Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ò Ń Rí “Ẹni Tí A Kò Lè Rí”?

Ǹjẹ́ Ò Ń Rí “Ẹni Tí A Kò Lè Rí”?

“Ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.”—HÉB. 11:27.

Ẹ̀RÙJẸ̀JẸ̀ ni ọba Fáráò, òrìṣà àkúnlẹ̀bọ làwọn ará Íjíbítì sì kà á sí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, When Egypt Ruled the East ṣe sọ, àwọn ará Íjíbítì gbà pé “kò sí ẹ̀dá alààyè tó gbọ́n bíi tiẹ̀ tàbí tó lágbára tó o.” Kí àwọn tí Fáráò ń jọba lé lórí lè máa bẹ̀rù rẹ̀, ó máa ń dé adé tó ní àwòrán ejò ṣèbé tó ṣe tán láti buni ṣán. Ìránnilétí lèyí jẹ́ pé lọ́gán ni wọ́n máa pa ẹnikẹ́ni tó bá fojú di ọba. A lè wá wo bó ṣe máa rí lára Mósè nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé: “Jẹ́ kí n rán ọ sí Fáráò, kí o sì mú àwọn ènìyàn mi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.”—Ẹ́kís. 3:10.

1, 2. (a) Ṣàlàyé ìdí tó fi jọ pé Mósè wà nínú ewu. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tí Mósè kò fi bẹ̀rù ìbínú ọba?

2 Mósè lọ sí Íjíbítì lóòótọ́ ó sì kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ Fáráò bínú sí i. Lẹ́yìn tí ìyọnu mẹ́sàn-án ti kọ lu ilẹ̀ náà, Fáráò kìlọ̀ fún Mósè pé: “Má gbìyànjú láti rí ojú mi mọ́, nítorí ní ọjọ́ tí o bá rí ojú mi ìwọ yóò kú.” (Ẹ́kís. 10:28) Kí Mósè tó kúrò níwájú Fáráò, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ọmọkùnrin ọba tó jẹ́ àkọ́bí, máa kú. (Ẹ́kís. 11:4-8) Níkẹyìn, Mósè sọ fún gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n pa ewúrẹ́ tàbí àgbò kan, kí wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wọ́n ara òpó ilẹ̀kùn wọn méjèèjì. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, òrìṣà kan tó ń jẹ́ Ra ni àwọn ará Íjíbítì ka ẹran tí Ọlọ́run ní kí wọ́n pa yìí sí.  (Ẹ́kís. 12:5-7) Kí wá ni Fáráò máa ṣe? Ẹ̀rù kò ba Mósè. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìgbàgbọ́ tó ní mú kó ṣègbọràn sí Jèhófà, “kò bẹ̀rù ìbínú ọba, nítorí tí ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.”—Ka Hébérù 11:27, 28.

3. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nípa ìgbàgbọ́ tí Mósè ní nínú “Ẹni tí a kò lè rí”?

3 Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ lágbára gan-an tó fi dà bíi pé ò ń “rí Ọlọ́run”? (Mát. 5:8) Láti mú kí ojú tẹ̀mí wa túbọ̀ mọ́lẹ̀ kedere ká bàa lè máa rí “Ẹni tí a kò lè rí,” ẹ jẹ́ ká jíròrò nípa Mósè. Báwo ni ìgbàgbọ́ tí Mósè ní nínú Jèhófà ṣe gbà á lọ́wọ́ ìbẹ̀rù èèyàn? Ọ̀nà wo ló gbà lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run? Báwo sì ni rírí tí Mósè ń rí “Ẹni tí a kò lè rí,” ṣe fún un lókun nígbà tí òun àti àwọn èèyàn rẹ̀ wà nínú ewu?

KÒ BẸ̀RÙ “ÌBÍNÚ ỌBA”

4. Tá a bá fi ojú èèyàn wò ó, báwo ni Mósè ṣe rí sí Fáráò?

4 Tá a bá fi ojú èèyàn wò ó, Mósè ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Fáráò. Ńṣe ló tiẹ̀ dà bíi pé ọwọ́ Fáráò ni ẹ̀mí Mósè, ire rẹ̀ àti ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ wà. Mósè alára ti béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: “Ta ni èmi tí èmi yóò fi lọ bá Fáráò, tí n ó sì fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì?” (Ẹ́kís. 3:11) Ní nǹkan bí ogójì ọdún ṣáájú ìgbà tí Mósè sọ̀rọ̀ yìí ló sá kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. Torí náà, ó ti lè máa ronú pé, ‘Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu pé kí n pa dà lọ sí Íjíbítì tó ti ṣeé ṣe kí n rí ìbínú ọba?’

5, 6. Kí ló ran Mósè lọ́wọ́ tó fi jẹ́ pé Jèhófà ló bẹ̀rù tí kò sì bẹ̀rù Fáráò?

5 Kí Mósè tó pa dà sí Íjíbítì, Ọlọ́run kọ́ ọ ní ìlànà pàtàkì kan tó wá pa dà kọ sínú ìwé Jóòbù. Ìlànà náà ni pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà—ìyẹn ni ọgbọ́n.” (Jóòbù 28:28) Kí Mósè bàa lè ní irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ kó sì máa fi ọgbọ́n hùwà, Jèhófà bi í ní ìbéèrè tó jẹ́ kó rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run Olódùmarè àti àwa èèyàn. Ó ní: “Ta ní yan ẹnu fún ènìyàn tàbí ta ní yan ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ tàbí adití tàbí ẹni tí ó ríran kedere tàbí afọ́jú? Èmi Jèhófà ha kọ́ ni?”—Ẹ́kís. 4:11.

6 Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ Mósè? Ó kọ́ Mósè pé kò sídìí fún un láti bẹ̀rù. Jèhófà ló rán Mósè níṣẹ́, òun náà ló sì máa fún un ní ohunkóhun tó bá nílò kó lè jíṣẹ́ tó rán an sí Fáráò. Àti pé ta ni Fáráò níbi tí Jèhófà wà. Ó ṣe tán, kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí ẹ̀mí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa wà nínú ewu lábẹ́ àkóso ọba Íjíbítì. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí Mósè ti ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe dáàbò bo Ábúráhámù, Jósẹ́fù àti Mósè alára nígbà ayé àwọn Fáráò tó ti kọjá. (Jẹ́n. 12:17-19; 41:14, 39-41; Ẹ́kís. 1:22–2:10) Torí pé Mósè ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà “Ẹni tí a kò lè rí,” ó fìgboyà tọ Fáráò lọ ó sì kéde gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà pa láṣẹ pé kó sọ fún Fáráò.

7. Báwo ni ìgbàgbọ́ tí arábìnrin kan ní nínú Jèhófà ṣe dáàbò bò ó?

7 Ìgbàgbọ́ tí arábìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ella ní nínú Jèhófà ló dáàbò bò ó tí ìbẹ̀rù èèyàn ò fi kó o láyà jẹ. Lọ́dún 1949, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB fi àṣẹ ọba mú Ella, wọ́n bọ́ ọ sí ìhòòhò, àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ ọlọ́pàá wá ń wò ó níwò ẹ̀sín. Arábìnrin náà sọ pé: “Ojú tì mí wẹ̀lẹ̀mù. Síbẹ̀, lẹ́yìn tí mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo wá ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn.” Lẹ́yìn yẹn, wọ́n ju Ella sí àtìmọ́lé fún ọjọ́ mẹ́ta. Ó sọ pé: “Àwọn ọlọ́pàá náà jágbe mọ́ mi pé: ‘A máa ṣe é débi pé kò sẹ́ni tó máa rántí orúkọ Jèhófà mọ́ ní orílẹ̀-èdè Estonia! A máa mú ẹ lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, a ó sì kó àwọn yòókù lọ sí àgbègbè Siberia!’ Wọ́n wá fi í ṣẹ̀sín pé, ‘Jèhófà rẹ dà?’” Ṣé èèyàn ni Ella máa bẹ̀rù àbí ó máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Nígbà tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, kò ṣojo rárá, ńṣe ló sọ fún àwọn tó ń ṣáátá rẹ̀ pé: “Mo ti ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, mo sì ti gbà pé ó sàn kí n ní àjọṣe rere pẹ̀lú Ọlọ́run bí mo tilẹ̀ wà lẹ́wọ̀n ju pé kí ẹ dá mi sílẹ̀ àmọ́ kí n pàdánù ojú rere Ọlọ́run.” Ní ti Ella, ṣe ló dà bíi pé ó ń rí Jèhófà bó ṣe  ń rí àwọn ọkùnrin tó wà níwájú rẹ̀. Ìgbàgbọ́ tí Ella ní mú kó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́.

8, 9. (a) Kí ni kò ní jẹ́ ká máa bẹ̀rù èèyàn? (b) Bó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o máa bẹ̀rù èèyàn, ọ̀dọ̀ ta ló yẹ kó o pọkàn pọ̀ sí?

8 Ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà ló máa jẹ́ kó o borí àwọn nǹkan tó ń bà ẹ́ lẹ́rù. Bí àwọn aláṣẹ ìjọba bá gbìyànjú láti dí ẹ lọ́wọ́ àtimáa sin Ọlọ́run, ó lè dà bíi pé ọwọ́ èèyàn ni ẹ̀mí rẹ, ire rẹ àti ọjọ́ ọ̀la rẹ wà. O sì lè máa ronú pé bóyá ló bọ́gbọ́n mu pé kó o máa sìn Jèhófà nìṣó níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìyẹn ló ń bí àwọn aláṣẹ nínú. Àmọ́, má ṣe gbàgbé pé ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ni kò ní jẹ́ kó o máa bẹ̀rù èèyàn. (Ka Òwe 29:25.) Jèhófà béèrè pé: “Ta ni ọ́ tí ìwọ yóò fi máa fòyà ẹni kíkú tí yóò kú, àti ọmọ aráyé tí a ó sọ di koríko tútù lásán-làsàn?”—Aísá. 51:12, 13.

9 Torí náà, ọ̀dọ̀ Baba rẹ tó jẹ́ alágbára gbogbo ni kó o pọkàn pọ̀ sí. Ó ń rí àwọn èèyàn tí àwọn alákòóso ń fìyà jẹ láìtọ́, ó ń gba tiwọn rò, ó sì máa ń gbèjà wọn. (Ẹ́kís. 3:7-10) Kódà, bó bá gba pé kó o gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ níwájú àwọn aláṣẹ ìjọba, ‘má ṣàníyàn nípa báwo tàbí kí ni wàá sọ; nítorí a ó fi ohun tí wàá sọ fún ọ ní wákàtí yẹn.’ (Mát. 10:18-20) Kí ni àwọn tó ń ṣàkóso àtàwọn aláṣẹ ìjọba jẹ́ níbi tí Jèhófà wà. Tó o bá ń fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun nísinsìnyí, wàá lè rí Jèhófà bí Ẹni gidi tó ń fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Ó LO ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ ÀWỌN ÌLÉRÍ ỌLỌ́RUN

10. (a) Àwọn ìtọ́ni wo ni Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní oṣù Nísàn ní ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni? (b) Kí nìdí tí Mósè fi ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run?

10 Ní oṣù Nísàn, ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì pé kí wọ́n fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àwọn ìtọ́ni tó ṣàrà ọ̀tọ̀: Ó ní kí wọ́n mú akọ àgùntàn tàbí ewúrẹ́ kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, kí wọ́n pa á, kí wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára òpó ìlẹ̀kùn wọn. (Ẹ́kís. 12:3-7) Kí ni Mósè wá ṣe? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Mósè nígbà tó yá pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni ó fi ṣe ayẹyẹ ìrékọjá àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí apanirun má bàa fọwọ́ kan àwọn àkọ́bí wọn.” (Héb. 11:28) Mósè mọ̀ pé Jèhófà ṣeé gbíyè lé, ó sì lo ìgbàgbọ́ nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa pa gbogbo ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí run nílẹ̀ Íjíbítì.

11. Kí nìdí tí Mósè fi kìlọ̀ fún àwọn míì?

11 Ó jọ pé Mídíánì ni àwọn ọmọ Mósè wà, níbi tí “apanirun” kò dé. * (Ẹ́kís. 18:1-6) Síbẹ̀, ó ṣègbọràn ní ti pé ó pèsè ìtọ́ni fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin wọn tó jẹ́ àkọ́bí wà nínú ewu. Mósè mọ̀ pé ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu, àmọ́ kò fẹ́ kí wọ́n kú torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Kí ló wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ní kánmọ́, Mósè pe gbogbo àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì, ó sì wí fún wọn pé: . . . ‘Ẹ pa ẹran ẹbọ ìrékọjá.’”—Ẹ́kís. 12:21.

12. Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jèhófà fi rán wa sáwọn èèyàn?

12 Jèhófà ń lo àwọn áńgẹ́lì láti darí àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n jíṣẹ́ pàtàkì kan fún aráyé. Ó ní kí wọ́n sọ fún wọn pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.” (Ìṣí. 14:7) Àkókò tó yẹ ká jíṣẹ́ náà la wà yìí. A gbọ́dọ̀ kìlọ̀ fáwọn aládùúgbò wa pé kí wọ́n jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá, kí wọ́n má bàa “gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣí. 18:4) “Àwọn àgùntàn mìíràn” ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn láti rọ àwọn tó ti di àjèjì sí Ọlọ́run pé kí wọ́n “padà bá Ọlọ́run rẹ́.”—Jòh. 10:16; 2 Kọ́r. 5:20.

Ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà á mú kó túbọ̀ máa wù ẹ́ láti wàásù ìhìn rere (Wo ìpínrọ̀ 13)

13 Ó dá wa lójú pé “wákàtí ìdájọ́” ti dé lóòótọ́. A tún ní ìgbàgbọ́ pé kò sí àsọdùn  nínú bí Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe jẹ́ kánjúkánjú. Nínú ìran, àpọ́sítélì Jòhánù “rí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n dúró lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, wọ́n di ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé mú pinpin.” (Ìṣí. 7:1) Ǹjẹ́ ìwọ náà ń fi ojú ìgbàgbọ́ rí àwọn áńgẹ́lì náà pé wọ́n ti múra tán láti tú ẹ̀fúùfù tí ń pani run náà dà sórí ayé yìí lásìkò ìpọ́njú ńlá? Tó o bá ń fi ojú ìgbàgbọ́ rí àwọn áńgẹ́lì yẹn, wàá lè máa fi ìgboyà wàásù ìhìn rere.

14. Kí ló ń mú ká máa ‘kìlọ̀ fún ẹni burúkú pé kí ó kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀’?

14 Àwa Kristẹni tòótọ́ ń gbádùn àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, a sì tún ní ìrètí ìyè ayérayé. Síbẹ̀, a mọ̀ pé ojúṣe wa ni pé ká ‘kìlọ̀ fún ẹni burúkú pé kó kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀ kó lè wà láàyè.’ (Ka Ìsíkíẹ́lì 3:17-19.) Àmọ́, kì í wulẹ̀ ṣe torí ká má bàa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ la ṣe ń wàásù o! Ohun tó ń mú ká wàásù ni pé a fẹ́ràn Jèhófà, a sì tún fẹ́ràn àwọn aládùúgbò wa. Jésù ṣàpẹẹrẹ ohun tí ìfẹ́ àti àánú túmọ̀ sí gan-an nínú àkàwé ọkùnrin ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere. A wá lè bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ “àánú” àwọn èèyàn máa ń ṣe mí bíi ti ará Samáríà náà, tí ìyẹn sì máa ń mú kí n fẹ́ láti wàásù?’ Ó ṣe tán, a kò ní fẹ́ dà bí àlùfáà àti ọmọ Léfì inú àkàwé náà, ká pẹ́ ohun tó yẹ ká ṣe sílẹ̀ ká sì “gba ẹ̀gbẹ́ òdì-kejì kọjá lọ.” (Lúùkù 10:25-37) Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run àti ìfẹ́ tá a ní fún àwọn aládùúgbò wa yóò mú kó máa wù wá láti kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù, kí Jèhófà tó sọ pé ó tó.

“WỌ́N LA ÒKUN PUPA KỌJÁ”

15. Kí nìdí tó fi dà bíi pé ọ̀nà dí mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

15 Ìgbàgbọ́ tí Mósè ní nínú “Ẹni  tí a kò lè rí” ràn án lọ́wọ́ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú ewu lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ojú wọn sókè, sì kíyè sí i, àwọn ará Íjíbítì ń lépa wọn; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fòyà gan-an, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Jèhófà.” (Ẹ́kís. 14:10-12) Ǹjẹ́ ó yẹ kó ṣàjèjì sí wọn pé àwọn ará Íjíbítì ń lépa wọn? Rárá o. Ìdí ni pé Jèhófà ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé: “Èmi . . . yóò jẹ́ kí ọkàn-àyà Fáráò di èyí tí ó ṣoríkunkun, òun yóò sì lépa wọn dájúdájú, èmi yóò sì gba ògo fún ara mi nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀; àwọn ará Íjíbítì yóò sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà.” (Ẹ́kís. 14:4) Àmọ́, ohun téèyàn lè fi ojú rí nìkan làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rí, Òkun Pupa rèé níwájú wọn tí kò ṣeé rọ́ lù, kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò ló ń já bọ̀ ṣòòròṣò yìí lẹ́yìn wọn, tó sì wá jẹ́ pé darandaran, ẹni ọgọ́rin [80] ọdún ló ń ṣáájú wọn! Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n rò pé ọ̀nà ti dí mọ́ àwọn.

16. Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe mú kí Mósè nígboyà nígbà tí wọ́n dé Òkun Pupa?

16 Síbẹ̀, Mósè kò mikàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ojú ìgbàgbọ́ tó ní mú kó rí ohun tó lágbára fíìfíì ju okun pupa àtàwọn ọmọ ogun Fáráò. Mósè ń rí “ìgbàlà Jèhófà,” ó sì mọ̀ pé Jèhófà máa jà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ka Ẹ́kísódù 14:13, 14.) Ìgbàgbọ́ tí Mósè ní mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà lo ìgbàgbọ́. Bíbélì sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni wọ́n la Òkun Pupa kọjá bí pé lórí ilẹ̀ gbígbẹ, ṣùgbọ́n àwọn ará Íjíbítì ni a gbé mì nígbà tí wọ́n dágbá lé e.” (Héb. 11:29) Lẹ́yìn náà, “àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀.”—Ẹ́kís. 14:31.

17. Kí ló ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tó máa dán ìgbàgbọ́ wa wò?

17 Láìpẹ́, ó máa dà bíi pé ẹ̀mí wá wà nínú ewu. Nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá ń parí lọ, àwọn ìjọba ayé yìí á ti fi òpin sí àwọn ètò ẹ̀sìn tí wọ́n tóbi tí wọ́n sì pọ̀ jù wá lọ. (Ìṣí. 17:16) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan, Jèhófà sọ bó ṣe máa dà bíi pé a wà nínú ewu nígbà tó ṣàpèjúwe ipò wa bí “ìgbèríko gbalasa . . . láìsí ògiri . . . ọ̀pá ìdábùú àti àwọn ilẹ̀kùn pàápàá.” (Ìsík. 38:10-12, 14-16) Tá a bá fi ojú tara wò ó, ńṣe ló máa dà bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ fún wa. Kí lo máa ṣe nígbà yẹn?

18. Ṣàlàyé ìdí tá ò fi ní mikàn nígbà ìpọ́njú ńlá?

18 Kò yẹ ká mikàn nítorí ìbẹ̀rù. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó tún wá sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ pé: “‘Ní ọjọ́ yẹn, ní ọjọ́ tí Gọ́ọ̀gù yóò wá sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘pé ìhónú mi yóò gòkè wá sí imú mi. Nínú ìgbóná-ọkàn mi, ní iná ìbínú kíkan mi, ni èmi yóò sọ̀rọ̀.’” (Ìsík. 38:18-23) Nígbà náà ni Ọlọ́run á wá pa gbogbo àwọn tó fẹ́ ṣèpalára fún àwọn èèyàn Jèhófà run. Ìgbàgbọ́ tó o ní pé Jèhófà máa ṣẹ́gun ní “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù . . . Jèhófà” ló máa mú kó o “rí ìgbàlà Jèhófà” kó o sì pa ìwà títọ́ rẹ mọ́.—Jóẹ́lì 2:31, 32.

19. (a) Báwo ni àjọṣe àárín Mósè àti Jèhófà ṣe rí? (b) Tó o bá ń kíyè sí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ, àwọn ìbùkún wo lo máa gbádùn?

19 Ní báyìí, máa múra sílẹ̀ de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amọ́kànyọ̀ yìí nípa bíbá a nìṣó ní “fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí”! Máa kẹ́kọ̀ọ́ kó o sì máa gbàdúrà déédéé kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run lè máa lágbára sí i. Irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ ni Mósè ní pẹ̀lú Jèhófà, Ọlọ́run sì lò ó lọ́nà kíkàmàmà débi tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà mọ Mósè “lójúkojú.” (Diu. 34:10) Wòlíì àrà ọ̀tọ̀ ni Mósè. Àmọ́ o, bí ìwọ náà bá ní ìgbàgbọ́, o lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà táá fi dà bíi pé ká tiẹ̀ ní ò ń fojú rí i ní, bí àárín yín ì bá ṣe rí náà nìyẹn. Tó o bá ń kíyè sí i “ní gbogbo ọ̀nà rẹ,” gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe, ó máa mú “àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:6.

^ ìpínrọ̀ 11 Ó dájú pé àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà rán láti mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn ará Íjíbítì.—Sm. 78:49-51.