ́ fàdákà àti wúrà àti gbogbo ilé ìhámọ́ra rẹ̀.—Aísáyà 39:1, 2.

Ìwọ̀nba lọ́fínńdà tàbí òróró tín-ń-tín ni wọ́n máa ń rí fún jáde lára onírúurú òdòdó, èso, ewé, oje igi tàbí èèpo igi, torí náà ó máa ń wọ́n gan-an. Bíbélì mẹ́nu ba àwọn kan lára àwọn ewéko olóòórùn títa sánsán yìí, irú bíi álóè, básámù, gọ́ọ̀mù bídẹ́líọ́mù, kálámọ́sì, kaṣíà, sínámónì, tùràrí, òjíá, sáfúrónì àti sípíkénádì. Àwọn kan lára wọn jẹ́ ewéko tó ń hù ní Àfonífojì Jọ́dánì ní àgbègbè ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Àwọn oníṣòwò láti ilẹ̀ òkèèrè bí Íńdíà, gúúsù ilẹ̀ Arébíà àti àwọn ibòmíì tó ń ta nǹkan wọ̀nyẹn látijọ́, ló ń kó àwọn míì lára wọn wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì.

Òróró Básámù Àràmàǹdà

Bíbélì mẹ́nu kan òróró Básámù nígbà tó ń sọ ìtàn nípa Ẹ́sítérì ayaba, ọbabìnrin Ṣébà àti Hesekáyà Ọba tí a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan. Lọ́dún 1988, wọ́n rí ìdẹ̀ òróró kékeré kan lẹ́bàá hòrò kan ní Qumran tó wà ní etíkun apá ìwọ̀ oòrùn Òkun Òkú. Ọ̀pọ̀ àbá ni àwọn èèyàn sì ní nípa òróró náà. Àwọn kan rò pé bóyá ni kò fi ní jẹ́ òróró básámù iyebíye kan ṣoṣo tó ṣẹ́ kù tí àwa èèyàn lè rí tọ́ka sí nìyẹn. Àmọ́ ṣá, àwọn olùṣèwádìí kò tíì rójútùú ọ̀rọ̀ náà. Bákan náà, títí dónìí, ṣe ni àwọn èèyàn ṣì ń ṣakitiyan lórí bí wọ́n á ṣe tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbin àwọn ewéko tí wọ́n gbà pé ó ń mú òróró básámù iyebíye tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ní ayé àtijọ́ jáde.

Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ṣe fi hàn, ó jọ pé àgbègbè Ẹ́ń-gédì ni wọ́n ti ń rí òróró básámù tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Nígbà tí wọ́n wa ilẹ̀ àgbègbè ibẹ̀, wọ́n rí àwọn ìléru, ìṣà àti oríṣiríṣi àwọn ohun èlò irin àti egungun, tí ẹ̀rí fi hàn pé ó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Irú àwọn ohun èlò yẹn sì ni àwọn tó ń ṣe lọ́fínńdà ní àwọn àgbègbè míì náà ń lò. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọ̀mọ̀wé ló gbà pé ilẹ̀ Arébíà tàbí Áfíríkà ni wọ́n ti mú ewéko básámù wá. Omi tí wọ́n ń fún jáde lára ewéko náà ni wọ́n fi ń ṣe òróró tó ń ta sánsán náà. Wọ́n ka òróró básámù yìí sí iyebíye débi pé wọn kì í fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe ń gbin ewéko yìí àti bí wọ́n ṣe yọ òróró ara rẹ̀.

Kódà àwọn aláṣẹ ayé ìgbàanì máa ń dọ́gbọ́n lo básámù bí ohun pàtàkì láti fi dúnàádúrà láàárín àwọn àti aláṣẹ míì láti ilẹ̀ òkèèrè. Bí àpẹẹrẹ, òpìtàn náà Josephus sọ pé, ọ̀gágun Mark Antony gba gbogbo básámù inú ọgbà kan ó sì gbé e tọrẹ fún Ọbabìnrin Kilẹopátírà Kìíní tó jẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀. Òpìtàn náà, Pliny tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Róòmù sọ pé nígbà ogun àwọn Júù tó wáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun àwọn Júù gbìyànjú láti run gbogbo ewéko básámù tí wọ́n ní kí ọwọ́ àwọn ará Róòmù tó ṣẹ́gun wọn má bàa tẹ básámù wọn.

Àwọn ohun tí Bíbélì sọ àti ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn wú jáde látinú ilẹ̀ ti jẹ́ kí a mọ díẹ̀ nípa bí àwọn èèyàn ṣe lo ohun ìṣaralóge ní ayé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Bíbélì kò sọ pé ó burú láti lo ohun èlò ìṣaralóge àti ohun ọ̀ṣọ́ míì, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fi yé wa kedere ni pé kéèyàn lò wọ́n ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì pẹ̀lú èrò inú tó yè kooro ló dáa. (1 Tímótì 2:9) Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ohun “tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run” ni pé ká jẹ́ ẹni tó ní “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù.” Lójú bí àṣà ìwọṣọ àti ìmúra ṣe ń yí pa dà lójoojúmọ́ yìí, ìmọ̀ràn yìí dáa gan-an ni fún àwọn obìnrin Kristẹni lọ́mọdé lágbà.—1 Pétérù 3:3, 4.