Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Ní Ìtara Fún “Iṣẹ́ Àtàtà”?

Ǹjẹ́ O Ní Ìtara Fún “Iṣẹ́ Àtàtà”?

“Kristi Jésù. . .fi ara rẹ̀ fúnni nítorí wa kí ó bàa lè. . .wẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe mọ́ fún ara rẹ̀, àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.”—TÍTÙ 2:13, 14.

1, 2. Àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní? Báwo nìyẹn ṣe rí lára rẹ?

ÀǸFÀÀNÍ ńláǹlà lọ̀pọ̀ èèyàn kà á sí tí wọ́n bá fún wọn ní ẹ̀bùn nítorí ohun ribiribi kan tí wọ́n gbé ṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti fún àwọn kan ní ẹ̀bùn ẹ̀yẹ torí pé wọ́n jà fitafita láti rí i pé àlàáfíà jọba láàárín àwọn tó ń bá ara wọn jagun. Àmọ́ o, kí la máa sọ nípa ẹni tí Ọlọ́run dìídì rán pé kó jẹ́ aṣojú òun láti mú kí àwọn èèyàn sún mọ́ òun kí wọ́n lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn? Ohun iyì wo ló tó ìyẹn? Ó dájú pé kò sí!

2 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ní àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Ọlọ́run àti Kristi ló yàn wá pé ká máa pàrọwà fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n “padà bá Ọlọ́run rẹ́.” (2 Kọ́r. 5:20) Jèhófà ló ní ká máa sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n wá jọ́sìn òun. Iṣẹ́ tá à ń jẹ́ fáwọn èèyàn yìí ló mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn láti ilẹ̀ tó lé ní igba àti márùnlélọ́gbọ̀n [235] ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń retí ìgbà tí wọ́n máa wà láàyè títí láé. (Títù 2:11) Ńṣe là ń fi ìtara pe ‘ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.’ (Ìṣí. 22:17) Nítorí pé a mọyì iṣẹ́ bàǹtàbanta tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ yìí tá a sì ń ṣe é taápọntaápọn, a lè fi gbogbo ẹnu sọ pé a jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:14) Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò bí ìtara wa fún àwọn iṣẹ́ àtàtà ṣe ń mú ká lè ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà. Èyí tá a máa kọ́kọ́ gbé yẹ̀ wò nínú wọn ni iṣẹ́ ìwàásù.

JẸ́ ONÍTARA BÍI TI JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ

3. Kí ni gbólóhùn náà, “àní ìtara Jèhófà” mú kó dá wa lójú?

3 Nígbà tí wòlíì Aísáyà ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jésù máa gbé ṣe nígbà tó bá ń ṣàkóso, ó sọ ní orí kẹsàn-án, ẹsẹ keje pé: “Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ó wu Baba wa ọ̀run gan-an pé káwọn èèyàn rí ìgbàlà. Ìtara Jèhófà mú ká túbọ̀ rí i pé ó fẹ́ kí àwa tá à ń polongo ìhìn rere Ìjọba rẹ̀ máa fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ náà, ká máa ṣe é tọkàntọkàn, ká sì máa fi ìtara ṣe é. Tó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn ló ń wù wá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run, èyí fi hàn pé Ọlọ́run la fìwà jọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Ọlọ́run ni wá, ó yẹ ká bi ara wa pé, “Ǹjẹ́ gbogbo ohun tí agbára mi gbé ni mò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà?”—1 Kọ́r. 3:9.

4. Báwo ni Jésù ṣe lo ìtara tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?

4 Ẹ jẹ́ ká tún wo bí Jésù ṣe lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Tó bá dọ̀rọ̀ ká lo ìtara àti ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, àpẹẹrẹ pípé ni Jésù fi lélẹ̀. Wọ́n ṣe inúnibíni tó lágbára sí i, àmọ́ ńṣe ló tún ń fìtara wàásù káàkiri. Kò sì yé lo ìtara títí tó fi kú. (Jòh. 18:36, 37) Bí àkókò tí Jésù máa kú ṣe ń sún mọ́, ńṣe ló túbọ̀ ń fi ìtara pàrọwà fún àwọn èèyàn láti wá mọ Jèhófà.

5. Báwo ni Jésù ṣe dà bí olùrẹ́wọ́ àjàrà ti inú àkàwé igi ọ̀pọ̀tọ́ tó sọ?

5 Lọ́dún 32 Sànmánì Kristẹni, Jésù ṣàkàwé ọkùnrin kan tó ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan nínú ọgbà àjàrà rẹ̀ àmọ́ tí kò so èso fún odidi ọdún mẹ́ta. Nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún olùrẹ́wọ́ àjàrà rẹ̀ pé kó gé igi ọ̀pọ̀tọ́ náà lulẹ̀, ó ní kí wọ́n fún òun ní àkókò díẹ̀, kí òun lè fi ajílẹ̀ sí i bóyá igi náà máa so èso. (Ka Lúùkù 13:6-9.) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ìwọ̀nba kéréje làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ìyẹn àwọn tá a lè pè ní èso tó ti ara iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ jáde. Àmọ́, bíi ti olùrẹ́wọ́ àjàrà inú àkàwé yẹn, Jésù lo ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ tó kù, ìyẹn nǹkan bí oṣù mẹ́fà láti jára mọ́ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ ní Jùdíà àti Pèríà. Lọ́jọ́ bíi mélòó kan ṣáájú ikú Jésù, ó sunkún nítorí àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìlú rẹ̀, torí pé “wọ́n gbọ́ láìsí ìdáhùnpadà.”—Mát. 13:15; Lúùkù 19:41

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa?

6 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí kò ní pẹ́ wá sópin, ǹjẹ́ kò ní dáa ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa? (Ka Dáníẹ́lì 2:41-45.) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Ní gbogbo ayé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan là ń sọ ohun tó jẹ́ ojútùú gidi sí ìṣòro aráyé. Nínú ìwé kan tí obìnrin oníròyìn kan kọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó sọ pé ìbéèré kan tí kò sẹ́ni tó lè dáhùn rẹ̀. Ìbéèrè náà ni pé, “Kí nìdí tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹni rere?” Ojúṣe wa ló jẹ́ láti mú káwọn èèyàn mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, àǹfààní ńláǹlà ló sì jẹ́ pẹ̀lú. Torí náà, ẹ jẹ́ kí “iná ẹ̀mí máa jó” nínú wa bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́. (Róòmù. 12:11) Lọ́lá Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tá à ń fi ìtara ṣe yìí máa mú kí àwọn èèyàn wá mọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

À Ń BỌLÁ FÚN ỌLỌ́RUN BÁ A ṢE Ń NÍ Ẹ̀MÍ ÌFARA-ẸNI-RÚBỌ

7, 8. Báwo la ṣe ń bọlá fún Ọlọ́run tá a bá ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ?

7 Pọ́ọ̀lù kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. Àwọn ìgbà míì wà tí kò lè sùn, tí kò sì lè jẹun. (2 Kọ́r. 6:5) Àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa náà máa ń fi irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ bẹ́ẹ̀ hàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ ìwàásù làwọn aṣáájú-ọ̀nà kà sí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì tún ń ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè máa gbọ́ bùkátà ara wọn. Àpẹẹrẹ míì ni àwọn míṣọ́nnárì, àwọn náà ń ṣiṣẹ́ kára bí wọ́n ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ní ilẹ̀ òkèèrè. (Fílí. 2:17) Àwọn alàgbà náà ò gbẹ́yìn o, àwọn ìgbà míì wà tí wọn kì í lè jẹun tàbí tí wọ́n kì í lè sùn nítorí pé wọ́n ń bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn akéde kan nínú ìjọ. A tún mọyì báwọn àgbàlagbà àtàwọn tí ara wọn kò le dáadáa ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí agbára wọn gbé kí wọ́n bàa lè máa wá sáwọn ìpàdé, kí wọ́n sì lè máa lọ sóde ẹ̀rí. Ohun ìwúrí ló jẹ́ bá a ṣe ń rí i tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn. Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàápàá máa ń kíyèsí ìtara wa, èyí sì máa ń jẹ́ kí wọ́n rí i pé iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe pàtàkì gan-an sí wa.

8 Ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ lẹ́tà kan sí iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń tẹ ìwé ìròyìn Boston Target nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó sọ pé: ‘Àwọn èèyàn ò fọkàn tán ẹ̀sìn mọ́ o. Iṣẹ́ wo làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí tiẹ̀ ń ṣe? Kì í kúkú ṣe pé wọ́n ń jáde lọ bá àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe. Ẹ̀sìn kan ṣoṣo tó jọ pé ó bìkítà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ló máa ń lọ bá àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ń fi tọkàntara wàásù òtítọ́.’ Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé lónìí ló jẹ́ onímọtara ẹni nìkan tí wọ́n sì ti kẹ́ ara wọn bà jẹ́. Àmọ́, nítorí pé àwa ń lo ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, à ń bọlá fún Jèhófà.—Róòmù 12:1.

Bí àwọn èèyàn ṣe ń rí ẹ lóde ẹ̀rí máa ń jẹ́rìí fún wọn lọ́nà tó lágbára

9. Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ṣẹlẹ̀ pé ìtara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ti ń dín kù?

9 Àmọ́, kí la lè ṣe tá a bá rí i pé ìtara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ti ń jó rẹ̀yìn? Á dára ká máa ronú nípa ohun tí Jèhófà ń gbé ṣe nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. (Ka Róòmù 10:13-15.) Káwọn èèyàn tó lè rí ìgbàlà, wọ́n gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà kí wọ́n sì máa pe orúkọ rẹ̀, àmọ́ wọn ò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀ láìjẹ́ pé a wàásù fún wọn. Níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí, ẹ jẹ́ ká máa fìtara ṣe iṣẹ́ àtàtà nìṣó, ká sì máa polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn.

ÌWÀ RERE WA MÁA Ń FA ÀWỌN ÈÈYÀN SỌ́DỌ̀ JÈHÓFÀ

Àwọn èèyàn máa ń kíyèsí bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́, tá a sì ń ṣiṣẹ́ kára

10. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìwà rere wa máa ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ Jèhófà?

10 Òótọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa. Àmọ́, ìyẹn nìkan kò tó láti fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ohun kejì lára àwọn iṣẹ́ àtàtà tó ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwà rere wa. Pọ́ọ̀lù sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa hùwà rere, ó kọ̀wé pé: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.” (2 Kọ́r. 6:3) Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí tó máa ń jáde lẹ́nu wa àti ìwà rere wa máa ń mú kó wu àwọn èèyàn láti wá jọ́sìn Jèhófà. (Títù 2:10) Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nítorí ìwà rere wa.

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà pé kí ìwà wa mú káwọn èèyàn wá sin Jèhófà?

11 Òótọ́ ni pé ìwà wa lè mú káwọn èèyàn wá sin Jèhófà, àmọ́, ìwà wa tún lè mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra kí àwọn èèyàn má bàa na ìka àbùkù sí iṣẹ́ ìwàásù wa. Ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa hùwà rere níbi yòówù ká wà, yálà níbi iṣẹ́, nílé, tàbí níléèwé. Tó bá jẹ́ pé ńṣe là ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, àbájáde rẹ̀ máa burú gan-an ni. (Héb. 10:26, 27) Torí náà, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó má ṣe jẹ́ kí ìwà àti ìṣe wa mú káwọn èèyàn jìnnà sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń sọ ìwà ọmọlúwàbí nù, ó yẹ ká máa “rí ìyàtọ̀ . . . láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Mál. 3:18) Kò sí àní-àní pé, ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa hùwà rere tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ Jèhófà.

12-14. Tá a bá ń fara da inúnibíni, ipa wo ló lè ní lórí àwọn èèyàn? Sọ àpẹẹrẹ kan.

12 Nínú lẹ́tà kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ fún wọn pé àwọn tí kò fẹ́ gbọ́ ìhìn rere ṣe inúnibíni sí òun, wọ́n na òun, wọ́n sì fi òun sẹ́wọ̀n. (Ka 2 Kọ́ríńtì 6:4, 5.) Tá a bá ń fara da inúnibíni, ó lè mú kí àwọn èèyàn wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Nígbà kan lórílẹ̀-èdè Àǹgólà, àwọn kan sọ pé àwọn ò fẹ́ rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ lágbègbè kan lórílẹ̀-èdè náà. Ìta gbangba ni àwọn alátakò yìí ti na tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì tí iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n [30] tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n nà wọ́n débi tí ara wọn fí bẹ́ tí ẹ̀jẹ̀ sì ń dà lára wọn. Kódà, wọn ò tiẹ̀ yọ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé sílẹ̀. Àwọn ará àdúgbò wá pé jọ, wọ́n sì ń wo báwọn alátakò yìí ṣe ń fìyà jẹ àwọn ẹni ẹlẹ́ni wọ̀nyí. Kí ló fà á táwọn alátakò yìí fi hùwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí wọn? Wọ́n ní ńṣe làwọn fẹ́ fi dẹ́rù ba àwọn aráàlú, kí ẹnì kankan má bàa tẹ́tí sí ìwàásù wọn mọ́. Àmọ́, ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Torí pé lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ńṣe ni ọ̀pọ̀ lára àwọn aráàlú yẹn lọ bá àwọn tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn pé àwọn fẹ́ kí wọ́n wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Àwọn ará wa ò rẹ̀wẹ̀sì, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

13 Àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí i pé tá a bá fìgboyà rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run, ó lè mú káwọn èèyàn wá sin Jèhófà. A ò lè sọ bí iye àwọn tó dara pọ̀ mọ́ àwọn àpọ́sítélì láti máa jọ́sìn Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó lẹ́yìn tí Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì míì fìgboyà jẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn. (Ìṣe 5:17-29) Táwa náà bá ń fìgboyà ṣe ohun tó tọ́, àwọn ọmọléèwé wa, àwọn ará ibiṣẹ́ wa tàbí àwọn ẹbí wa lè wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

14 Kò sígbà kan tí wọn kì í ṣenúnibíni sáwọn ará wa. Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ yìí, àwọn arákùnrin wa tó tó ogójì [40] ló wà lẹ́wọ̀n báyìí lórílẹ̀-èdè Armenia torí pé wọ́n kọ̀ láti báwọn jagun. Àìmọye àwọn míì ló tún máa kún wọn lọ́jọ́ iwájú. Lórílẹ̀-èdè Eritrea, márùndínlọ́gọ́ta [55] làwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n, àwọn kan lára wọn tiẹ̀ ti lé ní ẹni ọgọ́ta [60] ọdún. Ní South Korea, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń lọ bíi ọgọ́rùn-ún méje [700] ló wà lẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Ó ti tó ọgọ́ta [60] ọdún tí wọ́n ti ń fi àwọn ará wa sẹ́wọ̀n ní orílẹ̀-èdè yìí. Ẹ jẹ́ ká máa rántí àwọn ará wa nínú àdúrà, ká máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí wọ́n lè dúró ṣinṣin. Kí ìdúróṣinṣin wọn máa fògo fún Ọlọ́run, kí ó sì mú káwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo wá sin Jèhófà.—Sm. 76:8-10.

15. Sọ àpẹẹrẹ kan to fi hàn pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́, ó lè mú káwọn èèyàn wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

15 Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo nǹkan tá a bá ń ṣe, á mú káwọn èèyàn lè wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Ka 2 Kọ́ríńtì 6:4, 7.) Àpẹẹrẹ kan rèé: Arábìnrin kan fẹ́ sanwó ọkọ̀ fún ẹni tó ń gbowó nínú mọ́tò. Àmọ́, ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé kí ó ṣe bí ẹni tó ti sanwó ọkọ̀, nígbà tó jẹ́ pé ibi tó ń lọ ò kúkú jìnnà. Arábìnrin náà wá sọ pé tí ibi tí òun bá ń lọ kò bá tiẹ̀ jìnnà, ó yẹ kí òun sanwó. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí bọ́ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, awakọ̀ mọ́tò náà wá bi arábìnrin wa bóyá Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Arábìnrin náà dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ kí nìdí tẹ́ ẹ fi béèrè?” Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Mo gbọ́ nígbà tí obìnrin yẹn ní kẹ́ ẹ má sanwó ọkọ̀. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe màgòmágó, ẹ sì máa ń ṣòótọ́ nínú ohun gbogbo.” Ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, ọkùnrin kan wá bá arábìnrin wa nípàdé, ó sì bi í pé, “Ṣẹ́ ẹ mọ̀ mí? Èmi ni awakọ̀ ọjọ́sí tó gbé é yín, tí ọ̀rẹ́ yín fi ní kẹ́ ẹ ṣe bí ẹni tó ti sanwó ọkọ̀. Ìwà yín ló wú mi lórí tí mo fi ní káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ẹ ò rí pé báwọn èèyàn ṣe mọ̀ wá sí olóòótọ́ ń mú kí wọ́n gbà pé àwa là ń sin Ọlọ́run lóòótọ́.

JẸ́ KÍ ÌWÀ RẸ MÁA BUYÌ KÚN ỌLỌ́RUN NÍGBÀ GBOGBO

16. Kí nìdí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi túbọ̀ máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn nígbà tí wọ́n bá kíyè sí i pé a ní ìpamọ́ra, ìfẹ́ àti inú rere? Sọ àpẹẹrẹ kan.

16 Tá a bá ń lo ìpamọ́ra, ìfẹ́ àti inú rere, ó lè mú káwọn èèyàn wá sin Jèhófà. Ó ń mú kí àwọn tó ń kíyè sí wa fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti sún mọ́ àwa èèyàn Jèhófà. Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín àwa àtàwọn kan tó pe ara wọn ní Kristẹni, tó jẹ́ pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé ti Ọlọ́run làwọn ń ṣe. Àwọn aṣáájú ìsìn kan ti dolówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n ń lu àwọn ọmọ ìjọ wọn ní jìbìtì owó gọbọi, wọ́n sì ń fi owó náà ra ọ̀pọ̀ ilé àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Kódà, ọ̀kan lára wọn tún ra ilé kan tí ajá rẹ̀ á máa gbé, wọ́n sì ṣe ẹ̀rọ amúlétutù sínú rẹ̀. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò sí èyí tó ṣe tán láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́fẹ̀ẹ́ lára wọn. (Mát. 10:8) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n fìwà jọ àwọn àlùfáà oníwàkiwà ní Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, àwọn tó jẹ́ pé wọ́n ń fún àwọn èèyàn “ní ìtọ́ni kìkì fún iye kan.” Èyí tó sì pọ̀ jù lára ìtọ́ni ọ̀hún kò bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. (Míkà 3:11) Irú ìwà àgàbàgebè bẹ́ẹ̀ ò lè mú káwọn èèyàn sún mọ́ Ọlọ́run.

17, 18. (a) Báwo la ṣe lè máa bọlá fún Jèhófà nípa ìwà wa? (b) Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá máa bá iṣẹ́ àtàtà nìṣó?

17 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà táwọn èèyàn bá rí i pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ la fi ń kọ́ni, tá a sì ń hùwà rere sí àwọn èèyàn, ó máa ń wù wọ́n láti sún mọ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí arákùnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wàásù dé ilé kan, ìyá àgbàlagbà kan ló bá nílé, opó sì ni ìyá náà. Àmọ́, kíá ló sọ fún arákùnrin náà pé kó máa lọ, torí pé òun ò ráyè. Ó sọ pé orí àkàbà lòun wà nínú ilé ìdáná tí òun ń wá bí òun ṣe máa pààrọ̀ gílóòbù tó ti jó nígbà tóun gbọ́ tí aago ẹnu ọ̀nà dún. Arákùnrin yẹn wá sọ fún un pé: “Ìyá àgbà, ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe yẹn léwu gan-an o.” Ni ìyá náà bá ní kí arákùnrin wa wọlé. Arákùnrin wá pààrọ̀ gílóòbù náà, ó sì bá tiẹ̀ lọ. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin fi wá wò ó. Ni ìyá bá ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọmọ rẹ̀. Inú ọmọ yẹn dùn gan-an, ló bá sọ fún ìyá náà pé òun fẹ́ mọ onítọ̀hún kóun lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọmọ ìyà náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

18 Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá máa bá iṣẹ́ àtàtà nìṣó? Ó lè jẹ́ torí bó o ṣe mọ̀ pé tá a bá ń fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tá a sì ń ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ńṣe là ń bọlá fún Jèhófà, á sì tún mú káwọn èèyàn lè rí ìgbàlà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:31-33.) Ó dájú pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti fáwọn èèyàn ló mú ká máa lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Òun náà ló sì ń mú ká máa hùwà rere. (Mát. 22:37-39) Tá a bá jẹ́ onítara fún iṣẹ́ àtàtà, a ó máa láyọ̀, ọkàn wa á sì balẹ̀. Lọ́jọ́ iwájú, a máa wà níbẹ̀ nígbà tí gbogbo aráyé á máa fìtara sin Jèhófà, tí a ó sì máa bọlá fún Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa.