Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?”

“Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?”

“Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀?”—MÁT. 24:45.

1, 2. Ọ̀nà wo ni Jésù ń gbà bọ́ wa nípa tẹ̀mí lóde òní? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ ọ̀nà náà?

NÍNÚ lẹ́tà tí arábìnrin kan kọ sí orílé-iṣẹ́ wa, ó sọ pé: “Ẹ̀yin arákùnrin wa, mi ò lè ka iye ìgbà tó jẹ́ pé ohun tí mo bá nílò gan-an ló máa ń jáde lásìkò tí mo nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́ nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó bá dé.” Ṣé bó ṣe máa ń rí lára ìwọ náà nìyẹn? Kò yà wá lẹ́nu pé bó ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn nìyẹn.

2 Bá a ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí ní àsìkò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á máa pèsè oúnjẹ fún wa. Àmọ́, ta ló ń lò láti pèsè oúnjẹ yìí? Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀, ó sọ pé òun máa lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa fún àwọn ará ilé rẹ̀ ní ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’ * (Ka Mátíù 24:45-47.) Ẹrú olóòótọ́ yìí ni Jésù ń lò láti pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tòótọ́ ní àkókò òpin yìí. Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ẹrú olóòótọ́ tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ìdí ni pé ẹrú yìí ló ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí aṣaralóore fún wa, òun náà ló sì ń tọ́ wa sọ́nà ká lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà.—Mát. 4:4; Jòh. 17:3.

3. Àlàyé wo làwọn ìwé wa ti ṣe sẹ́yìn nípa àkàwé ẹrú olóòótọ́?

3 Nígbà náà, kí la lè sọ nípa ẹrú olóòótọ́ tí Jésù ṣàkàwé rẹ̀? Àlàyé táwọn ìwé wa ti ṣe sẹ́yìn rèé: Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Jésù yan ẹrú olóòótọ́ sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀. Ẹrú náà dúró fún gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò èyíkéyìí, bẹ̀rẹ̀ láti Pẹ́ńtíkọ́sì títí di ìsinsìnyí. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni àwọn ará ilé náà. Bákan náà, ọdún 1919 ni Jésù yan ẹrú yìí sípò “lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀,” ìyẹn gbogbo ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ o, lẹ́yìn tá a fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ṣàṣàrò tàdúràtàdúrà, a wá rí i pé ó pọn dandan pé ká ṣàtúnṣe sí bá a ṣe lóye ọ̀rọ̀ Jésù nípa ẹrú olóòótọ́ àti olóye. (Òwe 4:18) Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò àpèjúwe yìí, ká sì wo bó ṣe kan gbogbo wa, yálà a ní ìrètí àtilọ sí ọ̀run tàbí a ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé.

ÌGBÀ WO NI ÀKÀWÉ NÁÀ NÍ ÌMÚṢẸ?

4-6. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹ̀yìn ọdún 1914 ni àkàwé Jésù nípa ẹrú olóòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ?

4 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣáájú àti lẹ́yìn ibi tó ti sọ̀rọ̀ nípa ẹrú olóòótọ́ àti olóye fi hàn pé àkókò òpin tá a wà yìí ni àsọtẹ́lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, kì í ṣe ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ẹ jẹ́ ká wo bí Ìwé Mímọ́ ṣe jẹ́ ká rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.

5 Àkàwé nípa ẹrú olóòótọ́ jẹ́ apá kan àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa “àmì wíwàníhìn-ín [rẹ̀] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 24:3) Ẹ̀ẹ̀mejì ni apá àkọ́kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Mátíù 24:4-22 ṣẹ. Ìmúṣẹ àkọ́kọ́ wáyé láàárín ọdún 33 sí ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ìmúṣẹ kejì wáyé lọ́nà tó gbòòrò gan-an ní àkókò tá a wà yìí. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ẹ̀ẹ̀mejì ni ọ̀rọ̀ Jésù nípa ẹrú olóòótọ́ náà máa ṣẹ? Rárá o.

6 Ọ̀rọ̀ tó wà ní Mátíù 24:29 ni Jésù fi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò tá a wà yìí. (Ka Mátíù 24:30, 42, 44.) Nígbà tí Jésù ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá, ó sọ pé àwọn èèyàn ‘yóò rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run.’ Lẹ́yìn náà ló wá sọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ fún àwa tá à ń gbé lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí pé ká wà lójúfò, ó ní: “Ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀” àti pé, “Ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” * Ẹ kíyè sí i pé ẹ̀yìn ìgbà tí Jésù sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí tán ló tó wá ṣe àkàwé nípa ẹrú olóòótọ́. Nípa báyìí, a lè sọ pé ẹ̀yìn tí ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 ni ọ̀rọ̀ nípa ẹrú olóòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. Ó dájú pé èrò yìí bọ́gbọ́n mu. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

7. Ìbéèrè pàtàkì wo ló ń fẹ́ ìdáhùn bí ìgbà ìkórè ṣe bẹ̀rẹ̀? Kí nìdí?

7 Ẹ jẹ́ ká tún ronú díẹ̀ ná nípa ìbéèrè Jésù tó sọ pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye?” Ní ọ̀rúndún kìíní, kò sídìí láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Bá a ṣe ṣàlàyé nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, iṣẹ́ ìyanu táwọn àpọ́sítélì ń ṣe àti bí wọ́n ṣe ń fún àwọn míì lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu fi hàn pé Ọlọ́run ló fún wọn lágbára. (Ìṣe 5:12) Torí náà, kò sídìí tí ẹnì kan á fi máa béèrè ẹni tí Kristi yàn láti máa darí ìjọ Kristẹni. Àmọ́, nǹkan ti yàtọ̀ nígbà tó fi máa di ọdún 1914. Ọdún yẹn ni ìgbà ìkórè bẹ̀rẹ̀. Àkókò ti wá tó láti ya èpò sọ́tọ̀ kúrò lára àlìkámà. (Mát. 13:36-43) Nígbà tí ìkórè fi máa bẹ̀rẹ̀, ìbéèrè pàtàkì kan tó ń fẹ́ ìdáhùn ni pé: Pẹ̀lú bí àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà ṣe ń fọ́nnu pé àwọn ni ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù, báwo la ṣe máa dá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ̀, ìyẹn àwọn tá a fi wé àlìkámà? A máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àkàwé Jésù nípa ẹrú olóòótọ́. Àwọn ẹni àmì òróró ọmọ ẹ̀yìn Kristi yìí ló ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí ní àjẹyó.

TA NÍ ẸRÚ OLÓÒÓTỌ́ ÀTI OLÓYE?

8. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn tó máa di ẹrú olóòótọ́ náà jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró?

8 Àwọn tó máa di ẹrú olóòótọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà láyé. Bíbélì pè wọ́n ní “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” àti pé Ọlọ́run gbéṣẹ́ fún wọn láti “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá” ẹni tí ó pè [wọ́n] jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pét. 2:9) Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé àwọn tó wà nínú “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” gan-an ni yóò máa kọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ní ẹ̀kọ́ òtítọ́.—Mál. 2:7; Ìṣí. 12:17.

9. Ṣé gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló para pọ̀ jẹ́ ẹrú olóòótọ́? Ṣàlàyé.

9 Ṣé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó wà láyé ló para pọ̀ jẹ́ ẹrú olóòótọ́? Rárá. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kì í ṣe gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ló ń kópa nínú pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Àwọn ẹni àmì òróró kan ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà láwọn ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́. Wọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lóde ẹ̀rí àti nínú ìjọ, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí orílé-iṣẹ́ ń fún wa. Àmọ́, wọn ò lọ́wọ́ sí ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó wà fún ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Bákan náà, àwọn arábìnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró ń fi ìrẹ̀lẹ̀ sìn, wọn ò sì ní in lọ́kàn láé pé àwọn á dúró níwájú ìjọ láti máa kọ́ni.—1 Kọ́r. 11:3; 14:34.

10. Ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà?

10 Ta wá ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà? Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé ńṣe ni Jésù tipasẹ̀ àwọn èèyàn kéréje bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ní ọ̀rúndún kìíní, bákan náà ló ṣe rí lóde òní. Ẹrú náà ni ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró tó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní tààràtà tí wọ́n sì ń pín in nígbà wíwàníhìn-ín Kristi. Látìgbà tí ọjọ́ ìkẹyìn ti bẹ̀rẹ̀ títí di báyìí, orílé-iṣẹ́ wa làwọn arákùnrin tó para pọ̀ jẹ́ ẹrú olóòótọ́ yìí ti ń sìn pa pọ̀. Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹrú náà. Àmọ́, ẹ kíyè sí i pé nínú àkàwé Jésù, ńṣe ló sọ̀rọ̀ nípa ẹrú náà bí ìgbà tó jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ni. Ohun tí èyí fi hàn ni pé ńṣe làwọn tó para pọ̀ jẹ́ ẹrú náà á máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀ níṣọ̀kan. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ńṣe ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń panu pọ̀ ṣe ìpinnu.

ÀWỌN WO NI ARÁ ILÉ RẸ̀?

11, 12. (a) Ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo ni ọ̀gá náà yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye pé kó máa bójú tó? (b) Ìgbà wo ni Jésù yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀? Àwọn wo ló sì yàn sí ipò náà?

11 Nínú àkàwé Jésù, ẹ kíyè sí i pé ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọ̀gá náà yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye pé kó máa bójú tó. Àkọ́kọ́, ó yàn án sípò lórí àwọn ará ilé. Èkejì, ó yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní ọ̀gá rẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àkókò òpin yìí nìkan ni àkàwé náà ṣẹ, a jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914 ló tó yan ẹrú náà sípò.

12 Ìgbà wo ni Jésù yan ẹrú olóòótọ́ sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀? Ká lè rí ìdáhùn, ẹ́ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí ìkórè náà bẹ̀rẹ̀, lọ́dún 1914. Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, àìmọye àwùjọ onísìn ló ń sọ pé Kristẹni làwọn. Èwo lára wọn ni Jésù máa yàn sípò gẹ́gẹ́ bí ẹrú olóòótọ́? Ìgbà tí òun àti Baba rẹ̀ wá sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí la rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Ọdún 1914 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919 ni wọ́n wá wo báwọn èèyàn ṣe ń jọ́sìn Ọlọ́run. * (Mál. 3:1) Inú wọn dùn nígbà tí wọ́n rí àwùjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, tí wọ́n sì gbára lé Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lóòótọ́ wọ́n nílò ìwẹ̀nùmọ́, àmọ́ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fara da àdánwò ráńpẹ́ tó dé bá wọn, wọ́n sì gbà kí Ọlọ́run yọ́ wọn mọ́. (Mál. 3:2-4) Kò sí àní-àní pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì olóòótọ́ yìí ni Kristẹni tá a fi wé àlìkámà. Lọ́dún 1919 tí wọ́n gba okun nípa tẹ̀mí, Jésù yan àwọn arákùnrin mélòó kan tí wọ́n tóótun tí wọ́n sì jẹ́ ẹni àmì òróró láàárín wọn gẹ́gẹ́ bí ẹrú olóòótọ́ àti olóye, ó sì yàn wọ́n sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀.

13. Àwọn wo ló wá dara pọ̀ mọ́ àwọn ará ilé ọ̀gá náà? Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?

13 Àwọn wo wá ni ará ilé rẹ̀? Ní kúkúrú, àwọn tí ẹrú náà ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún ni. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ẹni àmì òróró ni gbogbo àwọn ará ilé ọ̀gá náà. Nígbà tó yá, ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn náà wá dara pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ará ilé ọ̀gá náà. Ní báyìí, àwọn àgùntàn mìíràn ló pọ̀ jù lára “agbo kan” tí Kristi ń bójú tó. (Jòh. 10:16) Nípa bẹ́ẹ̀, àwùjọ méjèèjì, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn, ló ń gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí kan náà tí ẹrú olóòótọ́ yìí ń pèsè. Kí la wá lè sọ nípa àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye? Àwọn náà nílò oúnjẹ tẹ̀mí yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n gbà pé, àwọn náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kàn jẹ́ ará ilé ọ̀gá náà bí àwa yòókù náà ṣe jẹ́.

Yálà a ní ìrètí àtilọ sí ọ̀run tàbí a ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé, ara ilé ọ̀gá náà ni gbogbo wa, oúnjẹ tẹ̀mí kan náà la sì ń jẹ

14. (a) Kí ni ojúṣe ẹrú olóòótọ́ náà, kí sì ni díẹ̀ lára iṣẹ́ rẹ̀? (b) Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fún ẹrú olóòótọ́ àti olóye? (Wo àpótí náà, “Bí Ẹrú Búburú Yẹn Bá Lọ Sọ Nínú Ọkàn-Àyà Rẹ̀ Pẹ́nrẹ́n . . .”)

14 Iṣẹ́ ńlá ni Jésù gbé fún ẹrú olóòótọ́ àti olóye. Lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì, ẹrú tàbí ìríjú tí ọ̀gá rẹ̀ fọkàn tán ló máa ń bójú tó ilé ọ̀gá rẹ̀. (Lúùkù 12:42) Torí náà, ojúṣe ẹrú olóòótọ́ àti olóye yìí ni pé kó máa bójú tó agbo ilé ìgbàgbọ́. Lára iṣẹ́ rẹ̀ ni pé kó máa bójú tó àwọn ilé àti irin iṣẹ́ tí ètò náà ń lò, iṣẹ́ ìwàásù, ètò àwọn àpéjọ gbogbo àti bá a ṣe ń tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tá à ń lò lóde ẹ̀rí, nínú ìjọ àti fún ìdákẹ́kọ̀ọ́. Ẹrú yìí làwọn ará ilé ń wojú fún gbogbo oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n á máa jẹ.

ÌGBÀ WO NÍ Ọ̀GÁ YÀN ÁN SÍPÒ LÓRÍ GBOGBO NǸKAN ÌNÍ RẸ̀?

15, 16. Ìgbà wo ni Jésù máa yan ẹrú olóòótọ́ sípò lórí gbogbo nǹkan ìní rẹ̀?

15 Ìgbà wo ni Jésù wá yan ẹrú yìí sípò lórí ohun kejì, ìyẹn “lórí gbogbo nǹkan ìní rẹ̀”? Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹrú náà bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé, bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Òun yóò yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Mát. 24:46, 47) Ẹ kíyè sí i pé ìgbà tí Jésù bá pa dà dé tó sì bá ẹrú náà “tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀,” ìyẹn tó ń fi ìṣòtítọ́ pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ará ilé, ló tó máa yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀. Èyí fi hàn pé àkókò kan máa wà láàárín ìgbà tí Jésù yan ẹrú náà sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀ àtìgbà tó yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀. Ká bàa lè lóye bí Jésù ṣe yan ẹrú yìí sípò lórí gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ àti ìgbà tó yàn án, ohun méjì kan wà tó yẹ ká mọ̀: a máa ní láti mọ ìgbà tí Jésù dé àti ohun tí gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ jẹ́.

16 Ìgbà wo ni Jésù dé? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kó tó sọ̀rọ̀ náà. Ẹ rántí pé nígbà tí Jésù sọ pé òun “ń bọ̀” nínú àwọn ẹsẹ tó ṣáájú, ìgbà tó máa wá ṣèdájọ́ ayé tó sì máa pa ayé búburú yìí run ló ní lọ́kàn. * (Mát. 24:30, 42, 44) Torí náà, àkókò ìpọ́njú ńlá ni Jésù máa “dé” tàbí tó “ń bọ̀” bó ṣe sọ nínú àkàwé nípa ẹrú olóòótọ́.

17. Àwọn ohun wo ló wà lára gbogbo nǹkan ìní Jésù?

17 Kí ni “gbogbo nǹkan ìní” Jésù? Kì í ṣe kìkì àwọn nǹkan ìní rẹ̀ tó wà láyé ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “gbogbo.” Ká sòótọ́, ọlá àṣẹ tí Jésù ní lọ́run kọjá sísọ. Ó sọ pé, “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mát. 28:18; Éfé. 1:20-23) Ní báyìí, Ìjọba Mèsáyà wà lára nǹkan ìní rẹ̀. Ọdún 1914 ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, ó sì máa ṣàkóso pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró.—Ìṣí. 11:15.

18. Kí nìdí tí Jésù fi máa yan ẹrú náà sípò lórí gbogbo nǹkan ìní rẹ̀?

18 Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, kí la lè sọ? Nígbà tí Jésù bá máa dé láti ṣèdájọ́ lákòókò ìpọ́njú ńlá, inú rẹ̀ á dùn tó bá rí i pé ẹrú olóòótọ́ náà ń fi ìṣòtítọ́ pèsè oúnjẹ fún àwọn ará ilé òun. Èyí á sì mú kó yan ẹrú náà sípò lórí ohun kejì, ìyẹn gbogbo nǹkan ìní rẹ̀. Ìgbà tí àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ẹrú olóòótọ́ yìí bá gba èrè wọn ní ọ̀run ni Kristi máa yàn wọ́n sípò lórí ohun kejì yìí, tí wọ́n á sì máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀.

19. Ṣé èrè tí ẹrú olóòótọ́ máa gbà lọ́run máa ju tàwọn ẹni àmì òróró yòókù lọ? Ṣàlàyé.

19 Ṣé èrè tí ẹrú olóòótọ́ yìí á gbà lọ́run máa wá ju tàwọn ẹni àmì òróró yòókù lọ ni? Rárá o. Ti pé ẹnì kan ṣèlérí ohun kan fún àwùjọ kékeré kan lákòókò kan kò túmọ̀ sí pé àwọn míì kò lè nípìn-ín nínú rẹ̀ nígbà tó bá yá. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ kó tó di pé ó kú. (Ka Lúùkù 22:28-30.) Jésù ṣèlérí fáwọn kéréje yẹn pé òun máa san wọ́n lẹ́san rere nítorí ìṣòtítọ́ wọn. Ó sọ pé wọ́n máa bá òun jọba. Àmọ́ lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, ó sọ pé gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ló máa bá òun jọba. (Ìṣí. 1:1; 3:21) Bákan náà, ó ṣèlérí nínú Mátíù 24:47 pé òun máa yan ìwọ̀nba kéréje àwọn arákùnrin tó para pọ̀ jẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà sípò lórí gbogbo nǹkan ìní òun. Àmọ́, ní ti gidi, gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] náà ló máa nípìn-ín nínú ọlá àṣẹ tó ní lọ́run.—Ìṣí. 20:4, 6.

Gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ló máa nípìn-ín nínú ọlá àṣẹ tí Jésù ní lọ́run (Wo ìpínrọ̀ 19)

20. Kí nìdí tí Jésù fi yan ẹrú olóòótọ́? Kí lo pinnu láti máa ṣe?

20 Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù lo ìwọ̀nba kéréje èèyàn láti bọ ọ̀pọ̀ èèyàn. Bákan náà ló ṣe ń tipasẹ̀ ẹrú olóòótọ́ àti olóye bọ́ àìmọye èèyàn lóde òní. Jésù yan ẹrú olóòótọ́ yìí láti rí i dájú pé àwọn ojúlówó ọmọ ẹyìn òun ń rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ déédéé àti ní àkókò tó yẹ, jálẹ̀ ọjọ́ ìkẹyìn yìí, yálà wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí àgùntàn mìíràn. Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò túbọ̀ máa fi hàn pé a mọrírì ìṣètò yìí. A sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kọ́wọ́ ti àwọn arákùnrin tó para pọ̀ jẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà lẹ́yìn.—Héb. 13:7, 17.

 

^ ìpínrọ̀ 2 Ìpínrọ̀ 2: Ní oṣù mélòó kan ṣáájú, Jésù ti ṣe irú àkàwé yìí. Nínú àkàwé náà, ó pe “ẹrú” náà ní “ìríjú,” ó sì pe “àwọn ará ilé” ní “ẹgbẹ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀.”—Lúùkù 12:42-44.

^ ìpínrọ̀ 6 Ìpínrọ̀ 6: Bíbọ̀ Kristi (erʹkho·mai lédè Gíríìkì) yàtọ̀ sí wíwàníhìn-ín rẹ̀ (pa·rou·siʹa). Wíwàníhìn-ín rẹ̀ tá ò fojú rí yìí ló ṣáájú bíbọ̀ rẹ̀ láti wá ṣèdájọ́.

^ ìpínrọ̀ 12 Ìpínrọ̀ 12: Wo àpilẹ̀kọ náà, “Wò Ó! Mo Wà Pẹ̀lú Yín ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́,” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí, ojú ìwé 10 sí 12, ìpínrọ̀ 5 sí 8.

^ ìpínrọ̀ 16 Ìpínrọ̀ 16: Wo àpilẹ̀kọ náà, “Sọ fún Wa, Ìgbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí, ojú ìwé 7 àti 8, ìpínrọ̀ 14 sí 18.