Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ló mú kí àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní máa “fojú sọ́nà” fún Mèsáyà?

Nígbà ayé Jòhánù Arinibọmi, “àwọn ènìyàn náà ti ń fojú sọ́nà, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ọkàn-àyà wọn nípa Jòhánù pé, ‘Àbí òun ni Kristi náà ni?’” (Lúùkù 3:15) Kí ló lè mú káwọn Júù máa retí pé kí Mèsáyà dé nígbà yẹn? Àwọn ìdí mélòó kan wà tí wọ́n fi lè máa retí rẹ̀ nígbà yẹn.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti bí Jésù, áńgẹ́lì Jèhófà fara han àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń tọ́jú agbo ẹran wọn nínú àwọn pápá tó wà nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (1) Áńgẹ́lì náà sọ pé: “A bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa, ní ìlú ńlá Dáfídì.” (Lúùkù 2:8-11) Lẹ́yìn yẹn, “ògìdìgbó ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run” dara pọ̀ mọ́ áńgẹ́lì náà, “wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ pé: * ‘Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.’”—Lúùkù 2:13, 14.

Ó dájú pé ipa kékeré kọ́ ni ohun táwọn áńgẹ́lì náà sọ ní lórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn onírẹ̀lẹ̀ yẹn. Lójú ẹsẹ̀ ni wọ́n forí lé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nígbà tí wọ́n sì rí Jósẹ́fù àti Màríà àti Jésù ọmọ jòjòló náà, “wọ́n sọ àsọjáde tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ kékeré yìí di mímọ̀.” Látàrí ìyẹn, “gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ . . . ni ẹnu yà sí àwọn ohun tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún wọn.” (Lúùkù 2:17, 18.) Gbólóhùn náà “gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́” fi hàn pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún àwọn mìíràn yàtọ̀ sí Jósẹ́fù àti Màríà. Bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà ṣe ń pa dà lọ sílé, ńṣe ni wọ́n tún “ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń yìn ín fún gbogbo ohun tí wọ́n gbọ́, tí wọ́n sì rí, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ìwọ̀nyí fún wọn.” (Lúùkù 2:20) Ó dájú pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn yẹn ń sọ àwọn ohun rere tí wọ́n ti gbọ́ nípa Kristi náà fún àwọn ẹlòmíì.

Nígbà tí Màríà gbé ọmọkùnrin àkọ́bí rẹ̀ yìí lọ sí Jerúsálẹ́mù kó lè gbé e han Jèhófà bí Òfin Mósè ṣe pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe, Ánà wòlíì obìnrin wà níbẹ̀. Ó “bẹ̀rẹ̀ sí dá ọpẹ́ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọ náà fún gbogbo àwọn tí ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.” (2) (Lúùkù 2:36-38; Ẹ́kís. 13:12) Torí náà, ìròyìn túbọ̀ ń tàn kalẹ̀ pé Mèsáyà náà ti fara hàn.

Nígbà tó ṣe, “àwọn awòràwọ̀ láti àwọn apá ìlà-oòrùn wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n wí pé: ‘Ibo ni ẹni tí a bí ní ọba àwọn Júù wà? Nítorí a rí ìràwọ̀ rẹ̀ nígbà tí a wà ní ìlà-oòrùn, a sì ti wá láti wárí fún un.’” (Mát. 2:1, 2) “Ní gbígbọ́ èyí, ṣìbáṣìbo bá Hẹ́rọ́dù Ọba, àti gbogbo Jerúsálẹ́mù pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀; nígbà tí ó sì  gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí lọ́wọ́ wọn ibi tí a ó ti bí Kristi.” (3) (Mát. 2:3, 4) Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbọ́ pé ẹni tó máa di Mèsáyà ti dé! *

Ìwé Lúùkù 3:15 tá a fa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan sọ pé àwọn Júù kan ń rò pé bóyá Jòhánù Arinibọmi ni Kristi. Àmọ́, Jòhánù mú iyè méjì yẹn kúrò nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi lágbára jù mí lọ, ẹni tí èmi kò tó láti bọ́ sálúbàtà rẹ̀ kúrò. Ẹni yẹn yóò fi ẹ̀mí mímọ́ àti iná batisí yín.” (Mát. 3:11) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Jòhánù fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ yìí á túbọ̀ mú káwọn èèyàn máa fojú sọ́nà fún dídé Mèsáyà.

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ti ṣírò ìgbà tí Mèsáyà máa dé lẹ́yìn tí wọ́n ka àsọtẹ́lẹ̀ nípa àádọ́rin [70] ọ̀sẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 9:24-27? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kò sí ẹ̀rí kankan tá a lè fi tì í lẹ́yìn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ àlàyé tó ta kora làwọn èèyàn ti ṣe nípa àádọ́rin [70] ọ̀sẹ̀ náà nígbà ayé Jésù, kò sì sí èyíkéyìí nínú wọn tó fi ibì kankan jọ bá a ṣe lóye rẹ̀ lóde òní. *

Àwọn Essene jẹ́ ẹ̀ya ìsìn àwọn Júù kan táwọn èèyàn gbà pé wọ́n jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Ohun tí wọ́n fi kọ́ àwọn èèyàn ni pé Mèsáyà méjì ló máa fara hàn lápá ìparí àádọ́rùn-ún lé nírínwó [490] ọdún, àmọ́ a ò lè sọ dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ni àwọn Essene gbé ìṣirò wọn kà. Bó bá sì jẹ́ pé orí rẹ̀ ni wọ́n gbé e kà, ó ṣòro láti gbà gbọ́ pé àwọn Júù lápapọ̀ máa fara mọ́ ìṣirò tí irú ẹ̀ya ìsìn tó ya ara rẹ̀ láṣo yẹn ṣe.

Ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù kan gbà gbọ́ pé àádọ́rin [70] ọ̀sẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ pa tẹ́ńpìlì run ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì parí nígbà tí wọ́n pa tẹ́ńpìlì run lẹ́ẹ̀kejì lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Àwọn kan sì sọ pé àkókò àwọn Mákábì ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ. Torí náà, èrò wọn ò ṣọ̀kan nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣírò àádọ́rin ọ̀sẹ̀ náà.

Ká sọ pé àwọn Júù ti lóye ìṣirò àádọ́rin [70] ọ̀sẹ̀ yẹn dáadáa ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni ni, à bá ronú pé àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni míì ní ọ̀rúndún kìíní á ti lo ẹ̀rí yẹn láti fi hàn pé Jésù Kristi, tí í ṣe Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí náà, dé ní àkókò tó yẹ kó dé. Àmọ́, kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe bẹ́ẹ̀.

Ohun mìíràn wà tó tún yẹ ká fiyè sí. Àwọn tó kọ ìwé ìhìn rere sábà máa ń tọ́ka sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tó ṣẹ sí Jésù Kristi lára. (Mát. 1:22, 23; 2:13-15; 4:13-16) Síbẹ̀, kò sí ìkankan lára wọn tó ṣàlàyé bí àsọtẹ́lẹ̀ àádọ́rin ọ̀sẹ̀ náà ṣe kan wíwá Jésù sórí ilẹ̀ ayé.

Ní àkópọ̀: A ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé àwọn èèyàn lóye ìṣirò àádọ́rin ọ̀sẹ̀ yẹn dáadáa nígbà tí Jésù wà láyé. Àmọ́, àwọn ìwé Ìhìn Rere fún wa ní àwọn ìdí míì tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó mú káwọn èèyàn náà máa “fojú sọ́nà” fún Mèsáyà.

^ ìpínrọ̀ 4 Bíbélì kò sọ pé àwọn áńgẹ́lì náà “kọrin” nígbà tí wọ́n bí Jésù.

^ ìpínrọ̀ 7 A lè bi ara wa pé, Báwo ni àwọn awòràwọ̀ náà ṣe mọ̀ pé “ìràwọ̀” tí wọ́n rí ní Ìlà Oòrùn ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìbí “ọba àwọn Júù”? Àbí wọ́n gbọ́ ìròyìn nípa ìbí Jésù nígbà tí wọ́n ń gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì kọjá lẹ́nu ìrìn àjò wọn ni?

^ ìpínrọ̀ 9 Tó o bá fẹ́ mọ bá a ṣe lóye àsọtẹ́lẹ̀ àádọ́rin ọ̀sẹ̀ náà sí lóde òní, wo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! orí 11.