Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà ‘Ń Bá Mi Gbé Ẹrù Mi Lójoojúmọ́’

Jèhófà ‘Ń Bá Mi Gbé Ẹrù Mi Lójoojúmọ́’

Látìgbà tí mo ti dáyé ni mo ti ń rọ́wọ́ Baba wa ọ̀run lára mi, ó ń tì mí lẹ́yìn bó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ọwọ́ ni àrùn tó ń ṣe mí máa ń yọ. Síbẹ̀, ńṣe ni inú mi máa ń dùn pé mo mọ Jèhófà, ó sì ti lé lógún ọdún báyìí tí mo ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà.

Ọdún 1956 ni wọ́n bí mi. Àmọ́ nígbà tí wọ́n máa bí mi, mo ti ní àrùn tó máa ń mú kí ọ̀pá ẹ̀yìn là, tí wọ́n ń pè ní spina bifida. Èyí máa ń wáyé nígbà tí àlàfo bá wà láàárín àwọn egungun ẹ̀yìn. Àrùn yìí ṣèpalára fún ọpọlọ mi, torí náà, mi ò lè rìn dáadáa. Ó sì tún dá àwọn àìsàn tó lágbára míì sí mi lára.

Kó tó di pé wọ́n bí mi ni tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì ti máa ń kọ́ àwọn òbí mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí mo ṣì kéré, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú wa, ìyẹn Usakos, lórílẹ̀-èdè Nàmíbíà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, ibi tí wọ́n ń gbé sì jìnnà síra gan-an. Torí náà, ńṣe la máa ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ láàárín ara wa gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méje, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ kan fún mi. Wọ́n dá ibi kan lu lára mi kí n lè máa gba ibẹ̀ tọ̀. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14], mo ní àrùn wárápá. Mi ò lè parí ẹ̀kọ́ mi nílé ìwé girama torí pé ilé ìwé tá a lè sọ pé ó sún mọ́ ilé wa jìnnà gan-an, yàtọ̀ síyẹn, ó tún pọn dandan kí àwọn òbí mi máa bójú tó mi lákànṣe.

Bó ti wù kó rí, mo pinnu pé màá túbọ̀ máa sapá gidigidi láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ìwé tí ètò Ọlọ́run tẹ̀ jáde ni kò sí lédè Afrikaans, tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ wa. Torí náà, mo kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì kí n lè máa ka àwọn ìwé wa. Nígbà tó yá mo di akéde, nígbà tí mo sì pé ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo ṣèrìbọmi. Láàárín ọdún mẹ́rin tó tẹ̀ lé e, onírúurú àìsàn ló ṣe mi, ó sì mú kí n máa banú jẹ gan-an. Láfikún, ní abúlé wa ojú kára gan-an, bí ọmọ ìyá la sì máa ń ṣe. Torí bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rù èèyàn kì í jẹ́ kí n lè fìtara wàásù fáwọn èèyàn.

Lẹ́yìn tí mo lé lógún ọdún, a kó lọ sí orílẹ̀-èdè South Africa. Ibẹ̀ sì ni mo ti kọ́kọ́ ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ará nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ẹ ò lè mọ bí inú mi ṣe dùn tó! Àmọ́, mo tún ní láti ṣe iṣẹ́ abẹ míì. Wọ́n dá ibi kan lu lọ́wọ́ ìsàlẹ̀ inú mi kí n lè máa gba ibẹ̀ ṣe ìgbọ̀nsẹ̀.

Kò pẹ́ sígbà yẹn la ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Arákùnrin náà sì sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ohun tó sọ wú mi lórí gan-an. Mo mọ̀ pé ara mi ò le débi tí mo fi lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ mo mọ̀ dáadáa pé Jèhófà náà ló ti ń bá mi ṣe é látọjọ́ yìí wá. Torí bẹ́ẹ̀, mo kọ̀wé pé mo fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àmọ́, àwọn alàgbà ò fọwọ́ sí i torí wọ́n ronú pé àìlera mi kò ní jẹ́ kí n lè ṣe é.

Síbẹ̀, mo pinnu pé màá sa gbogbo ipá mi lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Màmá mi àtàwọn ará míì ṣèrànwọ́ fún mi gan-an débi tí mo fi lè ròyìn iye wákàtí tí wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó lé lóṣù mẹ́fà. Èyí mú kó ṣe kedere pé mo lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ó sì fi hàn pé àìlera mí ṣi ṣeé dọ́gbọ́n sí. Nípa bẹ́ẹ̀, mo tún kọ̀wé pé mo fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà, àwọn alàgbà sì fọwọ́ sí i. Torí náà, ní September 1, ọdún 1988, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Látìgbà tí mo ti di aṣáájú-ọ̀nà ni mo ti ń rí ọwọ́ Jèhófà lára mi. Bí mo ṣe ń kọ́ àwọn ẹni tuntun lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ dípò ti màá fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àìlera mi gbà mí lọ́kàn pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń balẹ̀, tí inú mi ń dùn tí mo sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà. Ayọ̀ mi tún légbá kan bí mo ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tí wọ́n ń ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì ń ṣèrìbọmi.

Oríṣiríṣi ọwọ́ ni àìlera mi máa ń yọ. Àmọ́ Jèhófà ‘ń bá mi gbé ẹrù mi lójoojúmọ́.’ (Sm. 68:19) Kì í wulẹ̀ ṣe pé ó ń fún mi lókun láti máa fara dà á nìkan, ó tún ń mú kí n máa láyọ̀ pé mo wà láàyè!