Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí O Ṣe Lè Fara Da Ikú Ọkọ Tàbí Aya Rẹ

Bí O Ṣe Lè Fara Da Ikú Ọkọ Tàbí Aya Rẹ

Ọ̀RỌ̀ Bíbélì náà pé kí ọkọ “nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀” ṣe kedere. Ó sì tún sọ pé kí aya náà “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” Àwọn méjèèjì ní láti máa ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí “ara kan.” (Éfé. 5:33; Jẹ́n. 2:23, 24) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ńṣe làwọn tọkọtaya túbọ̀ máa ń mọwọ́ ara wọn, tí ìfẹ́ wọn á sì máa lágbára sí i. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí igi méjì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn tí gbòǹgbò wọn sì ń so kọ́ra. Bákan náà, ọwọ́ tọkọtaya tí ìgbéyàwó wọn ládùn máa ń wọ ọwọ́ gan-an débi pé ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan àti bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára wọn máa ń jọra gan-an.

Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀kan nínú wọ́n kú ńkọ́? A jẹ́ pé ìfẹ́ tó so wọ́n pọ̀, tó dà bí okùn alọ́májàá nígbà tí wọ́n ṣì jọ wà láàyè, ti já nìyẹn. Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú. A máa dá wà, inú lè máa bí i tàbí kó máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi. Nǹkan bí ọdún méjìdínlọ́gọ́ta [58] ni Daniella àti ọkọ rẹ̀ fi wà pa pọ̀, ó sì mọ ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti pàdánù alábàáṣègbéyàwó wọn. * Àmọ́ lẹ́yìn tí ọkọ tiẹ̀ náà kú, ó sọ pé: “Mi ò mọ bó ṣe ń rí lára tẹ́lẹ̀. Èèyàn ò sì lè mọ̀ ọ́n àfi tó bá ṣẹlẹ̀ séèyàn.”

Ẹ̀DÙN ỌKÀN TÓ DÀ BÍI PÉ KÒ NÍ LỌ

Àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé ìnira táwọn ti ọkọ tàbí aya wọn ọ̀wọ́n kú máa ń ní kò láfiwé. Ọ̀pọ̀ tó ti nírú ìrírí yìí ló gbà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ Millie ti kú ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Nígbà tó ń ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ kú, ó sọ pé, “Ńṣe ni mo dà bí aláàbọ̀ ara.” Ẹ̀dùn ọkàn tó ní torí pé ó pàdánù ọkọ rẹ̀ tí wọ́n ti jọ wà pa pọ̀ fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ló ní lọ́kàn.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Susan fìgbà kan rò pé àwọn obìnrin tó máa ń bara jẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún nítorí pé ọkọ wọn kú ń ti àṣejù bọ̀ ọ́. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé ọkọ rẹ̀ tí wọ́n ti jọ wà fún ọdún méjìdínlógójì [38] kú. Ó ti lé ní ogún [20] ọdún báyìí, síbẹ̀ ó sọ pé, “Ojoojúmọ́ ni mò ń ronú nípa rẹ̀.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń sunkún torí pé àárò ọkọ rẹ̀ máa ń sọ ọ́ gan-an.

Bíbélì jẹ́rìí sí i pé ikú ọkọ tàbí aya ẹni máa ń fa ìrora ńlá tí kì í tán bọ̀rọ̀. Nígbà tí Sárà kú, ńṣe ni Ábúráhámù ọkọ rẹ̀ “wọlé láti pohùn réré ẹkún Sárà àti láti sunkún lórí rẹ̀.” (Jẹ́n. 23:1, 2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù gbà gbọ́ pé àjíǹde wà, síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́ gan-an nígbà tí aya rẹ̀ ọ̀wọ́n kú. (Héb. 11:17-19) Kò rọrùn fún Jékọ́bù náà láti tètè gbé ikú Rákélì aya rẹ̀ ọ̀wọ́n kúrò lọ́kàn. Tìfẹ́tìfẹ́ ló fi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀.—Jẹ́n. 44:27; 48:7.

Kí la rí kọ́ nínú àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ yìí? Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn tí ọkọ tàbí aya wọn ti kú fi máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn. Torí náà, ká má ṣe rò pé àìnígbàgbọ́ ló fà á tí wọ́n fi máa ń domi lójú tàbí tí wọ́n fi ń banú jẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dà bí ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń sọ pé ẹni ìjà ò bá ní í pe ara rẹ̀ lọ́kùnrin. Ó lè gba pé ká máa gba tiwọn rò, ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ fún àkókò gígùn.

MÁ ṢE KÓ OHUN TÓ PỌ̀ JÙ SỌ́KÀN

Bí nǹkan ṣe máa ń rí fún ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú yàtọ̀ pátápátá sí tẹni tí kò lọ́kọ tàbí láya rí. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún nínú ìgbéyàwó, ọkọ kan á ti mọ bó ṣe lè tu ìyàwó rẹ̀ nínú nígbà tí inú rẹ̀ kò bá dùn tàbí tí nǹkan bá tojú sú u. Bí ọkọ náà ò bá wá sí mọ́, a jẹ́ pé ẹni tó ń fẹ́ ẹ lójú, tó ń fẹ́ ẹ nímú, tó sì ń tù ú nínú ni ò sí mọ́ yẹn. Bákan náà, bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ni aya kan máa ń mọ bó ṣe lè fi ọkọ rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ kó sì mú inú rẹ̀ dùn. Kò sóhun tá a lè fi wé bó ṣe máa ń rọra fọwọ́ kan ọkọ rẹ̀, tó máa ń bá a sọ̀rọ̀ tútù, bó ṣe máa ń tẹ́tí sí ọkọ rẹ̀ tó sì máa ń bójú tó ohun tó nílò. Tí aya bẹ́ẹ̀ bá wá kú, gbogbo nǹkan lè tojú sú u. Ìyẹn ló fà á tí àwọn kan tí ọkọ tàbí aya wọn kú fi máa ń ṣiyè méjì tí wọ́n sì máa ń bẹ̀rù ilẹ̀ tó máa mọ́ ọ̀la. Ìlànà Bíbélì wo ló lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àníyàn táá sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?

Ọlọ́run máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara dà á tó ò bá kó ohun tó pọ̀ jù sọ́kàn

“Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.” (Mát. 6:34) Àwọn nǹkan téèyàn nílò nípa tara ni Jésù dìídì ń sọ nípa rẹ̀, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro tó ń gani lára téèyàn máa ń ní tí èèyàn ẹni bá kú. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí aya ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Charles kú, ó ní: “Bí àárò Monique ṣe ń sọ mí nígbà tó kú kò tíì yí pa dà, ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé kàkà kó sàn, ńṣe ló ń le sí i. Àmọ́, mo wá mọ̀ pé bó ṣe máa ń rí nìyẹn àti pé bópẹ́ bóyá ẹ̀dùn ọkàn tí mo ní máa tó dín kù bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.”

Ó ṣe kedere pé Charles ní láti fara dà á “bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.” Kí ló mú kó lè fara dà á? Ó sọ pé, “Jèhófà ló ràn mí lọ́wọ́ tí mi ò fi máa kó ohun tó pọ̀ jù sọ́kàn.” Charles kò jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí òun kodò. Ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ kò lọ ní ọ̀sán kan òru kan, àmọ́ kò jẹ́ kó gba òun lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Bí ọkọ tàbí aya rẹ bá ti kú, sapá láti má ṣe kó ohun tó pọ̀ jù sọ́kàn. O kò lè sọ, bí oní ṣe rí ọ̀la lè máà rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o rí ohun tó máa tù ẹ́ nínú tàbí tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní lọ́la.

Nígbà tí Jèhófà dá àwa èèyàn, kò ní in lọ́kàn rárá pé ká máa kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú jẹ́ ara “àwọn iṣẹ́ Èṣù.” (1 Jòh. 3:8; Róòmù 6:23) Sátánì máa ń lo ikú àti ìbẹ̀rù ikú láti mú ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́rú kí wọ́n sì sọ ìrètí nù. (Héb. 2:14, 15) Inú Sátánì máa ń dùn tó bá rí ẹnì kan tó gbà pé òun ò lè ní ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn mọ́, kódà nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Torí náà, ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àtàwọn ètekéte Sátánì ló fa ìnira tí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ̀ máa ń ní. (Róòmù 5:12) Jèhófà máa ṣe àtúnṣe gbogbo aburú tí Sátánì ti fà, á sì ṣẹ́gun ikú tó jẹ́ irinṣẹ́ burúkú tí Sátánì ń lò. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí ọkọ tàbí aya wọn ti kú wà lára àwọn tó ti bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù tí Sátánì máa ń mú káwọn èèyàn ní, ó sì ṣeé ṣe kí ìwọ náà wà lára wọn.

Ní ti àwọn tí wọ́n á máa gbé lórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn àjínde, ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìyípadà máa wà nínú àjọṣe tí wọ́n ní láàárín ara wọn. Ronú nípa àwọn òbí, àwọn òbí àgbà àti àwọn babańlá míì tí wọ́n máa jíǹde, tí àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ wọn máa wà níbẹ̀, tí gbogbo wọn á sì jọ dàgbà dé ìjẹ́pípé. Kẹ́gẹkẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó kò ní sí mọ́. Ǹjẹ́ ojú tí àwọn tó ti jẹ́ ọmọ àti ọmọ-ọmọ tẹ́lẹ̀ rí á fi máa wo àwọn àgbà àtijọ́ ò ní yàtọ̀ pátápátá sí bí wọ́n ṣe ń wò wọ́n báyìí? Ṣé a ò sì gbà pé irú àwọn ìyípadà tó máa wáyé yìí á mú kí àjọṣe tó wà láàárín aráyé sunwọ̀n sí i?

Àìmọye ìbéèrè ló lè máa sọ sí wa lọ́kàn nípa bí nǹkan ṣe máa rí fáwọn tó máa jíǹde, irú bí àwọn tó pàdánù ọkọ tàbí aya méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn Sadusí béèrè nípa obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ kú, tí èkejì ná kú, títí dórí méje. (Lúùkù 20:27-33) Báwo ni àjọṣe àárín wọn ṣe máa rí nígbà tí wọ́n bá jíǹde? Kò sí bá a ṣe lè mọ̀ báyìí, kò sì sídìí láti máa méfò tàbí ká máa yọ ara wa lẹ́nu lórí ohun tá ò mọ̀. Ohun tá a lè ṣe báyìí ni pé ká fọkàn tán Ọlọ́run. Ohun kan dájú, ohun yòówù kí Jèhófà ṣe lọ́jọ́ iwájú máa ṣe wá níre, ohun tó yẹ ká máa fojú sọ́nà fún ni, kì í ṣe ohun tó yẹ ká máa bẹ̀rù.

OHUN ÌTÙNÚ NI ÌRÈTÍ ÀJÍǸDE

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere jù lọ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni pé àwọn èèyàn wa ọ̀wọ́n máa pa dà wà láàyè. Àkọsílẹ̀ inú Bíbélì nípa àwọn tó jíǹde mú kó da wá lójú pé “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòh. 5:28, 29) Inú àwọn tó wà láàyè nígbà àjíǹde máa dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń kí àwọn tó rí ìdáǹdè gbà lọ́wọ́ ikú káàbọ̀. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí inú àwọn tó jíǹde ṣe máa dùn á kọjá àfẹnusọ.

Ayọ̀ máa gbayé kan ju ti ìgbàkígbà rí lọ bí àwọn tó kú ṣe ń jí dìde. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó jíǹde á tún pa dà máa gbé láàárín àwọn alààyè. (Máàkù 5:39-42; Ìṣí. 20:13) Gbogbo àwọn téèyàn wọn ti kú máa rí ìtùnú tí wọ́n bá ń ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu ọjọ́ ọ̀la yìí.

Ǹjẹ́ ìdí èyíkéyìí á wà fún ẹnikẹ́ni láti bara jẹ́ nígbà tí àwọn òkú bá ń jí dìde? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò ní sídìí. Ọ̀rọ̀ Aísáyà 25:8, sọ pé Jèhófà “yóò gbé ikú mì títí láé.” Lára ọ̀nà tí Ọlọ́run máa gbà ṣe èyí ni pé ó máa mú ìpalára tí ikú ń fà kúrò, torí pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ síwájú sí i pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” Bó o bá ń bara jẹ́ báyìí torí pé ọkọ tàbí aya rẹ ti kú, ó dájú pé àjíǹde máa mú kó o láyọ̀.

Kò sẹ́ni tó lè sọ gbogbo ohun tí Ọlọ́run máa ṣe nínú ayé tuntun. Jèhófà sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.” (Aísá. 55:9) Ìlérí tí Jésù ṣe nípa àjíǹde mú ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bí Ábúráhámù ti ṣe. Ohun pàtàkì tó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan máa ṣe báyìí ni pé ká máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ “kà [wá] yẹ fún jíjèrè ètò àwọn nǹkan yẹn” pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó máa jíǹde.—Lúùkù 20:35.

Ó YẸ KÁ NÍ ÌRÈTÍ

Dípò tí wàá fi máa ṣàníyàn, ńṣe ni kó o nírètí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa. Lójú àwa èèyàn, ayé yìí ò lè dáa mọ́. Àmọ́ Jèhófà fún wa ní ìrètí pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. A ò lè mọ bí Jèhófà ṣe máa pèsè gbogbo nǹkan tá a nílò àti bó ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa lọ́rùn, àmọ́ kò yẹ ká ṣiyè méjì pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí mọ́, nítorí nígbà tí ẹnì kan bá rí ohun kan, ó ha máa ń retí rẹ̀ bí? Ṣùgbọ́n bí a bá ń retí ohun tí a kò rí, a óò máa bá a nìṣó ní dídúró dè é pẹ̀lú ìfaradà.” (Róòmù 8:24, 25) Tí ìlérí Ọlọ́run bá dá ẹ lójú dáadáa, wàá lè fara dà á. Tó o bá fara dà á, wàá lè ní ìpín nínú ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ níbi tí Jèhófà ti máa “fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.” Yóò tẹ́ “ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Sm. 37:4; 145:16; Lúùkù 21:19.

Ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọjọ́ iwájú aláyọ̀ tí Jèhófà ṣèlérí

Nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n pa Jésù, inú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bà jẹ́. Jésù wá fi ọ̀rọ̀ yìí tù wọ́n nínú, ó ní: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà yín dààmú. Ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú.” Ó sọ fún wọn pé: “Èmi kì yóò fi yín sílẹ̀ ní ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ yín.” (Jòh. 14:1-4, 18, 27) Kò sí ìgbà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kò ní máa fi ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró balẹ̀ táá sì jẹ́ kí wọ́n máa fara dà á. Bákan náà lọ̀rọ̀ ṣe rí fún àwọn tó ń hára gàgà láti rí àwọn èèyàn wọn ọ̀wọ́n nígbà àjíǹde, kò sí ìdí fún wọn láti sọ̀rètí nù. Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ kò ní fi wọ́n sílẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣọ̀fọ̀. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rẹ máa rí!

^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí orúkọ náà pa dà.