Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kekoo Latinu Apejuwe Nipa Talenti

Kekoo Latinu Apejuwe Nipa Talenti

“Ó sì fi tálẹ́ńtì márùn-ún fún ọ̀kan, méjì fún òmíràn, àti ẹyọ kan fún òmíràn síbẹ̀.”—MÁT. 25:15.

1, 2. Kí nìdí tí Jésù fi sọ àpèjúwe nípa tálẹ́ńtì?

NÍNÚ àkàwé tí Jésù sọ nípa tálẹ́ńtì, ó jẹ́ ká rí ojúṣe kan tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró ní. Ó yẹ ká mọ ìtumọ̀ àkàwé yìí, torí ó kan gbogbo Kristẹni tòótọ́, yálà wọ́n ń retí láti gbé ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé.

2 Jésù sọ àkàwé tálẹ́ńtì yìí nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í nípa “àmì wíwàníhìn-ín [rẹ̀] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 24:3) Torí náà, àkókò wa yìí ni àkàwé náà ń tọ́ka sí, ó sì wà lára àmì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ti wà níhìn-ín, ó sì ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba.

3. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn àpèjúwe tó wà nínú ìwé Mátíù orí 24 àti 25 kọ́ wa?

3 Àkàwé tálẹ́ńtì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpèjúwe mẹ́rin tó jọra wọn tó wà nínú ìwé Mátíù 24:45 sí 25:46. Àwọn mẹ́ta tó kù ni àpèjúwe nípa ẹrú olóòótọ́ àti olóye, àwọn wúńdíá mẹ́wàá àti ti àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́. Ìgbà tí Jésù ń dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bi í nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ ló sọ àwọn àpèjúwe yìí. Nínú àwọn àpèjúwe mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, Jésù pàfiyèsí sí àwọn ìwà tó máa mú káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ dá yàtọ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Jésù darí àpèjúwe nípa ẹrú náà, àwọn wúńdíá àti àpèjúwe nípa tálẹ́ńtì sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. Nínú àpèjúwe ẹrú olóòótọ́ náà, Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwùjọ kéréje lára àwọn ẹni àmì òróró tí òun gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láti máa bọ́ àwọn ará ilé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́, kó sì jẹ́ olóye. Nínú àpèjúwe nípa àwọn wúńdíá, Jésù tẹnu mọ́ ọn pé gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn yóò ní láti múra sílẹ̀, kí wọ́n sì wà lójúfò, torí wọ́n mọ̀ pé Jésù ń bọ̀ àmọ́ wọn ò mọ ọjọ́ tàbí wákátì tí yóò dé. Nínú àpèjúwe nípa tálẹ́ńtì, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ jẹ́ aláápọn bí wọ́n ṣe ń bójú tó ojúṣe wọn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Jésù wá darí àpèjúwe tó kẹ́yìn, ìyẹn àkàwé nípa àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́ sí àwọn tí wọ́n ń retí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin, kí wọ́n sì ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin Jésù tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé. * Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa àpèjúwe àwọn tálẹ́ńtì.

Ọ̀GÁ NÁÀ PÍN OWÓ FÚN ÀWỌN ẸRÚ RẸ̀

4, 5. Ta ni ọkùnrin tàbí ọ̀gá náà, báwo sì ni tálẹ́ńtì kan ṣe níye lórí tó?

4 Ka Mátíù 25:14-30. A ti ń ṣàlàyé tipẹ́tipẹ́ nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa pé Jésù ni ọkùnrin tàbí ọ̀gá inú àpèjúwe náà àti pé ó rìnrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀ nígbà tó gòkè lọ sí ọ̀run ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Nínú àkàwé tí Jésù sọ ṣáájú èyí, ó sọ ìdí tí òun fi máa rìnrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀, pé ó jẹ́ láti “gba agbára ọba síkàáwọ́ ara rẹ̀.” (Lúùkù 19:12) Jésù ò gba gbogbo agbára Ìjọba náà lójú ẹsẹ̀ tó pa dà sí ọ̀run. * Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló “jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, láti ìgbà náà lọ, ó ń dúró títí a ó fi fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.”—Héb. 10:12, 13.

5 Ọkùnrin inú àpèjúwe náà ní tálẹ́ńtì mẹ́jọ, owó tabua lèyí láyé igbà yẹn. * Kí ọkùnrin náà tó rìnrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀, ó pín owó náà fáwọn ẹrú rẹ̀, ó fẹ́ kí wọ́n fi owó náà ṣòwò nígbà tí òun kò bá sí nílé. Bíi ti ọkùnrin yẹn, Jésù ní ohun kan tó ṣeyebíye gan-an kó tó di pé ó lọ sí ọ̀run. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Ìyẹn ni iṣẹ́ tó fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ṣe.

6, 7. Kí ni àwọn tálẹ́ńtì náà dúró fún?

6 Ọwọ́ pàtàkì ni Jésù fi mú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ kíkọ́ni. (Ka Lúùkù 4:43.) Ó tipa báyìí dáwọ́ lé iṣẹ́ pàtàkì kan tó máa so èso jìgbìnnì. Ó ti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣáájú pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35-38) Ohun tí Jésù ń sọ ni báwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe máa kó àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ jọ táwọn náà sì máa di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bí àgbẹ̀ kan tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, Jésù kò ní fi pápá tàbí oko tí ire rẹ̀ ti tó kórè sílẹ̀ láìṣe nǹkan kan sí i. Torí náà, láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde kó tó di pé ó lọ sọ́rùn, ó gbé iṣẹ́ ńlá kan lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́, ó ní: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:18-20) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ gbé ohun iyebíye ńlá kan lé wọn lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.—2 Kọ́r. 4:7.

7 Kí wá ni tálẹ́ńtì náà? Nígbà tí Jésù ń gbéṣẹ́ lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ńṣe ni Jésù gbé “àwọn nǹkan ìní rẹ̀,” ìyẹn àwọn tálẹ́ńtì náà lé wọn lọ́wọ́. (Mát. 25:14) Torí náà, a lè sọ pé tálẹ́ńtì náà ni ojúṣe tá a ní láti wàásù àti láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn.

8. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iye tálẹ́ńtì tí ẹrú kọ̀ọ̀kan gbà yàtọ̀ síra, kí ni ọ̀gá náà retí pé kí wọ́n ṣe?

8 Àkàwé nípa tálẹ́ńtì náà jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀gá náà fún ẹrú kan ní tálẹ́ńtì márùn-ún, ó fún ẹrú míì ní méjì, ó sì fún ẹrú kẹta ní tálẹ́ńtì kan ṣoṣo. (Mát. 25:15) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iye tálẹ́ńtì tí ẹrú kọ̀ọ̀kan gbà yàtọ̀ síra, ọ̀gá náà retí pé kí gbogbo wọn jẹ́ aláápọn bí wọ́n ṣe ń fi àwọn tálẹ́ńtì náà ṣòwò. Ohun tí ìyẹn sì túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n sa gbogbo ipá wọn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ débi tí agbára wọn bá gbé e dé. (Mát. 22:37; Kól. 3:23) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn tálẹ́ńtì náà ṣòwò láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ìwé Ìṣe nínú Bíbélì ròyìn bí àwọn ọmọlẹ́yìn ṣe jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. *Ìṣe 6:7; 12:24; 19:20.

BÍ WỌ́N ṢE FI ÀWỌN TÁLẸ́ŃTÌ NÁÀ ṢÒWÒ LÁWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN

9. (a) Kí ni àwọn ẹrú méjì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ fi tálẹ́ńtì wọn ṣe, kí sì nìyẹn fi hàn? (b) Ipa wo ni àwọn “àgùntàn mìíràn” ń kó?

9 Àwọn ẹni àmì òróró ẹrú Kristi tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn tálẹ́ńtì Ọ̀gá náà ṣòwò láwọn ọjọ́ ìkẹyìn pàápàá láti ọdún 1919. Bíi tàwọn ẹrú méjì àkọ́kọ́, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ti sa gbogbo ipá wọn láti lo ohun tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ náà. Kò yẹ ká máa méfòó nípa ẹni tó gba tálẹ́ńtì márùn-ún àti ẹni tó gba tálẹ́ńtì méjì. Nínú àpèjúwe náà, àwọn ẹrú méjèèjì ló sọ tálẹ́ńtì tí ọ̀gá wọn fún wọn di ìlọ́po méjì, torí náà àwọn méjèèjì ló jẹ́ aláápọn. Ipa wo ni àwọn tí ìrètí wọn jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé ń kó? Ipa ribiribi ni wọ́n ń kó! Àpèjúwe Jésù tó dá lórí àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́ kọ́ wa pé àwọn tí ìrètí wọn jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé láǹfààní láti máa fi ìṣòtítọ́ kọ́wọ́ ti àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù nínú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó le koko yìí, àwùjọ méjèèjì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí “agbo kan” bí wọ́n ṣe ń fìtara ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Jòh. 10:16.

10. Ohun pàtàkì wo ló jẹ́ apá kan àmì wíwàníhìn-ín Jésù?

10 Ọ̀gá náà ń retí ohun táwọn ẹrú rẹ̀ máa fi tálẹ́ńtì náà ṣe. Bá a ṣe sọ ṣáájú, àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní mú kí nǹkan ìní ọ̀gá náà pọ̀ sí i. Àkókò òpin yìí tí àkàwé tí Jésù ṣe nípa àwọn tálẹ́ńtì náà ní ìmúṣẹ wá ńkọ́? Àwọn ìránṣẹ́ Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àti òṣìṣẹ́ kára ti ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tó tayọ jù lọ nínú ìtàn. Bí gbogbo wọn ṣe kọ́wọ́ ti iṣẹ́ yìí ń mú kí ọgọ́rùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn máa di ọmọ ẹ̀yìn tuntun tí wọ́n sì ń kún àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run lọ́dọọdún, èyí sì ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni di apá pàtàkì lára àmì wíwàníhìn-ín Jésù nínú agbára Ìjọba. Láìsí àní-àní, inú Ọ̀gá wọn máa dùn gan-an ni!

Kristi ti gbé iṣẹ́ tó ṣeyebíye lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ pé kí wọn máa wàásù (Wo ìpínrọ̀ 10)

ÌGBÀ WO NI Ọ̀GÁ NÁÀ MÁA WÁ ṢE ÌṢÍRÒ OWÓ?

11. Kí ló jẹ́ ká parí èrò sí pé ìgbà ìpọ́njú ńlá ni Jésù máa wá ṣe ìṣirò owó?

11 Jésù máa wá ṣe ìṣírò owó pẹ̀lú àwọn ẹrú rẹ̀ ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá náà, èyí tó máa bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́. Kí ló jẹ́ ká gbà pé bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rí? Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ tó wà nínú Mátíù orí 24 àti 25, ọ̀pọ̀ ìgbà ló mẹ́nu kan ìgbà tí òun n bọ̀. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ nígbà ìpọ́njú ńlá náà, ó sọ pé àwọn èèyàn yóò “rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run.” Ó rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn pé kí wọ́n wà lójúfò, ó sọ pé: “Ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀,” ó tún sọ pé, “wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Mát. 24:30, 42, 44) Torí náà, nígbà tí Jésù sọ pé “ọ̀gá ẹrú wọnnì dé, ó sì yanjú ìṣírò owó pẹ̀lú wọn,” ńṣe ló ń tọ́ka sí ìgbà tóun máa wá ṣèdájọ́ ní òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí. *Mát. 25:19.

12, 13. (a) Kí ni ọ̀gá náà sọ fún àwọn ẹrú méjì àkọ́kọ́, kí sì nìdí? (b) Ìgbà wo ni àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn máa gba èdìdì ìkẹyìn? (Wo àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “ Ìdájọ́ Nígbà Ikú.”) (d) Èrè wo làwọn tí Jésù ṣèdájọ́ wọn pé wọ́n jẹ́ àgùntàn máa gbà?

12 Nínú àkàwé náà, nígbà tí ọ̀gá náà dé, ó rí i pé ẹrú méjì àkọ́kọ́, ìyẹn èyí tó fún ní tálẹ́ńtì márùn-ún àtèyí tó fún ní méjì, ti fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti sọ tálẹ́ńtì wọn di ìlọ́po méjì. Ọ̀rọ̀ kan náà ni ọ̀gá wọn sọ fún àwọn méjèèjì, ó sọ pé: “O káre láé, ẹrú rere àti olùṣòtítọ́! Ìwọ jẹ́ olùṣòtítọ́ lórí ìwọ̀nba àwọn ohun díẹ̀. Dájúdájú, èmi yóò yàn ọ́ sípò lórí ohun púpọ̀.” (Mát. 25:21, 23) Kí ni ká wá máa retí tí Ọ̀gá náà, ìyẹn Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo, bá dé lọ́jọ́ iwájú láti ṣe ìdájọ́?

13 Àwọn akíkanjú ọmọ ẹ̀yìn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ni wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹrú méjì àkọ́kọ́. Wọ́n á sì ti gba èdìdì ìkẹyìn kó tó di pé ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀. (Ìṣí. 7:1-3) Kí Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, Jésù máa fún wọn ní èrè tí Ọlọ́run ṣèlérí fún wọn ní ọ̀run. Jésù yóò ti ṣèdájọ́ àwọn tí ìrètí wọn jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé tí wọ́n kọ́wọ́ ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù pé wọ́n jẹ́ àgùntàn, wọ́n á sì láǹfààní láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ àkóso Ìjọba náà.—Mát. 25:34.

ẸRÚ BURÚKÚ ÀTI ONÍLỌ̀Ọ́RA

14, 15. Ǹjẹ́ ohun tí Jésù ń sọ ni pé èyí tó pọ̀ nínú àwọn ọmọlẹ́yìn òun tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn máa di ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra? Ṣàlàyé.

14 Nínú àkàwé náà, ẹrú kẹta lọ ri tálẹ́ńtì rẹ̀ mọ́lẹ̀, dípò kó fi ṣòwò tàbí kó lọ fi sí báńkì. Ẹrú náà fi hàn pé èèyàn burúkú ni òun, torí ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó lòdì sí ohun tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́. Abájọ tí ọ̀gá náà fi pè é ní ẹrú “burúkú àti onílọ̀ọ́ra.” Ọ̀gá náà gba tálẹ́ńtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fún ẹrú tó ní mẹ́wàá. Wọ́n sì ju ẹrú burúkú náà “síta nínú òkùnkùn lóde.” “Níbẹ̀ ni ẹkún rẹ̀ àti ìpayínkeke rẹ̀ yóò wà.”—Mát. 25:24-30; Lúùkù 19:22, 23.

15 Jésù sọ pé ọ̀kan nínú àwọn ẹrú mẹ́ta náà fi tálẹ́ńtì rẹ̀ pa mọ́. Ṣé ohun tó wá ń sọ ni pé ìdá kan nínú mẹ́ta lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn yóò jẹ́ ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra? Rárá o. Jẹ́ ká wo àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kó tó sọ àkàwé yìí. Nínú àpèjúwe ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà, Jésù sọ nípa ẹrú burúkú kan tó na àwọn míì tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú. Jésù ò fìyẹn sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹgbẹ́ ẹrú búburú kan máa jẹ yọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń kìlọ̀ fún ẹrú olóòótọ́ náà pé kó má ṣe hùwà bí ẹrú burúkú náà. Bákan náà, nínú àpèjúwe àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà, Jésù ò sọ pé ìdajì nínú àwọn ọmọlẹ́yìn òun tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ló máa dà bí àwọn òmùgọ̀ wúńdíá márùn-ún náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọn ò bá wà lójúfò tí wọn ò sì múra sílẹ̀. * Látinú ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí, ó dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu tá a bá gbà pé Jésù ò fi àpèjúwe nípa tálẹ́ńtì sọ pé èyí tó pọ̀ nínú àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn yóò di ẹni burúkú àti onílọ̀ọ́ra láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù ń kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn pé kí wọ́n jẹ́ aláápọn bí wọ́n ṣe ń ‘fi tálẹ́ńtì wọn ṣòwò,’ kí wọ́n má sì fìwà àti ìṣe jọ ẹrú burúkú náà.—Mát. 25:16.

16. (a) Ẹ̀kọ́ wo la kọ́ nínú àkàwé nípa àwọn tálẹ́ńtì náà? (b) Báwo ni àpilẹ̀kọ yìí ṣe tún òye tá a ní nípa àkàwé àwọn tálẹ́ńtì ṣe? (Wo àpótí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “ Òye Wa Nípa Àpèjúwe Tálẹ́ńtì Náà.”)

16 Ẹ̀kọ́ méjì wo la kọ́ látinú àkàwé nípa àwọn tálẹ́ńtì? Àkọ́kọ́, Ọ̀gá náà, ìyẹn Kristi ti gbé ohun kan tó kà sí ohun iyebíye lé àwọn ẹrú rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn lọ́wọ́, ohun náà ni pé kí wọ́n wàásù, kí wọ́n sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Èkejì, Kristi retí pé kí gbogbo wa jẹ́ aláápọn nídìí iṣẹ́ ìwàásù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dá wa lójú pé Ọ̀gá náà máa san wá lẹ́san torí pé a nígbàgbọ́, a wà lójúfò, a sì jẹ́ adúróṣinṣin.—Mát. 25:21, 23, 34.

^ ìpínrọ̀ 3 A jíròrò bá a ṣe dá ẹrú olóòótọ́ àti olóye mọ̀ nínú Ilé Ìṣọ́, July 15, 2013, ojú ìwé 21 àti 22, ìpínrọ̀ 8 sí 10. Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí jíròrò bá a ṣe dá àwọn wúńdíá náà mọ̀. A ṣàlàyé àpèjúwe àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́ nínú Ilé Ìṣọ́, October 15, 1995, ojú ìwé 23 sí 28, a sì tún jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn nínú ìwé ìròyìn yìí.

^ ìpínrọ̀ 5 Nígbà ayé Jésù, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] owó dínárì ni tálẹ́ńtì kan. Tí òṣìṣẹ́ kan bá ń gba dínárì kan lójúmọ́, ó máa ṣiṣẹ́ nǹkan bí ogún ọdún kó tó lè gba tálẹ́ńtì kan ṣoṣo.

^ ìpínrọ̀ 8 Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, Sátánì mú kí àwọn apẹ̀yìndà rú yọ, wọ́n sì gbòde kan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Lákòókò yẹn, ọ̀pọ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ sapá mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ láti kó àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Kristi jọ. Àmọ́, nǹkan máa yí pa dà nígbà “ìkórè,” ìyẹn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (Mát. 13:24-30, 36-43) Wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 2013, ojú ìwé 9 sí 12.

^ ìpínrọ̀ 15 Wo ìpínrọ̀ 13 nínú àpilẹ̀kọ tí a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ṣé Wàá ‘Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà’?” nínú ìwé ìròyìn yìí.