Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mimura Awon Orile-Ede Sile fun “Eko Jehofa”

Mimura Awon Orile-Ede Sile fun “Eko Jehofa”

“Alákòóso ìbílẹ̀ . . . di onígbàgbọ́, níwọ̀n bí háà ti ṣe é sí ẹ̀kọ́ Jèhófà.”ÌṢE 13:12.

1-3. Àwọn ohun ìdènà wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù dojú kọ bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere náà ní “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè”?

IṢẸ́ tí Jésù Kristi gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà nìṣó, “ìhìn rere ìjọba yìí [á di èyí tí wọ́n wàásù] ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—Mát. 24:14; 28:19.

2 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn nífẹ̀ẹ́ Jésù àti ìhìn rere náà gan-an. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ṣe kàyéfì pé báwo làwọn ṣe máa ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé àwọn lọ́wọ́ yìí? Ó ṣe tán, wọ́n kéré níye. Àwọn èèyàn tún pa Jésù táwọn ọmọ ẹ̀yìn gbà pé ó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run. Ojú ẹni tí “kò mọ̀wé àti gbáàtúù” ni wọ́n fi ń wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Ìṣe 4:13) Àmọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ jíṣẹ́ to ta ko ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n gbajúmọ̀, tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú àwọn àṣà tó lòde nígbà náà lọ́hùn-ún. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn ará ìlú wọn. Yàtọ̀ síyẹn, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ò jẹ́ nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìlú tó kù tí wọ́n wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù nígbà yẹn.

3 Láfikún sí i, Jésù ti kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àwọn èèyàn máa kórìíra wọn, wọ́n á ṣe inúnibíni sí wọn àti pé wọ́n máa pa àwọn kan lára wọn. (Lúùkù 21:16, 17) Lára ohun tí wọ́n dojú kọ ni ìwà ọ̀dàlẹ̀, àwọn wòlíì èké àti ìwà àìlófin tó gbilẹ̀. (Mát. 24:10-12) Kódà, táwọn èèyàn bá tiẹ̀ máa fayọ̀ gba iṣẹ́ wọn, báwo ni wọ́n ṣe lè mú un dé “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé”? (Ìṣe 1:8) Àwọn ìṣòro yìí lè mú kí nǹkan tojú súni!

4. Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe ṣàṣeyọrí tó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

4 Ohun yòówù kó jẹ́ ìṣòro àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà, wọn ò jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn, wọ́n gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà ní Jerúsálẹ́mù àti Samáríà àti jákèjádò gbogbo ayé ìgbà yẹn. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà kojú ìṣòro lóríṣiríṣi, àmọ́ láàárín ọgbọ̀n ọdún, wọ́n ti “wàásù [ìhìn rere náà] nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run,” wọ́n ń ‘so èso wọ́n sì ń bí sí i ní gbogbo ayé.’ (Kól. 1:6, 23) Bí àpẹẹrẹ, torí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tó sì ṣe ní erékùṣù Kípírọ́sì, Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì tó jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀ kan nílẹ̀ Róòmù “di onígbàgbọ́, níwọ̀n bí háà ti ṣe é sí ẹ̀kọ́ Jèhófà.”—Ka Ìṣe 13:6-12.

5. (a) Kí ni Jésù mú kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú? (b) Nígbà táwọn kan wo bí ipò nǹkan ṣe rí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, kí ni wọ́n parí èrò sí?

5 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ pé agbára àwọn nìkan ò lè mú káwọn ṣe àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà. Jésù ti ṣèlérí fún wọn pé òun máa wà pẹ̀lú wọn àti pé ẹ̀mí mímọ́ yóò ràn wọ́n lọ́wọ́. (Mát. 28:20) Láwọn ọ̀nà kan, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láyé ìgbà yẹn jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù rọrùn. Ìwé kan tó ń jẹ́ Evangelism in the Early Church tó dá lórí iṣẹ́ ajíhìnrere ní ọ̀rúndún kìíní sọ pé: “Kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìgbà kankan nínú ìtàn tó rọrùn jù lọ láti bẹ̀rẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì tuntun bí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Ọdún Olúwa Wa . . . Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kejì . . . gbà pé Ọlọ́run ló pa ọ̀nà mọ́ kí ẹ̀sìn Kristẹni lè fìdí kalẹ̀ láyé.”

6. Kí la máa jíròrò (a) nínú àpilẹ̀kọ yìí (b) nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

6 Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú nǹkan rọrùn tó ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní kí iṣẹ́ ìwàásù lè gbòòrò síwájú? Bíbélì ò sọ, àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé, Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere, ṣùgbọ́n Sátánì kò fẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun pàtó kan tó mú kí iṣẹ́ ìwàásù rọrùn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ju bó ṣe rí láwọn àkókò míì nínú ìtàn. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa ṣàyẹ̀wò àwọn àyípadà tó wáyé lóde òní tó jẹ́ ká lè wàásù ìhìn rere dé ìpẹ̀kun ayé.

IPA TÍ ÀKÓKÒ PAX ROMANA

7. Kí ni Pax Romana, kí sì nìdí tó fi jẹ́ àkókò mánigbàgbé?

7 Àkóso Róòmù ṣe àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní láǹfààní láwọn ọ̀nà kan. Bí àpẹẹrẹ, àkókò kan wà nígbà yẹn tí kò sógun tàbí ọ̀tẹ̀, wọ́n pe àkókò náà ní Pax Romana, tó túmọ̀ sí Àlàáfíà Róòmù. Kò sí ẹnikẹ́ni tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù nígbà yẹn tó dá a láṣà láti ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba. Àmọ́, bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, nígbà míì “àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun” kò ṣàì wáyé. (Mát. 24:6) Lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, Róòmù pa ìlú Jerúsálẹ́mù run, àwọn ìjà abẹ́lé míì sì tún wáyé nítòsí ààlà ilẹ̀ ọba náà. Àmọ́, fún nǹkan bí igba [200] ọdún, àlàáfíà jọba ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba náà. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Kò sígbà kankan rí nínú ìtàn ẹ̀dá tí nǹkan rọgbọ níbi gbogbo fún àkókò tó gùn tó bẹ́ẹ̀, kò sì sírú àlàáfíà yẹn láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́.”

8. Àǹfààní wo ni bí àlàáfíà ṣe wà káàkiri nígbà yẹn ṣe fáwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀?

8 Ọ̀gbẹ́ni Origen tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta sọ pé: “Tí àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso bá pọ̀ rẹpẹtẹ, ó lè dí ẹ̀kọ́ Jésù lọ́wọ́ kó má tàn dé gbogbo ayé . . . torí pé wọ́n á fipá kó àwọn ọkùnrin wọnú iṣẹ́ ológun kí wọ́n lè máa dáàbò bo orílẹ̀-èdè wọn. . . . Bákan náà, ká ní ipò nǹkan ò yí pa dà kárí ayé, tí àwọn èèyàn ò sì lẹ́mìí tó dáa ní àsìkò Jésù, ǹjẹ́ ó máa rọrùn fáwọn èèyàn láti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ tó dá lórí àlàáfíà, tí kò sì fàyè gba káwọn èèyàn gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn?” Kì í ṣe pé wọn ò ṣe inúnibíni sáwọn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ ìjọba Róòmù, àmọ́ wọn ò sí nínú ewu, ó sì dájú pé wọ́n jàǹfààní nínú bí àlàáfíà ṣe gbilẹ̀ láyé nígbà yẹn.—Ka Róòmù 12:18-21.

IPA TÍ ÌRÌN ÀJÒ TÓ RỌRÙN KÓ

9, 10. Kí ló mú kó rọrùn díẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn láti rìnrìn àjò láwọn Ilẹ̀ Ọba Róòmù?

9 Bí ọ̀nà ṣe lọ geerege nígbà ìjọba Róòmù ṣèrànwọ́ fáwọn Kristẹni gan-an. Kí ìjọba Róòmù lè láṣẹ lórí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ dáadáa, ó láwọn ọmọ ogun tí wọ́n mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ tí wọ́n sì lágbára. Ojú ọ̀nà tó dáa ṣe pàtàkì kó lè rọrùn fáwọn ọmọ ogun láti yára lọ síbikíbi, torí náà, ìjọba ṣe ọ̀nà, àwọn ará Róòmù sì mọwọ́ iṣẹ́ yìí dáadáa. Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ilẹ̀ Róòmù ṣe ọ̀nà tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin [80,000] kìlómítà tó dé gbogbo agbègbè tó wà lábẹ́ ìjọba wọn. Wọ́n la àwọn ọ̀nà náà gba inú igbó kìjikìji, inú aṣálẹ̀ àti àwọn òkè.

10 Ní àfikún sí ojú ọ̀nà, àwọn ará Róòmù tún lè rìnrìn àjò tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27,000] kìlómítà lórí omi àti odò. Àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Róòmù láwọn ọ̀nà tí ó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] lórí omi tí wọ́n lè gbà já sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibùdó ọkọ̀ òkun. Èyí jẹ́ káwọn Kristẹni lè rìnrìn àjò jákèjádò ilẹ̀ Róòmù. Kò ṣàì sí àwọn ìṣòro kọ̀ọ̀kan, àmọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó kù rìnrìn àjò káàkiri àgbègbè náà láìsí ìwé àṣẹ ìwọ̀lú àti ìwé ìrìnnà. Kò sí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó ń yẹ ìwé ìwọ̀lú wò, kò sì sí àwọn aṣọ́bodè. Ẹ̀rù ìyà táwọn ará Róòmù fi ń jẹ ọ̀daràn ń ba àwọn èèyàn, torí náà, kò fi bẹ́ẹ̀ séwu láwọn ọ̀nà wọn. Bákan náà, kò séwu téèyàn bá rìnrìn àjò ojú omi torí àwọn ọmọ ogun Róòmù tó wà lórí omi kò gbojú bọ̀rọ̀ fáwọn ọ̀daràn orí omi. Lóòótọ́, ọkọ̀ òkun tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ rì láwọn ìgbà mélòó kan, àwọn ewu míì sì wà lórí òkun, àmọ́ Ìwé Mímọ́ kò sọ ní pàtó pé wọ́n kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn orí omi.—2 Kọ́r. 11:25, 26.

IPA TÍ ÈDÈ GÍRÍÌKÌ KÓ

Ìwé àfọwọ́kọ jẹ́ kó rọrùn láti tètè rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ (Wo ìpínrọ̀ 12)

11. Kí nìdí táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi lo èdè Gíríìkì?

11 Èdè Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní Koine tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ nílé lóko, mú kó rọrùn fáwọn ìjọ Kristẹni láti bá ara wọn sọ̀rọ̀, ó sì jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wọn. Ogun àjàṣẹ́gun tí Alẹkisáńdà Ńlá jà mú kó rọrùn gan-an láti sọ èdè Gíríìkì di èdè táwọn èèyàn ń sọ nílé lóko tó sì yé àwọn èèyàn dáadáa. Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè bá oríṣiríṣi èèyàn sọ̀rọ̀, èyí sì jẹ́ kí ìhìn rere náà lè dé ibi gbogbo. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Júù tó wà ní ilẹ̀ Íjíbítì ti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì. Àwọn èèyàn mọ Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì ìyẹn Septuagint dáadáa, àwọn tó sì kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi máa ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ dáadáa. Àwọn Kristẹni tún rí i pé èdè Gíríìkì rọrùn láti fi kọ̀wé. Èdè Gíríìkì láwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tó pọ̀ gan-an, èyí sì jẹ́ kó rọrùn láti lo oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fẹ́ ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọsìn.

12. (a) Báwo ni ìwé àfọwọ́kọ ṣe rí, àwọn ọ̀nà wo ló sì gbà sàn ju àkájọ ìwé lọ? (b) Ìgbà wo làwọn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé àfọwọ́kọ dáadáa?

12 Kí làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lò láti fi kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì? Wọ́n lo àkájọ ìwé. Àmọ́ kò rọrùn láti lò, torí ó gba pé kéèyàn máa tú u kó sì tún máa ká a pa dà, àti pé ọwọ́ iwájú nìkan ni wọ́n sábà máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí lórí àkájọ náà. Ìhìn Rere Mátíù nìkan máa gba odindi àkájọ ìwé kan. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé àfọwọ́kọ, òun sì ni ó dà bí ìwé táwọn èèyàn kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lò. Abala ìwé kọ̀ọ̀kan tí wọ́n dì pọ̀ mọ́ra ni ìwé àfọwọ́kọ yìí. Ó jẹ́ kó rọrùn láti tètè rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ téèyàn fẹ́ kà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ àkókò pàtó táwọn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé àfọwọ́kọ, àmọ́ ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Àwọn Kristẹni tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì lo ìwé àfọwọ́kọ dáadáa, ó sì dájú pé àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó a ti máa lò ó tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ọgọ́rùn-ún Ọdún Olúwa.”

IPA TÍ ÒFIN RÓÒMÙ KÓ

13, 14. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù tó ní? (b) Àǹfààní wo ni òfin àwọn ará Róòmù ṣe fáwọn Kristẹni?

13 Òfin ilẹ̀ Róòmù múlẹ̀ ní gbogbo ìlú tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù láwọn ẹ̀tọ́ àti àwọn ààbò kan lábẹ́ òfin. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù lo ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù tí ó ní. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n fẹ́ nà án lẹ́gba ní ìlú Jerúsálẹ́mù, ó sọ fún ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù kan pé: “Ó ha bófin mu fún yín láti na ẹni tí ó jẹ́ ará Róòmù, tí a kò sì dá lẹ́bi lọ́rẹ́?” Kò bófin mu rárá. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ọmọ bíbí ilẹ̀ Róòmù lòun, “àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ fi ìdálóró wádìí rẹ̀ wò fi í sílẹ̀; ọ̀gágun náà sì fòyà nígbà tí ó rí i dájú pé ará Róòmù ni [Pọ́ọ̀lù], tí òun sì ti dè é tẹ́lẹ̀.”—Ìṣe 22:25-29.

14 Torí pé Pọ́ọ̀lù jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù, wọ́n fọ̀wọ̀ wọ̀ ọ́ nílùú Fílípì. (Ìṣe 16:35-40) Nígbà táwọn jàǹdùkú kan ń da ìlú rú ní Éfésù, akọ̀wé ìlú náà mú kí wọ́n dákẹ́, ó wá rán wọn létí pé wọ́n lè jẹ̀bi lábẹ́ òfin Róòmù. (Ìṣe 19:35-41) Torí pé Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n fi òfin yanjú ọ̀ràn rẹ̀ nílùú Kesaréà, ó ṣeé ṣe fún un láti gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ̀ níwájú Késárì. (Ìṣe 25:8-12) Torí náà, òfin Róòmù mú kó ṣeé ṣe láti ‘gbèjà ìhìn rere, kí wọ́n sì fìdí ẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.’—Fílí. 1:7.

IPA TÍ ÀWỌN JÚÙ TÍ WỌ́N FỌ́N KÁÀKIRI KÓ

15. Báwo làwọn Júù ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe fọ́n káàkiri tó?

15 Ó ṣeé ṣe láwọn ọ̀nà kan kí iṣẹ́ ìwàásù rọrùn fáwọn Kristẹni torí pé àwọn Júù fọ́n káàkiri àwọn ìlú tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò yìí, àwọn ará Ásíríà lọ kó àwọn Júù lẹ́rù ní ìlú wọn. Nígbà tó yá, àwọn ará Bábílónì náà tún kó àwọn Júù lẹ́rù. Kódà bẹ̀rẹ̀ láti ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù ti ní àgbègbè mẹ́tàdínláàádóje [127] tí wọ́n ń gbé ní Ilẹ̀ Ọba Pásíà. (Ẹ́sít. 9:30) Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn Júù ní àgbègbè tí wọ́n ń gbé ní Íjíbítì àtàwọn apá ibòmíì ní Àríwá Áfíríkà, títí kan Gíríìsì, Éṣíà Kékeré àti Mesopotámíà. Wọ́n fojú bù ú pe nínú èèyàn tí ó tó ọgọ́ta mílíọ̀nù [60,000,000] tó ń gbé ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ẹnì kan nínú èèyàn mẹ́rìnlá ló jẹ́ Júù. Ibikíbi táwọn Júù bá sì dé, wọ́n ń dá ìjọsìn wọn sílẹ̀ níbẹ̀.—Mát. 23:15.

16, 17. (a) Báwo làwọn tí kì í ṣe Júù ṣe jàǹfààní nínú bí àwọn Júù ṣe fọ́n káàkiri? (b) Àwọn nǹkan wo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ́ látọ̀dọ̀ àwọn Júù?

16 Torí pé àwọn Júù fọ́n káàkiri lọ sí àwọn ibi tó jìnnà gan-an, ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Júù ló ka Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dáadáa. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà àti pé àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ń tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere tó ga. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà kún inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. (Lúùkù 24:44) Àwọn Júù àtàwọn Kristẹni mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí Ọlọ́run ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, èyí ló mú kí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù lè wọ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo lọ́kàn. Torí náà, ó ti di àṣà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti máa lọ sínú Sínágọ́gù àwọn Júù, ó sì máa ń bá wọn fèrò wérò láti inú Ìwé Mímọ́.—Ka Ìṣe 17:1, 2.

17 Àwọn Júù ti ní ọ̀nà pàtó kan tí wọ́n ń gbà ṣe ìjọsìn wọn. Wọ́n máa ń pàdé déédéé láwọn Sínágọ́gù tàbí láwọn ibi táwọn èèyàn ti máa ń pàdé níta gbangba. Lẹ́yìn tí wọ́n bá kọrin tán, wọ́n á gbàdúrà, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Àwọn ìjọ Kristẹni lóde òní náà ń tẹ̀ lé irú ọ̀nà tí àwọn Júù yìí gbà sin Ọlọ́run.

JÈHÓFÀ LÓ JẸ́ KÓ ṢEÉ ṢE

18, 19. (a) Kí ni bí ipò nǹkan ṣe rí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní jẹ́ kó ṣeé ṣe? (b) Èrò wo ni ohun tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ kó o ní nípa Jèhófà?

18 A ti rí àwọn nǹkan pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ tó wà lára ohun tó mú kí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere kẹ́sẹ járí. A sọ̀rọ̀ lórí àkókò Pax Romana, bó ṣe rọrùn láti rìnrìn àjò káàkiri, èdè Gíríìkì táwọn èèyàn ń sọ nílé lóko, òfin ilẹ̀ Róòmù àti bí àwọn Júù ṣe fọ́n káàkiri. Èyí jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run yàn fún wọn.

19 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ṣáájú kí Jésù tó wá sáyé, Plato tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì sọ nínú ìwé rẹ̀ kan pé: “Iṣẹ́ ńlá ni ká tó lè sọ pé a mọ ẹni tó ṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run tàbí ẹni tó ni ín, ká tiẹ̀ wá sọ pé a mọ̀ ọ́n, kò ṣeé ṣe ká sọ nípa rẹ̀ fún gbogbo èèyàn.” Àmọ́ Jésù sọ pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún ènìyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 18:27) Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run fẹ́ káwọn èèyàn wá òun kí wọ́n sì mọ òun. Bákan náà, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ . . . sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:19) Lọ́lá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run, iṣẹ́ tí Jésù gbé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ ṣeé ṣe. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dá lórí bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí lóde òní.