Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Jèhófà Mọ Àwọn Tí Í Ṣe Tirẹ̀”

“Jèhófà Mọ Àwọn Tí Í Ṣe Tirẹ̀”

“Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni ó mọ̀.”—1 KỌ́R. 8:3.

NÍ ÀÁRỌ̀ ọjọ́ kan, Áárónì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà dúró ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, ó mú ìkóná tàbí ohun èlò tí wọ́n fi ń sun tùràrí dání. Nítòsí ibi tó wà, Kórà àtàwọn àádọ́ta-lérúgba [250] ọkùnrin pẹ̀lú dúró, oníkálùkù pẹ̀lú ìkóná tirẹ̀, wọ́n ń sun tùràrí sí Jèhófà. (Núm. 16:16-18) Téèyàn bá kọ́kọ́ wò ó, ó lè dà bíi pé adúróṣinṣin ni gbogbo àwọn ọkùnrin tó ń sun tùràrí náà. Àmọ́, yàtọ̀ sí Áárónì, ọ̀dàlẹ̀ agbéraga tó ń fẹ́ láti gba ipò àlùfáà mọ́ Áárónì lọ́wọ́ ni àwọn yòókù. (Núm. 16:1-11) Wọ́n tan ara wọn jẹ débi pé wọ́n gbà lọ́kàn ara wọn pé Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. Ìwà àfojúdi ni èrò tí wọ́n ní yẹn jẹ́ sí Jèhófà, torí pé ó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ó sì lè rí i pé alágàbàgebè ni wọ́n.—Jer. 17:10.

2. Kí ni Mósè sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀, báwo sì ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ṣẹ?

2 Ó bá a mu wẹ́kú pé ní ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn, Mósè ti sọ pé: “Ní òwúrọ̀, Jèhófà yóò sọ ẹni tí ó jẹ́ tirẹ̀.” (Núm. 16:5) Gẹ́lẹ́ bó ṣe sọ náà ló rí, Jèhófà fìyàtọ̀ sáàárín àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn àtàwọn tó ń fi ẹnu lásán sìn ín, nígbà tí ‘iná jáde wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó [Kórà àti] àádọ́ta-lérúgba  ọkùnrin tí ń sun tùràrí run.’ (Núm. 16:35; 26:10) Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jèhófà dá ẹ̀mí Áárónì sí, èyí tó fi hàn pé ó tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí ojúlówó àlùfáà àti ẹni tó ń fi tọkàntọkàn sin òun.—Ka 1 Kọ́ríńtì 8:3.

3. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wáyé nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù? (b) Kí ni Jèhófà ṣe nípa ìdìtẹ̀ tó wáyé rí lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn tó jẹ́ ká mọ ọwọ́ tó fi ń mú irú ìwà bẹ́ẹ̀?

3 Ìṣẹ̀lẹ̀ tó fara pẹ́ èyí tún wáyé ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn kan tó pe ara wọn ní Kristẹni gba àwọn ẹ̀kọ́ èké gbọ́; síbẹ̀ wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ. Tí ẹnì kan bá kàn wo ìjọ náà, bóyá ló máa mọ àwọn apẹ̀yìndà yàtọ̀ sí àwọn ará yòókù nínú ìjọ. Àmọ́, bí wọ́n ṣe jẹ́ apẹ̀yìndà yẹn léwu gan-an fún àwọn Kristẹni adúróṣinṣin. Ńṣe ni àwọn ìkookò tó gbé àwọ̀ àgùntàn wọ̀ yìí “ń dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan dé.” (2 Tím. 2:16-18) Àmọ́, kì í ṣe pé Jèhófà kàn ń wo ohun tó ń lọ lásán, ó sì dájú pé Pọ́ọ̀lù náà mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé Ọlọ́run fìyà jẹ Kórà àtàwọn tí wọ́n jọ dìtẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Nípa báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó gbàfiyèsí ká sì wá wo ẹ̀kọ́ gidi tá a lè rí kọ́ nínú rẹ̀.

“ÈMI NI JÈHÓFÀ; ÈMI KÒ YÍ PA DÀ”

4. Kí ló dá Pọ́ọ̀lù lójú, báwo ló sì ṣe jẹ́ kí Tímótì mọ̀ bẹ́ẹ̀?

4 Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà máa mọ̀ téèyàn bá ń sìn ín lọ́nà àgàbàgebè, ó sì tún dá a lójú pé Jèhófà lè dá àwọn tó ń ṣègbọràn sí I mọ̀. Èyí ṣe kedere nínú àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò nígbà tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ̀wé sí Tímótì. Lẹ́yìn tó ti tọ́ka sí bí àwọn apẹ̀yìndà ṣe fẹ́ ba àjọṣe tí àwọn kan nínú ìjọ ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó sọ pé: “Láìka gbogbo èyíinì sí, ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run dúró sẹpẹ́, ó ní èdìdì yìí: ‘Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀,’ àti pé: ‘Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.’”—2 Tím. 2:18, 19.

5, 6. Kí ló gbàfiyèsí nínú gbólóhùn náà, “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run” èyí tí Pọ́ọ̀lù lò nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀? Kí ni gbólóhùn yẹn mú kó dá Tímótì lójú?

5 Kí ló ṣe pàtàkì nínú àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí? Ibí yìí nìkan ni gbólóhùn náà “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run” ti fara hàn nínú Bíbélì. Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “ìpìlẹ̀” láti fi ṣàpèjúwe onírúurú nǹkan. Kódà, ó lò ó láti ṣàpèjúwe ìlú Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú Ísírẹ́lì àtijọ́. (Sm. 87:1, 2) Ó tún fi ipa tí Jésù ń kó nínú ète Jèhófà wé ìpìlẹ̀. (1 Kọ́r. 3:11; 1 Pét. 2:6) Torí náà, kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run”?

6 Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí ohun tí Mósè sọ nínú Númérì 16:5, nípa Kórà àtàwọn tí wọ́n jọ dìtẹ̀ ló mẹ́nu kan gbólóhùn náà, “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run.” Ó dájú pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Mósè yẹn kó bàa lè fún Tímótì níṣìírí kó sì rán an létí pé Jèhófà lágbára láti mọ àwọn tó ń dáná ọ̀tẹ̀, ó sì mọ bó ṣe lè paná ọ̀tẹ̀ náà. Torí náà, bí Jèhófà kò ṣe gbà kí Kórà dí ète rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó dájú pé kò ní gbà kí àwọn apẹ̀yìndà tó wà nínú ìjọ ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ohun tí “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run” dúró fún. Síbẹ̀, ó ṣe kedere pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò yẹn mú kó dá Tímótì lójú pé Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó sì ṣeé fọkàn tán.

7. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa gbé ìgbésẹ̀ ní òdodo àti pẹ̀lú ìṣòtítọ́?

7 Àwọn ìlànà gíga Jèhófà kì í yí pa dà. Sáàmù 33:11 sọ pé: “Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ète Jèhófà yóò dúró; ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ ń bẹ láti ìran kan tẹ̀ lé ìran mìíràn.” Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì sọ pé àkóso Jèhófà, inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, òdodo rẹ̀ àti òótọ́ rẹ̀ á máa wà títí láé. (Ẹ́kís. 15:18; Sm. 106:1; 112:9; 117:2)  Málákì 3:6 sọ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí pa dà.” Bákan náà, Jákọ́bù 1:17 fi hàn pé Jèhófà kì í yí pa dà bí òjìji tó máa ń ṣípò pa dà.

“ÈDÌDÌ” KAN TÓ MÚ KÁ NÍ ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ JÈHÓFÀ

8, 9. Kí la rí kọ lára ohun tí Pọ́ọ̀lù pè ní “èdìdì” nínú àpèjúwe rẹ̀?

8 Àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò nínú 2 Tímótì 2:19 fi hàn pé wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kan sárá ìpìlẹ̀ ilé kan, tàbí lédè mìíràn wọ́n fi èdìdì ṣe àmì sí i lára. Láyé àtijọ́, ó wọ́pọ̀ gan-an pé kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sárá ìpìlẹ̀ ilé kan, bóyá káwọn èèyàn lè mọ bíríkìlà tó kọ́ ilé náà tàbí ẹni tó ni ín. Pọ́ọ̀lù ni òǹkọ̀wé Bíbélì àkọ́kọ́ tó lo àpèjúwe yìí. * Gbólóhùn méjì ló fara hàn nínú àmì tí wọ́n fi èdìdì ṣe sára “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run.” Àkọ́kọ́, “Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀” àti èkejì, “Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.” Àwọn ọ̀rọ̀ yìí mú ká rántí ohun tá a kà nínú Númérì 16:5.—Kà á.

9 Kí la rí kọ́ lára ohun tí Pọ́ọ̀lù pè ní “èdìdì” nínú àpèjúwe tó ṣe yìí? Fún àwa tá a jẹ́ ti Ọlọ́run, gbólóhùn méjì tó jẹ́ òótọ́ la lè fi ṣàkópọ̀ àwọn ìtọ́sọ́nà àti ìlànà Jèhófà: (1) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i, àti (2) Jèhófà kórìíra àìṣòdodo. Báwo ni ẹ̀kọ́ yìí ṣe kan ọ̀ràn ìpẹ̀yìndà tó wáyé nínú ìjọ?

10. Báwo ni ìwà àwọn apẹ̀yìndà ṣe rí lára àwọn olóòótọ́ tó wà lọ́jọ́ Pọ́ọ̀lù?

10 Ìwà tí àwọn apẹ̀yìndà tó wà láàárín ìjọ ń hù ba Tímótì àtàwọn olóòótọ́ míì nínú jẹ́ gan-an. Àwọn Kristẹni kan tiẹ̀ lè máa ṣe kàyéfì pé kí ló dé tí wọ́n ṣì fi gba irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ láyè nínú ìjọ. Àwọn tó ń fòótọ́ sin Ọlọrun nínú ìjọ lè máa ronú pé bóyá ni Jèhófà dá àwọn táwọn rọ̀ mọ́ ìlànà rẹ̀ láìyẹsẹ̀ mọ̀ yàtọ̀ sí àwọn apẹ̀yìndà alágàbàgebè tí wọ́n ń fi ẹnu lásán sìn ín.—Ìṣe 20:29, 30.

Ìwà àwọn tó ń ṣe bí apẹ̀yìndà ò lè bi ìgbàgbọ́ Tímótì ṣubú (Wo ìpínrọ̀ 10 sí 12)

11 Kò sí àní-àní pé lẹ́tà Pọ́ọ̀lù mú kí ìgbàgbọ́ Tímótì túbọ̀ lágbára. Ó rán Tímótì létí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá Áárónì tó jẹ́ adúróṣinṣin láre, tó sì fi Kórà àtàwọn alágàbàgebè bíi tiẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọlọ̀tẹ̀, tó wá tipa bẹ́ẹ̀ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ tó sì tún pa wọ́n run. Lédè míì, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn afàwọ̀rajà Kristẹni wà láàárín wọn, Jèhófà máa fi àwọn tó jẹ́ tirẹ̀ ní ti gidi hàn bó ti ṣe nígbà ayé Mósè.

11, 12. Báwo ni lẹ́tà Pọ́ọ̀lù ṣe mú kí ìgbàgbọ́ Tímótì túbọ̀ lágbára?

 12 Jèhófà kì í yí pa dà; ó ṣeé fọkàn tán. Ó kórìíra àìṣòdodo, kò sì ní jẹ́ kí àwọn aṣebi lọ láìjìyà. Níwọ̀n bí Tímótì náà sì ti wà lára àwọn tó ń “pe orúkọ Jèhófà,” Pọ́ọ̀lù rán an létí pé ojúṣe rẹ̀ ni láti má ṣe jẹ́ kí àwọn afàwọ̀rajà Kristẹni yẹn kó èèràn ran òun. *

ÌJỌSÌN TÒÓTỌ́ Ò NÍ JÁ SÍ ASÁN LÁÉ

13. Kí ló yẹ kó dá wa lójú?

13 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti sọ lè mú kí ìgbàgbọ́ tiwa náà túbọ̀ lókun. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà mọ̀ dáadáa pé à ń sin òun tọkàntọkàn. Kì í ṣe bí ìgbà téèyàn wulẹ̀ fọwọ́ lẹ́rán tó ń wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà dìídì nífẹ̀ẹ́ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíró. 16:9) Torí náà, ó dá wa lójú hán-únhán-ún pé ohun tá a bá ṣe fún Jèhófà “láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́” kò ní já sí asán.—1 Tím. 1:5; 1 Kọ́r. 15:58.

14. Irú ìjọsìn wo ni Jèhófà ò fẹ́?

14 Ó yẹ ká ronú jinlẹ̀ nípa ìjọsìn wa torí pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn téèyàn ń fi ara ṣe ṣùgbọ́n tí kò fi ọkàn ṣe. Bí ojú Jèhófà ṣe “ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé,” ó lè rí ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò “pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Ìwé Òwe 3:32 sọ pé: “Oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” Oníbékebèke lẹni tó máa ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ojú ayé, táá máa ṣe bíi pé ó ń pa òfin Ọlọ́run mọ́, àmọ́ tó ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oníbékebèke èèyàn lè fọgbọ́n tan àwọn míì jẹ fúngbà díẹ̀, àmọ́ torí pé Jèhófà jẹ́ olódùmarè tó sì tún jẹ́ olódodo, ó dájú pé “ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí.”—Òwe 28:13; ka 1 Tímótì 5:24; Hébérù 4:13.

15. Kí ni kò yẹ ká ṣe, kí sì nìdí?

15 Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwa èèyàn Jèhófà là ń sìn ín tọkàntọkàn. Torí náà, ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnì kan nínú ìjọ dìídì pinnu pé ẹ̀tàn ló kù tóun á máa lò báyìí bí òun ṣe ń jọ́sìn Jèhófà. Síbẹ̀, tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Mósè tó sì tún ṣẹlẹ̀ lásìkò àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, ó lè ṣẹlẹ̀ lónìí pẹ̀lú. (2 Tím. 3:1, 5) Àmọ́, ṣé ó wá yẹ ká máa fura sí àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ká máa kọminú pé bóyá ojú ayé lásán ni gbogbo bí wọ́n ṣe ń sin Jèhófà tọkàntọkàn? Kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ rárá! Kò ní bójú mu rárá pé ká máa fura sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa láìnídìí. (Ka Róòmù 14:10-12; 1 Kọ́ríńtì 13:7.) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ṣiyè méjì nípa ìṣòtítọ́ àwọn ará wa nínú ìjọ, ìyẹn lè ba àjọṣe tí àwa fúnra wa ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.

16. (a) Kí ni olúkúlùkù wa lè ṣe tí àgàbàgebè kò fi ní jọba lọ́kàn wa? (b) Kí la rí kọ́ nínú àlàyé tó wà nínú àpótí náà, “ Ẹ Máa Dán Ara Yín Wò . . . Ẹ Máa Wádìí . . . ”?

16 Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa “máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́.” (Gál. 6:4) Torí pé a jẹ́ aláìpé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè máa ṣojú ayé láìfura; a lè ní nǹkan kan lọ́kàn kó sì jẹ́ pé ohun míì là ń hù níwà. (Héb. 3:12, 13) Torí náà, látìgbàdégbà, á dára ká máa wádìí ohun tó ń sún wa tá a fi ń sin Jèhófà. A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà àti bí mo ṣe gbà pé òun ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run ló ń mú kí n máa sìn ín? Àbí àwọn ìbùkún tara tí màá gbádùn nínú Párádísè ló gba iwájú lọ́kàn mi?’ (Ìṣí. 4:11) Ó dájú pé ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ń yẹ ìwà wa wò tá a sì ń mú ohunkóhun tó bá lè fa àgàbàgebè tu kúrò lọ́kàn wa.

A MÁA LÁYỌ̀ TÁ A BÁ DÚRÓ ṢINṢIN

17, 18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi òótọ́ inú sin Jèhófà láìṣàbòsí?

17 Èrè púpọ̀ la máa rí bá a ṣe ń sapá  láti máa fòótọ́ inú sin Jèhófà, láìṣe àbòsí. Onísáàmù náà sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kò ka ìṣìnà sí lọ́rùn, ẹni tí ẹ̀tàn kò sì sí nínú ẹ̀mí rẹ̀.” (Sm. 32:2) Ká sòótọ́, àwọn tó ń sin Ọlọ́run láìṣe àgàbàgebè, máa ń láyọ̀ gan-an, irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ sì tún máa mú kí wọ́n gbádùn ojúlówó ayọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

18 Bó pẹ́ bó yá, Jèhófà máa tú àṣírí gbogbo olubi tàbí àwọn tó ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá lábẹ́lẹ̀. Á wá mú kí “ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín” túbọ̀ ṣe kedere. (Mál. 3:18) Ní báyìí ná, ọkàn wa balẹ̀ pé “ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.”—1 Pét. 3:12.

^ ìpínrọ̀ 8 Ìwé Ìṣípayá 21:14, tí wọ́n kọ ni ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti kọ àwọn lẹ́tà rẹ̀ sí Tímótì, sọ̀rọ̀ nípa “òkúta ìpìlẹ̀” méjìlá tí wọ́n kọ orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá sí.

^ ìpínrọ̀ 12 Àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn èyí máa jíròrò bá a ṣe lè fìwà jọ Jèhófà, ká rí i pé a kọ àìṣòdodo sílẹ̀ lákọ̀tán.