Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

Ọ̀nà wo ló dà bíi pé ó wọ́pọ̀ jù lọ jù táwọn èèyàn ń gbà lo Bíbélì lọ́nà tí kò tọ́, ṣé ó sì yẹ káwọn Kristẹni máa lọ́wọ́ sí àṣà yìí?

Àṣà kan tó dà bíi pé ó wọ́pọ̀ jù lọ táwọn èèyàn máa ń dá ni pé, wọ́n á kàn ṣí Bíbélì sí ibì kan ṣáá, wọ́n á ka gbólóhùn tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí níbẹ̀, wọ́n á sì gbà pé ohun tí wọ́n bá kà yẹn ló máa tọ́ àwọn sọ́nà. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í wá bí wọ́n ṣe máa fi agbára àràmàǹdà wádìí àwọn nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n bàa lè ní ìmọ̀ pípéye, kí Ọlọ́run sì lè máa darí wọn.—12/15, ojú ìwé 3.

“Ayé” wo ló máa kọjá lọ?

Gbogbo àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni “ayé” tó máa kọjá lọ. (1 Jòh. 2:17) Ilẹ̀ ayé àtàwọn èèyàn rere kò ní pa run.—1/1, ojú ìwé 5 sí 7.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ébẹ́lì ti kú, báwo ló ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀? (Héb. 11:4)

Ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó lágbára tó fi lélẹ̀ fún wa. A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìgbàgbọ́ rẹ̀, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa dà bíi pé oun fúnra rẹ̀ ń bá wa sọ̀rọ̀.—1/1, ojú ìwé 12.

Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó lè mú wa jìnnà sí Ọlọ́run tó yẹ ká ṣọ́ra fún?

Díẹ̀ lára àwọn nǹkan náà rèé: iṣẹ́, eré ìdárayá, àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́, àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, ìlera, owó, àti ìgbéraga.—1/15, ojú ìwé 12 sí 21.

Kí la rí kọ́ látinú bí Mósè ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

Mósè kò jẹ́ kí agbára gun òun, kàkà bẹ́ẹ̀ ń ṣe ló gbára lé Ọlọ́run. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí agbára tá a ní, ipò àṣẹ tá a wà tàbí ẹ̀bùn àbínibí tá a ní máa gùn wá gàràgàrà; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Òwe 3:5, 6)—2/1, ojú ìwé 5.

Ibo ni àwọn òkú máa jíǹde sí?

Ìwọ̀nba àwọn tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ló máa jíǹde sí ọ̀run. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó máa jíǹde ni yóò jíǹde sórí ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—3/1, ojú ìwé 6.

Kí ló túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà”? (Jer. 9:26)

Wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀, wọ́n sì kọ̀ láti yí pa dà. Èrò ọkàn wọn àti ìwà wọn burú lójú Jèhófà. (Jer. 5:23, 24)—3/15, ojú ìwé 9 àti 10.

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ ni Jésù gbé?

Ó pinnu láti fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. Ó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ gidigidi, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn pẹ̀lú. Bákan náà, ó dá Jésù lójú pé Baba òun nífẹ̀ẹ́ òun, inú rẹ̀ sì ń dùn sí òun. Àwọn nǹkan yìí gan-an ló sì ń mú kí ìgbésí ayé ẹni nítumọ̀.—4/1, ojú ìwé 4 sí 6.

Kí ni apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run?

Apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run rèé: Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà, àwọn ìjọ àti akéde kọ̀ọ̀kan.—4/15, ojú ìwé 29.

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run kò fi hàn pé ìkà ni?

Inú Jèhófà kò dùn sí ikú àwọn ẹni burúkú. (Ìsík. 33:11) Bíbélì fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń kọ́kọ́ kìlọ̀ dáadáa kó tó mú ìdájọ́ rẹ̀ wá. Èyí sì ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa dá wa sí nígbà tí àkókò ìdájọ́ rẹ̀ bá dé.—5/1, ojú ìwé 5 àti 6.

Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ṣé wọ́n máa ń kan àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá fẹ́ pa mọ́ igi?

Rárá. Àwọn orílẹ̀-èdè àtijọ́ tó kù máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, ńṣe ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ pa àwọn ọ̀daràn kí wọ́n tó gbé wọn kọ́ sórí igi. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n á kọ́kọ́ sọ ọ́ lókùúta pa. (Léf. 20:2, 27) Lẹ́yìn náà, wọ́n wá lè gbé òkú náà kọ́ sórí òpó igi kí ó bàa lè jẹ́ ìkìlọ̀ fáwọn míì.—5/15, ojú ìwé 13.

Kí nìdí tí kò fi sí àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ńlá làwa èèyàn ti gbé ṣe, síbẹ̀, kò ṣeé ṣe fún wa láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara wa. (Jer. 10:23) Nítorí pé Sátánì ni alákòóso ayé, kò ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti mú kí àlàáfíà wà láyé. (1 Jòh. 5:19)—6/1, ojú ìwé 16.