Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Yin Kristi, Ọba Ògo!

Ẹ Yin Kristi, Ọba Ògo!

“Nínú ọlá ńlá rẹ, kí o tẹ̀ síwájú dé àṣeyọrí sí rere.”SM. 45:4.

1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ohun tó wà nínú Sáàmù 45?

ỌBA ògo kan ń jagun nítorí òtítọ́ àti òdodo, ó sì ń gẹṣin lọ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. Lẹ́yìn tó ti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run pátápátá, ó gbé aya rẹ̀ ọ̀wọ́n níyàwó. Láti ìran dé ìran làwọn èèyàn ń rántí ọba náà wọ́n sì ń kan sáárá sí i. Ohun tí ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 45 dá lé nìyẹn.

2 Kì í ṣe pé Sáàmù 45 jẹ́ ìtàn alárinrin tó parí síbi tó dáa nìkan ni, àwọn ohun tó wà níbẹ̀ kàn wá gbọ̀ngbọ̀n. Wọ́n kan ìgbésí ayé wa ìsinsìnyí àti ti ọjọ́ iwájú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú Sáàmù yìí kínníkínní.

‘ỌKÀN MI TI GBÉ FÚKẸ́ NÍPA Ọ̀RÀN KAN TÍ Ó JỌJÚ’

3, 4. (a) “Ọ̀ràn kan tí ó jọjú” wo ló kàn wá, báwo ló sì ṣe lè nípa lórí ọkàn wa? (b) Ọ̀nà wo la lè gbà sọ pé ‘iṣẹ́ wa jẹ́ nípa ọba kan,’ báwo sì ni ahọ́n wa ṣe dà bíi kálàmù?

3 Ka Sáàmù 45:1. “Ọ̀ràn kan tí ó jọjú” tó wọ onísáàmù náà lọ́kàn tó sì mú kí ọkàn rẹ̀ “gbé fúkẹ́” ní í ṣe pẹ̀lú ọba kan. Ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù tá a túmọ̀ sí “gbé fúkẹ́” túmọ̀ sí “tú sókè,” tàbí “hó.” Ọ̀ràn yìí mú kí ọkàn onísáàmù náà máa hó pẹ̀lú ìtara, ó sì mú kí ahọ́n rẹ̀ dà bíi “kálàmù ọ̀jáfáfá adàwékọ.”

 4 Àwa ńkọ́? Ìhìn rere Ìjọba Mèsáyà jẹ́ ohun kan tó jọjú tó wọ àwa náà lọ́kàn. Ọdún 1914 ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tún wá “jọjú” lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Látọdún yẹn wá, ìhìn rere náà kì í ṣe nípa Ìjọba kan tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú mọ́, bí kò ṣe nípa ìjọba gidi kan tó ti ń ṣàkóso báyìí ní òkè ọ̀run. Èyí ni “ìhìn rere ìjọba” tá à ń wàásù rẹ̀ “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14) Ǹjẹ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ń mú kí ọkàn tiwa náà “gbé fúkẹ́”? Ǹjẹ́ à ń fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba náà? Bíi ti onísáàmù, ‘iṣẹ́ wa jẹ́ nípa ọba kan,’ ìyẹn Jésù Kristi Ọba wa. À ń polongo pé òun ni Ọba Ìjọba Mèsáyà tí a ti gbé gorí ìtẹ́ lókè ọ̀run. Bákan náà, à ń pe gbogbo èèyàn, àwọn alákòóso àtàwọn ọmọ abẹ́ wọn, pé kí wọ́n wá fi ara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀. (Sm. 2:1, 2, 4-12) Ahọ́n wa sì dà bíi “kálàmù ọ̀jáfáfá adàwékọ” ní ti pé à ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa.

À ń fayọ̀ polongo ìhìn rere nípa Jésù Kristi, Ọba wa

‘Ọ̀RỌ̀ ALÁRINRIN Ń TI ÈTÈ ỌBA JÁDE’

5. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà “rẹwà”? (b) Báwo ni ‘àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin ṣe ń jáde láti ẹnu Ọba,’ báwo la sì ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

5 Ka Sáàmù 45:2. Ìwé Mímọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìrísí Jésù. Kò sí iyè méjì pé ó “rẹwà,” torí pé ẹni pípé ni. Àmọ́, ohun tó mú kí ẹwà rẹ̀ ta yọ ni pé ó jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jèhófà, kò sì gbà kí ohunkóhun ba ìwà títọ́ òun jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù lo “àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin” nígbà tó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 4:22; Jòh. 7:46) Ǹjẹ́ olúkúlùkù wa náà ń sapá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ bá a ṣe ń wàásù? Ṣé a sì tún ń sapá láti máa lo àwọn ọ̀rọ̀ táá wọ àwọn èèyàn lọ́kàn?—Kól. 4:6.

6. Báwo ni Ọlọ́run ṣe bù kún Jésù “fún àkókò tí ó lọ kánrin”?

6 Torí pé Jésù sin Jèhófà tọkàntọkàn, Jèhófà bù kún un nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó sì tún san án lẹ́san lẹ́yìn tó kú ikú ìrúbọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí [Jésù] rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró. Fún ìdí yìí gan-an pẹ̀lú ni Ọlọ́run fi gbé e sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.” (Fílí. 2:8-11) Jèhófà bù kún Jésù “fún àkókò tí ó lọ kánrin” ní ti pé ó jí i dìde sí ìyè àìleèkú.—Róòmù 6:9.

ỌLỌ́RUN GBÉ ỌBA NÁÀ GA JU “ÀWỌN ALÁJỌṢE” RẸ̀ LỌ

7. Àwọn ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà yan Jésù ju “àwọn alájọṣe” rẹ̀ lọ?

7 Ka Sáàmù 45:6, 7. Jésù ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún òdodo ó sì kórìíra ohunkóhun tó lè tàbùkù sí Baba rẹ̀, Jèhófà. Nítorí náà, Jèhófà yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Mèsáyà. Ó “fòróró ayọ̀ ńláǹlà” yan Jésù ju “àwọn alájọṣe,” rẹ̀, ìyẹn àwọn ọba Júdà tó ti ìlà ìdílé Dáfídì wá. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ohun kan ni pé, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yan Jésù. Ó tún wá yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Àlùfáà Àgbà. (Sm. 2:2; Héb. 5:5, 6)  Ní àfikún sí ìyẹn, ẹ̀mí mímọ́ ni Ọlọ́run fi yan Jésù, ìṣàkóso rẹ̀ kò sì ní jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé bí kò ṣe ní òkè ọ̀run.

8. Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé ‘Ọlọ́run ni ìtẹ́ Jésù’? Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé ó máa fi òdodo ṣàkóso?

8 Ọdún 1914 ni Jèhófà gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ìtẹ́ ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba. “Ọ̀pá aládé àkóso rẹ̀ jẹ́ ọ̀pá aládé ìdúróṣánṣán,” torí náà ó dájú pé ó máa fi òdodo ṣàkóso kò sì ní ṣe ojúsàájú. Ọlá àṣẹ rẹ̀ bófin mu, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ‘Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ̀.’ Ìyẹn ni pé, Jèhófà ni ìpìlẹ̀ ìjọba rẹ̀. Síwájú sí i, ìtẹ́ Jésù máa wà “fún àkókò tí ó lọ kánrin,” tàbí títí láé. Ǹjẹ́ kò wú ẹ lórí láti máa sin Jèhófà lábẹ́ iru Ọba alágbára tí Ọlọ́run yàn sípò yìí?

ỌBA NÁÀ ‘SÁN IDÀ RẸ̀’

9, 10. (a) Ìgbà wo ni Kristi sán idà rẹ̀, báwo ló sì ṣe lò ó láìjáfara? (b) Báwo ni Kristi tún ṣe máa lo idà rẹ̀?

9 Ka Sáàmù 45:3. Jèhófà fún Ọba rẹ̀ ní ìtọ́ni pé kó “sán idà [rẹ̀] mọ́” ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fún Jésù ní àṣẹ pé kó bá gbogbo àwọn tó ta ko ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ jagun kó sì mú ìdájọ́ Òun ṣẹ lé wọn lórí. (Sm. 110:2) Torí pé Kristi jẹ́ Ọba Ajagun tí ẹnikẹ́ni ò lè borí, Bíbélì pè é ní “ìwọ alágbára ńlá.” Ọdún 1914 ló sán idà rẹ̀. Ó ṣẹ́gun Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, ó sì fi wọ́n sọ̀kò sí sàkáání ilẹ̀ ayé.—Ìṣí. 12:7-9.

10 Ńṣe nìyẹn wulẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ bí Ọba náà ṣe máa ja àjàṣẹ́gun. Ó ṣì ní láti “parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣí. 6:2) Ó ṣì ní láti mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ sórí gbogbo apá tí ètò Sátánì pín sí lórí ilẹ̀ ayé, ó sì tún máa sọ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ di asán. Ó máa kọ́kọ́ mú Bábílónì Ńlá, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé kúrò. Jèhófà ti pinnu pé òun máa lo àwọn olóṣèlú láti pa “aṣẹ́wó” búburú yìí run. (Ìṣí 17:16, 17) Lẹ́yìn náà, Ọba Ajagun náà máa gbéjà ko ètò òṣèlú ayé Sátánì yìí, á sì sọ ọ́ di asán. Kristi, tí Bíbélì tún pè ní “áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà” máa wá parí ìṣẹ́gun rẹ̀ nípa jíju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. (Ìṣí. 9:1, 11; 20:1-3) Ẹ jẹ́ ká wo bí Sáàmù 45 ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá yìí.

ỌBA NÁÀ Ń GẸṢIN “NÍTORÍ ÒTÍTỌ́”

11. Báwo ni Kristi ṣe ń ‘gẹṣin nítorí òtítọ́’?

11 Ka Sáàmù 45:4. Kì í ṣe nítorí kí Ọba Ajagun náà lè gba ilẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ tàbí nítorí kó lè tẹ̀ wọ́n lórí ba ló fi ń jagun. Ohun rere ló ní lọ́kàn bó ṣe ń jagun òdodo yìí. Ó ń gẹṣin “nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo.” Òtítọ́ tó ga jù lọ tó gbọ́dọ̀ gbèjà rẹ̀ ni pé Jèhófà ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ìdí sì ni pé nígbà tí Sátánì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ńṣe ló fẹ̀sùn kàn án pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso. Látìgbà yẹn wá ni àwọn ẹ̀mí èṣù àtàwọn èèyàn ti ń ta ko ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti ṣàkóso. Ó ti wá tó àkókò bàyìí fún Ọba tí Jèhófà fẹ̀mí yàn láti máa gẹṣin, ìyẹn ni pé kó máa jagun, kó lè hàn títí gbére pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ.

12. Báwo ni Ọba náà ṣe ń gẹṣin ‘nítorí ìrẹ̀lẹ̀’?

12 Ọba náà tún ń gẹṣin ‘nítorí ìrẹ̀lẹ̀.’ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká sì tún fi ara wa sábẹ́ Baba rẹ̀ tó jẹ́ ọba aláṣẹ. (Aísá. 50:4, 5; Jòh. 5:19) Nínú ohunkóhun tí gbogbo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọba yìí bá ń ṣe, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ kí wọ́n sì fi ara wọn sábẹ́ Jèhófà tó jẹ́ ọba aláṣẹ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. Àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan ló máa láǹfààní láti gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.—Sek. 14:16, 17.

13. Báwo ni Kristi ṣe ń gẹṣin lọ ‘nítorí òdodo’?

 13 Kristi tún ń gẹṣin lọ ‘nítorí òdodo.’ “Òdodo Ọlọ́run” ni Ọba náà ń gbèjà rẹ̀, ìyẹn àwọn ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Róòmù 3:21; Diu. 32:4) Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi Ọba, ó ní: “Ọba kan yóò jẹ fún òdodo.” (Aísá. 32:1) Ìṣàkóso Jésù ló máa mú “ọ̀run tuntun” àti “ilẹ̀ ayé tuntun” wá nínú èyí tí ‘òdodo yóò máa gbé.’ (2 Pét. 3:13) Jèhófà á sì fẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé inú ayé tuntun yẹn máa ṣe ohun tó bá àwọn ìlànà òun mu.—Aísá. 11:1-5.

ỌBA NÁÀ ṢE “ÀWỌN OHUN AMÚNIKÚN-FÚN-Ẹ̀RÙ”

14. Báwo ni ọwọ́ ọ̀tún Kristi á ṣe ṣe “àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù”? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

14 Bí Ọba náà ṣe ń gẹṣin lọ, ó sán idà kan mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. (Sm. 45:3) Àmọ́, àkókò ti tó fún un láti fa idà náà yọ kó sì máa fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jù ú. Onísáàmù náà wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: ‘Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò ṣe àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù.’ (Sm. 45:4) Nígbà tí Jésù Kristi bá ń gẹṣin lọ kó lè mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ó máa ṣe “àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù” lòdì sí àwọn ọ̀tá rẹ̀. A kò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bó ṣe máa pa ètò Sátánì run. Àmọ́, ohun tó máa ṣe á kó ìpayà bá àwọn èèyàn tí kò kọbi ara sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún wọn pé kí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ àkóso Ọba náà. (Ka Sáàmù 2:11, 12.) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa àkókò òpin, ó ní àwọn èèyàn á “máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé; nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì.” Ó wá fi kún un pé: “Wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.”—Lúùkù 21:26, 27.

15, 16. Àwọn wo ni “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” tó máa bá Kristi lọ sójú ogun?

15 Nígbà tí ìwé Ìṣípayá ń sọ bí Ọba náà ṣe ń bọ̀ “pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá” láti wá mú ìdájọ́ ṣẹ, ó sọ pé: “Mo sì rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó! ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a ń pè ní Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́, ó ń ṣèdájọ́, ó sì ń bá ogun lọ nínú òdodo. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ ní ọ̀run ń tẹ̀ lé e lórí àwọn ẹṣin funfun, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, funfun, tí ó mọ́. Idà gígùn mímú sì yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, kí ó lè fi í ṣá àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn. Bákan náà, ó ń tẹ ìfúntí wáìnì ìbínú ìrunú Ọlọ́run Olódùmarè.”—Ìṣí. 19:11, 14, 15.

16 Àwọn wo ni “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” ọ̀run tí wọ́n máa tẹ̀ lé Kristi lọ sójú ogun? Nígbà tí Jésù kọ́kọ́ sán idà rẹ̀ kó lè lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run, “àwọn áńgẹ́lì rẹ̀” wà pẹ̀lú rẹ̀. (Ìṣí. 12:7-9) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu tá a bá parí èrò pé àwọn áńgẹ́lì mímọ́ máa wà lára àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kristi nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Ǹjẹ́ àwọn míì máa wà lára àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀? Jésù ṣèlérí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, tí ó sì pa àwọn iṣẹ́ mi mọ́ títí dé òpin ni èmi yóò fún ní ọlá àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ tí a óò fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí àwọn ohun èlò amọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbà láti ọwọ́ Baba mi.” (Ìṣí. 2:26, 27) Torí náà, àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi, tí wọ́n á ti gba èrè wọn ní ọ̀run nígbà yẹn, máa wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kristi lókè ọ̀run. Àwọn ẹni àmì òróró tí yóò bá Jésù ṣàkóso yìí máa wà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tó bá ń ṣe  “àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù” bó ti ń fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè.

ỌBA NÁÀ PARÍ ÌṢẸ́GUN RẸ̀

17. (a) Kí ni ẹṣin funfun tí Kristi gùn ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni idà àti ọrun náà dúró fún?

17 Ka Sáàmù 45:5. Ọba náà gun ẹṣin funfun kan, èyí tó dúró fún ogun tó mọ́ tó sì jẹ́ ogun òdodo lójú Jèhófà. (Ìṣí. 6:2; 19:11) Yàtọ̀ sí pé Ọba náà ní idà, ọrun tún wà lọ́wọ́ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní ọrun kan; a sì fún un ní adé, ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” Idà àti ọrun náà ṣàpẹẹrẹ àwọn nǹkan tí Kristi máa fi mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

A ó pe àwọn ẹyẹ láti wá palẹ̀ ẹ̀gbin ilẹ̀ ayé mọ́ (Wo ìpínrọ̀ 18)

18. Báwo ni “àwọn ọfà” Kristi ṣe máa di èyí tó “mú”?

18 Onísáàmù náà lo èdè ewì nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “àwọn ọfà” Ọba náà “mú,” ó ‘ń gún ọkàn àwọn ọ̀tá ọba’ ó sì ‘ń mú kí àwọn ènìyàn ṣubú níwájú rẹ̀.’ Òkú á sùn lọ bẹẹrẹbẹ kárí ayé. Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé.” (Jer. 25:33) Àsọtẹ́lẹ̀ kan tó jọ èyí sọ pé: “Mo tún rí áńgẹ́lì kan tí ó dúró nínú oòrùn, ó sì ké jáde pẹ̀lú ohùn rara, ó sì wí fún gbogbo ẹyẹ tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run pé: ‘Ẹ wá níhìn-ín, ẹ kóra jọpọ̀ síbi oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run, kí ẹ lè jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ọba àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ọ̀gágun àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ọkùnrin alágbára àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ẹṣin àti ti àwọn tí ó jókòó sórí wọn, àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara gbogbo ènìyàn, ti òmìnira àti ti ẹrú àti ti àwọn ẹni kékeré àti ńlá.’”—Ìṣí. 19:17, 18.

19. Báwo ni Kristi ṣe máa “tẹ̀ síwájú dé àṣeyọrí sí rere” tí yóò sì parí ìṣẹ́gun rẹ̀?

19 Kristi máa pa ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì run. Lẹ́yìn náà, “nínú ọlá ńlá” rẹ̀ yóò “tẹ̀ síwájú dé àṣeyọrí sí rere.” (Sm. 45:4) Ó máa parí ìṣẹ́gun rẹ̀ nípa jíju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ títí tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Rẹ̀ fi máa pé. (Ìṣí. 20:2, 3) Ńṣe ni Èṣù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ máa dà bí òkú, tí wọ́n ò ní lè ṣe ohunkóhun. Nípa bẹ́ẹ̀, aráyé ò ní sí lábẹ́ ìdarí Sátánì mọ́, wọ́n á sì lè fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọba wọn ológo tó jagunmólú náà tọkàntara. Àmọ́, kó tó di pé ayé máa bẹ̀rẹ̀ sí í di Párádísè díẹ̀díẹ̀, ìdí mìíràn ṣì wà tí àwọn olùgbé ayé á fi bá Ọba wọn àtàwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ lọ́run yọ̀. A máa jíròrò ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ yẹn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.