Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbeyawo “Kiki Ninu Oluwa”—Nje O Si Bogbon Mu?

Gbeyawo “Kiki Ninu Oluwa”—Nje O Si Bogbon Mu?

“Mi ò rẹ́ni tó wù mí tí mo lè fẹ́ nínú ìjọ, ṣé mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ darúgbó láìlọ́kọ báyìí?”

“Àwọn ọkùnrin kan ṣì wà nínú ayé tí wọ́n dáa léèyàn, wọ́n nínúure, wọ́n fani mọ́ra, wọ́n sì máa ń gba tẹlòmíì rò. Wọn ò ta ko ẹ̀sìn mi, ó sì jọ pé wọ́n túra ká ju àwọn arákùnrin kan lọ.”

Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tí wọ́n ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ ti sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí rí. Síbẹ̀ wọ́n mọ̀ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé ká ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” Gbogbo Kristẹni ló sì yẹ kó fi ìmọ̀ràn yìí sílò. (1 Kọ́r. 7:39) Kí wá nìdí táwọn kan fi sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀?

ÌDÍ TÁWỌN KAN FI Ń ṢIYÈMÉJÌ

Àwọn tó sọ̀rọ̀ yìí lè rò pé àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ pọ̀ ju àwọn arákùnrin tí kò tíì láya lọ. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Wo àpẹẹrẹ méjì yìí: Lórílẹ̀-èdè Korea, wọ́n fojú bù ú pé nínú ọgọ́rùn-ún [100] èèyàn tí kò tíì lọ́kọ tàbí láya, mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57] nínú wọn ló jẹ́ arábìnrin tí mẹ́tàlélógójì [43] sì jẹ́ arákùnrin. Bákan náà, ní orílẹ̀-èdè Colombia, ìdá mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] nínú ọgọ́rùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ arábìnrin, nígbà tí ìdá mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] tó kù jẹ́ àwọn arákùnrin.

Ní àwọn ilẹ̀ kan, ìdí táwọn arábìnrin kan ò fi rí ọkọ fẹ́ ni pé, nǹkan ìdána táwọn òbí wọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ máa ń béèrè ti máa ń pọ̀ jù, èyí sì máa ń mú kó nira fáwọn arákùnrin tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ láti rí aya fẹ́. Tí arábìnrin kan bá wo gbogbo èyí, ó lè máa ronú pé kò sí bí òun ṣe lè ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” Torí náà, arábìnrin kan lè máa bi ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti máa retí pé mo ṣì lè rẹ́ni tó wù mí láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni?” *

Ó ṢE PÀTÀKÌ KÓ O GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

Tó o bá ti ní irú èrò yìí rí, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ ohun tó ò ń kojú. Kódà, ó mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ.—2 Kíró. 6:29, 30.

Síbẹ̀, Jèhófà ló sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká ṣègbéyàwó kìkì nínú Olúwa. Kí nìdí? Torí ó mọ ohun tó dáa fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Kò fẹ́ kójú àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ojú àwọn tí kò fọgbọ́n hùwà máa ń rí, ó sì tún fẹ́ ká máa láyọ̀. Ní ìgbà ayé Nehemáyà nígbà tí ọ̀pọ̀ Júù ń fẹ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ òkeere tí kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà, Nehemáyà rán wọn létí àpẹẹrẹ búburú Sólómọ́nì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì “jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run rẹ̀ nífẹ̀ẹ́, . . . Àní òun ni àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè mú dẹ́ṣẹ̀.” (Neh. 13:23-26) Torí náà fún àǹfààní ara wa ni Jèhófà ṣe sọ fún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ pé onígbàgbọ́ bíi tiwa nìkan ni ká fẹ́. (Sm. 19:7-10; Aísá. 48:17, 18) Àwa Kristẹni tòótọ́ mọrírì bí Ọlọ́run ṣe ń fìfẹ́ tọ́jú wa, a sì gbára lé ìdarí rẹ̀. Ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ara wa sábẹ́ àkóso rẹ̀, a sì gbà pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.—Òwe 1:5.

Ó dájú pé o kò ní fẹ́ fi “àìdọ́gba so pọ̀” pẹ̀lú ẹni tó máa fà ẹ́ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 6:14) Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà tó jẹ́ pé kò sígbà tí kò wúlò, wọ́n sì ti rí i pé ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu làwọn ṣe. Àmọ́, àwọn míì ti ṣe ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu.

Ó ṢÌ BỌ́GBỌ́N MU

Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Maggy * ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ aláìgbàgbọ́, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo pa ìpàdé jẹ torí kí n lè wà pẹ̀lú rẹ̀. Èyí mú kí ipò tẹ̀mí mi jó rẹ̀yìn gan-an.” Lórílẹ̀-èdè Íńdíà, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ratana ń fẹ́ ọmọ kíláàsì rẹ̀ kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, nígbà tó yá, ó wá hàn pé torí kó lè fẹ́ ẹ ló ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ Ratana kúrò nínú òtítọ́, ó sì lọ ń ṣe ẹ̀sìn mìíràn torí pé ó fẹ́ lọ́kọ.

Àpẹẹrẹ míì ni ti ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ndenguè lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni nígbà tó ṣègbéyàwó. Àfẹ́sọ́nà rẹ̀ sọ fún un pé òun ò dí i lọ́wọ́ kó má ṣe ẹ̀sìn tó ń ṣe. Àmọ́, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì péré tí wọ́n ṣègbéyàwó, ọkọ rẹ̀ sọ pé kò gbọ́dọ̀ lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni mọ́. Ó sọ pé: “Mo wá dẹni tí kò ní alábàárò, mo sì máa ń sunkún. Ọ̀rọ̀ ayé mi wá sú mi pátápátá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń kábàámọ̀.”

Lóòótọ́ kì í ṣe gbogbo ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ni òǹrorò àti aláìgbatẹnirò. Ká tiẹ̀ wá sọ pé ìwọ ò ní irú àwọn ìṣòro yìí bó o ṣe fẹ́ aláìgbàgbọ́, ipa wo ni irú ìpinnu tó o ṣe yìí máa ní lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Baba rẹ ọ̀run? Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ bó o ṣe mọ̀ pé o kò fetí sí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó fún ẹ fún àǹfààní ara rẹ? Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, báwo ni ìpinnu tó o ṣe yìí ṣe máa rí lára Baba rẹ ọ̀run?— Òwe 1:33.

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kárí ayé lè jẹ́rìí sí i pé kéèyàn ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa” ló bọ́gbọ́n mu jù lọ. Àwọn tí kò tíì lọ́kọ tàbí láya ti pinnu láti mú inú Ọlọ́run dùn bí wọ́n ṣe múra tán láti yan ẹni tí wọ́n máa fẹ́ láàárín àwọn olùjọ́sìn Jèhófà. Lórílẹ̀-èdè Japan, àwọn mọ̀lẹ́bí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Michiko gbìyànjú láti yí i lérò pa dà kó lè fẹ́ aláìgbàgbọ́. Yàtọ̀ sí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó ń fúngun mọ́ ọn, ó tún ń rí i pé àwọn ọ̀rẹ́ òun àtàwọn míì ń rẹ́ni fẹ́ nínú ìjọ. Ó wá sọ pé: “Mo máa ń sọ fún ara mi pé ‘Ọlọ́run aláyọ̀’ ni Jèhófà, bí èèyàn ṣègbéyàwó tàbí kò ṣe, ìyẹn kọ́ ló máa pinnu bóyá èèyàn máa láyọ̀ àbí kò ní láyọ̀. Mo tún gbà pé Jèhófà máa ń ṣe ohun tá a bá fẹ́ fún wa. Torí náà, tá ò bá tíì rẹ́ni fẹ́, tó sì wù wá pé ká ṣègbéyàwó, ohun tó dáa jù ni pé ká túbọ̀ ṣe sùúrù títí tá a fi máa rí onígbàgbọ́ bíi tiwa fẹ́.” (1 Tím. 1:11) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Arábìnrin Michiko rí arákùnrin dáadáa kan fẹ́, inú rẹ̀ sì dùn pé ó ṣe sùúrù.

Bákan náà, ńṣe làwọn arákùnrin kan ṣe sùúrù títí wọ́n fi rí onígbàgbọ́ bíi tiwọn fẹ́. Arákùnrin Bill láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn arákùnrin yìí. Ó sọ pé nígbà míì, ọkàn òun máa ń fà sí àwọn obìnrin tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, ó sapá gan-an kí ọ̀rọ̀ òun àtàwọn obìnrin náà má ṣe wọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Kí nìdí? Kò fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ tó máa yọrí sí fífi “àìdọ́gba so pọ̀” pẹ̀lú aláìgbàgbọ́. Fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ló ti máa ń kọnu ìfẹ́ sí àwọn arábìnrin mélòó kan nínú ìjọ, àmọ́ ọ̀rọ̀ wọn ò wọ̀. Ọgbọ̀n ọdún ni Arákùnrin Bill fi dúró kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí arábìnrin kan tọ́rọ̀ wọn jọ wọ̀. Ó sọ pé: “Mi ò kábàámọ̀ rárá. Jèhófà ti bù kún mi, torí pé èmi àti ìyàwó mi jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ a sì jọ ń sin Jèhófà. Inú mi dùn láti mọ àwọn ọ̀rẹ́ ìyàwó mi, torí pé olùjọ́sìn Jèhófà làwọn náà. Ìlànà Bíbélì ni èmi àti ìyàwó mi ń tẹ̀ lé, èyí ló mú kí ìgbéyàwó wa tòrò.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE BÓ O ṢE Ń WOJÚ JÈHÓFÀ

Ní báyìí, kí lo lè máa ṣe bó o ṣe ń dúró dé Jèhófà? Lákọ̀ọ́kọ́, ronú lórí ìdí tí o kò fi tíì ṣègbéyàwó. Tó bá jẹ́ torí pé o fẹ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni Bíbélì pé ká ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa” ni, a gbóríyìn fún ẹ pé o ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run yẹn. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà dùn sí ìpinnu tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó o ṣe láti ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (1 Sám. 15:22; Òwe 27:11) Máa ‘tú ọkàn rẹ jáde’ sí Ọlọ́run nínú àdúrà. (Sm. 62:8) Tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, tó o sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé àdúrà rẹ á túbọ̀ nítumọ̀. Àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà á máa lágbára sí i lójoojúmọ́, bó o ṣe pinnu láti pa ìṣòtítọ́ rẹ mọ́ láìka bọ́rọ̀ náà ṣe lè rí lára rẹ àti báwọn míì ṣe ń fúngun mọ́ ẹ tó. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ẹni Gíga Jù Lọ ka ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sí pàtàkì, wọ́n sì ṣeyebíye lójú rẹ̀. Ó mọ àwọn àìní rẹ àti ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ò ṣèlérí fún ẹnikẹ́ni pé òun máa fún un ní ọkọ tàbí ìyàwó. Síbẹ̀ tó o bá fẹ́ ní ọkọ tàbí ìyàwó, Ọlọ́run mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ tó máa gbà ṣe ohun tó wù ẹ́ fún ẹ.—Sm. 145:16; Mát. 6:32.

Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti onísáàmù náà Dáfídì, tó sọ pé: “Ṣe wéré, dá mi lóhùn, Jèhófà. Ẹ̀mí mi ti wá sí òpin. Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi.” (Sm. 143: 5-7, 10) Ní àwọn ìgbà tí o bá ti ní irú èrò yìí, ńṣe ni kó o ní sùúrù, kí Baba rẹ ọ̀run lè jẹ́ kó o mọ ohun tó fẹ́ kó o ṣe. O lè mọ ohun tó fẹ́ kó o ṣe tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó o sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tí ò ń kà. Wàá mọ àwọn òfin Jèhófà, wàá sì rí bó ṣe ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ látẹ̀yìnwá. Tó o bá ń fetí sí Jèhófà, ọkàn rẹ á túbọ̀ balẹ̀ pé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa ṣègbọràn sí Jèhófà.

Àwọn tí kò tíì lọ́kọ tàbí láya ṣeyebíye gan-an nínú ìjọ, wọ́n sábà máa ń ran àwọn ìdílé àti àwọn ọmọdé lọ́wọ́

Kí tún ni ohun míì tó máa mú kí àkókò tó o fi wà láìlọ́kọ tàbí láya fún ẹ láyọ̀ kó sì ṣàǹfààní? Lákòókò tó o fi wà láìlọ́kọ tàbí aya, o lè sapá láti mú kí òye rẹ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pọ̀ sí i, o lè túbọ̀ jẹ́ ọ̀làwọ́, òṣìṣẹ́ kára, ẹni tó ṣeé sún mọ́, ẹni tó ń fọkàn sin Ọlọ́run, kó o sì ní orúkọ rere. Àwọn ànímọ́ yìí ṣe pàtàkì gan-an kí ayọ̀ lè wà nínú ìdílé. (Jẹ́n. 24:16-21; Rúùtù 1:16, 17; 2:6, 7, 11; Òwe 31:10-27) Máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ nípa kíkópa kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn ìgbòkègbodò Kristẹni tó kù, ààbò ló máa jẹ́ fún ẹ. Nígbà tí Arákùnrin Bill tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọdún tó fi wà láìláya, ó ní: “Ńṣe ni àwọn ọjọ́ náà yára kọjá! Ẹnú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni mo ti lo gbogbo àkókò yẹn.”

Ó ṣe kedere pé ó ṣì bọ́gbọ́n mu ká gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” Tó o bá tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, wàá tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún Jèhófà wàá sì ní ayọ̀ tó wà pẹ́ títí. Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ní inú dídùn gidigidi sí àwọn àṣẹ rẹ̀. Àwọn ohun tí ó níye lórí àti ọrọ̀ wà nínú ilé rẹ̀, òdodo rẹ̀ sì dúró títí láé.” (Sm. 112:1, 3) Torí náà, pinnu pé wàá pa àṣẹ tí Ọlọ́run fún wa mọ́, pé ká gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.”

^ ìpínrọ̀ 7 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn arábìnrin la máa darí ọ̀rọ̀ sí, àmọ́ àwọn ìlànà yìí kan àwọn arákùnrin pẹ̀lú.

^ ìpínrọ̀ 13 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.