Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Olùṣọ́ Àgùntàn Méje àti Mọ́gàjí Mẹ́jọ ti Òde Òní

Olùṣọ́ Àgùntàn Méje àti Mọ́gàjí Mẹ́jọ ti Òde Òní

“Àwa pẹ̀lú yóò sì ní láti gbé olùṣọ́ àgùntàn méje dìde sí i, bẹ́ẹ̀ ni, mọ́gàjí mẹ́jọ nínú aráyé.”—MÍKÀ 5:5.

1. Kí nìdí tó fi dájú pé ọ̀tẹ̀ tí ọba Síríà àti ti Ísírẹ́lì jọ dì máa já sí asán?

NÍGBÀ kan láàárín ọdún 762 àti 759 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì àti ọba ilẹ̀ Síríà bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìjọba Júdà jagun. Kí ni wọ́n ń fẹ́? Wọ́n fẹ́ ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè rọ Áhásì Ọba lóyè, kí wọ́n sì fi ọkùnrin mìíràn rọ́pò rẹ̀, tó lè jẹ́ ẹni tí kì í ṣe àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba. (Aísá. 7:5, 6) Àmọ́ ó yẹ kí ọba Ísírẹ́lì mọ̀ pé àwọn ò lè ṣàṣeyọrí. Jèhófà ti sọ pé ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Dáfídì máa wà lórí ìtẹ́ rẹ̀ títí láé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́rùn kò sì ní lọ láì ṣẹ.—Jóṣ. 23:14; 2 Sám. 7:16.

2-4. Ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 7:14, 16 ṣe ṣẹ (a)  ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (b) ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni.

2 Ó kọ́kọ́ dà bíi pé àwọn ọmọ ogun Síríà àti Ísírẹ́lì máa borí. Nígbà ìjà ogun kan péré, Áhásì pàdánù ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] lára àwọn akíkanjú ọkùnrin ogun rẹ̀! Wọ́n tún pa Maaseáyà, “ọmọkùnrin ọba.” (2 Kíró. 28:6, 7) Àmọ́ Jèhófà ń wò wọ́n. Ó rántí ìlérí tó ṣe fún Dáfídì, torí náà, ó rán wòlíì Aísáyà sí wọn, láti sọ ọ̀rọ̀ tó máa fún wọn ní ìṣírí gan-an.

3 Aísáyà sọ pé: “Wò ó! Omidan náà yóò lóyún ní tòótọ́, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, dájúdájú, yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì. . . Kí ọmọdékùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ohun búburú sílẹ̀, tí a sì ń yan ohun rere, ilẹ̀ ọba méjèèjì tí ìwọ ní ìbẹ̀rùbojo amúniṣàìsàn fún [Síríà àti Ísírẹ́lì] ni a ó fi sílẹ̀ pátápátá.” (Aísá. 7:14, 16) A sábà máa ń tọ́ka sí apá àkọ́kọ́ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìbí Mèsáyà, èyí sí bá a mu. (Mát. 1:23) Ṣùgbọ́n nítorí pé àwọn “ọba méjèèjì,” ìyẹn ọba Síríà àti ọba Ísírẹ́lì, kò sí láyé mọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, ó ní láti jẹ́ pé nígbà ayé Aísáyà ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìmánúẹ́lì ti kọ́kọ́ ṣẹ.

4 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Aísáyà ṣe ìkéde àrà ọ̀tọ̀ yẹn ni ìyàwó rẹ̀ lóyún, tó sì bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n sọ ní Maheri-ṣalali-háṣí-básì. Ó lè jẹ́ pé ọmọ yìí ni Ìmánúẹ́lì tí Aísáyà ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. * Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n lè sọ ọmọ kan lórúkọ kan nígbà tí wọ́n bí i, bóyá nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó wáyé nígbà náà, àmọ́ kó jẹ́ orúkọ míì ni àwọn òbí rẹ̀ àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fi ń pè é. (2 Sám. 12:24, 25) Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé wọ́n pe Jésù ní Ìmánúẹ́lì nígbà tó wà láyé.—Ka Aísáyà 7:14; 8:3, 4.

5. Ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu wo ní Áhásì Ọba ṣe?

5 Bí Ísírẹ́lì àti Síríà ṣe ń bá Júdà jagun, orílẹ̀-èdè mìíràn wà tó fẹ́ gba gbogbo àgbègbè náà. Orílẹ̀-èdè Ásíríà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń di agbára ayé bọ̀ ni, ogun jíjà sì ni iṣẹ́ wọn. Aísáyà 8:3, 4 sọ pé Ásíríà máa kó “àwọn ohun àmúṣọrọ̀ Damásíkù” àti “ohun ìfiṣèjẹ Samáríà” lọ, kó tó wá gbógun ti ìjọba Júdà ní gúúsù. Dípò kí Áhásì aláìnígbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Aísáyà sọ yìí, ńṣe ló lọ bá àwọn ará Ásíríà ṣe àdéhùn, èyí sì mú kí wọ́n pọ́n àwọn ará Júdà lójú gan-an. (2 Ọba. 16:7-10) Ẹ ò rí i pé Áhásì kùnà gan-an ní ipò olùṣọ́ àgùntàn Júdà tó wà! Àwa náà lè bi ara wa pé, ‘Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ṣé Ọlọ́run ni mo máa ń gbẹ́kẹ̀ lé ni àbí àwọn èèyàn?’—Òwe 3:5, 6.

OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN TUNTUN KAN ṢE NǸKAN LỌ́NÀ TÓ YÀTỌ̀

6. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìjọba Áhásì àti ti Hesekáyà?

6 Áhásì kú lọ́dún 746 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Hesekáyà ọmọkùnrin rẹ̀ sì di ọba ilẹ̀ Júdà tí ọrọ̀ ajé rẹ̀ ti dẹnu kọlẹ̀, tí àwọn èèyàn rẹ̀ sì ti jìnnà sí Ọlọ́run. Kí ni ọba tuntun tó kéré lọ́jọ́ orí yìí máa fẹ́ kọ́kọ́ ṣe? Ṣé ọ̀rọ̀ ajé Júdà ló máa fẹ́ mú sunwọ̀n sí i? Rárá o. Hesekáyà nífẹ̀ẹ́ ìjọsìn Ọlọ́run gan-an, ó sì kúnjú ìwọ̀n láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ìgbésẹ̀ tó kọ́kọ́ gbé ni láti mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò, kó sì mú kí orílẹ̀-èdè aláìgbọràn náà ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà. Nígbà tí Hesekáyà lóye ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣe, kíákíá ló ṣe é. Àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún wa!—2 Kíró. 29:1-19.

7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ọba tuntun náà mú un dá àwọn ọmọ Léfì lójú pé òun máa tì wọ́n lẹ́yìn?

7 Àwọn ọmọ Léfì máa kó ipa pàtàkì nínú mímú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò. Iṣẹ́ bàǹtàbanta sì nìyẹn. Nítorí náà, Hesekáyà pè wọ́n jọ, ó sì mú kó dá wọn lójú pé òun máa tì wọ́n lẹ́yìn. Fojú inú wo bí omijé ayọ̀ á ṣe máa dà lójú àwọn ọmọ Léfì adúróṣinṣin tó wà ní ìpàdé náà nígbà tí ọba wọn kéde pé: “Ẹ̀yin ni Jèhófà ti yàn láti máa dúró níwájú rẹ̀ láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un.” (2 Kíró. 29:11) Ọba pàṣẹ tó ṣe kedere fún àwọn ọmọ Léfì, ó ní kí wọ́n mú kí ìjọsìn mímọ́ gbilẹ̀!

8. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni Hesekáyà tún gbé láti mú kí ìjọsìn Ọlọ́run túbọ̀ gbilẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

8 Hesekáyà pe gbogbo èèyàn Júdà àti Ísírẹ́lì jọ láti ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá kan tó fa kíki. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi ọjọ́ méje ṣe Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú. Àwọn èèyàn náà gbádùn àjọyọ̀ yẹn débi pé wọ́n tún fi ọjọ́ méje kún un! Bíbélì sọ pé: “Ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà sì wá wà ní Jerúsálẹ́mù, nítorí pé láti ọjọ́ Sólómọ́nì ọmọkùnrin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì kò sí ọ̀kan bí èyí ní Jerúsálẹ́mù.” (2 Kíró. 30:25, 26) Àjọyọ̀ tí wọ́n fi jọ́sìn Ọlọ́run yẹn mú kí àwọn èèyàn náà ṣe ohun tó tọ́. A rí i kà nínú 2 Kíróníkà 31:1 pé: “Gbàrà tí wọ́n sì parí gbogbo èyí, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì . . . bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ túútúú, wọ́n sì ké àwọn òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀, wọ́n sì bi àwọn ibi gíga àti àwọn pẹpẹ wó.” Bí Júdà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà lọ́nà tó kàmàmà nìyẹn o. Bí wọ́n ṣe wẹ ara wọn mọ́ fún ìjọsìn Ọlọ́run yìí ṣe pàtàkì nítorí ohun tí wọ́n máa dojú kọ lọ́jọ́ iwájú.

ỌBA MÚRA SÍLẸ̀ DE WÀHÁLÀ

9. (a) Báwo ni ìwéwèé Ísírẹ́lì ṣe di asán? (b) Àṣeyọrí wo ni Senakéríbù kọ́kọ́ ṣe nílẹ̀ Júdà?

9 Ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ nígbà tí àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun ìjọba Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá. Wọ́n kó àwọn olùgbé ibẹ̀ lọ sí ibòmíràn, ìwéwèé Ísírẹ́lì láti fipá gba ìtẹ́ Dáfídì, kí wọ́n sì gbé e fún ẹlòmíràn tipa báyìí já sí asán. Àmọ́ kí ni àwọn ará Ásíríà ń wéwèé? Júdà ni wọ́n wá dojú ìjà kọ báyìí. “Ní ọdún kẹrìnlá Hesekáyà Ọba, Senakéríbù ọba Ásíríà gòkè wá gbéjà ko gbogbo ìlú ńlá olódi Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbà wọ́n.” Ìròyìn fi hàn pé ìlú mẹ́rìndínláàádọ́ta [46] ni Senakéríbù ṣẹ́gun ní Júdà. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ ká ní Jerúsálẹ́mù lò ń gbé nígbà yẹn? Ńṣe làwọn ìlú Júdà ń ṣubú lọ́kọ̀ọ̀kan níwájú àwọn ọmọ ogun Ásíríà!—2 Ọba 18:13.

10. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ inú Míkà 5:5, 6 fi lè jẹ́ ìṣírí fún Hesekáyà nígbà yẹn?

10 Kò sí àní-àní pé Hesekáyà mọ̀ pé ewu ló rọ̀ dẹ̀dẹ̀ yìí, àmọ́ dípò kó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà bí Áhásì bàbá rẹ̀ tó jẹ́ apẹ̀yìndà ti ṣe, Jèhófà ni Hesekáyà gbẹ́kẹ̀ lé. (2 Kíró. 28:20, 21) Ó ṣeé ṣe kó mọ àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Míkà, tó ṣì ń gbé ayé nígbà yẹn, sọ nípa Ásíríà pé: “Ní ti ará Ásíríà. . . àwa pẹ̀lú yóò sì ní láti gbé olùṣọ́ àgùntàn méje dìde sí i, bẹ́ẹ̀ ni, mọ́gàjí mẹ́jọ nínú aráyé. Wọn yóò sì fi idà ṣe olùṣọ́ àgùntàn ilẹ̀ Ásíríà ní ti tòótọ́.” (Míkà 5:5, 6) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí yìí á jẹ́ ìṣírí fún Hesekáyà, torí ó fi hàn pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ máa kojú àwọn ará Ásíríà, á sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá burúkú tó gbógun wá bá àwọn ará Júdà yìí.

11. Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn olùṣọ́ àgùntàn méje àti mọ́gàjí mẹ́jọ máa ṣẹ lọ́nà tó ṣe pàtàkì jù lọ?

11 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn olùṣọ́ àgùntàn méje àti mọ́gàjí mẹ́jọ (ọmọ aládé, Bíbélì The New English Bible) máa ṣẹ lọ́nà tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn ìbí Jésù, tó jẹ́ “olùṣàkóso Ísírẹ́lì. . . ẹni tí orírun rẹ̀ jẹ́ láti àwọn àkókò ìjímìjí.” (Ka Míkà 5:1, 2.) Èyí máa jẹ́ ní àkókò kan tí ọ̀tá kan tá a lè pè ní “ará Ásíríà” òde òní máa fẹ́ pa gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà run. Àwọn ọmọ ogun wo ni Jèhófà máa ní kí Ọmọ rẹ̀ tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso báyìí fi kojú ọ̀tá tó bani lẹ́rù yìí? A máa rí ìdáhùn láìpẹ́. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú àwọn ohun tí Hesekáyà ṣe láti kojú ogun àwọn ará Ásíríà.

HESEKÁYÀ ṢE ÀWỌN OHUN TÓ LÈ ṢE

12. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni Hesekáyà àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbé láti dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run?

12 Ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń fẹ́ bá wa ṣe ohun tá ò lè dá ṣe, àmọ́ ó fẹ́ ká ṣe ohun tí a lè dá ṣe. Hesekáyà gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú “àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá,” wọ́n sì pinnu “láti sé omi inú àwọn ìsun tí ń bẹ ní òde ìlú ńlá náà pa . . . Pẹ̀lúpẹ̀lù, [Hesekáyà] mọ́kànle, ó sì mọ gbogbo ògiri tí a ti wó lulẹ̀, ó sì gbé àwọn ilé gogoro nà ró lé e lórí, àti ògiri mìíràn lóde, ó sì tún Òkìtì Ìlú Ńlá Dáfídì ṣe, ó sì ṣe àwọn ohun ọṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu àti àwọn apata.” (2 Kíró. 32:3-5) Jèhófà lo àwọn akíkanjú ọkùnrin mélòó kan láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n sì dáàbò bò wọ́n. Lára wọn ni Hesekáyà, àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn wòlíì tó nífẹ̀ẹ́ ìjọsìn Ọlọ́run.

13. Ìgbésẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù wo ni Hesekáyà gbé láti múra àwọn èèyàn náà sílẹ̀ fún ogun tó ń bọ̀? Ṣàlàyé.

13 Ohun tí Hesekáyà ṣe lẹ́yìn èyí tiẹ̀ tún ṣe pàtàkì ju bó ṣe sé àwọn omi pa, tó sì tún àwọn ògiri ìlú náà mọ. Nítorí pé Hesekáyà jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó bìkítà, ó pe àwọn èèyàn náà jọ pọ̀, ó sì fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. Ó ní: “Ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà nítorí ọba Ásíríà. . . , nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Apá tí ó jẹ́ ẹran ara ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run wa ni ó wà pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja àwọn ìjà ogun wa.” Ọ̀rọ̀ ìránnilétí yìí máa fún ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn náà lókun gan-an torí ó fi hàn pé Jèhófà máa jà fún àwọn èèyàn rẹ̀! Nígbà tí àwọn Júù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀rọ̀ Hesekáyà ọba Júdà gbé ara wọn ró.” Kíyè sí i pé “àwọn ọ̀rọ̀ Hesekáyà” ló mú káwọn èèyàn náà mọ́kàn le. Òun àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá rẹ̀ pẹ̀lú wòlíì Míkà àti wòlíì Aísáyà fi ara wọn hàn bí olùṣọ́ àgùntàn tó dáńgájíá, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀.—2 Kíró. 32:7, 8; ka Míkà 5:5, 6.

Ọ̀rọ̀ tí Hesekáyà sọ mú kí àwọn èèyàn náà mọ́kàn le (Wo ìpínrọ̀ 12, 13)

14. Kí ni Rábúṣákè ṣe, kí sì ni àwọn èèyàn náà ṣe?

14 Ọba Ásíríà pa ibùdó sí Lákíṣì tó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù. Ó wá rán aṣojú mẹ́ta láti ibẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó sì pàṣẹ pé kí ìlú náà túúbá. Agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀, tí orúkọ oyè rẹ̀ ń jẹ́ Rábúṣákè, lo ọ̀pọ̀ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Èdè Hébérù ló fi bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀, ó ní kí wọ́n da ọba wọn, kí wọ́n sì túúbá fún àwọn ará Ásíríà, ó ṣèlérí ẹ̀tàn pé àwọn á kó wọn lọ síbi tí wọ́n á ti máa gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ. (Ka 2 Ọba 18:31, 32.) Rábúṣákè wá sọ pé gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè kò ti lè dáàbò bo àwọn olùjọsìn wọn, Jèhófà kò ní lè gba àwọn Júù sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà. Àwọn èèyàn náà hùwà ọgbọ́n, wọ́n kò gbìyànjú láti fèsì sí àwọn ọ̀rọ̀ ìṣáátá yẹn. Ohun táwa ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní náà sábà máa ń ṣe nìyẹn.—Ka 2 Ọba 18:35, 36.

15. Kí ni àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù gbọ́dọ̀ ṣe, báwo sì ni Jèhófà ṣe gba ìlú náà là?

15 Inú Hesekáyà bàjẹ́ gan-an, àmọ́ kàkà tá á fi wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè míì, wòlíì Aísáyà ló ránṣẹ́ sí. Aísáyà sọ fún Hesekáyà pé: “[Senakéríbù] kì yóò wá sínú ìlú ńlá yìí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ta ọfà kan sí ibẹ̀.” (2 Ọba 19:32) Ohun tí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù gbọ́dọ̀ ṣe ò ju pé kí wọ́n dúró sínú ìlú wọn. Jèhófà máa jà fún Júdà. Jèhófà sì jà fún wọn lóòótọ́! “Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òru yẹn pé áńgẹ́lì Jèhófà tẹ̀ síwájú láti jáde lọ, ó sì ṣá ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n balẹ̀ nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà.” (2 Ọba 19:35) Kì í ṣe bí Hesekáyà ṣe sé àwọn ìsun omi ìlú náà tàbí bó ṣe tún ògiri rẹ̀ kọ́ ló mú kí Júdà rí ìgbàlà, Ọlọ́run ló gbà wọ́n là.

Ẹ̀KỌ́ TÁ A RÍ KỌ́ LÓDE ÒNÍ

16. Lóde òní, àwọn wo ni (a) àwọn ará Jerúsálẹ́mù (b) “ará Ásíríà” (d)  olùṣọ́ àgùntàn méje àti mọ́gàjí mẹ́jọ?

16 Àkókò tá a wà yìí ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn olùṣọ́ àgùntàn méje àti mọ́gàjí mẹ́jọ ń ṣẹ lọ́nà tó ṣe pàtàkì jù lọ. Láyé àtijọ́, àwọn ará Ásíríà gbéjà ko àwọn ará Jerúsálẹ́mù. Láìpẹ́ sí ìgbà tá a wà yìí, ọ̀tá tá a lè pè ní “ará Ásíríà” ti òde òní máa gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà tó dà bíi pé a kò lágbára, ó fẹ́ pa wá run. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìgbéjàkoni yẹn àti ti “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,” ti “ọba àríwá” àti ti “àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” (Ìsík. 38:2, 10-13; Dán. 11:40, 44, 45; Ìṣí. 17:14; 19:19) Ṣé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ìgbéjàkò yìí máa ṣẹlẹ̀ ni? Ó lè máà jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbéjàko kan náà ni Bíbélì pè ní orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. ‘Ohun ìjà àkànṣe’ wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Míkà fi hàn pé Jèhófà máa fi bá “ará Ásíríà” tí kò ṣeé tù lójú yìí jà? Èyí tí kò lè ronú kàn láéláé ni, ìyẹn ‘olùṣọ́ àgùntàn méje, bẹ́ẹ̀ ni, mọ́gàjí mẹ́jọ’! (Míkà 5:5) Àwọn alàgbà ìjọ ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn mọ́gàjí (tàbí ọmọ aládé, Bíbélì NEB) tó wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó yani lẹ́nu yìí. (1 Pét. 5:2) Lóde òní, Jèhófà ti pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọkùnrin tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti máa ṣe olùṣọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀ tó ṣeyebíye, kí wọ́n sì máa múra wọn sílẹ̀ de ìgbéjàkò látọ̀dọ̀ “ará Ásíríà” náà lọ́jọ́ iwájú. * Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa “fi idà ṣe olùṣọ́ àgùntàn ilẹ̀ Ásíríà.” (Míkà 5:6) Ara ‘àwọn ohun ìjà ogun wọn’ ni “idà ẹ̀mí,” ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—2 Kọ́r. 10:4; Éfé. 6:17.

17. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì mẹ́rin wo ni àwọn alàgbà lè rí fà yọ látinú ìtàn tá a jíròrò yìí?

17 Àwọn alàgbà tó bá ń ka àpilẹ̀kọ yìí lè rí àwọn kókó pàtàkì mélòó kan fà yọ látinú ìtàn tá a jíròrò yìí: (1) Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ tá a lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún ìgbéjàkò “ará Ásíríà” náà ni pé ká máa mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i, ká sì máa ran àwọn ará wa lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (2) Nígbà tí “ará Ásíríà” náà bá gbéjà kò wá, ó gbọ́dọ̀ dá àwọn alàgbà lójú pátápátá pé Jèhófà máa gbà wá. (3) Nígbà yẹn, àwọn ohun tí ètò Jèhófà bá ní ká ṣe láti rí ìgbàlà lè dà bí èyí tí kò bọ́gbọ́n mu lójú wa. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣègbọràn sí ìtọ́ni èyíkéyìí tá a bá rí gbà, yálà ó bá ohun tí àwa tàbí àwọn míì rò pé ó yẹ ká ṣe mu àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (4) Tá a bá rí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé owó, ẹ̀kọ́ ìwé, ohun ìní ti ara àti àwọn nǹkan míì tí àwọn èèyàn gbé kalẹ̀, àkókò ti tó fún wọn báyìí láti tún èrò wọn pa. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti ṣèrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣiyè méjì.

18. Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí ìtàn yìí, báwo ló ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú?

18 Bíi ti àwọn tí ogun ká mọ́ inú Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Hesekáyà, ìgbà kan ń bọ̀ tó máa dà bíi pé àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní kò lágbára. Tó bá di ìgbà yẹn, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí Hesekáyà sọ máa fún gbogbo wa lókun. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé “apá tí ó jẹ́ ẹran ara ni” àwọn ọ̀tá wa ní, “ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run wa ni ó wà pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja àwọn ìjà ogun wa”!—2 Kíró. 32:8.

^ ìpínrọ̀ 4 Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “omidan” ní Aísáyà 7:14 lè tọ́ka sí abilékọ tàbí wúńdíá. Nítorí ìdí yìí, a lè lo ọ̀rọ̀ náà fún ìyàwó Aísáyà àti fún ọmọbìnrin Júù kan, ìyẹn Màríà tó jẹ́ wúńdíá.

^ ìpínrọ̀ 16 Nínú Bíbélì, nọ́ńbà náà eéje sábà máa ń túmọ̀ sí ohun tó pé pérépéré. Nígbà míì, ẹẹ́jọ (eéje àti ẹyọ kan) máa ń túmọ̀ sí ohun tó pọ̀ yanturu.