Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÀNÍYÀN

Àníyàn Nípa Ìdílé

Àníyàn Nípa Ìdílé

Janet sọ pé: “Kò pẹ́ tí Bàbá mi kú ni ọkọ mi sọ fún mi pé òun ti ní ẹlòmíì tí òun ń fẹ́. Ọ̀sán kan òru kan ló kó ẹrù rẹ̀, tó sì fi èmi àti ọmọ méjì sílẹ̀ láì dágbére fún wa tẹ́lẹ̀.” Janet ríṣẹ́, àmọ́ owó tó ń gbà kò tó san owó ilé wọn. Ọ̀rọ̀ ìṣúnná owó nìkan kọ́ ni ìṣòro tó ní. Janet sọ pé: “Ti pé èmi nìkan ni gbogbo bùkátà náà já lé léjìká máa ń kó ìpayà bá mi. Ó sì ń dùn mí pé mi ò lè pèsè gbogbo ohun táwọn ọmọ mi nílò bí àwọn òbí míì ti ń ṣe. Kódà, mo máa ń ronú nípa ojú tí àwọn èèyàn fi ń wo èmi àtàwọn ọmọ mi. Bóyá wọ́n tiẹ̀ ń wò mí bíi pé mi ò ṣe ohun tó yẹ kí n ṣe ló jẹ́ kí ìgbéyàwó mi forí ṣánpọ́n.”

Janet

Àdúrà máa ń ran Janet lọ́wọ́ láti gbé àròdùn náà kúrò lọ́kàn, kó sì pọkàn pọ̀ sórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Janet sọ pé: “Tó bá ti di alẹ́, tí gbogbo nǹkan sì pa rọ́rọ́, ńṣe ni ìrònú yìí á tún gbà mí lọ́kàn. Àmọ́, tí mo bá gbàdúrà tí mo sì ka Bíbélì, mo máa ń rí oorun sùn. Ọ̀kan nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ràn mí lọ́wọ́ ni Fílípì 4:6, 7, tó sọ pé: ‘Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.’ Tí mo bá ti gbàdúrà lóru, ńṣe ni Jèhófà máa ń fi àlàáfíà rẹ̀ jíǹkí mi, èyí sì máa ń tù mí nínú.”

Nígbà tí Jésù ń wàásù lórí òkè, ó sọ̀rọ̀ nípa àdúrà. Ohun tó sọ sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí a bá ń ṣàníyàn, ó ní: “Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.” (Mátíù 6:8) Lóòótọ́, ó yẹ ká máa gbàdúrà torí pé àdúrà ló máa jẹ́ ká “sún mọ́ Ọlọ́run.” Tá a bá sì sún mọ́ Ọlọ́run, ‘òun náà máa sún mọ́ wa.’—Jákọ́bù 4:8.

Àǹfààní tí àdúrà ń ṣe wá kọjá kó kàn fi wá lọ́kàn balẹ̀ tá a bá ń ṣàníyàn. Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà,” tún máa wá nǹkan ṣe sí ìṣòro àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Sáàmù 65:2) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa “gbàdúrà nígbà gbogbo àti láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀.” (Lúùkù 18:1) A gbọ́dọ̀ máa bẹ Ọlọ́run pé kó tọ́ wa sọ́nà, kó sì ràn wá lọ́wọ́, ká sì gbà pé ó máa dáhùn àdúrà wa torí ìgbàgbọ́ tá a ní. A kò gbọ́dọ̀ ṣiyèméjì nípa bóyá ó máa dáhùn tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń “gbàdúrà láìdabọ̀,” èyí á fi hàn pé ìgbàgbọ́ wa jinlẹ̀ lóòótọ́.—1 Tẹsalóníkà 5:17.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI NÍ ÌGBÀGBỌ́

Àmọ́, kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́? Kéèyàn ní ìgbàgbọ́ gba pé kẹ́ni náà mọ Ọlọ́run dáadáa. (Jòhánù 17:3) Tá a bá fẹ́ mọ Ọlọ́run, ohun àkọ́kọ́ ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nínú Bíbélì. A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ń rí wa, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ ju pé ká kàn mọ nǹkan kan nípa Ọlọ́run, ó tún gba pé ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Èèyàn ò lè ní irú àjọṣe yìí lọ́sàn kan òru kan. Torí náà, bá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run, tá à ń “ṣe ohun tí ó wù ú,” tá a sì ń ronú nípa àwọn oore tó ń ṣe fún wa, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa “yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i gidigidi.” (Jòhánù 8:29; 2 Kọ́ríńtì 10:15) Irú ìgbàgbọ́ yìí ló ran Janet lọ́wọ́ láti kojú àwọn àníyàn rẹ̀.

Janet sọ pé: “Bí mo ṣe ń rọ́wọ́ Ọlọ́run nínú gbogbo nǹkan tí mò ń dáwọ́ lé ti mú kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń wà nínú ipò tó jọ pé kò sọ́nà àbáyọ. Àmọ́ pẹ̀lú àdúrà, ńṣe ni Jèhófà máa ń kó wa yọ nínú àwọn ipò yẹn lọ́nà tí mi ò tiẹ̀ lérò rárá. Tí mo bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, mo máa ń rántí gbogbo oore tó ti ṣe fún mi. Kò sígbà kan tá a nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tí kò ṣe é fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó fún mi láwọn ọ̀rẹ́ gidi lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ Kristẹni. Wọ́n ti dúró tì mí gbágbáágbá nígbà ìṣòro, wọ́n sì tún jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fún àwọn ọmọ mi.” *

Janet ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mo mọ ìdí tí Jèhófà fi sọ pé ‘òun kórìíra ìkọ̀sílẹ̀’ nínú Málákì 2:16. Òun ni ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó máa ń duni jù lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá tí ọkọ mi ti fi mí sílẹ̀, síbẹ̀ ẹ̀dùn ọkàn yẹn ò tíì tán lára mi. Tí ìrònú yìí bá ti sọ sí mi lọ́kàn, mo máa ń gbìyànjú láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, èyí sì máa ń jẹ́ kára tu èmi náà.” Janet tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kéèyàn má ṣe ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, èyí ti mú kí àníyàn rẹ̀ dínkù. *Òwe 18:1.

Ọlọ́run ni “baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti onídàájọ́ fún àwọn opó.”—Sáàmù 68:5

Janet sọ pé: “Ohun tó ń tù mí nínú jù ni mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Ọlọ́run ni ‘Baba àwọn ọmọ aláìníbaba àti onídàájọ́ fún àwọn opó.’ Kò sì ní pa wá tì láé bí ọkọ mi ṣe pa wá tì.” (Sáàmù 68:5) Janet mọ̀ pé Ọlọ́run kì í fi “ibi” tàbí nǹkan burúkú dán wa wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ìwà ọ̀làwọ́” Ọlọ́run pọ̀ gan-an débi pé ó máa ń fún gbogbo àwọn èèyàn ní ọgbọ́n àti “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ká lè fi kojú àwọn àníyàn wa.—Jákọ́bù 1:5, 13; 2 Kọ́ríńtì 4:7.

Àmọ́ tá a bá ń ṣàníyàn torí pé ẹ̀mí wa wà nínú ewu ńkọ́?

^ ìpínrọ̀ 10 Fún ìsọfúnni síwájú sí nípa béèyàn ṣe lè borí àníyàn, wo kókó iwájú ìwé nínú Jí! September–October 2015, “Ǹjẹ́ O Lè Pinnu Bí Ìgbésí Ayé Rẹ Ṣe Máa Rí?” Ó tún wà lórí ìkànnì www.pr418.com/yo.