Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | KÍ LÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ?

Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Aráyé Nídè

Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Aráyé Nídè

Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì pé “irú-ọmọ” tí òun ṣèlérí yẹn máa jẹ́ ọ̀kan lára àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Nípasẹ̀ irú-ọmọ yẹn ni gbogbo “àwọn orílẹ̀-èdè” yóò rí ìbùkún gbà. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Jékọ́bù tó jẹ́ ọmọ ọmọ Ábúráhámù ṣí lọ sí Íjíbítì, ibẹ̀ ni ìdílé rẹ̀ ti pọ̀ sí i, tí wọ́n sì di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́.

Nígbà tó yá, Fáráò Ọba Íjíbítì tó jẹ́ òǹrorò kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́rú kí Ọlọ́run tó wá gbé Mósè dìde láti ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì nípa iṣẹ́ ìyanu tó ṣe tó fi pín Òkun Pupa níyà. Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn òfin, títí kan Òfin Mẹ́wàá. Àwọn òfin yìí á máa tọ́ wọn sọ́nà, á sì máa dáàbò bò wọ́n. Àwọn òfin yẹn dìídì sọ àwọn ìrúbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n. Ọlọ́run tún gbẹnu Mósè sọ pé òun máa rán wòlíì míì sí wọn. Wòlíì yìí ló máa wá jẹ́ “irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí.

Ó lé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn kí Ọlọ́run tó ṣèlérí fún Dáfídì Ọba pé “irú-ọmọ” tí òun ṣèlérí ní Édẹ́nì yẹn máa ṣàkóso Ìjọba òun títí láé. Ẹni yẹn ló wá di Mèsáyà, ìyẹn olùdáǹdè tí Ọlọ́run yàn láti gba aráyé là, kí ó sì sọ ayé di Párádísè pa dà.

Ọlọ́run tipasẹ̀ Dáfídì àtàwọn wòlíì míì ṣí ọ̀pọ̀ nǹkan pa yá nípa Mèsáyà náà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Àwọn wòlíì yẹn sọ pé Mèsáyà náà á jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti onínúure, àti pé nígbà tó bá ń ṣàkóso, kò ní sí ebi, ìrẹ́jẹ àti ogun mọ́. Kódà, gbogbo èèyàn á máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà, kò ní sí ìṣọ̀tá láàárín èèyàn àtàwọn ẹranko mọ́. Àìsàn, ìyà àti ikú kò sí nínú nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ fún aráyé níbẹ̀rẹ̀ rárá. Gbogbo rẹ̀ ni yóò sì di àwátì. Kódà, àwọn tó ti kú á jíǹde.

Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Míkà sọ pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí, ó sì tún tipasẹ̀ wòlíì Dáníẹ́lì sọ pé àwọn èèyàn máa pa á tó bá yá. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run máa jí Mèsáyà náà dìde, á sì yàn án ṣe Ọba ní ọ̀run. Ọlọ́run tún fi han Dáníẹ́lì nínú ìran pé Ìjọba Mèsáyà náà máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn pátápátá. Ǹjẹ́ Mèsáyà náà dé gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ?

​—A gbé e ka Jẹ́nẹ́sísì orí 22-50 àti Ẹ́kísódù, Diutarónómì, 2 Sámúẹ́lì, Sáàmù, Aísáyà, Dáníẹ́lì, Míkà, Sekaráyà 9:9.