Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

Inú Ọba Dùn!

Inú Ọba Dùn!

NÍ OṢÙ August, ọdún 1936, ohun kan ṣẹlẹ̀ ní ààfin Ọba Sobhuza Kejì ti ìlú Swaziland tó mú inú rẹ̀ dùn gan-an. Àwọn arákùnrin wa méjì, ìyẹn Arákùnrin Robert àti George Nisbet lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n lè wàásù fún un. Ó kọ́kọ́ gbọ́ orin Ìjọba Ọlọ́run látinú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́. Lẹ́yìn náà, ó gbọ́ àsọyé Arákùnrin J. F. Rutherford tí wọ́n gbà sórí rẹ́kọ́ọ̀dù, inú rẹ̀ sì dùn gan-an. Arákùnrin George wá ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn yẹn. Ó ní: “Ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tó sọ pé òun fẹ́ ra gbogbo ẹ̀rọ tá a fi ń gbé ohùn sáfẹ́fẹ́, tó fi mọ́ àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù orin àti àsọyé!” Kí ni àwọn arákùnrin náà wá sọ?

[Àwọn Credit Line]

Arákùnrin Robert sọ fún ọba náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé wọn kì í ṣe títà torí pé kì í ṣe tàwọn. Ọba wá bi í pé, ‘Ta ló ni ẹ̀rọ àti àwọn àwo rẹ́kọ́ọ̀dù náà?’

Arákùnrin Robert dáhùn pé, “Ọba míì ló ni gbogbo ẹ̀.” Ọba Sobhuza tún bi í pé, ‘Ta ni Ọba náà?’ Arákùnrin Robert dáhùn pé: “Jésù Kristi lorúkọ rẹ̀, òun sì ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run.”

Ọba Sobhuza náà wá fèsì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé: “Áà, Ọba tó ju ọba lọ ni. Mi ò fẹ́ gba ohunkóhun tó bá jẹ́ tiẹ̀.”

Arákùnrin Robert kọ̀wé pé: ‘Ọba náà yàtọ̀ léèyàn, ìwà àti ìṣe rẹ̀ wú mi lórí gan-an. Gẹ̀ẹ́sì dùn lẹ́nu rẹ̀, kò gbéra ga, bọ́rọ̀ ṣe rí lọ́kàn rẹ̀ ló ṣe sọ ọ́, ó sì kóni mọ́ra. Nǹkan bí ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta [45] ni mo lò lọ́dọ̀ rẹ̀, Arákùnrin George sì ń gbé àwo orin sí i níta.’

Arákùnrin Robert ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: ‘Nígbà tó ṣe ní ọjọ́ yẹn, a lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kan tó ń jẹ́ Swazi National School. Ohun kan ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ tó dùn mọ́ wa gan-an. A wàásù fún ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ náà, ó sì tẹ́tí gbọ́rọ̀ wa dáadáa. Nígbà tá a sọ fún un pé a máa fẹ́ kí gbogbo wọn gbọ́ ohun tó wà nínú àwo rẹ́kọ́ọ̀dù wa, inú rẹ̀ dùn, ó sì ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún jókòó sórí koríko láti gbọ́ ọ. Wọ́n sọ fún wa pé ilé ẹ̀kọ́ náà ni wọ́n ti ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ọkùnrin ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìṣirò, iṣẹ́ àgbẹ̀, bíbójútó ọgbà, iṣẹ́ káfíńtà àti iṣẹ́ ilé kíkọ́; wọ́n sì ń kọ́ àwọn obìnrin ní iṣẹ́ nọ́ọ̀sì, àbójútó ilé àtàwọn iṣẹ́ míì tó wúlò. Ìyá rẹ̀ àgbà ló sì dá ilé ẹ̀kọ́ yẹn sílẹ̀.’ *

Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n gbọ́ àsọyé ní orílẹ̀-èdè Swaziland lọ́dún 1936

Láti ọdún 1933 ni Ọba Sobhuza ti máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n bá lọ sí ààfin rẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó pe àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún, pé kí wọ́n wá gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó wà lórí rẹ́kọ́ọ̀dù. Ó san àsansílẹ̀-owó fún ìwé ìròyìn ó sì gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Kò sì pẹ́ tí Ọba náà fi fẹ́rẹ̀ẹ́ ní gbogbo ìwé wa lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń ṣàkóso wọn fi òfin de àwọn ìwé wa, ọba náà kò jẹ́ kí ohunkóhun ṣe àwọn ìwé náà!

Ọ̀pọ̀ ọdún ni Ọba Sobhuza Kejì fi ń gbọ́rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ààfin rẹ̀ tó wà ní Lobamba, kódà ó máa ń pe àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì láti wá gbọ́ àwọn àsọyé Bíbélì wa. Nígbà kan, bí arákùnrin Helvie Mashazi ṣe ń ṣàlàyé Mátíù orí 23, àwọn àlùfáà kan fi ìbínú fò dìde wọ́n sì fẹ́ láti fipá mú kí arákùnrin náà jókòó. Àmọ́, Ọba náà dá sí i, ó sì ní kí Arákùnrin Mashazi máa bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ. Ọba tún sọ fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ pé kí wọ́n kọ gbogbo ẹsẹ Bíbélì tó lò nínú àsọyé náà sílẹ̀.

Ó tún ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé lẹ́yìn tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́rin kan gbọ́ àsọyé arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan, wọ́n yọ kọ́là ọrùn aṣọ wọn tó ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà kúrò, wọ́n sì sọ pé: “A kì í ṣe àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì mọ́, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá.” Wọ́n wá béèrè lọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà náà bóyá ó ṣì ní irú àwọn ìwé tó wà lọ́wọ́ ọba náà.

Láti ọdún 1930 títí di ìgbà tí Ọba náà kú lọ́dún 1982, ó bọ̀wọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sì í jẹ́ kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn torí pé wọn kò lọ́wọ́ sí àwọn ààtò orílẹ̀-èdè Swaziland. Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí mọrírì ohun tó ṣe, ikú rẹ̀ sì dùn wọ́n gan-an.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2013, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Swaziland ti ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] lọ. Àwọn èèyàn tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè náà lé ní mílíọ̀nù kan, torí náà, ní ìpíndọ́gba, akéde kan á wàásù fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [384] èèyàn. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà níbẹ̀ ju igba ó lé ọgọ́ta [260] lọ, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ takuntakun ní àádọ́rùn-ún [90] ìjọ. Ẹgbẹ̀rún méje, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó dín mẹ́rin [7,496] ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2012. Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ ṣì wà tí òùngbẹ òtítọ́ ń gbẹ. Ó dájú pé ìpìlẹ̀ tó lágbára ni àwọn tó kọ́kọ́ lọ wàásù ní orílẹ̀-èdè Swaziland láti ọdún 1930 sí 1939 fi lélẹ̀.—Látinú àpamọ́ wa ní orílẹ̀-èdè South Africa.

^ ìpínrọ̀ 8 Ìwé ìròyìn The Golden Age, June 30, ọdún 1937, ojú ìwé 629..