Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Àárẹ̀ Mú Yín

Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Àárẹ̀ Mú Yín

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára.”—GÁL. 6:9.

1, 2. Tá a bá ń fara balẹ̀ ronú lórí ohun tí ètò Jèhófà ń gbé ṣe, kí ló máa mú ká ṣe?

OHUN àgbàyanu ló jẹ́ pé a jẹ́ ara ètò kan ṣoṣo tí Jèhófà ń lò láyé àtọ̀run. Àwọn ìran tó wà ní Ìsíkíẹ́lì orí 1 àti Dáníẹ́lì orí 7 ṣe àlàyé tó ṣe kedere nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ń gbé ṣe kó bàa lè mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Jésù ni òléwájú lára àwọn tí Jèhófà ń lò láti máa darí apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀. Òun ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù. Jèhófà tún ń tipasẹ̀ rẹ̀ fún àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà ní ìtọ́ni tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa tẹ̀síwájú, kí wọ́n sì lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti di olùjọ́sìn Jèhófà. Gbogbo èyí ń mú ká máa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ètò Jèhófà.—Mát. 24:45.

2 Ṣé ìwọ náà ń bá ètò Ọlọ́run rìn nípa jíjẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ó ṣeé ṣe kó o rí i pé ìtara rẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn. Ó máa ń rí bẹ́ẹ̀ nígbà míì. Ní ọ̀rúndún kìíní pàápàá, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní láti rán àwọn Kristẹni létí pé kí wọ́n jẹ́ onítara. Ó sọ pé kí wọ́n máa rántí bí Jésù ṣe jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un. Ó ní tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ àárẹ̀ kò ní mú wọn, wọn ò sì ní rẹ̀wẹ̀sì. (Héb. 12:3) Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ribiribi tí ètò Ọlọ́run ń gbé ṣe lóde òní. Tá a bá fara balẹ̀ ronú lórí ohun tí ètò Jèhófà ń ṣe, àwa náà á lè máa bá a nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ìtara wa kò sì ní dín kù.

3. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí àárẹ̀ má bàa mú wa? Kí la máa gbẹ́ yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ó dára lóòótọ́ pé ká máa ronú lórí ohun tí ètò Jèhófà ń ṣe. Àmọ́, tí a kò bá fẹ́ kí àárẹ̀ mú wa, tàbí tá ò bá fẹ́ kí ìtara wa jó rẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Pọ́ọ̀lù sọ pé ká máa ṣe “ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” (Gál. 6:9) Ìyẹn fi hàn pé a ò kàn ní jókòó tẹtẹrẹ! Torí náà, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ohun márùn-ún tí kò ní jẹ́ kí ìtara wa jó rẹ̀yìn, táá sì jẹ́ ká lè máa gba ibi tí ètò Ọlọ́run bá darí wa sí. Lẹ́yìn náà, a lè wá fara balẹ̀ ronú bóyá àwọn ibì kan wà tó yẹ kí àwa tàbí ìdílé wa ti sunwọ̀n sí i.

Ẹ PÉJỌ LÁTI JỌ́SÌN KÍ Ẹ SÌ FÚN ARA YÍN NÍ ÌṢÍRÍ

4. Kí nìdí tí àwọn ìpàdé wa fi jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́?

4 Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti kà á sí ohun pàtàkì láti máa pé jọ. Ní ọ̀run, àwọn ańgẹ́lì máa ń pé jọ síwájú Jèhófà. (1 Ọba 22:19; Jóòbù 1:6; 2:1; Dán. 7:10) Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa pàdé pọ̀ “kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́.” (Diu. 31:10-12) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Júù máa ń lọ sínú sínágọ́gù kí wọ́n lè lọ ka Ìwé Mímọ́. (Lúùkù 4:16; Ìṣe 15:21) Kódà, nígbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀ àwọn ará máa ń pé jọ, títí di báyìí, ó ṣì jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa. Àwa Kristẹni tòótọ́ máa ń “gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” A gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti máa “fún ara wa ní ìṣírí,” pàápàá jù lọ nítorí pé à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.—Heb. 10:24, 25.

5. Báwo la ṣe lè máa fún ara wa níṣìírí láwọn ìpàdé wa?

5 Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà máa fún ara wa níṣìírí ni pé ká máa dáhùn láwọn ìpàdé. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá ń bójú tó apá tó jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn, a lè nawọ́ ká sì dáhùn, a lè ṣàlàyé bá a ṣe lè fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan sílò, tàbí ká sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká rí bó ṣe bọ́gbọ́n mu pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. (Sm. 22:22; 40:9) Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé bó ti wù kó pẹ́ tó tá a ti wà nínú ètò Ọlọ́run, àwọn àlàyé tá a máa ń gbọ́ lẹ́nu tàgbà tèwe máa ń fún wa ní ìṣírí gan-an.

6. Báwo ni àwọn ìpàdé wa ṣe ń mú ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run?

6 Àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń mú ká ní ìgboyà láti wàásù fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, bí wọ́n bá tilẹ̀ ń ṣàtakò sí wa tàbí tí wọn kò fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa. (Ìṣe 4:23, 31) Àwọn àsọyé tá a máa ń gbọ́ àtàwọn ọ̀rọ̀ míì tó dá lórí Bíbélì máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. (Ìṣe 15:32; Róòmù 1:11, 12) A máa ń ní ojúlówó ayọ̀, a sì máa ń rí ìtùnú gbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn ará wa. (Sm. 94:12, 13) Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń ṣètò àwọn ìtọ́ni tí gbogbo àwa èèyàn Jèhófà ń rí gbà láwọn ìpàdé wa. Àfi ká máa dúpẹ́ nítorí àwọn ẹ̀kọ́ tó jíire tá à ń rí kọ́ láwọn ìpàdé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, jálẹ̀ ọdún.

7, 8. (a) Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ ká máa lọ sípàdé? (b) Báwo làwọn ìpàdé ṣe ń mú kó o ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run?

7 Àmọ́ kì í ṣe torí àwọn àǹfààní tá à ń rí gbà láwọn ìpàdé wa nìkan la ṣe ń lọ síbẹ̀ o! Ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a fi ń pé jọ ni pé ká lè máa sin Jèhófà. (Ka Sáàmù 95:6.) Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa kọrin yin Jèhófà, Ọlọ́run àgbàyanu! (Kól. 3:16) Torí náà, ó yẹ ká máa jọ́sìn Jèhófà nípa lílọ sí àwọn ìpàdé àti àpéjọ wa déédéé, ká sì máa lóhùn sí àwọn ìpàdé náà. (Ìṣí. 4:11) Abájọ tó fi ṣe pàtàkì pé ká má máa “kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà.”—Héb. 10:25.

8 Ẹ̀bùn Ọlọ́run làwọn ìpàdé wa jẹ́. Àwọn ìpàdé náà ló sì ń mú ká lè máa fara dà á títí Ọlọ́run fi máa pa ayé búburú yìí run. Ṣé ojú táwa náà fi ń wo àwọn ìpàdé wa nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a ó máa sapá gidigidi ká lè máa wà ní gbogbo ìpàdé, bó ti wù kí ọwọ́ wa dí tó. (Fílí. 1:10) A kò sì ní fẹ́ pàdánù àǹfààní tá a ní láti máa jọ́sìn Jèhófà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa, àyàfi nítorí ìdí tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.

WÁ ÀWỌN TÓ NÍFẸ̀Ẹ́ ÒTÍTỌ́ RÍ

9. Báwo la ṣe mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì?

9 Ká lè máa gba ibi tí ètò Jèhófà bá ń darí wa sí, a gbọ́dọ̀ máa fi ìtara wàásù. Ìgbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù. (Mát. 28:19, 20) Látìgbà náà sì ni iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ti di ọ̀kan lára iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ètò Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ìrírí fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà, wọ́n sì ń darí wa sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Ìṣe 13:48; Ìṣí. 14:6, 7) Iṣẹ́ pàtàkì yìí ni apá tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà ń ṣètò tó sì tún ń ṣètìlẹ́yìn fún. Ǹjẹ́ àwa náà ka iṣẹ́ ìwàásù sí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ?

10. (a) Báwo ni arákùnrin kan ṣe ń mú kí ìfẹ́ tó ní sí òtítọ́ túbọ̀ máa pọ̀ sí i? (b) Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe mú kó o túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?

10 Tá a bá ń fi ìtara wàásù, ìfẹ́ tá a ní fún òtítọ́ á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ọ̀rọ̀ Mitchel, alàgbà kan tó ti ń sìn tipẹ́ tó sì tún jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ràn láti máa wàásù fáwọn èèyàn. Tí mo bá ronú nípa àpilẹ̀kọ tuntun kan nínú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! ìyàlẹ́nu ni ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, tó sì tún kún fún ìjìnlẹ̀ òye àti àlàyé tí kò pọ̀n sápá kan tó wà nínú wọ́n máa ń jẹ́ fún mi. Ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n lọ sóde ẹ̀rí kí n lè mọ bí ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà ṣe máa rí lára àwọn èèyàn, kí n sì tún mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní pọ̀ sí i.” Mitchel tún sọ pé iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ kí òun fi ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ sí ipò kìíní, òun kì í sì í jẹ́ kí ohunkóhun gba àkókò tó yẹ kóun fi wàásù mọ́ òun lọ́wọ́. Bí àwa náà bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, a ó lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé yìí.—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.

MÁA KA ÀWỌN ÌWÉ WA

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka àwọn ìwé wa ká sì máa ṣàṣàrò lé wọn lórí?

11 Jèhófà ń fún wa lókun nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ìwé tí ètò rẹ̀ ń tẹ̀ jáde. Ó ṣeé ṣe kó o rántí ìgbà kan tó o ka ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde náà tó o sì sọ pé, ‘Ohun tí mò ń fẹ́ gan-an nìyí! Ńṣe ló dà bíi pé torí tèmi ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí wọ́n kọ ọ́!’ Kò ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ o. Àwọn ìtẹ̀jáde yẹn ni Jèhófà fi ń kọ́ wa, ó sì tún ń lò wọ́n láti tọ́ wa sọ́nà. Ó sọ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀.” (Sm. 32:8) Ǹjẹ́ à ń sa gbogbo ipá wa láti ka àwọn ìwé náà gbàrà tí wọ́n bá ti tẹ̀ wá lọ́wọ́ ká sì tún ṣe àṣàrò lórí wọn? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè máa fara dà á, a ó sì tún máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìṣó ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó le koko yìí.—Ka Sáàmù 1:1-3; 35:28; 119:97.

12. Kí ló máa jẹ́ ká mọyì àwọn ìtẹ̀jáde wa?

12 A máa mọyì àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a bá ń ronú lórí iṣẹ́ ribiribi táwọn ará ń ṣe káwọn ìwé náà tó jáde. Ó pọn dandan pé kí wọ́n ṣe ìwádìí, kí wọ́n kọ àwọn ohun tí wọ́n ṣèwádìí náà sílẹ̀, kí wọ́n kà á, kí wọ́n gbé àwòrán sí i, kí wọ́n túmọ̀ wọn, kí wọ́n sì gbé wọn sórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì wa. Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń bójú tó gbogbo èyí. Lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó ń tẹ àwọn ìwé náà á wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ tó wà lábẹ́ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń tẹ̀wé fún. Kí nìdí tá a fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ yìí? À ń ṣe iṣẹ́ yìí ká bàa lè máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí yóò máa tọ́ àwa èèyàn Jèhófà sọ́nà. (Aísá. 65:13) Ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa ka àwọn ìwé tí ètò Jèhófà ń tẹ̀ jáde.—Sm. 119:27.

MÁA ṢÈTÌLẸ́YÌN FÚN ÈTÒ JÈHÓFÀ

13, 14. Àwọn wo ló ń ṣètìlẹ́yìn fún ètò Jèhófà lọ́run? Báwo làwa náà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?

13 Nínú ìran kan tí Jèhófà fi han àpọ́sítélì Jòhánù, ó rí Jésù lórí ẹṣin funfun, ó sì ń jáde lọ láti pa gbogbo àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. (Ìṣí. 19:11-15) Ó tún rí àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ti jíǹde sí ọ̀run àti àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tí wọ́n ń gẹṣin tẹ̀ lé Jésù. Èyí fi hàn pé wọ́n ń ṣètìlẹ́yìn fún Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wọn. (Ìṣí. 2:26, 27) Àpẹẹrẹ àtàtà tí wọ́n fi lélẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé ó yẹ káwa náà máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tó ń múpò iwájú nínú ètò Jèhófà.

14 Bákan náà, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ tí àwọn arákùnrin Kristi tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé ń ṣe. (Ka Sekaráyà 8:23.) Báwo la ṣe lè máa ṣètìlẹ́yìn fún ètò Jèhófà? Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa tẹrí ba fún àwọn tó ń múpò iwájú. (Héb. 13:7, 17) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tá à ń sọ nípa àwọn alàgbà inú ìjọ wa ń mú kó rọrùn fún àwọn míì láti máa bọ̀wọ̀ fún wọn, kí wọ́n sì tún mọyì iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe? Ǹjẹ́ à ń kọ́ àwọn ọmọ wa pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí kí wọ́n sì máa tẹ́tí sí ìmọ̀ràn wọn? Awọn ọ̀nà míì tún wà tá a lè gbà máa ṣètìlẹ́yìn fún ètò Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a máa ń ṣètò gẹ́gẹ́ bí ìdílé láti fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù? (Òwe 3:9; 1 Kọ́r. 16:2; 2 Kọ́r. 8:12) Ǹjẹ́ a máa ń lọ́wọ́ sí títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe? Tí Jèhófà bá rí i pé à ń ṣètìlẹ́yìn fún ètò òun láwọn ọ̀nà yìí, ó máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sì máa fún wa lókun tá a nílò kí àárẹ̀ má bàa mú wa.—Aísá. 40:29-31.

MÁA ṢE OHUN TÓ WU ỌLỌ́RUN

15. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa sapá láti ṣe ohun tó tọ́?

15 Tá a bá fẹ́ ní ìfaradà, tá a sì tún fẹ́ kí ètò Ọlọ́run máa darí wa, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run. (Éfé. 5:10, 11) Sátánì, ayé búburú yìí àti àìpé wa máa ń mú kó ṣòro fún wa gan-an láti ṣe ohun tó tọ́. A mọ̀ pé ojoojúmọ́ ni ẹ̀yin ará wa kan lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń jìjàkadì kẹ́ ẹ lè máa bá a nìṣó láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Inú Jèhófà ń dùn sí yín bẹ́ ẹ ṣe ń ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe. Ẹ má ṣe jẹ́ kó rẹ̀ yín! Tá a bá ń ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, ayé wa á dùn, á sì lóyin. Ó sì dájú pé Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀.—1 Kọ́r. 9:24-27.

16, 17. (a) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì? (b) Kí la lè rí kọ́ lára Anne?

16 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ńkọ́, kí ló yẹ ká ṣe? Má ṣe bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀. Tètè wá bó o ṣe máa rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Rántí bí nǹkan ṣe rí fún Dáfídì nígbà tó gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó sọ pé: “Egungun mi ti di gbígbó nítorí ìkérora mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sm. 32:3) A ò lè láyọ̀ tá a bá gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì mọ́lẹ̀, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà sì lè bà jẹ́. Àmọ́, tá a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, Ọlọ́run máa “fi àánú hàn sí” wa.—Òwe 28:13.

17 Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Anne. * Kò tíì pé ọmọ ogún ọdún tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í yọwọ́ kọ́wọ́, aṣáájú-ọ̀nà sì ni nígbà yẹn. Látàrí èyí, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dá a lẹ́bi. Ó sọ pé: “Inú mi kì í dùn, mo sì rẹ̀wẹ̀sì.” Lọ́jọ́ kan, wọ́n jíròrò Jákọ́bù 5:14, 15 nígbà tẹ́ni kan ń ṣiṣẹ́ nípàdé. Anne wá rí i pé òun nílò ìrànlọ́wọ́. Kí ló ṣe? Ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́, ó fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn alàgbà létí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sọ pé ńṣe ló dà bíi pé òun ń ṣàìsàn tí Jèhófà sì wá fún òun ní oògùn. Lẹ́yìn náà, ó wá ṣàlàyé pé: “Oògùn yẹn ò rọrùn láti lò, àmọ́ ó máa ń woni sàn.” Ní báyìí, Anne ti ń fìtara sin Jèhófà, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò sì dà á láàmù mọ́.

18. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

18 Ó yẹ ká máa rántí nígbà gbogbo pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa pé a wà nínú ètò Jèhófà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí! Ẹ jẹ́ kí àwa àti gbogbo ìdílé wa pinnu pé a ó máa lọ sí àwọn ìpàdé déédéé. Ká pinnu pé a ó máa fìtara wàásù ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, a ó sì máa ka àwọn ìwé wa. Ẹ jẹ́ ká tún máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tó ń múpò iwájú, ká sì máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí yóò máa mú inú Jèhófà dùn. Tá a bá ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan yìí, a ò ní fi ètò Jèhófà sílẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní mú wa.

^ ìpínrọ̀ 17 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.