Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÌJÍRÒRÒ LÁÀÁRÍN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ÀTI ẸNÌ KAN

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?

Ìjíròrò kan tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Bọ́lá lọ sí ilé obìnrin kan tó ń jẹ́ Ṣadé.

BÁWO LÓ ṢE MÁA Ń RÍ LÁRA ỌLỌ́RUN TÁ A BÁ Ń JÌYÀ?

Bọ́lá: Ẹ ǹ lẹ́ o, inú mi dùn pé mo bá yín ń lé.

Ṣadé: Èmi náà láyọ̀ láti rí yín.

Bọ́lá: Nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín, a sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run tá a bá ń jìyà. * Ẹ sọ lọ́jọ́ yẹn pé, ó ti pẹ́ tí ẹ ti ń ronú lórí ọ̀rọ̀ náà, pàápàá láti ìgbà ti mọ́mì yín ti fara pa nínú jàǹbá ọkọ̀. Báwo lara màmá báyìí?

Ṣadé: A ṣì wà lẹ́nu ẹ̀ o, ìgbà míì ara wọn á balẹ̀, ìgbà míì sì rèé, á tún yọ wọ́n lẹ́nu. Àmọ́, ara wọn tún balẹ̀ lónìí.

Bọ́lá: A dúpẹ́ pé ara wọn ti ń balẹ̀. Ẹ kú iṣẹ́ gan-an, kì í rọrùn láti tọ́jú ẹni tó wà ní irú ipò yẹn.

Ṣadé: Kò rọrùn rárá. Mo tiẹ̀ máa ń ṣe kàyéfì pé ìgbà wo ni ara wọn máa yá, tí wọn á sì bọ́ nínú ìrora yìí.

Bọ́lá: Bó ṣe máa ń rí lára wa nìyẹn. Nígbà tí a jọ sọ̀rọ̀ gbẹ̀yìn, ṣé ẹ rántí pé kí n tó kádìí ọ̀rọ̀ mi, mo béèrè lọ́wọ́ yín pé, tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run lágbára láti fòpin sí gbogbo ìṣòro wa, kí nìdí tí kò fi tíì ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni, mo rántí.

Bọ́lá: Ká tó wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ ìbéèrè náà, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo díẹ̀ nínú àwọn kókó tí a ti jọ jíròrò.

Ṣadé: Ó dáa bẹ́ẹ̀.

Bọ́lá: A kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọkùnrin olóòótọ́ kan tó wà láyé nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì, tí òun náà sì ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run ṣe fàyè gba ìyà. Síbẹ̀, Ọlọ́run ò bá a wí fún ohun tó béèrè, kò sì sọ fún un pé àìnígbàgbọ́ ló ń dà á láàmú.

Ṣadé: Ṣé ẹ rí i, ohun tí a kọ́ lọ́jọ́ yẹn yà mí lẹ́nu gan-an ni.

Bọ́lá: A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé inú Ọlọ́run ò dùn sí bí ìyà ṣe ń jẹ wá. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé nígbà tí wàhálà bá àwọn èèyàn Ọlọ́run, “ó jẹ́ wàhálà fún un.” * Ǹjẹ́ kò tù wá nínú láti mọ̀ pé ìyà tí à ń jẹ kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú?

Ṣadé: Ìtùnú ńlá ni.

Bọ́lá: A sì gbà lọ́jọ́ náà pé agbára Ẹlẹ́dàá wa kò láàlà. Abájọ tó fi yẹ kó dá wa lójú pé ìgbàkigbà ló lè wá nǹkan sẹ sí ọ̀rọ̀ aráyé kó sì fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ wá.

Ṣadé: Ohun tí kò tíì yé mi gan-an nìyẹn. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ káwọn nǹkan búburú yìí máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó lágbára láti fòpin si?

TA LÓ Ń SỌ ÒTÍTỌ́?

Bọ́lá: A máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí tí a ba wo inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. Ǹjẹ́  ẹ mọ ìtàn Ádámù àti Éfà dáadáa àti èso tí Ọlọ́run sọ pé wọ́n ò gbọ́dọ̀ jẹ?

Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ti kọ́ wa ní ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi. Ọlọ́run ní kí wọ́n má ṣe jẹ nínú èso igi kan, àmọ́ wọ́n ṣàìgbọràn, wọ́n sì jẹ ẹ́.

Bọ́lá: Ẹ ṣeun. Bó ṣe rí gan an nìyẹn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀. Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ náà máa jẹ́ ká mọ ìdí tí a fi ń jìyà. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ka Jẹ́nẹ́sísì orí 3, ẹsẹ 1 sí 5.

Ṣadé: Ó kà pé: “Wàyí o, ejò jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra jù lọ nínú gbogbo ẹranko inú pápá tí Jèhófà Ọlọ́run dá. Nítorí náà, ó sọ fún obìnrin náà pé: ‘Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?’ Látàrí èyí, obìnrin náà sọ fún ejò pé: ‘Àwa lè jẹ nínú àwọn èso igi ọgbà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti sọ nípa èso igi tí ó wà ní àárín ọgbà pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, rárá, ẹ kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án, kí ẹ má bàa kú.” Látàrí èyí, ejò náà sọ fún obìnrin náà pé: ‘Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ bá jẹ nínú rẹ̀ ni ojú yín máa là, ó sì dájú pé ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.’”

Bọ́lá: Ẹ ṣeun. Ẹ jẹ́ ká ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a kà yìí ná. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ kíyè sí i pé ejò kan bá Éfà sọ̀rọ̀. Apá míì nínú Bíbélì fi hàn pé Sátánì Èṣù gan-an ni ó lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀. * Ohun tí Sátánì ṣe ni pé, ó bi Éfà nípa òfin tí Ọlọ́run fún wọ́n nípa igi kan tó wà nínú ọgbà yẹn. Ǹjẹ́ ẹ kíyè sí ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ tí Ádámù àti Éfà bá jẹ́ nínú èso igi náà?

Ṣadé: Ó ní wọ́n máa kú.

Bọ́lá: Ẹ ṣeun. Nínú ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ tẹ̀lé e, ẹ̀sùn ńlá ló fi kan Ọlọ́run. Ẹ gbọ́ nǹkan tó sọ, ó ní: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” Lọ́rọ̀ kan, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé, irọ́ ni Ọlọ́run pa!

Ṣadé: Ẹ̀n ẹ́n, mi ò gbọ́ apá ibẹ̀ yẹn rí nínú ìtàn yìí.

Bọ́lá: Nígbà tí Sátánì pe Ọlọ́run ní òpùrọ́, ọ̀ràn ńlá ló dá sílẹ̀. Ọ̀ràn náà sì máa gba àkókò láti yanjú. Ǹjẹ́ ẹ mọ ìdí tó fi máa rí bẹ́ẹ̀?

Ṣadé: Rárá, kò tíì yé mi dáadáa.

Bọ́lá: Ó dáa, ẹ jẹ́ kí n fún yín ní àpèjúwe kan. Ká sọ pé lọ́jọ́ kan mo wá bá yín, mo sì sọ fún yín pé mo lágbára jù yín lọ. Báwo ni ẹ ṣe máa fi hàn mí pé ohun tí mo sọ ò rí bẹ́ẹ̀?

Ṣadé: Àfi kí àwa méjèèjì ṣe ìdánrawò, ìyẹn la máa fi mọ ẹni tó lágbára jù.

Bọ́lá: Bó ṣe rí gan ni ẹ sọ. Ńṣe ni a máa wá nǹkan tó wúwo, àá wá wo ẹni tó lè dáa gbé nínú àwa méjèèjì. Ìyẹn rọrùn láti yanjú, àbí?

Ṣadé: Ọ̀rọ̀ yín ti ń yé mi.

Bọ́lá: Àmọ́, ká ní ohun tí mo sọ ni pé mo máa ń ṣòótọ́ jù yín lọ. Ǹjẹ́ ìyẹn ò lè ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ ńlá ni.

Bọ́lá: Ó ṣe tán, agbára kọ́ la máa fi mọ̀ pé ẹnì kan ṣòótọ́.

Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni.

Bọ́lá: Ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn le gbà yanjú ọ̀ràn yìí ni pe ká fi àkókò tó pọ̀ sílẹ̀, kí àwọn èèyàn lè kíyè sí àwa méjèèjì, kí wọ́n lè mọ ẹni tó ń ṣòótọ́ jù nínú wa. Àbí?

Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni.

Bọ́lá: Ó dáa, ẹ tún ìwé Jẹ́nẹ́sísì tá a kà lẹ́ẹ̀kan yẹ̀ wò. Ṣé ohun tí Sátánì sọ ni pé òun lágbára ju Ọlọ́run lọ?

Ṣadé: Rárá o.

Bọ́lá: Ká ní ó sọ bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gba àkókò tí á fi yanjú rẹ̀. Àmọ́, ohun tí Sátánì sọ ni pé òun ń ṣòótọ́ ju Ọlọ́run lọ. Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ fún Éfà ni pé ‘irọ́ ni Ọlọ́run ń pa fún un yín, ṣùgbọ́n òótọ́ lèmi ń sọ.’

Ṣadé: Ó ga o.

Bọ́lá: Jèhófà jẹ́ ọlọgbọ́n, ó mọ̀ pé ọ̀nà tó dáa jù láti yanjú ọ̀ràn náà ni pé kí òun fi ọ̀pọ̀ àkókò sílẹ̀. Tó bá yá, òótọ́ ọ̀rọ̀ á fara hàn, àá sì mọ ẹni tó ń sòótọ́ àti ẹni tó ń pa irọ́.

Ọ̀RÀN PÀTÀKÌ KAN

Ṣadé: Àmọ́ gbàrà tí Éfà kú ló ti ṣe kedere pé òótọ́ ni Ọlọ́run ń sọ, àbí?

Bọ́lá: Lọ́nà kan, a lè sọ pé bó ṣe jẹ́ nìyẹn.  Ṣùgbọ́n, ohun tí Sátánì sọ ju ìyẹn lọ. Ẹ tún wo ẹsẹ 5 yẹn lẹ́ẹ̀kan sí i. Ǹjẹ́ ẹ kíyèsí nǹkan míì tí Sátánì tún sọ fún Éfà?

Ṣadé: Ó sọ fún un pé ojú rẹ̀ máa là tó bá jẹ èso yẹn.

Bọ́lá: Ẹ ṣeun, ó tún sọ fún un pé ó máa dà “bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Torí náà, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé Ọlọ́run ń fawọ́ ohun rere sẹ́yìn fáwọn èèyàn.

Ṣadé: Ẹ̀n ẹ́n.

Bọ́lá: Ọ̀ràn ńlá sì nìyẹn jẹ́.

Ṣadé: Kí lẹ ní lọ́kàn?

Bọ́lá: Ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ wẹ́rẹ́ yẹn kan gbogbo èèyàn, Éfà nìkan kọ́ ló ń bá wí, gbogbo wa pátá lọ̀ràn náà kàn. Torí ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé nǹkan máa sàn fún àwa èèyàn láìsí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Bíi ti ẹ̀sùn àkọ́kọ́, Jèhófà mọ̀ pé ọ̀nà tó dáa jù láti yanjú ọ̀ràn yìí ni pé kí òun fún Sátánì láyè láti fi hàn bóyá òótọ́ lọ̀rọ̀ tó sọ yìí. Torí náà, Ọlọ́run fàyè gba Sátánì láti ṣàkóso ayé fún ìgbà díẹ̀. Ọlọ́run kọ́ ló ń ṣàkóso ayé, Sátánì ni, ìdí nìyẹn tí ìyà fi pọ̀ gan an láyé. * Àmọ́ o, ìròyìn ayọ̀ wà.

Ṣadé: Ṣé lóòótọ́?

Bọ́lá: Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì kọ́ sọ nǹkan pàtàkì méjì nípa Ọlọ́run. Àkọ́kọ́ ni pé, tá a ba ń jìyà, inú Jèhófà kì í dùn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọba Dáfídì wà láyé, ó ní ìṣòro tó pọ̀. Síbẹ̀, ẹ wo sí ohun tó sọ nígbà tó gbàdúrà sí Ọlọ́run nínu Sáàmù 31:7. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kà á.

Ṣadé: Ó sọ pe: “Èmi yóò kún fún ìdùnnú nítorí ìfẹ́ adúróṣinṣin tí o fi hàn sí mi, torí o ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́; o sì mọ ìdààmú ọkàn mi.”

Bọ́lá: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì jìyà gan-an, ohun tó tù ú nínú ni bó ṣe mọ̀ pé Jèhófà rí gbogbo ìṣòro tó ń bá òun fínra. Ọ̀rọ̀ ìtùnú ni èyí jẹ́ fún àwa náà pé Jèhófà ń rí gbogbo ìṣòro tí a ní, kódà ó mọ ẹ̀dùn ọkàn wa tó lè má yé àwọn ẹlòmíì.

Ṣadé: Háà! Ọ̀rọ̀ ìtùnú ni lóòótọ́.

Bọ́lá: Òtítọ́ kejì tó ṣe pàtàkì ni pé, Ọlọ́run ò ní gbà kí ìyà yìí máa báa nìṣó. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìṣàkóso burúkú Sátánì láìpẹ́. Á mú gbogbo ìwà ibi kúrò pátápátá, títí kan gbogbo ohun tí ẹ̀yin àti mọ́mì yin ń fara dà báyìí. Àmọ́ màá fẹ́ kí a jọ jíròrò ìbéèrè pàtàkì kan tó sọ pé, kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé láìpẹ́? Ṣé kí n pa dà wá lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ ká jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. *

Ṣadé: Kò burú, màá máa retí yín.

Ǹjẹ́ o ní ìbéèrè kan nínú Bíbélì tó ò ń ṣe kàyéfì nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀kan lára ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́ra láti béèrè ohun náà lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá bá pàdé. Inú rẹ̀ yóò dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.