Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Tó Wà Nínú Àdúrà Tí Wọ́n Ronú Jinlẹ̀ Gbà

Ẹ̀kọ́ Tó Wà Nínú Àdúrà Tí Wọ́n Ronú Jinlẹ̀ Gbà

‘Kí wọ́n fi ìbùkún fún orúkọ rẹ ológo.’​—NEH. 9:5.

1. Àpéjọ táwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe wo la máa jíròrò, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

“Ẹ DÌDE, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà Ọlọ́run yín láti àkókò tí ó lọ kánrin dé àkókò tí ó lọ kánrin.” Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tani jí yìí ni àwọn ọmọ Léfì fi pe àwọn èèyàn Ọlọ́run jọ pọ̀ nígbà yẹn kí wọ́n lè jọ gbàdúrà, àdúrà náà sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àdúrà tó gùn jù lọ nínú Bíbélì. (Neh. 9:4, 5) Gbogbo wọn pé jọ pọ̀ sí Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù keje àwọn Júù, ìyẹn oṣù Tíṣírì, ní ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bí a ó ṣe máa jíròrò àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ kó tó di ọjọ́ pàtàkì tí àpéjọ yẹn wáyé, bi ara rẹ pé: ‘Kí ló ti mọ́ àwọn ọmọ Léfì lára láti máa ṣe tó mú kí àpéjọ yẹn kẹ́sẹ járí? Kí ni mo tún lè rí kọ́ nínú àdúrà tí àwọn ọmọ Léfì ronú jinlẹ̀ gbà yìí?’—Sm. 141:2.

OṢÙ ÀKÀNṢE

2. Àpẹẹrẹ rere wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi lélẹ̀ fún wa ní àpéjọ tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí wọ́n ti tún àwọn odi Jerúsálẹ́mù kọ́?

2 Oṣù kan ti kọjá lẹ́yìn táwọn Júù ti tún àwọn odi Jerúsálẹ́mù kọ́ kí wọ́n tó ṣe àpéjọ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. (Neh. 6:15) Ọjọ́ méjìléláàádọ́ta [52] péré làwọn èèyàn Ọlọ́run fi parí iṣẹ́ náà, ẹ̀yìn náà ni wọ́n wá gbájú mọ́ àwọn ohun tó jẹ mọ́ àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Torí náà, lọ́jọ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù tuntun, ìyẹn oṣù Tíṣírì, wọ́n pé jọ sí gbàgede ìlú láti tẹ́tí sí Ẹ́sírà àtàwọn ọmọ Léfì míì, bí wọ́n ṣe ń ka Òfin Ọlọ́run sókè ketekete tí wọ́n sì ń ṣàlàyé rẹ̀. Gbogbo ìdílé, títí kan “gbogbo àwọn tí ó ní làákàyè tó láti fetí sílẹ̀,” ló wà ní ìdúró tí wọ́n sì ń tẹ́tí sílẹ̀ “láti àfẹ̀mọ́jú títí di ọjọ́kanrí.” Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ gidi lèyí jẹ́ fún àwa tá à ń ṣèpàdé láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó tuni lára! Síbẹ̀, ṣé kì í ṣẹlẹ̀ sí ẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé kí ọkàn rẹ kúrò lórí ohun tó ò ń gbọ́, kó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, tún ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì lẹ́ẹ̀kan sí i. Yàtọ̀ sí pé wọ́n tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́, ọ̀rọ̀ náà tún wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún torí pé gbogbo wọn lápapọ̀ kò pa Òfin Ọlọ́run mọ́.—Neh. 8:1-9.

3. Ìtọ́ni wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi sílò?

3 Àmọ́ ṣá o, àpéjọ yẹn kì í ṣe àkókò fún wọn láti jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba. Ọjọ́ àjọyọ̀ ni, Jèhófà sì fẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń sin òun. (Núm. 29:1) Torí náà, Nehemáyà sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ lọ, ẹ jẹ àwọn ohun ọlọ́ràá, kí ẹ sì mu àwọn ohun dídùn, kí ẹ sì fi ìpín ránṣẹ́ sí ẹni tí a kò pèsè nǹkan kan sílẹ̀ fún; nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́ lójú Olúwa wa, ẹ má sì ba inú jẹ́, nítorí ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára yín.” Ohun táwọn èèyàn náà ṣe gan-an nìyẹn, ọjọ́ náà sì já sí ọjọ́ “ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà.”—Neh. 8:10-12.

4. Kí ni àwọn olórí ìdílé ní Ísírẹ́lì ṣe? Kí ni ohun pàtàkì tó wáyé lásìkò tí wọ́n ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà?

4 Ní ọjọ́ kejì àpéjọ yẹn, àwọn olórí ìdílé kóra jọ kí wọ́n lè rí i dájú pé gbogbo Òfin Ọlọ́run làwọn ń pa mọ́ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. Nígbà tí wọ́n ń yẹ Ìwé Mímọ́ wò, wọ́n rí i pé ó yẹ káwọn máa ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà nínú oṣù keje, kí wọ́n sì ṣe àpéjọ mímọ́ tí wọ́n fi máa ń kádìí rẹ̀ láti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún sí ọjọ́ kejìlélógún nínú oṣù Tíṣírì. Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀. Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí wọ́n ṣe lọ́dún yẹn ló tíì kẹ́sẹ járí jù lọ láti ọjọ́ Jóṣúà, wọ́n sì yọ “ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà.” Ohun pàtàkì kan tó wáyé lásìkò àjọyọ̀ yẹn ni pé wọ́n ka Òfin Ọlọ́run sí wọn létí, “láti ọjọ́ dé ọjọ́, láti ọjọ́ kìíní títí di ọjọ́ tí ó kẹ́yìn.”—Neh. 8:13-18.

ỌJỌ́ ÌJẸ́WỌ́ Ẹ̀ṢẸ̀

5. Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe kó tó di pé àwọn ọmọ Léfì ṣáájú wọn nínú àdúrà sí Jèhófà?

5 Ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba torí pé wọn kò pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Ọjọ́ yẹn kì í ṣe ọjọ́ ayẹyẹ rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn èèyàn Ọlọ́run gbààwẹ̀, wọ́n sì wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ láti fi hàn pé wọ́n ń ṣọ̀fọ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tún ka Òfin Ọlọ́run sáwọn èèyàn náà létí fún nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta láàárọ̀ ọjọ́ náà. Nígbà tó di ọ̀sán, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í “jẹ́wọ́” àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, “wọ́n sì ń tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run wọn.” Lẹ́yìn yẹn ni àwọn ọmọ Léfì wá ṣáájú àwọn èèyàn náà nínú àdúrà tí wọ́n ronú jinlẹ̀ gbà. —Neh. 9:1-4.

6. Kí ló mú kí àdúrà tí àwọn ọmọ Léfì gbà nítumọ̀? Kí la rí kọ́ lára àwọn ọmọ Léfì?

6 Ó dájú pé bí àwọn ọmọ Léfì ṣe máa ń ka Òfin Ọlọ́run déédéé ló mú kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ kí wọ́n tó gbàdúrà tó nítumọ̀ yẹn. Iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ ni wọ́n dìídì sọ̀rọ̀ lé lórí ní apá àkọ́kọ́ nínú àdúrà náà. Nínú apá tó kù, wọ́n tẹnu mọ́ “ọ̀pọ̀ yanturu àánú” Ọlọ́run léraléra, wọ́n sì gbà láìjanpata pé àwọn kò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń fi àánú hàn sí. (Neh. 9:19, 27, 28, 31) Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ tá a sì ń ṣe àṣàrò lé e lórí, ńṣe ló máa dà bíi pé Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀. Tá a bá wá gbàdúrà lẹ́yìn náà, a máa ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti sọ, àdúrà wa á sì nítumọ̀.—Sm. 1:1, 2.

7. Kí ni àwọn ọmọ Léfì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run? Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ wọn?

7 Ohun kan ṣoṣo péré làwọn ọmọ Léfì béèrè nínú àdúrà wọn. Ó wà nínú ẹsẹ kejìlélọ́gbọ̀n [32] tó kà pé: “Wàyí o, ìwọ Ọlọ́run wa, Ọlọ́run títóbi, alágbára ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù, tí ń pa májẹ̀mú àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo ìnira tí ó bá àwa, àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé wa àti àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì wa àti àwọn baba ńlá wa àti gbogbo ènìyàn rẹ láti ọjọ́ àwọn ọba Ásíríà títí di òní yìí, dà bí ohun kékeré níwájú rẹ.” Lọ́nà yìí, àwọn ọmọ Léfì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa pé ká kọ́kọ́ máa fi ọpẹ́ àti ìyìn fún Jèhófà, ká tó béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ rẹ̀.

WỌ́N YIN ORÚKỌ RẸ̀ OLÓGO

8, 9. (a) Báwo ni àwọn ọmọ Léfì ṣe bẹ̀rẹ̀ àdúrà tí wọ́n fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà? (b) Ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run méjì wo ló dájú pé àwọn ọmọ Léfì ní lọ́kàn?

8 Àwọn ọmọ Léfì yẹn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ronú jinlẹ̀ kí wọ́n tó gbàdúrà, wọn ò gbà pé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú àdúrà náà dára tó láti fún Jèhófà ní ògo tó tọ́ sí i. Torí náà, nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà fún gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run, wọ́n bẹ Jèhófà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Kí wọ́n sì fi ìbùkún fún orúkọ rẹ ológo, èyí tí a gbé ga lékè gbogbo ìbùkún àti ìyìn.”—Neh. 9:5.

9 Wọ́n ń bá àdúrà náà lọ pé: “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Jèhófà, ìwọ alára ṣe ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run, àti gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó wà lórí rẹ̀, àwọn òkun àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn; ìwọ sì ń pa gbogbo wọn mọ́ láàyè; ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run sì ń tẹrí ba fún ọ.” (Neh. 9:6) Àwọn ọmọ Léfì tipa báyìí mẹ́nu kan àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà Ọlọ́run dá. Ó dá ọ̀run àti “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” wọn, ìyẹn àìmọye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀. Ó tún dá gbogbo ohun tó wà lórí ilẹ̀ ayé wa rírẹwà yìí. Ó sì ṣe ilẹ̀ ayé wa lọ́nà tó kàmàmà èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún onírúurú ohun alààyè tó ń gbé níbẹ̀ láti máa mú irú tirẹ̀ jáde. Àwọn tó wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run ń ṣẹ̀dá àwọn nǹkan yìí ni àwọn áńgẹ́lì mímọ́, tá a tún lè pè ní “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run.” (1 Ọba 22:19; Jóòbù 38:4, 7) Ìyẹn nìkan kọ́, àwọn áńgẹ́lì yìí tún ń fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bí wọ́n ṣe ń ṣèránṣẹ́ fún àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ “tí yóò jogún ìgbàlà.” (Héb. 1:14) Àpẹẹrẹ títayọ gbáà làwọn áńgẹ́lì yìí fi lélẹ̀ fún wa bá a ṣe ń sin Jèhófà níṣọ̀kan bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó dáńgájíá!—1 Kọ́r. 14:33, 40.

10. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù?

10 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Léfì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúrámù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúrámù ti di ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99], tí Sáráì ìyàwó rẹ̀ kò sì tíì bímọ kankan, Jèhófà yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Ábúráhámù, èyí tó túmọ̀ sí “baba ogunlọ́gọ̀.” (Jẹ́n. 17:1-6, 15, 16) Ọlọ́run tún ṣèlérí fún Ábúráhámù pé irú ọmọ rẹ̀ máa jogún ilẹ̀ Kénáánì. Ó ṣe kedere nínú àdúrà àwọn ọmọ Léfì pé Jèhófà kì í gbàgbé ìlérí tó bá ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn sábà máa ń gbàgbé ìlérí tá a bá ṣe. Wọ́n ní: “Ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tí ó yan Ábúrámù, tí ó sì mú un jáde kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà, tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ di Ábúráhámù. Ìwọ sì rí i pé ọkàn-àyà rẹ̀ jẹ́ aṣeégbíyèlé níwájú rẹ; nítorí náà, dídá májẹ̀mú kan pẹ̀lú rẹ̀ wáyé láti fún un ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, . . . láti fi í fún irú-ọmọ rẹ̀; ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ọ̀rọ̀ rẹ ṣẹ, nítorí pé ìwọ jẹ́ olódodo.” (Neh. 9:7, 8) Ǹjẹ́ kí àwa náà fìwà jọ Ọlọ́run wa tó jẹ́ olódodo, ká sì máa sapá láti mú ìlérí wa ṣẹ.—Mát. 5:37.

WỌ́N SỌ ÀWỌN OHUN TÍ JÈHÓFÀ TI ṢE

11, 12. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ náà, Jèhófà? Kí ni Jèhófà ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù láti fi hàn pé òun ló tọ́ sí láti máa jẹ́ Jèhófà?

11 Orúkọ náà, Jèhófà túmọ̀ sí “Alèwílèṣe,” tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ń ṣe àwọn nǹkan ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ọ̀nà kan tó gbádùn mọ́ni tí Ọlọ́run gbà ṣe èyí ni bó ṣe mú ìlérí tó ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ṣẹ. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lóko ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó jọ pé àlá tí kò lè ṣẹ ni pé wọ́n máa dòmìnira, wọ́n á sì lọ máa gbé ní Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́, Ọlọ́run ṣe àwọn nǹkan ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Lọ́nà yìí, ó fi hàn pé òun ló tọ́ sí láti máa jẹ́ orúkọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó sì tún tayọ lọ́lá náà, Jèhófà.

12 Nehemáyà ròyìn ohun tí àwọn ọmọ Léfì sọ nípa Jèhófà nínú àdúrà náà pé: “Ìwọ . . . rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn baba ńlá wa níṣẹ̀ẹ́ ní Íjíbítì, o sì gbọ́ igbe ẹkún wọn ní Òkun Pupa. Nígbà náà ni ìwọ pèsè àwọn àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu lòdì sí Fáráò àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn ilẹ̀ rẹ̀, nítorí o mọ̀ pé wọ́n fi ìkùgbù gbé ìgbésẹ̀ sí wọn; ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe orúkọ fún ara rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí. Ìwọ sì pín òkun níyà níwájú wọn, tí wọ́n fi gba àárín òkun sọdá lórí ilẹ̀ gbígbẹ; àwọn tí ń lépa wọn ni ìwọ sì fi sọ̀kò sínú ibú bí òkúta nínú omi tí ó lágbára.” Lẹ́yìn náà, wọ́n wá ń sọ àwọn nǹkan míì tí Jèhófà ti ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ìwọ . . . bẹ̀rẹ̀ sí tẹ àwọn olùgbé ilẹ̀ náà, àwọn ọmọ Kénáánì, lórí ba níwájú wọn . . . Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ìlú ńlá olódi àti ilẹ̀ ọlọ́ràá, àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun rere ni wọ́n sì gbà fi ṣe ìní, àwọn ìkùdu tí a gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà àti àwọn oko ólífì àti àwọn igi fún oúnjẹ ní ọ̀pọ̀ yanturu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n sì yó, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń ṣe fàájì nínú oore rẹ ńláǹlà.”—Neh. 9:9-11, 24, 25.

13. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà sin òun, àmọ́ kí ni wọ́n ṣe?

13 Ọ̀pọ̀ nǹkan míì ni Ọlọ́run tún ṣe ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé kó bàa lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì tí Jèhófà fi jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà sin òun. Àwọn ọmọ Léfì sọ nínú àdúrà tí wọ́n gbà sí Ọlọ́run pé, O “sọ kalẹ̀ sórí Òkè Ńlá Sínáì, o sì bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, o sì tẹ̀ síwájú láti fún wọn ní àwọn ìpinnu ìdájọ́ dídúróṣánṣán àti àwọn òfin òtítọ́, àwọn ìlànà àti àwọn àṣẹ tí ó dára.” (Neh. 9:13) Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ajogún Ilẹ̀ Ìlérí, kí wọ́n lè máa hùwà tí kò ní tàbùkù sí orúkọ mímọ́ rẹ̀, àmọ́ wọn ò fi àwọn ohun rere tí wọ́n kọ́ sílò.—Ka Nehemáyà 9:16-18.

Ó YẸ KÍ ỌLỌ́RUN BÁ WỌN WÍ

14, 15. (a) Nígbà táwọn èèyàn Jèhófà dẹ́ṣẹ̀, báwo ló ṣe ṣàánú fún wọn? (b) Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Ọlọ́run ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀?

14 Nínú àdúrà tí àwọn ọmọ Léfì gbà, wọ́n mẹ́nu ba ẹ̀ṣẹ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn tí wọ́n ṣèlérí ní Òkè Sínáì pé àwọn á máa pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Ó tọ́ kí Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n kú torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá yẹn. Àmọ́, àwọn ọmọ Léfì wá yin Jèhófà nínú àdúrà wọn pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ [ìwọ] kò fi wọ́n sílẹ̀ nínú aginjù. . . . Ogójì ọdún ni ìwọ fi pèsè oúnjẹ fún wọn . . . Wọn kò ṣaláìní nǹkan kan. Ẹ̀wù wọn kò gbó, ẹsẹ̀ wọn kò sì wú.” (Neh. 9:19, 21) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, Jèhófà ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò fún wa ká lè máa fi òótọ́ sìn ín. Ǹjẹ́ ká kíyè sára ká máa bàa dà bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kú sínú aginjù torí àìgbọràn àti àìnígbàgbọ́ wọn. Àpẹẹrẹ tí kò dára ni wọ́n fi lélẹ̀, torí náà la ṣe “kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.”—1 Kọ́r. 10:1-11.

15 Ó bani nínú jẹ́ pé lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti jogún Ilẹ̀ Ìlérí, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà àwọn ará Kénáánì, èyí tó kún fún ìṣekúṣe àti ìpànìyàn. Látàrí ìyẹn, Jèhófà jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ àyànfẹ́ ká, ni wọ́n lára. Nígbà tí wọ́n bá ronú pìwà dà, Jèhófà máa ń ṣàánú wọn, á dárí jì wọ́n, á sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. “Léraléra” lèyí sì máa ń ṣẹlẹ̀. (Ka Nehemáyà 9:26-28, 31.) Àwọn ọmọ Léfì jẹ́wọ́ pé: “Ìwọ gbà wọ́n ní àyè fún ọ̀pọ̀ ọdún, o sì ń jẹ́rìí lòdì sí wọn nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ, wọn kò sì fi etí sílẹ̀. Níkẹyìn, o fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àwọn ilẹ̀ náà.”—Neh. 9:30.

16, 17. (a) Báwo ni ipò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó dé láti ìgbèkùn bá ara wọn ṣe yàtọ̀ sí táwọn baba ńlá wọn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí? (b) Kí lohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́wọ́ rẹ̀? Kí ni wọ́n ṣèlérí pé àwọn máa ṣe?

16 Kódà lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé láti ìgbèkùn ńṣe ni wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìgbọràn léraléra. Àmọ́ kí ni wọ́n ṣe tó yàtọ̀? Ẹ gbọ́ ohun tí àwọn ọmọ Léfì sọ nínú àdúrà wọn: “Wò ó! A jẹ́ ẹrú lónìí; àti ní ti ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wa láti jẹ èso rẹ̀ àti ohun rere rẹ̀, wò ó! a jẹ́ ẹrú lórí rẹ̀, èso rẹ̀ sì ń pọ̀ gidigidi fún àwọn ọba tí ìwọ fi ṣolórí wa nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, . . . a sì wà nínú wàhálà ńláǹlà.”—Neh. 9:36, 37.

17 Ṣé ohun tí àwọn ọmọ Léfì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé kò dáa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí wàhálà dé bá àwọn? Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá! Wọ́n jẹ́wọ́ pé: “Ìwọ . . jẹ́ olódodo ní ti gbogbo ohun tí ó dé bá wa, nítorí ìwọ ti hùwà lọ́nà ìṣòtítọ́, ṣùgbọ́n àwa ni a hùwà burúkú.” (Neh. 9:33) Ní ìparí àdúrà tí wọ́n ti sọ ohun tó jóòótọ́ nípa ara wọn àti Ọlọ́run yìí, wọ́n ṣe ìlérí látọkànwá pé látìgbà yẹn lọ, orílẹ̀-èdè àwọn á máa ṣègbọràn sí Òfin Ọlọ́run. (Ka Nehemáyà 9:38; 10:29) Látàrí èyí, wọ́n kọ ìpinnu wọn sílẹ̀, àwọn àgbààgbà Júù mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] sì fi èdìdì dì í, tó jẹ́ àmì pé wọ́n buwọ́ lu àkọsílẹ̀ náà.—Neh. 10:1-27.

18, 19. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè là á já wọnú ayé tuntun Ọlọ́run? (b) Kí ló yẹ ká máa gbàdúrà fún, kí sì nìdí?

18 A nílò ìbáwí Jèhófà ká bàa lè là á já wọnú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ọmọ wo ni baba kì í bá wí?” (Héb. 12:7) Bá ò ṣe jẹ́ kó sú wa láti máa fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, tá a sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ máa sọ wá dọ̀tun, tàbí kó máa yí wa pa dà, ńṣe là ń fi hàn pé a gbà kí Ọlọ́run máa darí wa. Tá a bá sì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, kí ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tá a sì gba ìbáwí.

19 Láìpẹ́, Jèhófà máa ṣe àwọn ohun tó túbọ̀ pabanbarì ju èyí tó fi ṣe orúkọ fún ara rẹ̀ nígbà tó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. (Ìsík. 38:23) Àti pé bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jogún Ilẹ̀ Ìlérí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn Kristẹni tó ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà láìyẹsẹ̀ ṣe máa jogún ìyè nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. (2 Pét. 3:13) Bá a ṣe ń fojú sọ́nà fún ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí orúkọ ológo Ọlọ́run di èyí tá a sọ di mímọ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò àdúrà míì tó máa mú ká ṣe ohun tó yẹ ká bàa lè gbádùn ìbùkún Ọlọ́run nísinsìnyí àti títí láé.