Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí O Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu Nígbà Ọ̀dọ́

Bí O Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu Nígbà Ọ̀dọ́

‘Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá, ẹ máa yin orúkọ Jèhófà.’—SM. 148:12, 13.

1. Àwọn àǹfààní àgbàyanu wo ni ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń gbádùn?

ÀKÓKÒ mánigbàgbé la wà yìí. Ìdí ni pé lọ́nà tá ò tíì rí irú rẹ̀ rí, ńṣe ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ń wá sínú ìjọsìn tòótọ́ láti gbogbo orílẹ̀-èdè. (Ìṣí. 7:9, 10) Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń ní ìrírí alárinrin bí wọ́n ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye òtítọ́ Bíbélì tó ń gbani là. (Ìṣí. 22:17) Àwọn kan lára àwọn ọ̀dọ́ yìí ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa. Ìtara tí àwọn míì ní fún wíwàásù ìhìn rere ti mú kí wọ́n lọ sáwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. (Sm. 110:3; Aísá. 52:7) Báwo lo ṣe lè máa ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ táwọn èèyàn Jèhófà ń ṣe yìí kó o lè ní ìtẹ́lọ́rùn pé ò ń ṣe ìwọ̀n tó o lè ṣe?

2. Báwo ni àpẹẹrẹ Tímótì ṣe fi hàn pé Jèhófà ṣe tán láti fa iṣẹ́ lé àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

2 Ní báyìí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, o lè ṣe àwọn ìpinnu táá jẹ́ kó o lè gbádùn ọ̀pọ̀ àǹfààní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, ó dájú pé Tímótì tó wá láti ìlú Lísírà ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ìyẹn ló sì mú kó di míṣọ́nnárì nígbà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún tàbí tó lé díẹ̀ lógún ọdún. (Ìṣe 16:1-3) Ó jọ pé ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, àtakò gbígbóná janjan mú kó di dandan fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kúrò ní ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nílùú Tẹsalóníkà. Ó wá fa iṣẹ́ lé Tímótì tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ lọ́wọ́ pé kó pa dà sí ìlú Tẹsalóníkà kó lè fún àwọn ará tó wà níbẹ̀ lókun. (Ìṣe 17:5-15; 1 Tẹs. 3:1, 2, 6) Ṣé o lè fojú inú wo bó ṣe máa rí lára  Tímótì nígbà tí Pọ́ọ̀lù fa iṣẹ́ yẹn lé e lọ́wọ́?

ÌPINNU TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ LỌ TÓ O LÈ ṢE

3. Ìpinnu wo ló ṣe pàtàkì jù lọ tó o lè ṣe, ìgbà wo lo sì lè ṣe é?

3 Ìgbà ọ̀dọ́ ló dáa kéèyàn ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Àmọ́ ìpinnu kan wà tó ṣe pàtàkì ju àwọn ìpinnu yòókù lọ, ìyẹn ni ìpinnu tó o ṣe pé Jèhófà ni wàá sìn. Ìgbà wo ló dára jù lọ pé kó o ṣe ìpinnu yẹn? Jèhófà sọ pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá . . . ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” (Oníw. 12:1) Ọ̀nà kan ṣoṣo tí Jèhófà fẹ́ kó o gbà “rántí” òun ni pé kó o fi gbogbo ayé rẹ sin òun. (Diu. 10:12) Ìpinnu tó o ṣe pé wàá fi gbogbo ọkàn rẹ sin Ọlọ́run ni ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o lè ṣe. Ó sì máa nípa lórí ìgbésí ayé rẹ.—Sm. 71:5.

4. Yàtọ̀ sí bó o ṣe pinnu láti sin Jèhófà, àwọn ìpinnu pàtàkì míì wo ló máa nípa lórí bó o ṣe ń sin Ọlọ́run?

4 Àmọ́, ìpinnu tó o ṣe pé wàá sin Jèhófà kọ́ ni ìpinnu kan ṣoṣo tó máa nípa lórí ọjọ́ iwájú rẹ o! Bí àpẹẹrẹ, o tún lè máa ronú nípa bóyá kó o lọ́kọ tàbí kó o láya, ẹni tó o máa fẹ́ àti iṣẹ́ tí wàá fi máa gbọ́ bùkátà ara rẹ. Àwọn ìpinnu yìí ṣe pàtàkì gan-an, àmọ́ ó bọ́gbọ́n mu pé kó o kọ́kọ́ pinnu bóyá wàá fẹ́ fi gbogbo ayé rẹ sin Jèhófà. (Diu. 30:19, 20) Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ìpinnu náà wọnú ara wọn. Ìpinnu tó o bá ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti iṣẹ́ máa nípa lórí bó o ṣe máa sin Ọlọ́run. (Fi wé Lúùkù 14:16-20) Bákan náà, bó o ṣe fẹ́ láti sin Ọlọ́run máa nípa lórí irú ẹni tí wàá fẹ́ àti irú iṣẹ́ tí wàá fẹ́ ṣe. Torí náà, kọ́kọ́ ṣe ìpinnu lórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ.—Fílí. 1:10.

KÍ LO FẸ́ FI ÌGBÀ Ọ̀DỌ́ RẸ ṢE?

5, 6. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé téèyàn bá ṣe àwọn ìpinnu tó dára, ó máa ní àwọn ìrírí alárinrin tó bá yá. (Tún wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ìpinnu Tí Mo Ṣe Nígbà Tí Mo Wà ní Kékeré,” èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí.)

5 Tó o bá ti pinnu pé wàá sin Ọlọ́run, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ohun tó fẹ́ kó o ṣe, kó o sì wá pinnu wàá ṣe sìn ín. Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Japan kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá [14], alàgbà kan tí èmi àti ẹ̀ jọ jáde òde ẹ̀rí kíyè sí i pé ọkàn mi ò fi bẹ́ẹ̀ sí nínú iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Ó wá fi ẹ̀sọ̀ sọ fún mi pé: ‘Yuichiro, máa lọ sílé. Tó o bá délé, jókòó sídìí tábìlì ìkọ̀wé rẹ kó o sì fara balẹ̀ ronú lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ.’ Mo ṣe bó ṣe sọ. Kódà, ńṣe ni mò ń ronú tí mo sì ń gbàdúrà fún ọjọ́ mélòó kan. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìṣarasíhùwà mi yí pa dà. Kò sì pẹ́ tí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn mọ́ mi. Mo gbádùn kí n máa kà nípa àwọn míṣọ́nnárì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bí màá ṣe túbọ̀ sin Ọlọ́run.”

6 Yuichiro ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìpinnu tó máa jẹ́ kí n lè sin Jèhófà nílẹ̀ òkèèrè nígbà tó bá yá. Bí àpẹẹrẹ, mo yàn láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà tí mo parí iléèwé, mo yàn láti máa ṣe iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní èdè Gẹ̀ẹ́sì kí n lè máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tí mo pé ọmọ ogún [20] ọdún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Mongolian mo sì láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwùjọ àwọn akéde kan tí wọ́n ń sọ èdè Mongolian. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 2007, mo lọ sí orílẹ̀-èdè Mòǹgólíà. Nígbà tí mo bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan tó wà níbẹ̀ jáde òde ẹ̀rí, tí mo sì rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ mọ òtítọ́, ó wù mí pé kí n kó lọ síbẹ̀ kí n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Mo bá pa dà sí orílẹ̀-èdè Japan láti ṣètò bí màá ṣe lọ. Mo ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní orílẹ̀-èdè Mòǹgólíà láti oṣù April, ọdún 2008. Nǹkan ò rọrùn lórílẹ̀-èdè Mòǹgólíà. Àmọ́ àwọn èèyàn ń gbọ́ ìhìn rere tá à ń wàásù rẹ̀, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà. Mo gbà pé ohun tí mo yàn yìí ni ọ̀nà tó dára jù lọ tí mo lè gbà lo ayé mi.”

7. Àwọn nǹkan wo ló pọn dandan kí àwa fúnra wa yàn láti ṣe, àpẹẹrẹ wo sì ni Mósè fi lélẹ̀ fún wa?

7 Ó pọn dandan pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa  yan bó ṣe máa lo ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Jóṣ. 24:15) Ó ṣe tán, a ò lè sọ pé kó o ṣe ìgbéyàwó tàbí kó o má ṣe é, a ò sì lè sọ ẹni tó yẹ kó o fẹ́ tàbí iṣẹ́ tó yẹ kó o ṣe. Ṣé iṣẹ́ tí kò gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ lo máa yàn láti ṣe? Ohun mìíràn ni pé abúlé táwọn èèyàn ò ti lówó lọ́wọ́ làwọn kan lára ẹ̀yìn ọ̀dọ́ Kristẹni ń gbé, àwọn míì lára yín sì ń gbé láwọn ìlú tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Àti pé ibi yòówù kẹ́ ẹ wà láyé, ìwà yín, agbára yín, ìrírí yín, ohun tó ń wù yín àti ìwọ̀n ìgbàgbọ́ tẹ́ ẹ ní yàtọ̀ síra gan-an ni. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ yín yàtọ̀ sí ti àwọn ọ̀dọ́ Hébérù tó gbé ní ìlú Íjíbítì ìgbàanì, bí ọ̀rọ̀ tiwọn náà ṣe yàtọ̀ sí ti Mósè. Gbogbo àǹfààní tó wà láàfin ọba ló tẹ Mósè lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ẹrú ni àwọn Hébérù yòókù. (Ẹ́kís. 1:13, 14; Ìṣe 7:21, 22) Bíi tẹ̀yin ọ̀dọ́ òde òní, àkókò mánigbàgbé làwọn náà gbé. (Ẹ́kís. 19:4-6) Ńṣe ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní láti yan ohun tó máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Mósè sì yan ohun tó tọ́.—Ka Hébérù 11:24-27.

8. Ibo lẹ̀yin ọ̀dọ́ ti lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà tẹ́ ẹ bá ń yan ohun tẹ́ ẹ máa fi ìgbésí ayé yín ṣe?

8 Jèhófà ń ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nígbà tẹ́ ẹ ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Ó ń gbà yín nímọ̀ràn nípasẹ̀ àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ lè fi sílò nínú àwọn ipò tó bá dojú kọ yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Sm. 32:8) Bákan náà, àwọn òbí yín tí wọ́n jẹ́ Kristẹni àtàwọn alàgbà ìjọ lè fèrò wérò pẹ̀lú yín kẹ́ ẹ lè mọ bẹ́ ẹ ṣe máa fi àwọn ìlànà náà sílò. (Òwe 1:8, 9) Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìlànà pàtàkì mẹ́ta látinú Bíbélì tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè yan àwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu, táá sì ṣe yín láǹfààní lọ́jọ́ iwájú.

ÀWỌN ÌLÀNÀ MẸ́TA LÁTINÚ BÍBÉLÌ TÓ LÈ TỌ́ Ẹ SỌ́NÀ

9. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe pọ́n wa lé bó ṣe fún wa lómìnira láti yan ohun tá a fẹ́? (b) Àwọn àǹfààní wo ni wíwá ‘Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́’ mú kó ṣí sílẹ̀ fún wa?

9 Máa wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. (Ka Mátíù 6:19-21, 24-26, 31-34.) Jèhófà yẹ́ wa sí ní ti pé ó fún wa lómìnira láti yan ohun tá a fẹ́. Kò sọ iye ọdún tó yẹ kó o fi tara bọ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run nígbà tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Àmọ́ Jésù fún wa ní ìlànà tó máa ràn wá lọ́wọ́, ìyẹn sì ni pé ká máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Bó o bá ṣe ń fi ohun tó sọ yìí sílò ló máa jẹ́ kó o lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, pé ọ̀rọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ jẹ ọ́ lógún àti pé o mọrírì ìyè àìnípẹ̀kun tó ò ń retí. Torí náà, bó o ṣe ń yiiri ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti iṣẹ́ wò, rò ó dáadáa bóyá àwọn ìpinnu tó o ṣe á mú kó o máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tó o nílò nípa tara tàbí á mú kó o máa fìtara wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo Rẹ̀.

10. Kí ló mú kí Jésù láyọ̀, àwọn ìpinnu wo ló sì máa mú kí ìwọ náà láyọ̀?

10 Máa ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì kó o lè láyọ̀. (Ka Ìṣe 20:20, 21, 24, 35.) Jésù ló fìfẹ́ kọ́ wa pé ká máa fi ìlànà pàtàkì yìí sílò nínú ìgbésí ayé wa. Inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an torí pé kì í ṣe ìfẹ́ inú ara rẹ̀, ìfẹ́ inú Baba rẹ̀ ló máa ń ṣe. Jésù máa ń láyọ̀ bó ṣe ń rí i táwọn ọlọ́kàn tútù ń tẹ́tí sí ìhìn rere. (Lúùkù 10:21; Jòh. 4:34) Ó ṣeé ṣe kí ìwọ alára ti ní ìrírí ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Tó o bá sì ń gbé àwọn ìpinnu pàtàkì tó ò ń ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ karí àwọn ìlànà tí Jésù fi kọ́ wa, ó dájú pé wàá láyọ̀, wàá sì múnú Jèhófà dùn.—Òwe 27:11.

11. Kí nìdí tí Bárúkù fi pàdánù ayọ̀ tó ní? Ìmọ̀ràn wo ni Jèhófà fún un?

11 Ohun tó lè mú kéèyàn láyọ̀ jù lọ ni pé kó máa ṣiṣẹ́ sin Jèhófà. (Òwe 16:20) Ó jọ pé Bárúkù tó jẹ́ akọ̀wé Jeremáyà gbàgbé pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Láwọn àkókò kan, kò fi bẹ́ẹ̀ gbádùn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà mọ́. Jèhófà wá sọ fún un pé: “Ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́. Nítorí kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara, . . . èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ bí ohun ìfiṣèjẹ ní gbogbo ibi tí ìwọ bá lọ.” (Jer. 45:3, 5) Kí lèrò rẹ? Kí ni ì bá ti mú kí Bárúkù láyọ̀? Ṣé wíwá àwọn nǹkan ńláńlá ni àbí  líla ìparun Jerúsálẹ́mù já gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run?—Ják. 1:12.

12. Ìpinnu wo ni Ramiro ṣe tó mú kó gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀?

12 Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ramiro rí ayọ̀ nínú kéèyàn máa ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì. Ó sọ pé: “Tálákà làwọn òbí mi, abúlé kan tó wà nítòsí àwọn Òkè Andes là ń gbé. Torí náà, àǹfààní ńlá ló jẹ́ nígbà tí bùrọ̀dá mi sọ pé òun máa rán mi lọ sí yunifásítì. Àmọ́, mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn ni àti pé aṣáájú-ọ̀nà kan sọ pé kí n wá bá òun ká jọ máa wàásù ní ìlú kékeré kan. Mo lọ síbẹ̀, mo kọ́ṣẹ́ irun gígẹ̀, mo ṣí ṣọ́ọ̀bù bábà, owó tí mò ń rí níbẹ̀ ni mo sì fi ń gbọ́ bùkátà ara mi. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ni wọ́n mọrírì rẹ̀ tí wọ́n sì ní ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, mo dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀. Ọdún kẹwàá rèé tí mo ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Kò sí iṣẹ́ míì tó lè fún mi nírú ayọ̀ ti mò ń rí bí mo ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè ìbílẹ̀ wọn.”

Láti ìgbà tí Ramiro ti wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti ń rí ayọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 12)

13. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìgbà ọ̀dọ́ ló dáa jù kéèyàn fi gbogbo okun tó ní sin Jèhófà?

13 Gbádùn sísin Jèhófà nígbà tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. (Ka Oníwàásù 12:1.) Kò yẹ kó o ronú pé o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ní iṣẹ́ gidi lọ́wọ́ kó o tó wá sin Jèhófà. Ìgbà ọ̀dọ́ ló dáa jù kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo okun tó ní sin Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò fi bẹ́ẹ̀ ní bùkátà tí wọ́n ń bójú tó, wọ́n sì ní ìlera àti okun tí wọ́n fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ tó lágbára. Kí ni wàá fẹ́ ṣe fún Jèhófà nígbà tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́? Bóyá àfojúsùn rẹ ni pé kó o ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó lè wù ẹ́ pé kó o lọ sí ìpínlẹ̀ táwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè wà. Tàbí kẹ̀, o lè ti rí àwọn ọ̀nà tí wàá gbà ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ tó o wà báyìí. Àfojúsùn yòówù kó o ní nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ó pọn dandan pé kó o wá bí wàá ṣe máa gbọ́ bùkátà ara rẹ. Báwo ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó o nílò  ṣe máa gbà ẹ́ lákòókò tó? Kí ni wàá yàn láti ṣe?

MÁA LO ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ LÁTI ṢE ÌPINNU TÓ BỌ́GBỌ́N MU

14. Kí ló yẹ kéèyàn ṣọ́ra fún tó bá ń wéwèé ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?

14 Àwọn ìlànà mẹ́ta látinú Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yan irú iṣẹ́ tí wàá ṣe. Kò sí àní-àní pé àwọn agbaninímọ̀ràn iléèwé rẹ mọ àwọn iṣẹ́ tó wà lágbègbè rẹ. Ó sì lè jẹ́ pé àjọ kan tí ìjọba gbé kalẹ̀ ló máa sọ iṣẹ́ tó ṣí sílẹ̀ lágbègbè rẹ tàbí níbi tó o ti fẹ́ lọ sìn. Òótọ́ ni pé àwọn ìsọfúnni yìí lè wúlò, àmọ́ ṣọ́ra o! Àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lè gbìyànjú láti mú kó o nífẹ̀ẹ́ ayé. (1 Jòh. 2:15-17) Tó o bá ń wo àwọn nǹkan tí ayé ń gbé jáde, wẹ́rẹ́ báyìí ni ọkàn rẹ máa tàn ẹ́ jẹ.—Ka Òwe 14:15; Jer. 17:9.

15, 16. Ọ̀dọ̀ àwọn wo lo ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dára jù lọ lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́?

15 Lẹ́yìn tó o bá ti mọ àwọn iṣẹ́ tó ṣí sílẹ̀ fún ẹ láti ṣe, o nílò ìmọ̀ràn tó yè kooro. (Òwe 1:5) Ta ló lè jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe fi àwọn ìlànà Bíbélì yan irú iṣẹ́ tí wàá ṣe? Tẹ́tí sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ, tí wọ́n mọ̀ ẹ́, tí wọ́n sì mọ ipò tó o wà dáadáa. Wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara balẹ̀ ronú nípa ẹ̀bùn tó o ní àti ohun tó wà lọ́kàn rẹ. Ó ṣeé ṣe kí ohun tí wọ́n sọ mú kó o tún àfojúsùn rẹ gbé yẹ̀ wò. Tó o bá tún wá ní àwọn òbí tí wọ́n fẹ́ràn Jèhófà, a jẹ́ pé àǹfààní ńlá lo ní yẹn! Bákan náà, àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ rẹ jẹ́ àwọn ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn tí wọ́n lè tọ́ ẹ sọ́nà. O tún lè béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. O lè bi wọ́n pé kí nìdí tí wọ́n fi yàn láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún? Báwo ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, iṣẹ́ wo ni wọ́n sì fi gbọ́ bùkátà ara wọn? Ìtẹ́lọ́rùn wo ni wọ́n ti rí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn?—Òwe 15:22.

16 Àwọn tó mọ̀ ẹ́ dáadáa máa lo ìfòyemọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fún ẹ nímọ̀ràn. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé torí ohun tó o ṣe fẹ́ fi ilé ẹ̀kọ́ girama sílẹ̀ kó o lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni pé o kò fẹ́ràn iṣẹ́ àṣekára tẹ́ ẹ̀ ń ṣe níléèwé. Ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ rẹ lè fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ gan-an kó wá jẹ́ kó o mọ̀ pé lára ohun tó o máa kọ́ níléèwé ni bó o ṣe lè ní ìforítì. Ó sì yẹ kó o ní ìforítì tó o bá máa fi gbogbo agbára rẹ sin Jèhófà.—Sm. 141:5; Òwe 6:6-10.

17. Àwọn ìpinnu wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún?

17 Gbogbo ẹni tó bá ń sin Jèhófà máa dojú kọ àwọn ewu tẹ̀mí, ìyẹn àwọn nǹkan tó lè fani kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:33; Kól. 2:8) Àmọ́, àwọn iṣẹ́ kan wà tí wọ́n lè ba àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ju irú àwọn iṣẹ́ mìíràn lọ. Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan ládùúgbò rẹ tí “ọkọ̀ ìgbàgbọ́” wọn rì látàrí irú iṣẹ́ tí wọ́n yàn. (1 Tím. 1:19) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o yẹra fún ṣíṣe àwọn ìpinnu tó lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.—Òwe 22:3.

GBÁDÙN ÌGBÀ Ọ̀DỌ́ RẸ

18, 19. Tí kò bá tíì wu ẹnì kan pé kó sin Jèhófà, kí ló yẹ kó ṣe?

18 Tó bá jẹ́ pé àtọkànwá ló ti wù ẹ́ pé kó o sin Jèhófà, rí i pé o lo gbogbo àǹfààní tó o ní láti sin Ọlọ́run ní báyìí tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Ṣe àwọn ìpinnu tó máa mú kó o gbádùn bó o ṣe ń sin Jèhófà láwọn àkókò amóríyá yìí.—Sm. 148:12, 13.

19 Àmọ́ tí kò bá ṣe ẹ́ bíi pé kó o sin Jèhófà, kí ló yẹ kó o ṣe? Má ṣe jáwọ́ nínú ṣíṣe ohun tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lókun. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ bó ṣe sapá láti máa gbé ìgbé ayé táá mú kó rí ìbùkún Ọlọ́run, ó sọ pé: “Bí ẹ bá sì ní èrò orí tí ó tẹ̀ sí ibòmíràn lọ́nà èyíkéyìí, Ọlọ́run yóò ṣí ẹ̀mí ìrònú tí ó wà lókè yìí payá fún yín. Bí ó ti wù kí ó rí, dé àyè tí a ti tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní rírìn létòletò nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yìí.” (Fílí. 3:15, 16) Túbọ̀ máa ronú lórí ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n rẹ̀. Ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nígbà ọ̀dọ́ rẹ.