Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Fi Hàn Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?

Ṣé Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Fi Hàn Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?

OHUN TÍ ÀWỌN KAN SỌ: “Ọlọ́run ló ń ṣàkóso ayé, òun ló sì ń fa àjálù tó ń ṣẹlẹ̀; torí náà, ìkà ni.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ta ni “ẹni burúkú náà”? Bíbélì pè é ní Sátánì. (Mátíù 13:19; Máàkù 4:15) Ǹjẹ́ èyí ṣòro láti gbà gbọ́? Rò ó wò ná: Tí Sátánì bá ń ṣàkóso ayé, a jẹ́ pé òun ló ń mú kí àwọn èèyàn máa ṣe bíi tirẹ̀, kí wọ́n jẹ́ olójú kòkòrò, kí wọ́n má ro ti ọ̀la mọ́ ohun tí wọ́n bá ń ṣe, òun ló sì ń mú kí wọ́n má mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ. Ǹjẹ́ ìyẹn kò jẹ́ ká rí ìdí tí àwọn èèyàn fi ń ba ilẹ̀ ayé táwọn fúnra wọn ń gbé jẹ́? Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ṣèwádìí ló ti kìlọ̀ pé bí àwọn èèyàn ṣe ń lo àyíká wọn nílòkulò lè wà lára ohun tó ń fa àjálù, tàbí kó mú kí àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì tún lè mú kí àkóbá tí àjálù ń ṣe fún àwọn èèyàn túbọ̀ pọ̀.

Kí wá nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba Sátánì tó bẹ́ẹ̀? Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìran èèyàn ni ọ̀rọ̀ yẹn ti wọ́ wá. Sátánì mú kí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Alákòóso wọn. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ló ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ burúkú àwọn òbí wa àkọ́kọ́ látìgbà yẹn. Àwọn èèyàn ti gbé ara wọn lé Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run lọ́wọ́ torí bí wọ́n ṣe kọ̀ kí Ọlọ́run máa ṣàkóso wọn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé.” (Jòhánù 14:30) Ṣé Sátánì á máa ṣàkóso títí láé ni? Rara o!

Inú Jèhófà * kò dùn rárá sí bí Sátánì ṣe ń fi ìyà jẹ aráyé. Kódà, ó máa ń dun Ọlọ́run wọra bó ṣe ń rí i tí ìyà ń jẹ wá. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ bí nǹkan ṣe rí lára Ọlọ́run nígbà tí nǹkan nira gan-an fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó ní: “Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” (Aísáyà 63:9) Nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú, ó ti ṣètò bí àkóso Sátánì tó jẹ́ òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ ṣe máa dópin láìpẹ́! Ó ti yan Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Ọba tó máa fi òdodo àti òtítọ́ ṣàkóso títí láé.

BÍ Ó ṢE KÀN Ọ́: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkóso Sátánì kò lè dáàbò bo àwọn èèyàn lọ́wọ́ àjálù tó ń ṣẹlẹ̀, ìṣàkóso Jésù kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ìgbà kan wà tí Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ là lọ́wọ́ ìjì kan tó lágbára. Bíbélì sọ pé: “Ó sì bá ẹ̀fúùfù náà wí lọ́nà mímúná, ó sì wí fún òkun náà pé: ‘Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!’ Ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.” Èyí ya àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́nu, wọ́n sọ pé: “Ta nìyí ní ti gidi, nítorí ẹ̀fúùfù àti òkun pàápàá ń ṣègbọràn sí i?” (Máàkù 4:37-41) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé Jésù máa dáàbò bo gbogbo èèyàn tó jẹ́ onígbọràn nígbà tó bá ń ṣàkóso bí Ọba.—Dáníẹ́lì 7:13, 14.

^ ìpínrọ̀ 5 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.