Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Mo Rí I, Ṣùgbọ́n Kò Yé Mi”

“Mo Rí I, Ṣùgbọ́n Kò Yé Mi”

Ọdún 1975, nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún méjì, ni ìyá mi kọ́kọ́ fura pé nǹkan kan ń ṣe mí. Bó ṣe gbé mi dání, ẹnì kan sọ kinní kan tó wúwo sílẹ̀, ó sì dún gbàmù. Màmá mi kíyè sí i pé mi ò tiẹ̀ mira. Títí mo fi di ọmọ ọdún mẹ́ta mi ò tíì lè sọ̀rọ̀. Ìdílé wa wá gba ìròyìn tó dunni láti ọ̀dọ̀ àwọn dókítà pé etí mi di pátápátá ni!

Ìkókó ṣì ni mí nígbà tí àwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀. Màmá mi nìkan ló wá tọ́ èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi yòókù, tó jẹ́ ọkùnrin méjì àti obìnrin kan. Ní ìgbà yẹn, bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ tó jẹ́ adití nílẹ̀ Faransé yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń kọ́ wọn lónìí. Ọ̀nà tí wọ́n sì ń gbà kọ́ wọn ń mú kí wọ́n fìyà jẹ wọ́n gan-an nígbà míì. Àmọ́ ṣá, mo ní àǹfààní kan láti kékeré tí ọ̀pọ̀ àwọn adití kò ní. Ẹ jẹ́ kí n sọ bó ṣe jẹ́ fún yín.

Ìgbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún

Láyé ìgbà kan, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n gbà pé ọ̀nà tó dáa láti gbà kọ́ àwọn adití ni pé kí wọ́n fipá kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ sísọ àti bí wọ́n ṣe lè máa ṣàkíyèsí ẹnu ẹni tó ń sọ̀rọ̀ láti fi mọ ohun tó ń sọ. Kódà ní ilẹ̀ Faransé tí mo gbé dàgbà, wọ́n ka fífi ọwọ́ ṣàpèjúwe lọ́nà ti àwọn adití léèwọ̀ nílé ìwé. Nígbà yẹn, wọ́n tiẹ̀ máa ń de ọwọ́ àwọn ọmọ míì tó jẹ́ adití sẹ́yìn tí olùkọ́ bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.

Nígbà tí mo ṣì wà ní kékeré, ọdún mélòó kan ni mo fi ń lọ sí ọ̀dọ̀ dókítà tó ń tọ́jú àwọn tó ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ. Tí mo máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí níbẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Wọ́n á di orí tàbí àgbọ̀n mi mú, pé tipátipá, kí n máa pe àwọn ìró ọ̀rọ̀ kan léraléra, ìró tí mi ò gbọ́ rárá! Mi kì í lè bá àwọn ọmọdé yòókù sọ̀rọ̀. Áà, ojú mi rí màbo láwọn ìgbà yẹn!

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́fà, wọ́n fi mí sí ilé ìwé àwọn adití tó ní ibùgbé àwọn ọmọ ilé ìwé. Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo máa bá àwọn ọmọ míì tó jẹ́ adití pàdé nìyẹn. Àmọ́, wọ́n tún ka èdè àwọn adití léèwọ̀ nílé ìwé yìí. Tí a bá fọwọ́ bá ara wa sọ̀rọ̀ pẹ́nrẹ́n ní kíláàsì, wọ́n lè fi nǹkan di ìkúùkù ọwọ́ wa tàbí kí wọ́n fa irun orí wa. Ṣùgbọ́n a máa ń yọ́lẹ̀ fọwọ́ bá ara wa sọ̀rọ̀, a sì ti ní bí a ṣe ń fọwọ́ ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ kan láàárín ara wa. Ní mo bá dẹni tó ń bá àwọn ọmọdé bíi tèmi sọ̀rọ̀. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ayé mi nìyẹn fún ọdún mẹ́rin.

Àmọ́ nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá, wọ́n mú mi lọ sí ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti àwọn ọmọ tí kì í ṣe adití. Inú mi bà jẹ́ gidigidi! Ṣe ni mo rò pé gbogbo ọmọ yòókù tó jẹ́ adití ní ayé ti kú, pé èmi nìkan ló ṣẹ́ kù. Ó tún ṣẹlẹ̀ pé àwọn ará ilé mi kò kọ́ èdè àwọn adití, wọn kì í sì í jẹ́ kí n wà níbi tí ọmọ míì tó jẹ́ adití bá wà, torí àwọn dókítà ti sọ fún wọn pé ìyẹn kò ní jẹ́ kí n lè máa lo ohun tí mo kọ́ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ. Mo rántí ìgbà kan tí mo lọ sọ́dọ̀ dókítà àwọn adití àtàwọn tí kì í gbọ́rọ̀ dáadáa, ìwé èdè àwọn adití kan sì wà lórí tábìlì rẹ̀. Nígbà tí mo rí àwọn àwòrán tó wà lẹ́yìn ìwé náà, mo nawọ́ sí i mo ní, “Ẹ fún mi ní ìwé yẹn!” Àmọ́, kíá ni dókítà yẹn mú ìwé náà pa mọ́. *

MO BẸ̀RẸ̀ SÍ Í KỌ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ

Màmá mi rí i pé òun fi àwọn ìlànà Bíbélì kọ́ àwa ọmọ rẹ̀. Ó máa ń kó wa lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìjọ Mérignac nítòsí ìlú Bordeaux. Nígbà tí mo wà ní ọmọdé, ìwọ̀nba díẹ̀ ló ń yé mi nínú ohun tí wọ́n ń sọ ní ìpàdé. Ṣùgbọ́n, àwọn ará ìjọ máa ń wá jókòó tì mí lọ́kọ̀ọ̀kan, wọ́n á máa kọ ohun tí wọ́n ń sọ sínú ìwé fún mi. Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí mi àti bí ọ̀rọ̀ mi ṣe jẹ wọ́n lógún wú mi lórí. Ní ilé, màmá mi máa ń kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì, àmọ́ ohun tí wọ́n ń kọ́ mi kò fi bẹ́ẹ̀ yé mi. Ṣe ni ọ̀rọ̀ mi dà bí ti wòlíì Dáníẹ́lì tó jẹ́ pé, lẹ́yìn tí áńgẹ́lì kan sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un, ó ní, “Emi si gbọ, ṣugbọn kò ye mi.” (Dáníẹ́lì 12:8, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ní tèmi, ṣe ni “mo rí i, ṣùgbọ́n kò yé mi.”

Àmọ́ ṣá, ẹ̀kọ́ òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í yé mi díẹ̀díẹ̀ nígbà tó yá. Mo fi àwọn tó yé mi kedere sọ́kàn, mo sì gbìyànjú láti fi wọ́n sílò. Mo tún kíyè sí ìwà àwọn ẹlòmíì, kí n lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ní ká jẹ́ onísùúrù. (Jákọ́bù 5:7, 8) Mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ bí èèyàn ṣe lè jẹ́ onísùúrù. Ṣùgbọ́n mo kíyè sí bí àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tèmi ṣe ń mú sùúrù, ìyẹn ni mo fi mọ bí èèyàn ṣe lè jẹ́ onísùúrù. Ká sòótọ́, ìjọ Kristẹni ti ṣe mí láǹfààní gan-an ni.

ÌBÀNÚJẸ́ ŃLÁ BÁ MI, ẸNU SÌ TÚN YÀ MÍ GAN-AN

Stéphane tó jẹ́ kí Bíbélì yé mi rèé

Nígbà tí mi ò tíì tó ọmọ ogún ọdún, mo rí àwọn ọ̀dọ́ adití kan tí wọ́n ń fi èdè adití bá ara wọn sọ̀rọ̀ nígboro lọ́jọ́ kan. Mo bá ń yọ́lẹ̀ wá wọn lọ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Faransé lọ́dọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n mo ṣì ń lọ sí ìpàdé ìjọ. Ìpàdé yìí ni èmi àti ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Stéphane ti mọra, ó sì mú mi bí ọ̀rẹ́. Ó máa ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti bá mi sọ̀rọ̀. Bó ṣe di pé ọ̀rẹ́ wa wọ̀ gan-an nìyẹn. Àmọ́ láìpẹ́, ìbànújẹ́ ńlá dé bá mi. Wọ́n ṣàdédé sọ Stéphane sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò jẹ́ kó wọ iṣẹ́ ológun. Ó dùn mí gan-an ni! Bí mi ò ṣe rí Stéphane mọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi gidigidi, mo sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má lọ sí ìpàdé mọ́.

Oṣù mọ́kànlá lẹ́yìn náà, wọ́n fi Stéphane sílẹ̀, ó sì wá sílé. Ẹ wá wo bí ẹnu ṣe yà mí tó nígbà tí Stéphane bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè àwọn adití bá mi sọ̀rọ̀. Bí àlá ló rí lójú mi! Báwo ló ṣe mọ̀ ọ́n? Ìgbà tó wà lẹ́wọ̀n ló kọ́ ọ. Bí mo ṣe ń wo ọwọ́ àti ìrísí ojú Stéphane bó ṣe ń fi èdè àwọn adití bá mi sọ̀rọ̀, ṣe ni inú mi kàn ń dùn pé òye òtítọ́ máa yé mi wàyí.

Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ YÉ MI WÀYÍ

Ni Stéphane bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìgbà yẹn ni mo tó bẹ̀rẹ̀ sí í rí bí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ̀ọ̀kan tí mo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe tan mọ́ra. Nígbà tí mo wà ní ọmọdé, mo fẹ́ràn kí n máa wo àwọn àwòrán mèremère tó wà nínú àwọn ìwé tí a fi ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Màá fi àwọn tó wà nínú àwòrán náà wé ara wọn, màá sì tún wò wọ́n fínnífínní kí n lè rántí àwọn ìtàn náà. Mo ti kọ́ nípa Ábúráhámù, “irú-ọmọ” rẹ̀, àti “ogunlọ́gọ̀ ńlá.” Àmọ́ ìgbà tí wọ́n tó fi èdè àwọn adití ṣàlàyé ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé mi kedere. (Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18; Ìṣípayá 7:9) Mo wá rí i pé èdè tó yé mi jù nìyí, òun ni èdè tó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.

Nígbà tí mo ti wá ń lóye ohun tí wọ́n ń sọ ní ìpàdé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì ń wù mí kí n mọ̀ sí i. Ìrànlọ́wọ́ tí Stéphane ṣe fún mi jẹ́ kí ẹ̀kọ́ Bíbélì túbọ̀ yé mi. Ní ọdún 1992, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, mo sì ṣe ìrìbọmi. Lóòótọ́ o, mo ń tẹ̀ síwájú, àmọ́ bí mi ò ṣe lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nígbà tí mo wà ní kékeré ti sọ mi di ẹni tó máa ń tijú gan-an, ara mi kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ yọ̀ mọ́ni.

BÍ MO ṢE BORÍ ÌTÌJÚ MI

Nígbà tó yá, wọ́n da àwùjọ àwọn adití kéréje tí a jọ ń ṣèpàdé pọ̀ mọ́ ìjọ kan ní ìlú Pessac, nítòsí ìlú Bordeaux. Ìyẹn ràn mí lọ́wọ́ gidigidi, mo sì tẹ̀ síwájú gan-an nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú ṣì máa ń tì mí láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rẹ́ mi tí kì í ṣe adití máa ń sa gbogbo ipá wọn láti jẹ́ kí n lóye gbogbo nǹkan bó ṣe yẹ. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Gilles àti aya rẹ̀ Elodie, sapá gan-an láti lè máa bá mi sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn ìpàdé, wọ́n sábà máa ń pè mí wá jẹun tàbí kí wọ́n po kọfí fún mi nílé wọn. Bí a ṣe di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nìyẹn. Inú mi dùn gan-an pé mo wà láàárín àwọn tó ń fi ìfẹ́ báni lò bí ti Ọlọ́run!

Ìyàwó mi, Vanessa, jẹ́ alátìlẹyìn gidi fún mi

Inú ìjọ yìí ni mo ti pàdé ọmọbìnrin dáadáa kan tó ń jẹ́ Vanessa. Bó ṣe jẹ́ ẹni tó láájò èèyàn àti ẹni tí kì í fi igbá kan bọ̀kan nínú wù mí. Kò ka bí mo ṣe jẹ́ adití sí ìṣòro, kódà ṣe ló fi ìyẹn kọ́ béèyàn ṣe ń bá àwọn adití sọ̀rọ̀. Bí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe wọ̀ mí lọ́kàn nìyẹn tí a sì fẹ́ ara wa lọ́dún 2005. Lóòótọ́, ó ṣì máa ń ṣòro fún mi láti ṣàlàyé ara mi dáadáa, àmọ́ Vanessa ti jẹ́ kí n borí ìtìjú mi, kí n sì máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láìfi bẹ́ẹ̀ tijú. Alátìlẹyìn gidi ló jẹ́ fún mi, bí mo ṣe ń bójú tó àwọn ojúṣe mi gbogbo.

Ẹ̀BÙN MÍÌ LÁTỌ̀DỌ̀ JÈHÓFÀ

Lọ́dún tí a ṣègbéyàwó, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé, tó wà ní ìlú Louviers, ní kí n wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù kan nípa iṣẹ́ títúmọ̀ èdè. Ó ṣẹlẹ̀ pé ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ takuntakun láti ṣe ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí sórí àwo DVD ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Faransé. Ṣùgbọ́n torí pé iṣẹ́ yẹn túbọ̀ ń pọ̀ sí i, àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè yẹn nílò àwọn tó máa kún wọn lọ́wọ́.

Mo ń fi Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Faransé sọ àsọyé Bíbélì

Èmi àti Vanessa gbà pé ẹ̀bùn àti àǹfààní ńláǹlà ni Jèhófà Ọlọ́run fún wa yẹn. Àmọ́ ọkàn wa kò kọ́kọ́ balẹ̀. A rò ó pé kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwùjọ àwọn tó ń sọ èdè adití tí a wà? Ilé wa ń kọ́, kí la ti máa ṣe é? Ṣé Vanessa máa lè rí iṣẹ́ sí àgbègbè ibẹ̀? Àmọ́ Jèhófà yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ yìí lọ́kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà àrà. Mo rí ọwọ́ ìfẹ́ Jèhófà lára wa gan-an àti pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn adití gidigidi.

ÀWỌN ÈÈYÀN TÓ WÀ NÍṢỌ̀KAN Ń TÌ MÍ LẸ́YÌN

Bí mo ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè yìí ti jẹ́ kí n túbọ̀ rí iṣẹ́ ńlá tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe láti lè rí i pé àwọn adití lóye ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìdùnnú ńlá ló sì máa ń jẹ́ fún mi láti rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè bá mi sọ̀rọ̀. Bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti fi ìwọ̀nba tí wọ́n kọ́ nínú èdè àwọn adití bá mi sọ̀rọ̀ wú mi lórí gan-an. Kì í ṣe mí bíi pé mo dá yàtọ̀ láàárín wọn rárá, torí ṣe ni wọ́n kó mi mọ́ra. Gbogbo bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ èèyàn yìí fi hàn pé ìṣọ̀kan àrà ọ̀tọ̀ ló wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà.—Sáàmù 133:1.

Mo ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìtumọ̀ Èdè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé gbogbo ìgbà ló ń jẹ́ kí n rí ẹni táá ràn mí lọ́wọ́ lọ́nà kan ṣáà nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo tún mọrírì ìwọ̀nba ipa tí mo ń kó nínú ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn adití míì kí wọ́n lè mọ Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì sún mọ́ ọn. Mo ń fojú sọ́nà de ìgbà tí gbogbo èèyàn a lè máa bára wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà láìsí ìdíwọ́, tí gbogbo aráyé yóò pa pọ̀ jẹ́ ìdílé kan ṣoṣo tó wà níṣọ̀kan, tí a ó sì máa sọ “èdè mímọ́ gaara,” ìyẹn òtítọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn ohun tó máa ṣe.—Sefanáyà 3:9.

^ ìpínrọ̀ 9 Ọdún 1991 ni ìjọba ilẹ̀ Faransé tó fọwọ́ sí i pé kí wọ́n máa fi èdè àwọn adití kọ́ àwọn ọmọ tó jẹ́ adití.