Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ Jẹ Jèhófà Lógún Lóòótọ́?

Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ Jẹ Jèhófà Lógún Lóòótọ́?

Obìnrin kan tó ṣòro fún láti gbà pé ọ̀rọ̀ òun lè jẹ Jèhófà lógún sọ pé: “Èrò pé mi ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run ni mo fẹ́ẹ̀ lè sọ pé ó jẹ́ olórí ìṣòro tí mò ń gbìyànjú láti borí.” Ṣé irú èrò tí ìwọ náà ní nìyẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ Jèhófà bìkítà nípa àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó bìkítà! A rí ẹ̀rí pé Jèhófà dìídì nífẹ̀ẹ́ wa nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ.—Ka Jòhánù 6:44.

Kí ni Jésù, ẹni tó mọ ìwà Jèhófà lámọ̀dunjú, tó sì mọ ìfẹ́ inú Jèhófà dáadáa ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ sọ? (Lúùkù 10:22) Ó sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” Èyí fi hàn pé, a kò lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, tàbí ká di olùjọsìn Jèhófà, Baba wa ọ̀run, láìjẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ fà wá. (2 Tẹsalóníkà 2:13) Tí a bá lóye ọ̀rọ̀ Jésù, a máa rí ẹ̀rí tó lágbára pé ọ̀rọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ Ọlọ́run lógún.

Kí ló túmọ̀ sí pé kí Jèhófà fà wá? Kì í ṣe pé Jèhófà ń fi dandan mú wa pé ká sin òun. Ó fún wa ní òmìnira, torí náà kì í fi tipátipá fà wá. (Diutarónómì 30:19, 20) Jèhófà ń wo ọkàn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé, ó ń wá àwọn tó ń fẹ́ láti mọ òun. (1 Kíróníkà 28:9) Tó bá rí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ó máa ń fi ìfẹ́ fà wọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Báwo ló ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Jèhófà máa ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fa àwọn tó bá ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́” mọ́ra. (Ìṣe 13:48) Ọ̀nà méjì ni Jèhófà máa ń gbà ṣe èyí. Àkọ́kọ́ jẹ́ nípasẹ̀ ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì tó ń dé ọ̀dọ̀ olúkúlùkù wa. Èkejì jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Tí Jèhófà bá rí i pé ọkàn ẹnì kan ṣí sílẹ̀ láti gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ran ẹni yẹn lọ́wọ́, kó lè lóye òtítọ́ yìí, kó sì fi í sílò ní ìgbésí ayé rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 2:11, 12) Láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a kò lè di ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù, a kò sì ní lè fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà láéláé.

Jèhófà fún wa ní òmìnira, torí náà kì í fi tipátipá fà wá

Kí wá ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 6:44 kọ́ wa nípa Jèhófà Ọlọ́run? Ó kọ́ wa pé, Jèhófà máa ń fà wá torí ó rí ohun rere nínú ọkàn wa àti pé ọ̀rọ̀ olúkúlùkù wa jẹ ẹ́ lógún. Nígbà tí obìnrin tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí wá lóye òtítọ́ tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí, ó tù ú nínú. Obìnrin náà sọ pé: “Àǹfààní tó ga jù lọ téèyàn lè ní láyé yìí ni pé kó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Níwọ̀n bí Jèhófà sì ti yàn mí ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, á jẹ́ pé mo ṣeyebíye lójú rẹ̀ nìyẹn.” Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ bí o ṣe wá mọ̀ pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa mú kí o sún mọ́ ọn?

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún May Lúùkù 22-24Jòhánù 1-16