Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Yín

Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Yín

“Fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó.”—LÉF. 19:32.

1. Ipò tó ń bani nínú jẹ́ wo ni aráyé bá ara wọn?

JÈHÓFÀ ò ní in lọ́kàn rárá pé tá a bá dàgbà ká máa ní àìlera. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fẹ́ ni pé kí tọkùnrin tobìnrin máa gbádùn ìlera pípé nínú Párádísè. Àmọ́ ní báyìí ná, “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora.” (Róòmù 8:22) Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Ọlọ́run bó ṣe ń rí i tí ẹ̀ṣẹ̀ ń sọ àwa èèyàn di ìdàkudà? Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àgbàlagbà làwọn èèyàn ti pa tì lásìkò tí wọ́n túbọ̀ nílò ìrànlọ́wọ́.—Sm. 39:5; 2 Tím. 3:3.

2. Kí nìdí tí àwa Kristẹni fi máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà?

2 Inú àwa èèyàn Jèhófà máa ń dùn pé a ní àwọn àgbàlagbà nínú àwọn ìjọ wa. À ń jèrè látinú ọgbọ́n wọn, àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn sì máa ń fún wa níṣìírí. A rí lára àwọn àgbàlagbà yìí tó jẹ́ bàbá, ìyá tàbí ìbátan ọ̀pọ̀ nínú wa. Síbẹ̀, bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó ti dàgbà yìí ò bá tiẹ̀ bá wa tan, ọ̀rọ̀ wọn ṣì jẹ wá lógún. (Gál. 6:10; 1 Pét. 1:22) Torí náà, ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá jíròrò nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn àgbàlagbà. A tún máa jíròrò nípa ojúṣe tí ìdílé àti ìjọ ní láti bójú tó àwọn àgbàlagbà wa ọ̀wọ́n yìí.

“MÁ ṢE GBÉ MI SỌNÙ”

3, 4. (a) Ẹ̀bẹ̀ tó gba àfiyèsí wo ni ẹni tó kọ Sáàmù kọkànléláàádọ́rin bẹ Jèhófà? (b) Kí ni àwọn àgbàlagbà nínú ìjọ lè béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run?

3 “Ẹni tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Sáàmù 71:9 bẹ Ọlọ́run pé: “Má  ṣe gbé mi sọnù ní àkókò ọjọ́ ogbó; ní àkókò náà tí agbára mi ń kùnà, má ṣe fi mí sílẹ̀.” Ó jọ pé ọ̀rọ̀ inú Sáàmù àádọ́rin tó ní àkọlé náà, “Ti Dáfídì” ló ń bá a nìṣó nínú Sáàmù kọkànléláàádọ́rin yìí. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ Dáfídì ló wà nínú Sáàmù 71:9. Láti kékeré ló ti ń sin Ọlọ́run títí tó fi dàgbà, Jèhófà sì lò ó ní onírúurú ọ̀nà. (1 Sám. 17:33-37, 50; 1 Ọba 2:1-3, 10) Síbẹ̀ náà, Dáfídì ṣì rí i pé ó dára kí òun bẹ Jèhófà pé kó má ṣe dáwọ́ rere tó ń ṣe fún òun dúró.—Ka Sáàmù 71:17, 18.

4 Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti dàgbà ni ọ̀rọ̀ wọn jọ ti Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ogbó ti ń dé, tí àwọn “ọjọ́ oníyọnu àjálù” sì ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí agbára wọn gbé nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Oníw. 12:1-7) Ọ̀pọ̀ wọn ni kò lè ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, títí kan iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́ àwọn náà lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí àwọn máa rí ojúure rẹ̀, kó sì máa tọ́jú àwọn. Àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ adúróṣinṣin yìí lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà àwọn. Ó ṣe tán, irú ohun tí Dáfídì náà gbà ládùúrà nìyẹn nígbà tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ̀wé.

5. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ adúróṣinṣin?

5 Ìwé Mímọ́ mú kó ṣe kedere pé Jèhófà mọyì àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ adúróṣinṣin gan-an ó sì retí pé kí àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa bọlá fún wọn. (Sm. 22:24-26; Òwe 16:31; 20:29) Ìwé Léfítíkù 19:32 sọ pé: “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó, kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ. Èmi ni Jèhófà.” Láìsí àní-àní, ojúṣe ńlá ló jẹ́ láti máa bọlá fún àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ lásìkò tí wọ́n kọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, ojúṣe yẹn ò sì tíì yí pa dà títí dòní. Àmọ́ ṣá o, tó bá di pé ká máa bójú tó wọn ńkọ́? Ojúṣe ta nìyẹn?

OJÚṢE ÌDÍLÉ

6. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa bójú tó àwọn òbí?

6 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Ẹ́kís. 20:12; Éfé. 6:2) Jésù sọ bí òfin yìí ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó dá àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin lẹ́bi torí pé wọ́n kọ̀ láti bójú tó àwọn òbí wọn. (Máàkù 7:5, 10-13) Jésù alára fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń kú lọ lórí òpó igi oró, ó ní kí Jòhánù ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ọ̀wọ́n máa bójú tó ìyá òun, tó ṣeé ṣe kó ti di opó nígbà yẹn.—Jòh. 19:26, 27.

7. (a) Ìlànà wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa bójú tó àwọn òbí? (b) Ọ̀rọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù sọ débẹ̀?

7 Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fún àwọn onígbàgbọ́ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn tó wà nínú agbo ilé wọn. (Ka 1 Tímótì 5:4, 8, 16.) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ débi ìtọ́ni yìí nínú ìwé tó kọ sí Tímótì. Pọ́ọ̀lù jíròrò nípa àwọn tí ìjọ lè fi owó ṣètìlẹ́yìn fún àtàwọn tí wọn ò lè rí irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ gbà. Ó mú kó ṣe kedere pé àwọn tó dìídì ni ojúṣe àtimáa bójú tó àwọn àgbàlagbà tí ọkọ tàbí aya wọn ti kú ni àwọn ọmọ wọn, àwọn ọmọ ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn tó wà nínú òtítọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní sí pé ìjọ ń tọrùn bọ ìnáwó tí kò pọn dandan. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, ọ̀kan lára ọ̀nà tí Kristẹni kan lè gbà fi hàn pé òun ní “ìfọkànsin Ọlọ́run” ni pé kó máa pèsè ohun tí àwọn ẹbí rẹ̀ ṣe aláìní nípa tara fún wọn.

8. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé Bíbélì kò sọ ọ̀nà pàtó tó yẹ ká gbà bójú tó àwọn àgbàlagbà?

8 Ní kúkúrú, ohun àìgbọ́dọ̀máṣe ni fún àwọn ọmọ tó ti dàgbà pé kí wọ́n máa pèsè ohun tara tí àwọn òbí wọn nílò. Òótọ́ ni pé àwọn ẹbí tó jẹ́ onígbàgbọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ, àmọ́ ìyẹn ò ní ká wá pa àwọn ẹbí tí kì í ṣe Kristẹni tì. Ọ̀nà tí àwọn ọmọ ń gbà bójú àwọn òbí wọn yàtọ̀ síra. Ìṣòro ẹnì kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Ohun tẹ́ni kọ̀ọ̀kan nílò yàtọ̀ síra, bí nǹkan ṣe máa ń káni lára àti ìlera olúkúlùkù ò sì rí bákan náà. Àwọn àgbàlagbà kan wà tọ́mọ wọn pọ̀; àwọn míì ò sì ní ju ọmọ kan ṣoṣo lọ.  Àwọn kan máa ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́dọ̀ ìjọba, àwọn míì ò sì lè rí gbà. Bákan náà, ohun tó máa ń wu àwọn tó nílò àbójútó yàtọ̀ síra. Torí náà, kò ní bọ́gbọ́n mú, kò sì ní fìfẹ́ hàn pé ká máa ṣe lámèyítọ́ ọ̀nà tí ẹnì kan ń gbà bójú tó àwọn ìbátan rẹ̀ tó ti di arúgbó. Ó ṣe tán, Jèhófà lè bù kún ìpinnu èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe tó bá ṣáà ti bá Ìwé Mímọ́ mu, á sì jẹ́ kí ìpinnu náà bọ́ sójú ẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn látìgbà ayé Mósè.—Núm. 11:23.

9-11. (a) Ìṣòro wo làwọn kan lè ní? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ kí àwọn ọmọ tó ti dàgbà kánjú fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Bí àwọn òbí àtàwọn ọmọ bá ń gbé níbi tó jìnnà síra, ó máa ń ṣòro láti bójú tó àwọn òbí tó ti di àgbàlagbà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Bí ìlera òbí kan bá ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn, bóyá torí pé ó ṣubú, tó fi apá tàbí ẹsẹ̀ dá, tàbí tí ìṣòro míì yọjú, ó lè gba pé kí àwọn ọmọ wá sílé láti wá wo àwọn òbí wọn. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ lè wá rí i pé àwọn òbí àwọn máa nílò àwọn, bóyá fún àkókò díẹ̀ tàbí fún àkókò gígùn. *

10 Ìpinnu ńlá ló sábà máa ń kojú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún láwọn ibi tó jìn sílé. Ojú ribiribi ni àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò fi ń wo iṣẹ́ ìsìn wọn, ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà ni wọ́n sì kà á sí. Síbẹ̀, tí òbí wọn bá ń ṣàìsàn, ohun tó máa ń kọ́kọ́ wá sí wọn lọ́kàn ni pé, ‘Àfi ká yáa fi iṣẹ́ yìí sílẹ̀, ká sì pa dà sílé lọ tọ́jú àwọn òbí wa.’ Àmọ́, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí wọ́n ronú lórí ọ̀rọ̀ náà tàdúràtàdúrà bóyá ohun tí ọ̀rọ̀ òbí wọn gbà nìyẹn àbí ńṣe làwọn òbí wọn kàn fẹ́ kí wọ́n fi iṣẹ́ ìsìn sílẹ̀. Kò yẹ kéèyàn kánjú fi iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sílẹ̀, àti pé lọ́pọ̀ ìgbà ó tiẹ̀ lè má pọn dandan láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé àìsàn ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, èyí tí àwọn ará tó wà nínú ìjọ tí òbí náà wà máa fẹ́ láti bá wọn bójú tó?—Òwe 21:5.

11 Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ọmọ-ìyá méjì kan tí wọ́n ń sìn níbi tó jìnnà sílé. Amẹ́ríkà ti Gúúsù ni ọ̀kan ti ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì tí èkejì sì ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York. Àwọn òbí wọn ti di àgbàlagbà, wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́ wọn. Àwọn ọmọ náà àtàwọn ìyàwó wọn bá gbéra láti lọ bẹ òbí wọn wò níbi tí wọ́n ń gbé ní Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé kí wọ́n lè mọ ohun tó máa dára jù lọ pé kí wọ́n ṣe fún wọn àti bí wọ́n ṣe máa ṣe é. Nígbà tó ṣe, èyí tó wà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé kóun àti ìyàwó òun fi iṣẹ́ sílẹ̀, kí àwọn sì pa dà sílé. Ṣùgbọ́n olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ tí àwọn òbí wọn wà bá wọn sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Ó sọ fún wọn pé àwọn alàgbà ìjọ yẹn ti forí korí nípa ìṣòro náà, wọ́n sì fẹ́ kí àwọn míṣọ́nnárì náà máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn nìṣó títí dìgbà tí wọ́n bá lè ṣe é dà. Àwọn alàgbà yẹn mọrírì iṣẹ́ táwọn tọkọtaya náà ń ṣe, wọ́n sì pinnu pé àwọn á ṣe gbogbo ohun tí àwọn bá lè ṣe láti bá wọn bójú tó àwọn òbí wọn. Gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé náà mọrírì ẹ̀mí rere tí àwọn alàgbà yẹn fi hàn.

12. Kí ló yẹ kó jẹ ìdílé Kristẹni kan lógún nígbà tí wọ́n bá ń pinnu bí wọ́n ṣe máa tọ́jú àwọn òbí wọn?

12 Ọ̀nà yòówù kí ìdílé Kristẹni kan pinnu láti gbà tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti di àgbàlagbà, á dára kí gbogbo wọn rí i dájú pé ìpinnu táwọn ṣe máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ dà bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ọjọ́ Jésù. (Mát. 15:3-6) A fẹ́ kí ìpinnu wa bọlá fún orúkọ Ọlọ́run àti ìjọ rẹ̀.—2 Kọ́r. 6:3.

OJÚṢE ÌJỌ

13, 14. Látàrí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn ará máa ń fẹ́ láti bójú tó àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ?

13 Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè ran àwọn  òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lọ́wọ́ lọ́nà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí. Àmọ́, tá a bá wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, ó ṣe kedere pé ó wu àwọn ìjọ pé kí wọ́n máa bójú tó àìní àwọn àgbàlagbà lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Bíbélì sọ nípa ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé “kò sí ọ̀kan láàárín wọn tí ó wà nínú àìní.” Kò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ náà ló rí já jẹ. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn kan ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, àmọ́ ṣe ni ‘wọn máa ń pín nǹkan fún olúkúlùkù, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní rẹ̀ bá ṣe rí.’ (Ìṣe 4:34, 35) Nígbà tó yá, ìṣòro kan yọjú nínú ìjọ náà. Àwọn kan ròyìn pé “àwọn opó wọn ni a ń gbójú fò dá nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́” lórí ọ̀rọ̀ oúnjẹ. Látàrí ìyẹn, àwọn àpọ́sítélì ní kí wọ́n yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n, àwọn yìí ló wá ń rí sí i pé àwọn opó náà ń rí ohun tí wọ́n nílò gbà láìsí pé a tún ń gbójú fo ẹnì kankan dá. (Ìṣe 6:1-5) Òótọ́ ni pé torí àwọn tó di Kristẹni ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni tí wọ́n sì máa wà ní Jerúsálẹ́mù fún ìgbà díẹ̀ ká lè gbé wọn ró nípa tẹ̀mí ni àwọn àpọ́sítélì ṣe ṣe ètò tó wà fúngbà díẹ̀ náà. Síbẹ̀ ètò pípín oúnjẹ fúnni náà jẹ́ ká rí i pé àwọn ará lè ṣètò bí wọ́n ṣe máa bójú tó àwọn aláìní tó wà nínú ìjọ.

14 Bí a ṣe sọ ṣáájú, Pọ́ọ̀lù fún Tímótì ní àwọn ìtọ́ni nípa ohun tó lè mú kí Kristẹni opó kan tóótun láti rí ìrànwọ́ nípa tara gbà nínú ìjọ. (1 Tím. 5:3-16) Jákọ́bù tí Ọlọ́run mí sí láti kọ lára Bíbélì náà sọ̀rọ̀ nípa ojúṣe tí àwa Kristẹni ní láti bójú tó àwọn ọmọ aláìlóbìí, àwọn opó àti àwọn míì tí wọ́n wà nínú ìpọ́njú tàbí tí wọ́n ṣaláìní. (Ják. 1:27; 2:15-17) Àpọ́sítélì Jòhánù náà sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yìí fún ìtìlẹyìn ìgbésí ayé, tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní, síbẹ̀ tí ó sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn, lọ́nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi dúró nínú rẹ̀?” (1 Jòh. 3:17) Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ló ṣe pàtàkì tó pé kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan bójú tó àwọn aláìní, ǹjẹ́ kò ṣe pàtàkì pé kí àwọn ìjọ náà ṣe bẹ́ẹ̀?

Bí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ kí ni ìjọ lè ṣe? (Wo ìpínrọ̀ 15 àti 16)

15. Àwọn nǹkan wo ló lè wé mọ́ ríran àwọn àgbàlagbà lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́?

15 Ní àwọn ilẹ̀ kan, ìjọba máa ń ní àwọn ètò kan fún àwọn àgbàlagbà, bí owó ìfẹ̀yìntì, ìrànwọ́ fún àwọn mẹ̀kúnnù àti ìtọ́jú àwọn àgbàlagbà nínú ilé. (Róòmù 13:6) Irú ètò yìí ò sí ní àwọn ibòmíì. Torí náà, bí ipò nǹkan bá ṣe rí ló máa pinnu irú ìrànwọ́ tí àwọn ẹbí àtàwọn ará nínú ìjọ máa ṣe fún àwọn àgbàlagbà lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Tí àwọn ọmọ bá ń gbé níbi tó jìnnà sí àwọn òbí, ó lè nípa lórí irú ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n máa lè ṣe. Á dára kí àwọn ọmọ máa fikùn lukùn pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ tí àwọn òbí wọn  wà, kí tọ̀tún tòsì wọn lè mọ irú ìrànlọ́wọ́ tí ìdílé náà nílò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà lè jẹ́ káwọn òbí mọ bí wọ́n ṣe lè jàǹfààní lára ètò ìjọba tàbí ti àjọ afẹ́nifẹ́re tó wà fún ìdẹ̀rùn àwọn àgbàlagbà. Wọ́n sì tún lè kíyè sí àwọn ìṣòro míì tó yẹ káwọn ọmọ wọn mọ̀ nípa rẹ̀, bí àwọn ìwé gbèsè tó nílò àbójútó, tàbí bí àwọn òbí náà ṣe ń ṣi oògùn lò. Irú ìjíròrò tó múná dóko tó sì fìfẹ́ hàn bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kí ìṣòro di ohun tí apá ò lè ká, ó sì lè jẹ́ kí wọ́n rí ojútùú tó wúlò. Ó dájú pé bí àwọn ọmọ bá lè ní àwọn agbọ̀ràndùn àti agbani-nímọ̀ràn nítòsí tí wọ́n á máa ṣojú fún ìdílé náà lọ́nà yìí, àníyàn ṣíṣe á dín kù.

16. Báwo ni àwọn Kristẹni kan ṣe ń ran àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́?

16 Ìfẹ́ tí àwọn ará wa kan ní sí àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n, máa ń mú kí wọ́n yọ̀ǹda àkókò wọn, kí wọ́n sì tún lo okun wọn láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún wọn. Wọ́n kà á sí ohun àìgbọ́dọ̀máṣe pé ó yẹ kí àwọn túbọ̀ máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ jẹ àwọn lógún. Àwọn kan tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa pèsè ìrànwọ́ fáwọn àgbàlagbà tiẹ̀ máa ń pín iṣẹ́ náà ṣe pẹ̀lú àwọn míì nínú ìjọ, wọ́n á sì jọ máa gbà á ṣe. Irú àwọn ará bẹ́ẹ̀ gbà pé bí ipò àwọn ò tiẹ̀ jẹ́ kí àwọn ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àwọn láyọ̀ láti máa ṣèrànwọ́ fún àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ náà kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn nìṣó títí dìgbà tí wọ́n bá fẹ́. Ẹ ò rí i pé ẹ̀mí rere làwọn ará bẹ́ẹ̀ ní! Ṣùgbọ́n, torí pé àwọn ará ti ń ṣe ìrànlọ́wọ́ kò wá sọ pé kí àwọn ọmọ pa ojúṣe wọn láti máa bójú tó àwọn òbí wọn tì o.

MÁA FI Ọ̀RỌ̀ TÓ Ń GBÉNI RÓ BỌLÁ FÚN ÀWỌN ÀGBÀLAGBÀ

17, 18. Kí nìdí tó fi dáa ká kíyè sí ìwà wa tó bá dọ̀rọ̀ àbójútó àwọn àgbàlagbà?

17 Àwọn àgbàlagbà àti àwọn tó ń bójú tó wọn lè mú kí iṣẹ́ àbójútó náà jẹ́ èyí tó gbádùn mọ́ni. Torí náà, sa gbogbo ipá rẹ kó o lè máa láyọ̀. Ọjọ́ ogbó máa ń ba àwọn àgbàlagbà kan nínú jẹ́, wọ́n tiẹ̀ lè sorí kọ́. Èyí lè wá mú kó o túbọ̀ sapá gan-an kó o lè máa bọlá fún àwọn ará tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà nípa bíbá wọn sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró. A gbóríyìn fún ẹ̀yin tẹ́ ẹ ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tẹ́ ẹ sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Jèhófà ò gbàgbé iṣẹ́ ribiribi tẹ́ ẹ ti ṣe fún un, àwa arákùnrin àti arábìnrin yín náà ò sì gbàgbé.—Ka Málákì 3:16; Hébérù 6:10.

18 Láfikún, ètò àtimáa bójú tó àwọn àgbàlagbà lójoojúmọ́ lè ṣòro, àmọ́ ó lè rọ tọ̀tún tòsì lọ́rùn tí wọ́n bá ń ṣàwàdà nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. (Oníw. 3:1, 4) Èyí tó pọ̀ lára àwọn àgbàlagbà ti pinnu pé àwọn ò ní mú nǹkan le fún àwọn tó ń tọ́jú àwọn. Wọ́n mọ̀ pé ìwà àwọn lè mú kí àwọn èèyàn máa bẹ àwọn wò kí wọ́n sì máa ṣìkẹ́ àwọn, ó sì lè mú kí wọ́n sá fún àwọn. A sábà máa ń gbọ́ tí àwọn tó lọ bẹ àwọn àgbàlagbà wò máa ń sọ pé, ‘Mo ní kí n lọ fún Mọ́mì tàbí Dádì ní ìṣírí ni, àmọ́ èmi gan-an ni mo rí ìṣírí gbà.’—Òwe 15:13; 17:22.

19. Kí ni tàgbà tèwe wa lè máa retí lọ́jọ́ ọ̀la?

19 Áà, ọjọ́ lọjọ́ náà yóò jẹ́ nígbà tí a ò ní jìyà mọ́, tá a sì máa di ẹni pípé! Àmọ́ ní báyìí ná, àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa fi ọkàn wa sí àwọn ohun tó máa wà títí ayé. A mọ̀ pé ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run ló ń fún wa lókun lásìkò wàhálà tàbí ìpọ́njú. Lọ́lá ìgbàgbọ́ yìí, “àwa kò juwọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro, dájúdájú, ẹni tí àwa jẹ́ ní inú ni a ń sọ dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (2 Kọ́r. 4:16-18; Héb. 6:18, 19) Àmọ́ o, yàtọ̀ sí pé kó o má ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run yingin, kí ló tún lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ bíbójú tó àwọn àgbàlagbà? A máa jíròrò àwọn àbá tó ṣeé mú lò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 9 Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa jíròrò díẹ̀ lára irú àbójútó tó ṣeé ṣe kó wà fún àwọn òbí tó ti di àgbàlagbà, tí àwọn ọmọ sì lè yan irú èyí tí wọ́n máa lò níbẹ̀.